ORIN 104
Ẹ̀bùn Ọlọ́run Ni Ẹ̀mí Mímọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Bàbá aláàánú ni ọ́, Jèhófà. - O nífẹ̀ẹ́ wa bá a tiẹ̀ jẹ́lẹ́ṣẹ̀. - Jọ̀ọ́ ràn wá lọ́wọ́, jẹ́ kára tù wá. - Fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ tù wá nínú. 
- 2. Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ń mú ká ṣàṣìṣe, - Ká sì pàdánù ojúure rẹ. - Bàbá, a bẹ̀ ọ́, gbọ́ àdúrà wa: - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ máa darí wa. 
- 3. Tá a bá sorí kọ́ tàbí tó rẹ̀ wá, - Bàbá, jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ - Fún wa lágbára bíi t’ẹyẹ idì; - Jẹ́ ká máa rí ẹ̀mí mímọ́ rẹ gbà. 
(Tún wo Sm. 51:11; Jòh. 14:26; Ìṣe 9:31.)