ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g25 No. 1 ojú ìwé 14-15
  • Gbà Pé Nǹkan Ṣì Máa Dáa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbà Pé Nǹkan Ṣì Máa Dáa
  • Jí!—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
  • OHUN TÓ O LÈ ṢE
  • KÍ NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN, ÀWỌN NǸKAN WO LÓ SÌ MÁA ṢE?
  • Kí Ló Lè Fún Mi Ní Ìrètí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
  • Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Jí!—2025
g25 No. 1 ojú ìwé 14-15
Ìdílé kan wà níbi tí wọn ti ń gbafẹ́, wọ́n ń wo ilẹ̀ tó tẹ́jú tó wà lọ́ọ̀ọ́kán.

NǸKAN Ń GBÓWÓ LÓRÍ! ỌGBỌ́N WO LO LÈ DÁ SÍ I?

Gbà Pé Nǹkan Ṣì Máa Dáa

Ṣé bí nǹkan ṣe ń gbówó lórí, tí owó tó ń wọlé fún ẹ ò sì pọ̀ sí i ń mú kí nǹkan nira fún ẹ? Ṣó o máa ń kọ́kàn sókè nípa bó o ṣe máa gbọ́ bùkátà ara ẹ àti ti ìdílé ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè máa wò ó pé tí nǹkan bá nira lásìkò tá a wà yìí, báwo ló ṣe máa wá rí lọ́dún bíi mélòó kan sí i? Tó o bá gbà pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa, ọkàn ẹ á balẹ̀ bí nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Ẹni tó bá gbà pé nǹkan ṣì máa dáa ò kàn ní káwọ́ gbera, kó wá máa retí pé nǹkan á ṣàdédé yí pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, á máa ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe kí nǹkan lè dáa. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí fi hàn pé tẹ́nì kan bá gbà pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa . . .

  • á rọrùn fún un láti fara da ìṣòro

  • á rọrùn fún un láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ tí ìṣòro bá dé

  • á máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí ìgbé ayé ẹ̀ àti ìlera ẹ̀ túbọ̀ dáa

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Àkọ́kọ́, ṣàyẹ̀wò bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn ló wà nínú Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fara dà á bí nǹkan ṣe ń gbówó lórí. Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn yìí, kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sọ́nà àbáyọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹ á balẹ̀ ní báyìí, wàá sì mọ ohun tó o máa ṣe tí ìṣòro bá tún dé lọ́jọ́ iwájú.

“Làákàyè yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò sì máa dáàbò bò ọ́.”—Òwe 2:11.


Ìkejì, ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Tó o bá rí báwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì ṣe wúlò tó, á wù ẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la. Bí àpẹẹrẹ, wàá rí i pé Ọlọ́run fẹ́ kí ‘ọjọ́ ọ̀la ẹ dáa, ó sì ti fún ẹ ní ìrètí àgbàyanu!’ Wàá tún rí ẹ̀rí tó dájú pé Ọlọ́run máa mú ohun tó ní lọ́kàn yìí ṣẹ. (Jeremáyà 29:11) Ìjọba Ọlọ́run ni ẹ̀rí tó dájú yìí.

KÍ NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN, ÀWỌN NǸKAN WO LÓ SÌ MÁA ṢE?

Ìjọba Ọlọ́run ni ìjọba tó máa gba àkóso gbogbo ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Ìjọba yìí máa ṣàkóso látọ̀run, á fòpin sí ìṣẹ́ àti òṣì, á mú kí àlàáfíà jọba kárí ayé, àwa èèyàn ò ní máa jìyà mọ́, àá sì ní ànító àti àníṣẹ́kù. Ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀.

“Wàá láyọ̀, wàá sì láásìkí.”—Sáàmù 128:2.

A “ò ní ṣiṣẹ́ kára lásán.”—Àìsáyà 65:23.

“Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀.”—Sáàmù 72:16.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń retí ìgbà táwọn ìlérí yìí máa ṣẹ, torí ó dá wọn lójú pé Ọlọ́run ‘ò lè parọ́.’ (Títù 1:2) Oò ṣe gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó lè dá ìwọ náà lójú pé àwọn ìlérí yìí máa ṣẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè máa fara dà á bí nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn, á sì dá ẹ lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

Ramaz.

“Àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì ti jẹ́ kí n gbà pé àwọn ìṣòro tó wà láyé ò ní pẹ́ dópin. Bí mo ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan yìí, ó máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀ bí nǹkan tiẹ̀ ń burú sí i.”—Ramaz, Georgia.

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I

Ṣé àwọn nǹkan rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú máa ṣẹ lóòótọ́? Wo àwọn fídíò yìí lórí jw.org kó o lè mọ ìdáhùn: Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? àti Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Obìnrin kan ń mú Bíbélì níbi tí wọ́n ń kó ìwé sí.
    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́