ORIN 27
Ọlọ́run Máa Ṣí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Payá
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jáà ti yan àwọn ọmọ rẹ̀. - Ó máa ṣí wọn payá. - Wọ́n máa jọba pẹ̀lú Kristi. - Ẹ̀dá ẹ̀mí ni wọ́n. - (ÈGBÈ) - Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá - Pẹ̀lú Jésù Kristi. - Wọ́n máa jagun, wọ́n máa ṣẹ́gun. - Jáà yóò san wọ́n lẹ́san. 
- 2. Láìpẹ́, àwọn tó bá ṣẹ́ kù - Máa gbọ́ ìpè ‘kẹyìn. - Olúwa àwọn olúwa - Yóò gbà wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀. - (ÈGBÈ) - Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá - Pẹ̀lú Jésù Kristi. - Wọ́n máa jagun, wọ́n máa ṣẹ́gun. - Jáà yóò san wọ́n lẹ́san. - (ÀSOPỌ̀) - Kristi àtàwọn ọmọ Jáà - Máa jagun ìkẹyìn. - ’Gbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn - Máa wà títí ayé. - (ÈGBÈ) - Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá - Pẹ̀lú Jésù Kristi. - Wọ́n máa jagun, wọ́n máa ṣẹ́gun. - Jáà yóò san wọ́n lẹ́san.