Ara Èèpo Iwájú Ìwé
Òǹkàwé Wa Ọ̀wọ́n:
Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Máa yọ̀, ọ̀dọ́kùnrin [tàbí ọ̀dọ́bìnrin], ní ìgbà èwe rẹ, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ọ́ ní ire ní àwọn ọjọ́ ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ, kí o sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà ọkàn-àyà rẹ àti nínú àwọn ohun tí ojú rẹ bá rí.” (Oníwàásù 11:9) Ìgbà èwe máa ń dùn ó sì máa ń lárinrin, a sì fẹ́ kó o gbádùn ara ẹ. Àmọ́, a fẹ́ kó jẹ́ lọ́nà tó máa múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn. Má gbàgbé pé kedere ni Ọlọ́run ń rí gbogbo ohun tó o bá ń ṣe, ìyẹn ló sì máa fi dá ẹ lẹ́jọ́. O lè wá rí i nígbà náà pé, ó bọ́gbọ́n mu kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Sólómọ́nì fúnni síwájú sí i pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.”—Oníwàásù 12:1.
Àdúrà wa ni pé kí ohun tó o máa kà nínú ìwé yìí ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa juwọ́ sílẹ̀ nítorí àwọn ìṣòro àti ìdẹwò táwọn ọ̀dọ́ òde òní ń dojú kọ, kó sì tún jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè máa mú inú Jèhófà dùn.—Òwe 27:11.
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà