ORIN 119
Ó Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́
- 1. Ọlọ́run bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ - Nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀. - Lónìí, ó ń lo Ọmọ rẹ̀ láti sọ - Pé ká ronú pìwà dà. - (ÈGBÈ) - Ṣé a nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀? - Ohun tá à ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn. - Ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì; - Ìgbàgbọ́ wa yóò mú kí á níyè. 
- 2. À ń fi ayọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ Jésù - Pé ká wàásù ìhìn rere. - À ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ìrètí - Tí Ọlọ́run ṣèlérí. - ÈGBÈ) - Ṣé a nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀? - Ohun tá à ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn. - Ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì; - Ìgbàgbọ́ wa yóò mú kí á níyè. 
- 3. Ìdákọ̀ró ni ìgbàgbọ́ wa jẹ́, - Yóò jẹ́ ká lè nífaradà. - Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jáà, a ò ní bẹ̀rù; - Torí ìgbàlà dé tán. - ÈGBÈ) - Ṣé a nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀? - Ohun tá à ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn. - Ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì; - Ìgbàgbọ́ wa yóò mú kí á níyè. 
(Tún wo Róòmù 10:10; Éfé. 3:12; Héb. 11:6; 1 Jòh. 5:4.)