ORIN 21
Ẹ Máa Wá Ìjọba Ọlọ́run Lákọ̀ọ́kọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ohun kan tó ṣeyebíye, - Tó ń mú Jèhófà láyọ̀, - Ni Ìjọba Jésù Kristi - Tó máa mú ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ. - (ÈGBÈ) - Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà - Àtòdodo Jèhófà. - Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé, - Ká sì máa fòtítọ́ sìn ín. 
- 2. Má jẹ́ k’áníyàn rẹ pọ̀ jù; - ‘Kí la máa jẹ, kí la ó mu?’ - Jèhófà máa pèsè fún wa, - Ká fi tirẹ̀ sákọ̀ọ́kọ́. - (ÈGBÈ) - Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà - Àtòdodo Jèhófà. - Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé, - Ká sì máa fòtítọ́ sìn ín. 
- 3. Ká wàásù ìhìnrere náà. - Ká jẹ́ kí ẹni yíyẹ - Mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà - Nìkan ló ṣeé gbọ́kàn lé. - (ÈGBÈ) - Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà - Àtòdodo Jèhófà. - Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé, - Ká sì máa fòtítọ́ sìn ín. 
(Tún wo Sm. 27:14; Mát. 6:34; 10:11, 13; 1 Pét. 1:21.)