ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yp2 ojú ìwé 6-10
  • Ibo Ni Mo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Dáa Jù Lọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Ni Mo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Dáa Jù Lọ?
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
yp2 ojú ìwé 6-10

Ọ̀RỌ̀ ÌṢÁÁJÚ

Ibo Ni Mo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Dáa Jù Lọ?

Fáwọn Obìnrin

Ọmọkùnrin kan tó rẹwà ṣẹ̀ṣẹ̀ dé síléèwé yín ni, ọkàn ẹ ò sì kúrò lára ẹ̀. O lè máa sọ fúnra ẹ pé, ‘Kò tiẹ̀ wo ọ̀dọ̀ mi rí, torí náà, kí ló burú nínú kí n máa fọ̀rọ̀ ẹ̀ dánú ara mi dùn?’ Ó ṣe tán, kì í ṣe ìwọ nìkan. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gba tiẹ̀. Ohun tó sì mú kó o mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé o máa ń gbọ́ táwọn ọmọbìnrin míì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ṣáá.

Àfi bójú ìwọ àti ẹ̀ ṣe ṣe mẹ́rin. Kó o tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́rìn-ín sí ẹ. Nìwọ náà bá rẹ́rìn-ín músẹ́. Bó ṣe wá bá ẹ nìyẹn.

Ó fìtìjú sọ pé: “Báwo ni.”

Ìwọ náà fèsì pé: “Mo wà pa.”

“Brett lorúkọ mi.”

Kò tíì sọ tẹnu ẹ̀ tán tó o fi bi í pé: “O ṣẹ̀ṣẹ̀ déléèwé wa ni ṣá?”

Ló bá dáhùn pé: “Kò tíì pẹ́ náà tá a kó dé àdúgbò yìí.”

Ó wá ń ṣe ẹ́ bí àlá pé, ‘àbémi náà kọ́ ni Brett ń bá sọ̀rọ̀ yìí!’

Brett ń sọ̀rọ̀ lọ ní tiẹ̀, ó ní: “Mo mà fẹ́ dá-a-á-lẹ̀ nílé wa nírọ̀lẹ́ òní. Ṣé wàá wá?”

Ló bá sún mọ́ ẹ bíi pé ó fẹ́ sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ sí ẹ létí.

Ó ní: “Jẹ́ n sọ fún ẹ, àwọn òbí mi ò ní sí nílé, wọn ò dẹ̀ ní tilẹ̀kùn ibi tí wọ́n máa ń kọ́tí sí. Ṣé kí n máa retí ẹ?”

Brett dúró, ó fẹ́ gbọ́ ohun tó o máa sọ. Ká láwọn ọmọ tẹ́ ẹ jọ wà níléèwé ni, ọwọ́ kan ni wọ́n máa gbà fún un!

Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí lo máa sọ?

Fáwọn Ọkùnrin

Méjì lára àwọn ọmọ iléèwé yín ń bọ̀ wá bá ẹ. Àyà ẹ já, torí pé ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti fi sìgá lọ̀ ẹ́ lọ́sẹ̀ yìí. Ẹlẹ́ẹ̀kẹta rèé.

Èyí àkọ́kọ́ lára àwọn ọmọkùnrin náà sọ fún ẹ pé: “Ìwọ nìkan lo tún wà níbí ni? Jẹ́ n fi ọ̀rẹ́ mi kan hàn ẹ́.” Bó ṣe sọ pé “ọ̀rẹ́” bẹ́ẹ̀ ló rọra dẹ́ńgẹ̀, tó kọwọ́ bàpò tó sì na ohun tá à ń wí yìí sí ẹ.

Lo bá rí kiní kan lọ́wọ́ ẹ̀ tó jọ sìgá. O mọ̀ pé ohun tó jẹ́ gan-an nìyẹn, làyà ẹ bá tún lù kì.

O wá sọ pé: “Ẹ máà bínú o, mo rò pé mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀ pé mi kì í mu . . . ”

Kó o tó sọ ọ́ délẹ̀ báyìí lèyí èkejì bá dá a mọ ẹ́ lẹ́nu pé: “Ìjọ yín yẹn ló ń dà ẹ́ láàmú, àbí? Wọn kì í jẹ́ kẹ́ ẹ jayé orí yín!”

Èyí àkọ́kọ́ bá kàn ẹ́ lábùkù pé: “Àbí, sùẹ̀gbẹ̀ ni ẹ́ ni?”

Ìwọ náà ṣe bí ọkùnrin, lo bá dá a lóhùn pé: “Mi ò ń ṣe sùẹ̀gbẹ̀ o!”

Lọmọkùnrin kejì bá fọwọ́ kọ́ ẹ lọ́rùn, ó wá bá ẹ sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́, ó ní: “Ṣebí wàá tiẹ̀ ṣì gbà á ná.”

Lọmọkùnrin àkọ́kọ́ yẹn bá tún na kiní funfun náà sí ẹ, ó sì fohùn jẹ́jẹ́ sọ pé: “A ò ní sọ fẹ́nì kankan. Gbà bẹ́ẹ̀, kò sẹ́ni tó máa mọ̀.”

Kí lo máa ṣe?

OJOOJÚMỌ́ nirú nǹkan báyìí máa ń ṣẹlẹ̀ níbi gbogbo lágbàáyé. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ọ̀dọ́ kan mọ bí wọ́n ṣe lè bójú tó ọ̀ràn náà ju àwọn ọ̀dọ́ mìíràn lọ. Bí wọ́n bá fi ayé ni ọ̀dọ́ míì lára tán, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé: “Mi ò fẹ́ gbà fún wọn, àmọ́ wàhálà yìí ti sú mi o jàre. Kí ló dé témi náà ò tiẹ̀ jẹ́ káwọn ọmọléèwé mi mọ̀ pé mi ò kẹ̀rẹ̀? Ọmọbìnrin tí ọkùnrin sì fẹ́ gbé jáde lè máa ronú pé: ‘Ọmọkùnrin yìí sì wà pa o. Bó tiẹ̀ ṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré, kí ló dé tí mi ò lè gbà fún un?’

Ní tàwọn ọ̀dọ́ mìíràn, ọ̀pọ̀ lára wọn la ti kọ́ láti fìgboyà dúró lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Torí náà, ó lè ya ọ̀pọ̀ lẹ́nu pé irú ìyọlẹ́nu bẹ́ẹ̀ kì í sábàá tu irun kankan lára wọn. Ṣé irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ nìwọ náà á fẹ́ jẹ́? Ìròyìn ayọ̀ tó wà níbẹ̀ ni pé ìwọ náà lè jẹ́ irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀! Lọ́nà wo?

Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fìgboyà dojú kọ àwọn ìṣòro ìgbà èwe. Inú Bíbélì ni ìmọ̀ràn tó dára jù lọ wà, torí pé Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni. (2 Tímótì 3:16, 17) Irú àwọn ìṣòro wo ni Bíbélì lè bá ẹ wá ojútùú sí? Wo àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí, kó o sì fi àmì ✔ sí àwọn àkòrí tó bá wù ẹ́ jù lọ.

□ Bó ṣe yẹ kí n máa ṣe sí ẹní tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèmi

□ Bí mo ṣe lè lóye ìyípadà tó ń bá ara mi

□ Bí mo ṣe lè yan ọ̀rẹ́

□ Bí mo ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ wàhálà iléèwé

□ Bí mo ṣe lè máa ṣọ́ owó ná

□ Bí èmi àtàwọn òbí mi ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wa

□ Ohun tí mo lè ṣe sí bí nǹkan ṣe máa ń rí lára mi

□ Bí mo ṣe lè yan irú eré ìtura tí mo fẹ́

□ Bí mo ṣe lè mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i

Wàá kíyè sí i lójú ìwé 4 àti 5 nínú ìwé yìí pé àwọn kókó tá a tò sókè yìí ni apá mẹ́sàn-án tí ìwé yìí pín sí. Èwo lo fàmì sí? O lè fẹ́ láti kọ́kọ́ ka àwọn apá tó o fàmì sí yẹn. Àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fàwọn ohun tó wà nínú apá tó o yàn yẹn sílò nígbèésí ayé rẹ. Ìwé tó ò ń kà yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe.a

Ìwé yìí á tún fún ẹ láǹfààní tó pọ̀ láti sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lọ́kàn ẹ. Bí àpẹẹrẹ, lápá ìparí orí kọ̀ọ̀kan, wàá rí àpótí tó ní àkọlé náà, “Ohun Tí Màá Ṣe!” Ibẹ̀ ni wàá máa kọ bó o ṣe máa lo àwọn ohun tó o bá kà nínú ìwé yìí sí. Àwọn ojú ìwé míì tún wà tó o lè kọ nǹkan sí, irú bíi “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” ní ojú ìwé 132 àti 133, èyí tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ìṣòro tó ò ń bá pàdé, tá á sì jẹ́ kó o ronú kan ojútùú sáwọn ìṣòro náà. Ní àfikún sí i, ojú ìwé tó ní àkọlé náà, “Ohun Tí Mo Rò,” la fi parí apá kọ̀ọ̀kan, ibẹ̀ lo máa kọ báwọn àpilẹ̀kọ tó o kà ṣe kàn ẹ́ gbọ̀ngbọ̀n sí. Bó o ṣe ń ka ìwé náà lọ, wàá tún máa rí àwọn ojú ìwé tí gbogbo ẹ̀ jẹ́ mẹ́sàn-án tó ní àkọlé náà, “Àwòkọ́ṣe.” Láwọn ojú ìwé yìí la ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn kan nínú Bíbélì tó o lè fara wé.

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “ní ọgbọ́n” ká sì “ní òye.” (Òwe 4:5) Àwọn ọ̀rọ̀ náà, “ọgbọ́n” àti “òye” kọjá kéèyàn wulẹ̀ mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Èèyàn gbọ́dọ̀ mọ tinú tòde bí nǹkan ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ronú nípa ibi tí ìwà búburú máa já sí tó o sì ronú nípa èrè tó wà nínú kó o hùwà rere, ìyẹn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fìgboyà àti ìgbàgbọ́ fàyà rán ìṣòro tó bá tọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà ẹ wá.

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, bó ti wù kí ìṣòro rẹ pọ̀ tó, bó ṣe ń ṣe ẹ́ náà ló ń ṣe àwọn ẹlòmíì. A sì ti rí lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ti dojú kọ ìṣòro, síbẹ̀ tí wọ́n kẹ́sẹ járí. Ó dájú pé ìwọ náà lè kẹ́sẹ járí! Lo ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì dáadáa. Ó máa mú kó dá ẹ lójú pé inú Bíbélì lo ti lè rí ìmọ̀ràn tó dára jù lọ!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀pọ̀ lára ohun tó wà nínú ìwé yìí la mú látinú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá à ń pè ní “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé,” tó máa ń jáde déédéé nínú ìwé ìròyìn Jí! táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́