ORIN 105
“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Bàbá wa ọ̀run jẹ́ ìfẹ́, - Ó ní káwa náà nífẹ̀ẹ́. - Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wa, - Tá a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, - Ìgbé ayé wa á ládùn, - Ó sì máa jẹ́ ká níyè. - Jésù Kristi náà fìfẹ́ hàn; - Ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. 
- 2. Ìfẹ́ tòótọ́ máa ń ta wá jí; - Ó máa ń mú ká fìfẹ́ hàn. - Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run - Máa s’agbára wa dọ̀tun. - Ìfẹ́ máa ń ṣoore, kìí jowú; - Ìfẹ́ máa ń ní ‘faradà. - Ẹ jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa; - Ká gbádùn ìfẹ́ tòótọ́. 
- 3. Má di ẹnikẹ́ni sínú; - Má fàyè gba ìbínú. - Jèhófà ni kó o yíjú sí, - Àwọn òfin rẹ̀ dára. - Ẹ jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, - Yóò mú kífẹ̀ẹ́ wa jinlẹ̀. - Ká fara wé Ọlọ́run wa; - Ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn. 
(Tún wo Máàkù 12:30, 31; 1 Kọ́r. 12:31–13:8; 1 Jòh. 3:23.)