February
Wednesday, February 1
Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.—Ják. 4:8.
Ṣé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, tí o sì ti ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o ní ohun iyebíye kan, ìyẹn ni pé o ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́, ayé Sátánì ń gbógun ti àjọṣe àwa àti Ọlọ́run, ẹran ara wa aláìpé kò sì jẹ́ ká gbádùn. Gbogbo àwa Kristẹni là ń kojú ìṣòro yìí. Torí náà, àjọṣe àwa àti Jèhófà gbọ́dọ̀ lágbára gan-an. Ǹjẹ́ ó dá ẹ lójú pé o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà? Ṣé wàá fẹ́ kí àjọṣe yẹn dán mọ́rán sí i? Ẹsẹ ojúmọ́ tòní, ìyẹn Jákọ́bù 4:8, sọ bó o ṣe lè ṣe é. Kíyè sí i pé ọ̀nà méjì ni ìgbésẹ̀ yìí pín sí. Bá a ṣe ń sapá láti sún mọ́ Ọlọ́run, òun náà á máa sún mọ́ wa. Tá a bá wá ń tẹra mọ́ ọn, àjọṣe àwa àti Jèhófà á máa dán mọ́rán síwájú àti síwájú sí i. Èyí máa jẹ́ kó dá wa lójú pé a ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Àwa náà á lè ní irú ìdánilójú tí Jésù ní nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó rán mi jẹ́ ẹni gidi, . . . Èmi mọ̀ ọ́n.”—Jòh. 7:28, 29. w15 4/15 3:1, 2
Thursday, February 2
Ẹ máa ní ìfaradà lábẹ́ ìpọ́njú. Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà.—Róòmù 12:12.
Ká sọ pé wọ́n yọ mọ̀lẹ́bí rẹ kan lẹ́gbẹ́. Àwọn ohun tí o kọ́ nínú Bíbélì sì ti jẹ́ kó o mọ bó ṣe yẹ kó o ṣe sí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́. (1 Kọ́r. 5:11; 2 Jòh. 10) Síbẹ̀, ìpinnu tó bá Ìwé Mímọ́ mu náà lè nira fún ẹ, kódà o lè má fara mọ́ ọn. Ṣé wàá gbẹ́kẹ̀ lé Baba wa ọ̀run pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣègbọràn sí ìtọ́ni Bíbélì nípa àwọn tá a bá yọ lẹ́gbẹ́? Ǹjẹ́ o wá rí i pé àǹfààní nìyẹn jẹ́ fún ẹ láti mú kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà lágbára sí i, kó o sì túbọ̀ sún mọ́ ọn? Ǹjẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù fi hàn pé kò yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa tọkàntọkàn? Rárá o! Àmọ́, Jèhófà ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́ jù lọ. (Mát. 22:37, 38) Èyí ló máa ṣe àwọn mọ̀lẹ́bí wa láǹfààní jù lọ, bóyá wọ́n ń sin Jèhófà àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Tó bá sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ mọ̀lẹ́bí rẹ kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ṣì ń kó ìdààmú bá ẹ, sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún Jèhófà nínú àdúrà.—Fílí. 4:6, 7. w15 4/15 4:14, 16
Friday, February 3
Àwa fúnra wa ń fi yín yangàn láàárín àwọn ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín.—2 Tẹs. 1:4.
Kò burú tí inú wa bá ń dùn nítorí ohun táwọn míì ṣe tàbí kéèyàn fi ohun dáadáa téèyàn ṣe yangàn. Ojú kì í tì wá láti sọ fáwọn èèyàn nípa ìdílé tá a ti wá, àṣà ìbílẹ̀ wa tàbí ibi tá a dàgbà sí. (Ìṣe 21:39) Àmọ́, ìgbéraga burú, ó lè ba àárín àwa àtàwọn èèyàn jẹ́, ó sì lè já okùn ọ̀rẹ́ tó wà láàárín àwa àti Jèhófà. Ìgbéraga lè mú kéèyàn kọ etí dídi sí ìmọ̀ràn tàbí kéèyàn pa ìmọ̀ràn náà tì, dípò kéèyàn gbà á tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. (Sm. 141:5) Ìwé kan sọ pé ìgbéraga máa ń jẹ́ “kéèyàn jọ ara rẹ̀ lójú,” ó sì “jẹ́ ìwà tí àwọn tó gbà pé àwọn sàn ju àwọn èèyàn míì lọ máa ń hù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìdí tó fi hàn pé wọ́n sàn jù.” Jèhófà kórìíra ìgbéraga. (Ìsík. 33:28; Ámósì 6:8) Àmọ́, ó dájú pé inú Sátánì máa ń dùn nígbà táwọn èèyàn bá ń fọ́nnu, torí pé òun ni wọ́n fìwà ìgbéraga bẹ́ẹ̀ jọ. Ẹ wo bí inú Sátánì ṣe dùn tó nígbà táwọn èèyàn bíi Nímírọ́dù, Fáráò àti Ábúsálómù ń fọ́nnu, torí pé agbéraga ẹ̀dá ni wọ́n!—Jẹ́n. 10:8, 9; Ẹ́kís. 5:1, 2; 2 Sám. 15:4-6. w15 5/15 2:5, 6
Saturday, February 4
Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.—Sm. 145:16.
Torí pé ‘Kristi tó jẹ́ agbára Ọlọ́run’ fìwà jọ Baba rẹ̀, ìgbà gbogbo ló ń ṣí ọwọ́ rẹ̀, tó sì ń tẹ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́rùn. (1 Kọ́r. 1:24) Kò ṣe bẹ́ẹ̀ torí kó lè fi hàn pé òun ní agbára. Àmọ́, ìfẹ́ àtọkànwá tó ní sáwọn èèyàn ló mú kó ràn wọ́n lọ́wọ́. Wo Mátíù 14:14-21. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá bá a kí wọ́n lè sọ ìṣòro oúnjẹ tí wọ́n ní fún un. Yàtọ̀ sí pé ebi ti ń pa àwọn fúnra wọn, wọ́n tún ro ipò tí àwọn èrò tó ń tẹ̀ lé Jésù láti ìlú kan sí òmíràn wà. Á ti rẹ̀ wọ́n, ebi á sì ti máa pa wọ́n. (Mát. 14:13) Kí ni Jésù máa ṣe? Jésù fi ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ọkùnrin, títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé! Àwọn ogunlọ́gọ̀ náà “jẹ, wọ́n sì yó.” Èyí fi hàn pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ ló wà níbẹ̀. Jésù ò kàn fún àwọn èèyàn náà ní ìpápánu búrẹ́dì mélòó kan lásán, àmọ́ wọ́n jẹ ẹ́ ní àjẹyó débi pé wọ́n lókun láti rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn pa dà sí ilé wọn. (Lúùkù 9:10-17) Kódà, àṣẹ́kù tí wọ́n kó jọ kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá! w15 6/15 1:8, 9
Sunday, February 5
A gbé ìwà búburú jáì ga láàárín àwọn ọmọ ènìyàn.—Sm. 12:8.
Ní báyìí tí ìṣekúṣe ti wá di ohun tó gbòde kan, a lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí èèyàn jẹ́ oníwà mímọ́ nínú ayé yìí?’ Ó dájú torí pé Jèhófà á ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́, tí a bá fẹ́ jẹ́ oníwà mímọ́, a gbọ́dọ̀ kọ ìfẹ́ ìṣekúṣe sílẹ̀ lákọ̀tán. Bí ìdẹ tó wà lẹ́nu ìwọ̀ ṣe máa ń fa ẹja mọ́ra, bẹ́ẹ̀ náà ni èròkerò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ṣe lè fa Kristẹni kan lọ, tí kò bá tètè gbé e kúrò lọ́kàn. Wọ́n lè ṣàkóbá fún ara àìpé wa, kí wọ́n sì sún wa ṣèṣekúṣe. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, adùn tẹ́nì kán rò pé ó wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ lè kó sí i lórí débi pé kò ní lè kápá irú èròkerò bẹ́ẹ̀ mọ́. Ní irú àkókò yìí, kódà ìránṣẹ́ Jèhófà kan lè ṣe ohun tó ń rò lọ́kàn tí àyè bá ṣí sílẹ̀. Kò sí àní-àní pé “ìfẹ́-ọkàn náà . . . a bí ẹ̀ṣẹ̀.” (Ják. 1:14, 15) Ó yẹ ká ronú jinlẹ̀ lórí bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó wà fún ìgbà díẹ̀ ṣe lè di ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Àmọ́, ó tù wá nínú láti mọ̀ pé tí a kò bá jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jọba lọ́kàn wa, a kò ní lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe ká sì jìyà àwọn àbájáde rẹ̀!—Gál. 5:16. w15 6/15 3:1-3
Monday, February 6
Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ . . . lórí ilẹ̀ ayé.—Mát. 6:10.
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ lórí ilẹ̀ ayé. Abájọ tí Jèhófà fi wo àwọn ohun rere tó ṣe fún àwọn ẹ̀dá èèyàn tó wá sọ pé: “Ó dára gan-an ni.” (Jẹ́n. 1:31) Nígbà tó yá, Sátánì di ọlọ̀tẹ̀, látìgbà yẹn sì rèé, ìwọ̀nba èèyàn kéréje ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ lóde òní, àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń gbé lásìkò tí iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ. Gbogbo wọn ń gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì tún ń sapá láti gbé ìgbé ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà náà. Wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó mú inú Ọlọ́run dùn, wọ́n sì ń kópa kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù. Títí dìgbà tí Ọlọ́run yóò fi pa àwọn ọ̀tá Ìjọba náà run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, a óò máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, a óò rí bí ìfẹ́ Ọlọ́run yóò ṣe nímùúṣẹ lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́ nígbà tí bílíọ̀nù àwọn òkú bá jí dìde. (Jòh. 5:28, 29) Ẹ ò rí i pé àsìkò aláyọ̀ ló máa jẹ́ fún wa nígbà tá a bá ń kí àwọn èèyàn wa tó ti kú káàbọ̀! w15 6/15 4:15, 17
Tuesday, February 7
Èmi yóò sì ṣe àyè ẹsẹ̀ mi gan-an lógo.—Aísá. 60:13.
Gbólóhùn náà, “Párádísè tẹ̀mí” ti di ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa ń lò nínú ètò Ọlọ́run. Ó túmọ̀ sí àyíká tàbí ipò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó kún fún ọ̀pọ̀ nǹkan tẹ̀mí, tó sì ń fúnni láǹfààní láti gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run àti pẹ̀lú àwọn ará wa. Àmọ́, a ò wá lè torí ìyẹn sọ pé kò sí ìyàtọ̀ láàárín “Párádísè tẹ̀mí” àti “tẹ́ńpìlì tẹ̀mí” o! Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ni ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìjọsìn tòótọ́. Ṣùgbọ́n, Párádísè tẹ̀mí ló ń jẹ́ ká mọ àwọn tó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run tí wọ́n sì ń sìn ín nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ lónìí. (Mál. 3:18) Ẹ wo bó ti múni lọ́kàn yọ̀ tó pé láti ọdún 1919, Jèhófà ti jẹ́ kí àwọn èèyàn aláìpé máa bá òun ṣiṣẹ́ láti mú àwọn èèyàn wá sínú Párádísè tẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé, kí wọ́n máa sọ ọ́ dọ̀tun, kí wọ́n sì mú kó máa gbòòrò sí i! Ṣé ìwọ náà ń ṣe ipa tìrẹ nínú iṣẹ́ àgbàyanu yìí? Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ láti máa bá Jèhófà ṣiṣẹ́ kó o lè máa ṣe ‘àyè ẹsẹ̀ rẹ̀’ lógo? w15 7/15 1:10, 11
Wednesday, February 8
Mo [máa] sọ ara mi di mímọ́ nínú rẹ níwájú wọn, ìwọ Gọ́ọ̀gù.—Ìsík. 38:16.
Ṣáájú kí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó lọ sí ọ̀run, Gọ́ọ̀gù máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ó máa dà bíi pé àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé kò ní olùgbèjà. Wọ́n máa ṣègbọràn sí ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn nígbà ayé Ọba Jèhóṣáfátì, pé: “Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà nínú ọ̀ràn yìí. Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín. Ìwọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà.” (2 Kíró. 20:17) Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́run? Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí gbogbo àwọn ẹni àmì òróró á ti wà ní ọ̀run, Ìṣípayá 17:14 sọ nípa ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run pé: “Àwọn wọ̀nyí yóò bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun, ṣùgbọ́n, nítorí pé òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣe bẹ́ẹ̀.” Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n máa bá a ṣàkóso ní ọ̀run máa wá láti gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé. w15 7/15 2:16
Thursday, February 9
Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.—Oníw. 3:1.
Ọ̀wọ̀ tí a ní fún Ọlọ́run tó ní ká máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ gbọ́dọ̀ fara hàn nínú ìwà wa, aṣọ wa àti ọ̀nà tá à ń gbà múra. Ọ̀wọ̀ fún ibi ìjọsìn wa tún gba pé ká yẹra fún ṣíṣe àṣejù. Jèhófà fẹ́ kí ara tu gbogbo àwọn ará àti àwọn àlejò tó bá wá sí ìpàdé wa. Síbẹ̀, kò yẹ ká máa ṣe ohun tó máa tàbùkù sí àwọn ìpàdé wa. Kò yẹ ká máa múra lọ́nà tí kò bójú mu, kò sì yẹ ká máa tẹ àtẹ̀jíṣẹ́, ká máa sọ̀rọ̀ tàbí ká máa jẹun nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn mọ̀ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba kì í ṣe ibi ìṣeré tàbí ibi tí wọ́n á ti máa sáré kiri. Nígbà tí Jésù rí àwọn tó ń tajà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run, inú bí i, ó sì lé wọn síta. (Jòh. 2:13-17) Bákan náà, àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa jẹ́ ibi tí a ti ń ṣe ìjọsìn tòótọ́, tí a sì ti ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí. Torí náà, bí ọ̀rọ̀ èyíkéyìí bá la owó lọ, tí kò sì ní í ṣe pẹ̀lú ohun tá a nílò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ibòmíì ló yẹ ká ti bójú tó irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.—Fi wé Nehemáyà 13:7, 8. w15 7/15 4:7, 8
Friday, February 10
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.—2 Tím. 3:1.
Ohun tí Bíbélì sọ ni pé ìwà búburú máa lékenkà sí i “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tím. 3:13; Mát. 24:21; Ìṣí. 12:12) Torí náà, a lè retí pé kí ayé tó ti burú yìí túbọ̀ máa burú sí i. Báwo lo ṣe rò pé àwọn nǹkan á burú tó nínú ayé kí “ìpọ́njú ńlá” tó dé? (Ìṣí. 7:14) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o retí pé kí gbogbo orílẹ̀-èdè máa jagun, kí ẹnikẹ́ni máà rí oúnjẹ jẹ, kí gbogbo èèyàn sì máa ṣàìsàn? Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn tó ń ṣiyè méjì pàápàá máa gbà pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ń ṣẹ. Àmọ́, Jésù sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn “kò” ní “fiyè sí” wíwàníhìn-ín rẹ̀, wọ́n á máa gbé ìgbé ayé wọn nìṣó títí tí òpin á fi dé bá wọn lójijì. (Mát. 24:37-39) Ìwé Mímọ́ tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ipò àwọn nǹkan ò ní burú nínú ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn débi tí àwọn èèyàn á fi gbà lọ́ranyàn pé òpin ti sún mọ́lé.—Lúùkù 17:20; 2 Pét. 3:3, 4. w15 8/15 2:6, 7
Saturday, February 11
Inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sàn ju ìyè.—Sm. 63:3.
Tó bá jẹ́ pé ohun táá mú ká gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí là ń fi àkókò wa ṣe, ṣó wá túmọ̀ sí pé à ń pàdánù àǹfààní tá a ní láti fi ìgbésí ayé wa ṣe ohun tó ní láárí jùyẹn lọ ni? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀! Kò sí ohun tó dáa tó kéèyàn fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà. Kì í ṣe pé à ń fi tìpá tìkúùkù sin Jèhófà ká ṣáà lè la ìpọ́njú ńlá já o! Bí Ọlọ́run ṣe dá wa nìyẹn, ìyẹn sì loun tó lè fún wa láyọ̀ tó gadabú. Bí Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ. (Sm. 63:1, 2) Àmọ́, kò dìgbà tá a bá dénú ayé tuntun ká tó gbádùn àwọn ìbùkún tẹ̀mí tó ń wá látinú fífi tọkàntọkàn sin Jèhófà, a ti ń gbádùn àwọn ìbùkún náà báyìí. Kódà, àwọn kan lára wa ti ń gbádùn ìbùkún náà fún ọ̀pọ̀ ọdún, a sì mọ̀ pé kò sí ọ̀nà ìgbésí ayé míì tó lè mú kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn jùyẹn lọ.—Sm. 1:1-3; Aísá. 58:13, 14. w15 8/15 3:16
Sunday, February 12
A ti gbà yín là nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.—Éfé. 2:8.
Ìgbàgbọ́ tá a ní lè mú ká ṣe ohun tó lè dà bí èyí tí kò ṣeé ṣe lójú èèyàn. (Mát. 21:21, 22) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ lára wa ti yí ìwà àti ìṣe wa pa dà débi pé àwọn tó mọ̀ wá tẹ́lẹ̀ á fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè gbà gbọ́ pé a ti ṣe ìyípadà tó tóyẹn nínú ìgbésí ayé wa. Jèhófà bù kún ìsapá wa torí pé ìgbàgbọ́ tá a ní nínú rẹ̀ ló mú ká ṣe irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀. (Kól. 3:5-10) Níwọ̀n bí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà sì ti mú ká ya ara wa sí mímọ́ fún un, a di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni kò sí bá a ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ tá a ní túbọ̀ ń sọ wá di alágbára. Ìgbàgbọ́ yìí ń mú ká gbéjà ko Èṣù, alátakò tó lágbára ju ẹ̀dá lọ. (Éfé. 6:16) Ní àfikún síyẹn, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa máa ṣàníyàn jù nígbà ìṣòro. Jèhófà sọ pé tí ìgbàgbọ́ wa bá mú ká fi ire Ìjọba òun sípò àkọ́kọ́, òun á pèsè àwọn ohun tá a nílò nípa tara fún wa. (Mát. 6:30-34) Yàtọ̀ síyẹn, ìgbàgbọ́ tá a ní á mú kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀bùn tó jẹ́ pé òun nìkan ló lè fúnni, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 3:16. w15 9/15 3:4, 5
Monday, February 13
Àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí [Ọlọ́run] ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.—1 Jòh. 4:19.
Báwo ni Jèhófà ṣe “kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa”? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Ìfẹ́ ni ànímọ́ Jèhófà tó ta yọ jù lọ, torí náà a lè lóye ìdí tí Jésù fi sọ fún ẹnì kan tó ń wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ pé òfin àkọ́kọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Ohun tí Jésù sọ yìí mú kó yé wa pé inú ọkàn ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run ti ń bẹ̀rẹ̀. Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹni tí kò bá fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin òun. Àmọ́, a kíyè sí i pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run tún wé mọ́ gbogbo ọkàn, èrò inú àti okun wa. Èyí túmọ̀ sí pé ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọ́run kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Yàtọ̀ sí pé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ti ọkàn wa wá, a tún gbọ́dọ̀ fi hàn pé a fẹ́ràn rẹ̀ nínú èrò àti ìṣe wa. Ohun tí wòlíì Míkà sì sọ pé Jèhófà fẹ́ ká ṣe gan-an nìyẹn.—Míkà 6:8. w15 9/15 5:1-3
Tuesday, February 14
Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ojú mi ti rí ọ.—Jóòbù 42:5.
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí kì í jẹ́ ká rí ọwọ́ Ọlọ́run kedere nínú ìgbésí ayé wa? Àwọn ìṣòro tá à ń kojú lè tán wa lókun. Tí ìṣòro bá ń bá wa fínra, a lè gbàgbé ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ti ṣe fún wa. Nígbà tí Jésíbẹ́lì Ayaba fẹ́ pa wòlíì Èlíjà, fún ìgbà díẹ̀ Èlíjà gbàgbé bí Ọlọ́run ṣe ran òun lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé Èlíjà ní kí Ọlọ́run “gba ọkàn [òun] kúrò.” (1 Ọba 19:1-4) Níbo ni Èlíjà ti lè rí ìṣírí tó nílò gbà? Àfi kó yíjú sí Jèhófà. (1 Ọba 19:14-18) Ìṣòro gba Jóòbù lọ́kàn débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo ipò tó bára ẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀ sí bí Ọlọ́run ṣe ń wò ó. (Jóòbù 42:3-6) Bíi ti Jóòbù, ó lè gba pé kí àwa náà sapá gidigidi ká tó lè rí àwọn ohun tí Ọlọ́run ń ṣe fún wa. Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Tá a bá ń ka Ìwé Mímọ́, ó ṣe pàtàkì ká ronú lórí ọ̀nà tó gbà kàn wá. Bá a bá sì ṣe ń rí ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà tì wá lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ la ó máa rí ìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e. w15 10/15 1:15, 16
Wednesday, February 15
Ọkùnrin yìí, ta ní yàn mí ṣe onídàájọ́ tàbí olùpín nǹkan fún yín?—Lúùkù 12:14.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tó lè mú kó má pọkàn pọ̀, àmọ́ kò gba ìpínyà ọkàn láyè. Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àwọn ará ìlú Kápánáúmù bẹ̀ ẹ́ pé kó má ṣe kúrò nílùú àwọn lẹ́yìn tó ti kọ́ wọn tó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Àmọ́, kí ni Jésù ṣe? Ó sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:42-44) Ohun tí Jésù sì ṣe gan-an nìyẹn, ó rìn jákèjádò ilẹ̀ Palẹ́sìnì, ó ń wàásù ó sì ń kọ́ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe káàkiri máa ń mú kó rẹ̀ ẹ́ nígbà míì, ó sì máa ń nílò ìsinmi. (Lúùkù 8:23; Jòh. 4:6) Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè fara da àtakò, ọkùnrin kan já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín ogún pẹ̀lú mi.” Àmọ́ Jésù kọ̀ láti bá wọn dá sí i.—Lúùkù 12:13-15. w15 10/15 3:10, 11
Thursday, February 16
Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.—1 Jòh. 4:8.
Ìfẹ́ ni olórí ànímọ́ tí Ọlọ́run ní, òun ló sì ṣe pàtàkì jù nínú gbogbo ànímọ́ rẹ̀. Kì í ṣe pé Jèhófà kàn ní ìfẹ́ àmọ́ òun tó jẹ́ gan-an nìyẹn. Ẹ wo bó ṣe yẹ ká kún fún ọpẹ́ tó pé Ọlọ́run ìfẹ́ ló dá ayé àtọ̀run àti gbogbo ohun alààyè! Ìfẹ́ ló sì ń mú kó ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Torí pé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú ó sì nífẹ̀ẹ́ gbogbo ohun tó dá, ìyẹn mú kó dá wa lójú pé gbogbo ìlérí tó ṣe fún aráyé máa ṣẹ, á sì ṣe gbogbo àwọn tó bá fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, torí ìfẹ́ tí Jèhófà ní, ó “ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò,” ìyẹn Jésù Kristi. (Ìṣe 17:31) Ó dá wa lójú pé ìlérí yìí máa ṣẹ. Ọlọ́run máa fi ojú rere hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tí wọ́n sì ń ṣègbọràn, wọ́n á sì rí ìbùkún ayérayé gbà. w15 11/15 3:1, 2
Friday, February 17
Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.—Kól. 4:6.
Lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, onírúurú èèyàn la máa ń bá pàdé, àwọn kan máa ń gbọ́ ìwàásù wa àwọn míì kì í fẹ́ gbọ́ rárá. Àmọ́, yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó yẹ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ṣe. Nígbàkigbà tá a bá ń gbèjà ìhìn rere níwájú ẹnikẹ́ni tó bá ń béèrè ìdí tá a fi ní ìrètí, ẹ jẹ́ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ “pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (1 Pét. 3:15) Kódà tí àwọn tá à ń wàásù fún bá kọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere tàbí tí wọ́n bá fìbínú sọ̀rọ̀ sí wa, ìyẹn ò ní ká má fìfẹ́ hàn sí wọn. Lọ́nà yìí, à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni [Jèhófà] tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” (1 Pét. 2:23) Yálà a wà pẹ̀lú àwọn ará wa tàbí a wà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ó yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká sì máa fi ìmọ̀ràn yìí sílò pé: “Kí ẹ má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe tàbí ìkẹ́gàn san ìkẹ́gàn, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre.”—1 Pét. 3:8, 9. w15 11/15 4:17, 18
Saturday, February 18
Pe orí [wọn] wálé . . . láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn.—Títù 2:4.
Jésù máa ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. (Jòh. 15:9) Bó ṣe máa ń wà pẹ̀lú wọn tún fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́. (Máàkù 6:31, 32; Jòh. 2:2; 21:12, 13) Torí náà, máa sọ fáwọn ọmọ rẹ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ọ́ lógún. (Òwe 4:3) Samuel tó ń gbé nílẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, Dádì máa ń ka Ìwé Ìtàn Bíbélì fún mi lálaalẹ́. Wọ́n máa ń dáhùn àwọn ìbéèrè mi, wọ́n á gbá mi mọ́ra, wọ́n á sì fẹnu kò mí lẹ́nu ká tó lọ sùn. Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo wá mọ̀ pé nígbà tí dádì mi wà ní kékeré, àwọn òbí wọn kì í gbá wọn mọ́ra tàbí fẹnu kò wọ́n lẹ́nu! Síbẹ̀, Dádì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí n lè mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi. Ìdí nìyẹn témi náà fi nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, ara máa ń tù mí ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ pé mo nírú wọn ní Bàbá.” Ẹ̀yin òbí, ẹ jẹ́ kó mọ́ yín lára láti máa sọ fáwọn ọmọ yín pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an,” kí ọkàn wọn lè balẹ̀ bíi ti Samuel tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ rẹ̀ tán. Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn. Ẹ jọ máa sọ̀rọ̀, ẹ jọ máa jẹun, kẹ́ ẹ sì máa bá wọn ṣeré. w15 11/15 1:3, 4
Sunday, February 19
Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?—Mát. 24:45.
Nígbà tí Jésù yan àwùjọ àwọn èèyàn kéréje kan láti jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lọ́dún 1919, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n sábà máa ń lò láti kọ́ “àwọn ará ilé” ìgbàgbọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. “Ẹrú” náà ti ṣe gudugudu méje kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè wà ní èdè tó pọ̀ sí i, èdè tí wọ́n sì fi ń tẹ àwọn ìwé wa báyìí ti lé ní ọgọ́rùn-ún méje [700]. A tún rí i pé a nílò Bíbélì tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ á bá àwọn ohun tó wà nínú èyí tí wọ́n fọwọ́ kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu gẹ́lẹ́ tó sì jẹ́ pé èdè tó bóde mu tó sì rọrùn lóye ni wọ́n á fi kọ ọ́. Torí náà, ètò Ọlọ́run dá ìgbìmọ̀ kan sílẹ̀, ìyẹn Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun. Láàárín ọdún 1950 sí 1960, ìgbìmọ̀ yìí tẹ Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì jáde ní ìdìpọ̀ mẹ́fà. Nígbà tí Arákùnrin N. H. Knorr ń mú ìdìpọ̀ àkọ́kọ́ jáde ní August 2, 1950, ó jẹ́ kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà mọ̀ pé Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun máa mú kó rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. w15 12/15 1:15, 17
Monday, February 20
Akónijọ wá ọ̀nà àtirí àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.—Oníw. 12:10.
Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára tó o máa sọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé o ṣì ní láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ lédè rẹ. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa kọ́ bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ nínú Bíbélì àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Tó o bá rí ọ̀rọ̀ kan tó ò mọ̀ tẹ́ lẹ̀, gbìyànjú láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kọ́ bó o ṣe lè máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àti àkọ́bí Ọmọ rẹ̀, ó sọ pé: ‘Jèhófà ti fún mi [Jésù] ní ahọ́n àwọn tí a kọ́, kí n lè mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn.’ (Aísá. 50:4) Tá a bá ń fẹ̀sọ̀ ronú lórí ohun tá a fẹ́ sọ, àá lè máa sọ ọ̀rọ̀ tó tọ́, tó sì yẹ. (Ják. 1:19) A lè bi ara wa pé, ‘Ṣé ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ yìí máa yé ẹni tí mo fẹ́ sọ ọ́ fún? Báwo ni ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ yìí ṣe máa rí lára ẹ̀?’ w15 12/15 3:12
Tuesday, February 21
Ìsọdahoro [Jerúsálẹ́mù] ti sún mọ́lé.—Lúùkù 21:20.
Ní báyìí táwọn ọmọ ogun yí Jerúsálẹ́mù ká gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tẹ́lẹ̀, àwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà, pàápàá jù lọ àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì kan ní kíákíá. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé tí wọ́n bá rí i tí àwọn ọmọ ogun yí Jerúsálẹ́mù ká, kí wọ́n sá lọ sí àwọn òkè ńlá. (Lúùkù 21:21-24) Ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìkìlọ̀ yìí. Nígbà yẹn, àwọn Kristẹni tó wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì jẹ́ adúróṣinṣin láìka àtakò àti inúnibíni tó le koko tí wọ́n ń fojú winá rẹ̀ sí. (Héb. 10:32-34) Àmọ́, Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ de ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Wọ́n máa tó dojú kọ ọ̀kan lára àdánwò ìgbàgbọ́ tó lágbára jù lọ. (Mát. 24:20, 21; Héb. 12:4) Wọ́n túbọ̀ nílò ìgbàgbọ́ àti ìfaradà kí wọ́n lè sà bí Jésù ṣe sọ, ìyẹn ló sì máa pinnu bóyá wọ́n á là á já tàbí wọn ò ní là á já. (Héb. 10:36-39) Torí náà, Jèhófà mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà sáwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n yẹn kó lè fún ìgbàgbọ́ wọn lókun kó sì múra ọkàn wọn sílẹ̀ dé ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Lẹ́tà yẹn la wá mọ̀ sí ìwé Hébérù lónìí. w16.01 1:1, 2
Wednesday, February 22
Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.—1 Jòh. 4:11.
Tá a bá mọrírì ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa, ó pọn dandan pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. (1 Jòh. 3:16) Báwo la ṣe lè fìfẹ́ hàn sí wọn? A rí àpẹẹrẹ bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn nínú àwọn ohun tí Jésù ṣe. Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ pàápàá àwọn òtòṣì. Ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó la ojú àwọn afọ́jú, ó sì mú àwọn arọ, adití àtàwọn odi lára dá. (Mát. 11:4, 5) Jésù ò dà bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, ó máa ń kọ́ àwọn tó fẹ́ mọ̀ nípa Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́. (Jòh. 7:49) Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn táwọn èèyàn kà sí òtòṣì yẹn, ó sì máa ń sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Mát. 20:28) A ò ṣe ronú lórí bá a ṣe lè ran àwọn ará inú ìjọ wa lọ́wọ́, pàápàá jù lọ àwọn tó ti dàgbà? Jẹ́ kí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ẹ mú kí ìwọ náà máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará. w16.01 2:12-14
Thursday, February 23
Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe ara ọ̀wọ́ yìí; àwọn pẹ̀lú ni èmi yóò mú wá, . . . wọn yóò sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.—Jòh. 10:16.
Ṣó lẹ́tọ̀ọ́ pé kí àwọn àgùntàn mìíràn mọ orúkọ gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró báyìí? Rárá. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti mọ̀ dájú bóyá wọ́n máa gba èrè wọn tàbí wọn ò ní gbà á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yàn wọ́n láti lọ sọ́run, bí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ nìkan ni wọ́n máa gba èrè wọn. Sátánì mọ èyí, ìdí nìyẹn tó fi ń gbìyànjú láti ‘ṣì wọ́n lọ́nà’ nípasẹ̀ “àwọn èké wòlíì.” (Mát. 24:24) Ìgbà tí Jèhófà bá mú kó ṣe kedere sí àwọn ẹni àmì òróró yìí pé òun ti kà wọ́n sí olóòótọ́ nìkan ló tó lè dá wọn lójú pé wọ́n máa gba èrè wọn. Tó bá kù díẹ̀ kí “ìpọ́njú ńlá” bẹ̀rẹ̀ tàbí kí wọ́n tó kú ni Jèhófà máa fún wọn ní èdìdì ìkẹyìn tó túmọ̀ sí pé ó ti tẹ́wọ́ gbà wọ́n pátápátá.—Ìṣí. 2:10; 7:3, 14. w16.01 4:2, 3
Friday, February 24
[Ọ̀rọ̀ mi] yóò . . . ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.—Aísá. 55:11.
Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ṣe ń mú ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fáráyé ṣẹ? Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí àwa èèyàn wà láàyè títí láé, ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù dá ò sì yí èyí pa dà. Ọlọ́run ṣe ohun táá mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Kí ló ṣe? Ó rán Jésù wá sáyé láti wá fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ. Àmọ́ káwọn èèyàn tó lè jàǹfààní látinú ẹbọ tí Jésù fẹ̀mí rẹ̀ rú yìí, àfi kí wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Jésù kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí àwọn náà máa kọ́ àwọn èèyàn. Bá a ṣe ń wàásù tá a sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti dọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ńṣe là ń bá Ọlọ́run ìfẹ́ ṣiṣẹ́ bó ṣe ń gba aráyé là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Èyí fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. “Ìfẹ́ rẹ̀ [ni] pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tím. 2:4. w16.01 5:15, 16
Saturday, February 25
[Áhásì] sun àwọn ọmọ tirẹ̀ nínú iná.—2 Kíró. 28:3.
Àpẹẹrẹ búburú Áhásì Ọba lè mú kí Hesekáyà ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bínú sí Jèhófà. Lónìí, ohun táwọn kan fara dà ò tiẹ̀ tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Hesekáyà, síbẹ̀ wọ́n rò pé àwọn ní ìdí tó fi yẹ káwọn “kún fún ìhónú sí Jèhófà” tàbí káwọn bínú sí ètò rẹ̀. (Òwe 19:3) Àwọn míì rò pé ilé búburú táwọn ti jáde lè mú káwọn máa gbé ìgbé ayé búburú tàbí kó mú káwọn náà tún ṣe irú àṣìṣe táwọn òbí àwọn ṣe. (Ìsík. 18:2, 3) Àmọ́, ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́? Irú ìgbé ayé tí Hesekáyà gbé fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀! Kò sídìí tó fi yẹ kí ẹnikẹ́ni bínú sí Jèhófà. Jèhófà kọ́ ló ń fa ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn. (Jóòbù 34:10) Òótọ́ ni pé àpẹẹrẹ táwọn òbí fi lélẹ̀ lè ní ipa rere tàbí ipa búburú lórí àwọn ọmọ wọn. (Òwe 22:6; Kól. 3:21) Àmọ́ ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé irú ilé tá a ti jáde ló máa pinnu irú èèyàn tá a máa jẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ti fún wa lẹ́bùn kan, ìyẹn òmìnira láti yan ohun tó wù wá, tó túmọ̀ sí pé a lè yàn láti máa ṣe ohun tó dáa tàbí ohun tó burú.—Diu. 30:19. w16.02 2:8-10
Sunday, February 26
Àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ . . . ń wá ọkàn mi.—Sm. 54:3.
Ábínérì ò ti Dáfídì lẹ́yìn. Kódà, Ábínérì tún ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ nígbà tó ń wá ọ̀nà láti pa Dáfídì. Jónátánì àti Ábínérì mọ̀ pé Dáfídì ni Ọlọ́run ti yàn láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. (1 Sám. 26:1-5) Àmọ́, lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù kú, Ábínérì ò ti Dáfídì lẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló gbìyànjú láti fi Iṣibóṣẹ́tì, ọmọ Sọ́ọ̀lù, jọba. Lẹ́yìn náà, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí Ábínérì fúnra rẹ̀ fẹ́ di ọba, bóyá torí ẹ̀ ló ṣe bá ọ̀kan lára àwọn ìyàwó Sọ́ọ̀lù Ọba sùn. (2 Sám. 2:8-10; 3:6-11) Bíi ti Ábínérì, Ábúsálómù ọmọ Dáfídì Ọba náà jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run torí pé kò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó fẹ́ di ọba, torí náà ó ṣe “kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún ara rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin tí ń sáré níwájú rẹ̀.” (2 Sám. 15:1) Ó tiẹ̀ yí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lérò pa dà kí wọ́n lè tì í lẹ́yìn. Kódà, ó tún gbìyànjú láti pa bàbá rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé Jèhófà ti fi Dáfídì jẹ ọba Ísírẹ́lì. (2 Sám. 15:13, 14; 17:1-4) Tí ẹnì kan ò bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tó sì fẹ́ dé ipò ńlá, ó máa ṣòro fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Lóòótọ́, a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò sì fẹ́ jẹ́ onímọtara ẹni nìkan àti ìkà bíi ti Ábínérì àti Ábúsálómù. w16.02 4:9-11
Monday, February 27
Ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́, jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀.—Ják. 2:17.
Tí àwọn ohun tó o gbà gbọ́ bá dá ọ lójú lóòótọ́, ó máa hàn nínú ìwà rẹ. Àwọn ọ̀dọ́ náà gbọ́dọ̀ ní “ìṣe ìwà mímọ́.” (2 Pét. 3:11) Kéèyàn ní ìṣe ìwà mímọ́ túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ oníwà mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ìwà tó o hù lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Nígbà tó ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o ṣe ohun tí kò tọ́, ǹjẹ́ o fara balẹ̀ ronú kó o lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́? (Héb. 5:14) Ǹjẹ́ o rántí àwọn ìgbà kan tó ò jẹ́ káwọn èèyàn mú ẹ ṣe ohun tí kò tọ́, tó ò sì jẹ́ káwọn ojúgbà rẹ sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà? Ṣé ìwà tó dáa lo máa ń hù níléèwé rẹ? Ṣé o máa ń pa òfin Jèhófà mọ́ ní gbogbo ìgbà, àbí o máa ń hu irú ìwà táwọn ọmọ iléèwé rẹ ń hù kí wọ́n má bàa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́? (1 Pét. 4:3, 4) Adára-má-kù-síbì-kan ò sí. Nígbà míì pàápàá, àwọn kan tó ti ń sin Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lè máa tijú tàbí kó ṣòro fún wọn láti wàásù fáwọn ẹlòmíì. Àmọ́, ẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run máa ń yangàn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, ó sì máa ń hàn nínú ìwà rẹ̀. w16.03 2:10, 11
Tuesday, February 28
Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.—Aísá. 30:21.
Látijọ́ táláyé ti dáyé ni Jèhófà ti ń tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà tó sì máa ń fún wọn láwọn ìtọ́ni pàtó. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní ìtọ́ni kedere táá mú kí wọ́n wà láàyè títí láé kí wọ́n sì máa láyọ̀. (Jẹ́n. 2:15-17) Àmọ́ Ádámù àti Éfà kò tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Baba wọn onífẹ̀ẹ́ fún wọn. Éfà gba ìmọ̀ràn tí ejò fún un, Ádámù náà sì wá fetí sí ohùn aya rẹ̀. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Àwọn méjèèjì jẹ palaba ìyà, wọ́n sì kú láìnírètí láti tún pa dà wà láàyè mọ́. Àìgbọràn wọn ló sì ti gbogbo aráyé sọ́nà ìparun. Ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wa jùyẹn lọ fíìfíì. Ó ń tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà kí wọ́n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì máa ń tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n má bàa kó sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Ṣe ni Jèhófà dà bí olùṣọ́ àgùntàn kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn rẹ̀, tó ń tọ́ wọn sọ́nà, tó sì ń dáàbò bò wọ́n kí wọ́n má bàa kó sí kòtò. w16.03 4:2, 3