Ara Èèpo Iwájú Ìwé
Sí Ọ̀dọ́ Wa Ọ̀wọ́n,
Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ ọ̀run nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an. Ó fẹ́ kí inú rẹ máa dùn. Àmọ́ o lè máa wò ó pé, ‘Ṣé inú èèyàn tiẹ̀ lè dùn láyé tá a wà yìí?’ Ìbéèrè tó dáa ni ìbéèrè yìí, torí pé àwa èèyàn máa ń ní oríṣiríṣi ìṣòrò. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ làwọn ohun tó lè bani nínú jẹ́ máa ń ṣẹlẹ̀. Àmọ́ inú wa dùn gan-an pé Bàbá wa tó nífẹ̀ẹ́ wa máa ń ràn wá lọ́wọ́! Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe sáwọn ìṣòro tá a máa ń ní láyé wa. Òótọ́ ni pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì, síbẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣì wúlò lóde òní bíi ti ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ọ́.—Sáàmù 119:98, 99; 2 Tímótì 3:16, 17.
Torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an la ṣe ṣe ìwé yìí. A fẹ́ kí inú rẹ máa dùn, kí ayé rẹ sì dùn bí oyin. Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ka ìwé yìí láti páálí dé páálí, kó o sì tún máa yẹ̀ ẹ́ wò nígbàkigbà tó o bá níṣòro. Yàtọ̀ síyẹn, ara ìdí tá a fi ṣe ìwé yìí ni pé a fẹ́ kí ìwọ àtàwọn òbí rẹ túbọ̀ máa gbọ́ ara yín yé dáadáa. A nírètí pé wàá kà á tàbí pé kí ìwọ àtàwọn òbí rẹ tiẹ̀ jọ ka àwọn ibì kan nínú ìwé yìí pa pọ̀. A gbà ẹ́ níyànjú pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ dáadáa torí pé wọ́n gbọ́n, wọ́n sì tún ní ìrírí jù ẹ́ lọ.
Ire o,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà