ORIN 72
À Ń Kéde Òtítọ́ Ìjọba Náà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ìgbà kan wà tí a kò mọ - Ọ̀nà tó yẹ kí a máa rìn. - Jèhófà tan ìmọ́lẹ̀ - Òótọ́ Ìjọba rẹ̀ fún wa. - A wá ríi pé Jèhófà fẹ́ - Ká kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀. - Ká kéde rẹ̀ fáráyé, - Ká sì tún gbórúkọ mímọ́ rẹ̀ ga. - À ńwàásù fún gbogbo èèyàn - Nílé délé, lójú ọ̀nà. - À ńkọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ òótọ́ - Tó ńsọni di òmìnira. - À ńsapá ní gbogbo ayé - Káwọn tó ńsin Jáà lè pọ̀ síi. - Ká máa ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan - Títí Jèhófà yóò sọ pé ó tó. 
(Tún wo Jóṣ. 9:9; Àìsá. 24:15; Jòh. 8:12, 32.)