Orin 140
Ìgbé Ayé Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà
- Ní òwúrọ̀ kùtù, tí oòrùn kò tí ì yọ, - À ń jáde lọ wàásù - oorun wà lójú wa, - à ń bẹ Jáà. - À ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sáwọn èèyàn tá a pàdé. - Àwọn kan gbọ́rọ̀ wa, - àwọn mí ì kò fẹ́ gbọ́, kò sú wa. - (ÈGBÈ) - Iṣẹ́ tá a fẹ́ nìyẹn; - Ti Jèhófà la jẹ́. - Gbogbo ohun tó fẹ́ la ó máa ṣe. - Nípòkípò tá a wà, - A ó máa fara dà á lọ. - Èyí la fi lè sọ pé: - “A nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.” 
- Ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn bá ti ń wọ̀, - Pẹ̀lú bó ṣe rẹ̀ wá, - inú wa ń dùn, - a sì tún ń dúpẹ́. - À ń fayé wa sin Jáà, èyí sì ń dùn mọ́ wa. - À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, - Ojoojúmọ́ ló máa ń bù kún wa. - (ÈGBÈ) - Iṣẹ́ tá a fẹ́ nìyẹn; - Ti Jèhófà la jẹ́. - Gbogbo ohun tó fẹ́ la ó máa ṣe. - Nípòkípò tá a wà, - A ó máa fara dà á lọ. - Èyí la fi lè sọ pé: - “A nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.” 
(Tún wo Jóṣ. 24:15; Sm. 92:2; Róòmù 14:8.)