Orin 141
À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà
- Jésù pàṣẹ pé: ‘Ẹ wàásù òótọ́.’ - Lójò lẹ́ẹ̀rùn, níbi gbogbo, - Ó ń sọ̀rọ̀ Jáà fáwọn èèyàn. - Jésù nífẹ̀ẹ́ àgùntàn Ọlọ́run. - Ó ń wá wọn lọ - ní òwúrọ̀ títí ’lẹ̀ fi ṣú. - Nílé délé, lópòópónà, - À ń wàásù fún gbogbo èèyàn - Pé láìpẹ́ gbogbo - ìṣòro yóò dópin. - (ÈGBÈ) - Kárí ayé - À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà, - Ó yẹ ká rí - Àwọn èèyàn tó fẹ́ rí’gbàlà, - Ká sì rí i pé - A sapá wa. 
- Àkókò ń lọ, ká tẹra mọ́ṣẹ́ yìí. - Ọ̀pọ̀ èèyàn, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí, - Là ń sapá láti gbà là. - Ìfẹ́ ló ń mú ká ṣáà máa wá wọn lọ. - À ń wo ọgbẹ́ ọkàn wọn sàn, - à ń táyé wọn ṣe. - Nílùú délùú, lópòópónà, - Tá a bá rẹ́ni tó gbọ́rọ̀ wa, - Ayọ̀ tó ń fún wa ń mú ká máa báṣẹ́ lọ. - (ÈGBÈ) - Kárí ayé - À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà, - Ó yẹ ká rí - Àwọn èèyàn tó fẹ́ rí’gbàlà, - Ká sì rí i pé - A sapá wa. 
(Tún wo Aísá. 52:7; Mát. 28:19, 20; Lúùkù 8:1; Róòmù 10:10.)