May
Monday, May 1
Ẹnu sì ń yà wọ́n nítorí àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin tí ń jáde láti ẹnu rẹ̀.—Lúùkù 4:22.
Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, tá a sì ń gba tiwọn rò, á rọrùn fún wa láti bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rí làálàá táwọn ogunlọ́gọ̀ kan ṣe torí kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àánú wọn ṣe é, ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:34) Kódà, nígbà táwọn kan bú Jésù, kò bú wọn pa dà. (1 Pét. 2:23) Ó lè ṣòro fún wa láti lo òye ká sì fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni tó sún mọ́ wa dáadáa là ń bá sọ̀rọ̀. A lè máa rò ó pé a lè bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa tàbí ọ̀rẹ́ wa nínú ìjọ sọ̀rọ̀ bó ṣe wù wá. Àmọ́, ṣé Jésù sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bó ṣe wù ú torí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́? Rárá o! Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń jiyàn nípa ẹni tó lọ́lá jù láàárín wọn, Jésù fi ohùn pẹ̀lẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì fi ọmọ kékeré kan ṣàpèjúwe fún wọn. (Máàkù 9:33-37) Àwọn alàgbà náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n máa gbani nímọ̀ràn pẹ̀lú “ẹ̀mí ìwà tútù.”—Gál. 6:1. w15 12/15 3:15, 16
Tuesday, May 2
Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.—Héb. 13:1.
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa? Ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará ni pé ohun tí Jèhófà ní ká ṣe nìyẹn. A ò lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tá ò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. (1 Jòh. 4:7, 20, 21) Ìdí míì ni pé a máa nílò ìrànlọ́wọ́ ara wa pàápàá jù lọ nígbà ìṣòro. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni, ó mọ̀ pé àwọn kan lára wọn máa tó fi ilé àtàwọn ohun ìní wọn sílẹ̀. Jésù sì ti sọ bí àkókò náà ṣe máa le tó. (Máàkù 13:14-18; Lúùkù 21:21-23) Torí náà, kí àkókò náà tó tó, àwọn Kristẹni yẹn gbọ́dọ̀ mú kí ìdè ìfẹ́ tó wà láàárín wọn lágbára sí i. (Róòmù 12:9) Ìpọ́njú tá ò tíì rí irú rẹ̀ rí látijọ́ táláyé ti dáyé máa tó dé. (Máàkù 13:19; Ìṣí. 7:1-3) Lílọ sí ìpàdé déédéé nìkan ò tó o! Pọ́ọ̀lù rán àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni yẹn létí pé kí wọ́n máa gba ara wọn níyànjú láti máa fi ìfẹ́ hàn kí wọ́n sì máa ṣoore fún ara wọn.—Héb. 10:24, 25. w16.01 1:6-8
Wednesday, May 3
Gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́.—Ìṣe 2:4.
Ọjọ́ pàtàkì lọjọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ti ọdún 33 tó wáyé nílùú Jerúsálẹ́mù. Inú yàrá òkè kan ni ọgọ́fà [120] lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wà, tí gbogbo wọn ń gbàdúrà pa pọ̀. (Ìṣe 1:13-15) Ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn máa mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Jóẹ́lì ṣẹ. (Jóẹ́lì 2:28-32; Ìṣe 2:16-21) Lọ́jọ́ yẹn, Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni yẹn ní ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì di ẹni àmì òróró. (Ìṣe 1:8) Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn èrò yí wọn ká, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ohun àgbàyanu tí wọ́n ti rí tí wọ́n sì ti gbọ́. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ tán fún wọn, ó sì tún sọ ìdì tó fi ṣe pàtàkì gan-an. Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́.” Lọ́jọ́ yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn ló ṣe batisí, Ọlọ́run sì fún àwọn náà ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́.—Ìṣe 2:37, 38, 41. w16.01 3:1-3
Thursday, May 4
Ẹnì yòówù tí ó bá jẹ ìṣù búrẹ́dì náà tàbí tí ó bá mu ife Olúwa láìyẹ yóò jẹ̀bi nípa ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.—1 Kọ́r. 11:27.
Báwo ni ẹni àmì òróró kan ṣe lè jẹ búrẹ́dì kó sì mu wáìnì “láìyẹ” níbi Ìrántí Ikú Kristi? Bí ẹni àmì òróró kan ò bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, tí kò sì jẹ́ olóòótọ́ sí i, tó wá ń jẹ búrẹ́dì tó sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi, ìwà àìlọ́wọ̀ gbáà nìyẹn máa jẹ́. (Héb. 6:4-6; 10:26-29) Ìkìlọ̀ pàtàkì yìí rán àwọn ẹni àmì òróró létí pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn bí wọ́n bá fẹ́ gba “ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 3:13-16) Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ẹni àmì òróró pé kí wọ́n “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ ìpè tí a fi pè [wọ́n].” Báwo ló ṣe yẹ káwọn ẹni àmì òróró ṣe èyí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́, kí ẹ máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:1-3) Ńṣe ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ń mú káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kì í sọ wọ́n di agbéraga.—Kól. 3:12. w16.01 4:5, 6
Friday, May 5
Ọlọ́run tòótọ́ dán Ábúráhámù wò.—Jẹ́n. 22:1.
Fojú inú wo Ábúráhámù, ẹni tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọdún márùndínláàádóje [125], bó ṣe rọra ń gorí òkè lọ. Ísákì ọmọ rẹ̀ tóun náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ń tẹ̀ lé e. Ísákì ru igi ìdáná, Ábúráhámù sì mú ọ̀bẹ àtàwọn ohun tí wọ́n á fi dáná dání. Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ìrìn-àjò tó le jù nígbèésí ayé Ábúráhámù nìyẹn. Àmọ́ kì í ṣe torí pé ó ti darúgbó o, koko lara ẹ̀ le. Ohun tó mú kí ìrìn-àjò yẹn le ni pé Jèhófà ní kó fi ọmọ rẹ̀ rúbọ sí òun! (Jẹ́n. 22:1-8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àdánwò ìgbàgbọ́ tó lágbára jù lọ tí Ábúráhámù kojú nìyẹn. Àmọ́ kì í ṣe pé Ábúráhámù ò mọ ohun tó ń ṣe tàbí pé kò ronú kó tó mú ọmọ rẹ̀ láti lọ fi rúbọ. Ojúlówó ìgbàgbọ́ tó ní ló mú kó ṣègbọràn. Ábúráhámù mọ̀ pé bí òun bá tiẹ̀ fi ọmọ òun rúbọ sí Jèhófà, Jèhófà lè jí i dìde. Ó mọ̀ pé tóun bá ṣègbọràn, Jèhófà á bù kún òun àti ọmọ òun ọ̀wọ́n. Kí ló jẹ́ kí Ábúráhámù ní irú ìgbàgbọ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀? Àwọn ohun tó kọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ni. w16.02 1:3, 4
Saturday, May 6
Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.—Lúùkù 1:38.
Màríà máa lóyún, á bí Ọmọ Ọlọ́run, á sì tọ́jú rẹ̀ dàgbà! A sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní ńlá tí Màríà ní. Àmọ́ àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kó máa ronú nípa rẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún un pé ó máa lóyún láìní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kankan. Àmọ́ Gébúrẹ́lì ò sọ fún Màríà pé òun á bá a ṣàlàyé fáwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn aládùúgbò rẹ̀. Ojú wo wá làwọn yẹn á máa fi wo Màríà? Báwo ló ṣe máa ṣàlàyé fún Jósẹ́fù pé òun ò ṣèṣekúṣe? Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ ńlá ló já lé e léjìká, òun ló máa tọ́ Ọmọ Ọlọ́run dàgbà! A ò mọ gbogbo ohun tó ń jẹ Màríà lọ́kàn, àmọ́ a mọ ohun tó ṣe lẹ́yìn tí Gébúrẹ́lì bá a sọ̀rọ̀ tán. Màríà dáhùn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojoojúmọ́ tòní.—Lúùkù 1:26-37. w16.02 2:13, 14
Sunday, May 7
Húṣáì tí í ṣe Áríkì rèé tí ó wá pàdé rẹ̀, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ gbígbọ̀nya àti ìdọ̀tí ní orí rẹ̀.—2 Sám. 15:32.
Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Dáfídì Ọba tó jẹ́ adúróṣinṣin ni Húṣáì. Nígbà táwọn èèyàn fẹ́ fi Ábúsálómù jọba, Húṣáì nílò ìgboyà kó lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì àti sí Ọlọ́run. Húṣáì mọ̀ pé Ábúsálómù ti wá sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ àti pé Dáfídì ti sá lọ. (2 Sám. 15:13; 16:15) Àmọ́, kí ni Húṣáì ṣe? Ṣé ńṣe ló pa Dáfídì tì tó wá ń ti Ábúsálómù lẹ́yìn? Rárá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ti darúgbó tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń fẹ́ pa á, Húṣáì jẹ́ adúróṣinṣin sí i torí pé òun ni Jèhófà yàn láti jẹ́ ọba. Torí náà, Húṣáì lọ bá Dáfídì lórí Òkè Ólífì. (2 Sám. 15:30) Dáfídì ní kí Húṣáì pa dà lọ sí Jerúsálẹ́mù kó sì díbọ́n bíi pé ọ̀rẹ́ Ábúsálómù lòun kó wá rí i dájú pé nǹkan tí òun bá sọ ni Ábúsálómù ṣe dípò ti Áhítófẹ́lì. Húṣáì lo ìgboyà, ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè ṣe ohun tí Dáfídì fẹ́ kó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó ran Húṣáì lọ́wọ́, Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Húṣáì ni Ábúsálómù fetí sí dípò Áhítófẹ́lì.—2 Sám. 15:31; 17:14. w16.02 4:15, 16
Monday, May 8
Gbogbo ìbùkún wọ̀nyí yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì dé bá ọ, nítorí pé ìwọ ń bá a nìṣó láti máa fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ.—Diu. 28:2.
Àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Òfin tí Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ṣe àwa Kristẹni náà láǹfààní. Lọ́nà wo? Àwa náà lè fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ìlànà tí Òfin náà dá lé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin Mósè kọ́ ló ń darí àwa Kristẹni, àwọn ìlànà inú rẹ̀ ṣì wúlò fún wa, nígbèésí ayé wa àti lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn òfin yẹn sínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, kí àwọn ìlànà inú rẹ̀ lè máa tọ́ wa sọ́nà, ká sì lè túbọ̀ mọyì bí Jésù ṣe kọ́ wa ní ohun tó ju Òfin lọ. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” Torí náà, kì í ṣe pé ó yẹ ká máa sá fún ìṣekúṣe nìkan ni, a ò tún gbọ́dọ̀ gba èròkerò tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè nínú ọkàn wa.—Mát. 5:27, 28. w16.03 4:6, 8
Tuesday, May 9
Yan ọba sípò fún wa láti máa ṣe ìdájọ́ wa.—1 Sám. 8:5.
Sámúẹ́lì lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ohun táwọn èèyàn náà fẹ́ débi pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ fún un pé kó ṣe ohun táwọn èèyàn náà ń sọ. (1 Sám. 8:7, 9, 22) Síbẹ̀, Sámúẹ́lì ò di ọkùnrin tó máa gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ sínú tàbí kó kórìíra rẹ̀. Nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé kó fòróró yan Sọ́ọ̀lù, wòlíì náà ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé ó kàn gbà bẹ́ẹ̀ torí pé ó di dandan, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ló mú kó múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lónìí, àwọn alàgbà tó jẹ́ onírìírí máa ń fi ìfẹ́ dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ bíi ti Sámúẹ́lì. (1 Pét. 5:2) Irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ kì í fà sẹ́yìn láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ torí ìbẹ̀rù pé àwọn tí wọ́n bá dá lẹ́kọ̀ọ́ máa gba àwọn iṣẹ́ kan tí wọ́n ń bójú tó nínú ìjọ mọ́ wọn lọ́wọ́. Àwọn olùkọ́ tó lọ́kàn tó dáa máa ń gbà pé àwọn tó múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe abánidíje, àmọ́ wọ́n jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀,” wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye fún ìjọ. (2 Kọ́r. 1:24; Héb. 13:16) Ẹ wo bí inú àwọn olùkọ́ tí kò mọ tara wọn nìkan yìí ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá ń kíyè sí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń lo ẹ̀bùn tí wọ́n ní lọ́nà tó máa ṣe ìjọ láǹfààní!—Ìṣe 20:35. w15 4/15 1:16, 17
Wednesday, May 10
Èmi yóò tọ́ ọ sọ́nà dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.—Jer. 30:11.
Asaráyà Ọba “ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó dúró ṣánṣán ní ojú Jèhófà.” Síbẹ̀, “Jèhófà fi àrùn kọlu ọba, ó sì ń bá a lọ ní jíjẹ́ adẹ́tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.” (2 Ọba 15:1-5) Kí nìdí? Ẹsẹ Bíbélì yẹn kò sọ fún wa. Ṣé ó wá yẹ kí àkọsílẹ̀ náà máa kọ wá lóminú tàbí kó mú ká máa ronú pé Jèhófà fìyà jẹ Asaráyà láìnídìí? A ò ní rò bẹ́ẹ̀ tá a bá mọ Jèhófà dunjú. Asaráyà Ọba náà ni Ùsáyà Ọba. (2 Ọba 15:7, 32) Níbòmíì tá a ti rí ìtàn yìí nínú Bíbélì, ìyẹn nínú 2 Kíróníkà 26:3-5, 16-21, a rí i pé Ùsáyà ṣe ohun tó dára lójú Jèhófà fún àwọn àkókò kan, àmọ́ nígbà tó yá “ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera àní títí dé àyè tí ń fa ìparun.” Ìkùgbù mú kó gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ àlùfáà tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí. Àwọn àlùfáà mọ́kànlélọ́gọ́rin [81] ló lọ bá a tí wọ́n sì gbìyànjú láti tún èrò rẹ̀ ṣe. Kí ni Ùsáyà ṣe? Ohun tó ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbéraga ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù. Ńṣe ló “kún fún ìhónú” sí àwọn àlùfáà náà. Abájọ tí Jèhófà ṣe fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú! w15 4/15 3:8, 9
Thursday, May 11
A fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.—Ìṣí. 12:9.
Bí ẹsẹ ojúmọ́ tòní ṣe sọ, a pe Sátánì ní Èṣù, èyí tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” Orúkọ yìí rán wa létí pé Sátánì ba Jèhófà lórúkọ jẹ́, ó pe Jèhófà ní òpùrọ́. Ọ̀rọ̀ náà, “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà” rán wa létí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ burúkú yẹn ní ọgbà Édẹ́nì nígbà tí Sátánì lo ejò láti tan Éfà jẹ. Tá a bá gbọ́ gbólóhùn náà “dírágónì ńlá,” ohun tó máa wá síni lọ́kàn ni ẹranko abàmì kan, èyí sì bá Sátánì mu wẹ́kú torí pé ó ń jà fitafita láti dènà ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún aráyé, ó sì ń wá ọ̀nà láti pa àwọn èèyàn Jèhófà run. Kò sí àní-àní, Sátánì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè ba ìṣòtítọ́ wa jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pét. 5:8) Inú Sátánì máa ń dùn nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì bá sọ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run di ẹlẹ́gbin, ó sì máa ń lo irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti rọ́wọ́ mú bẹ́ẹ̀ láti fi ṣáátá Jèhófà.—Òwe 27:11. w15 5/15 1:3, 4, 10
Friday, May 12
Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.—1 Tím. 6:10.
Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn ara wa, èyí sì ṣe kedere tá a bá rántí pé inú ọgbà tó lẹ́wà ni Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà sì. (Jẹ́n. 2:9) Àmọ́, Sátánì máa ń lo “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” láti mú kí ọkàn wa máa fà sí ohun tí kò tọ́. (Mát. 13:22) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé owó ló ń mú kéèyàn láyọ̀ tàbí pé ìgbà téèyàn bá kó nǹkan tara jọ lèèyàn rọ́wọ́ mú láyé. Ńṣe lẹni tó bá nírú èrò bẹ́ẹ̀ ń tan ara rẹ̀ jẹ, ó sì lè mú kéèyàn pàdánù ohun tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn jíjẹ́ tá a jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mát. 6:24) Tó bá jẹ́ pé Ọrọ̀ là ń lé lójú méjèèjì, a jẹ́ pé a ò sin Jèhófà mọ́, ohun tí Sátánì sì fẹ́ ká ṣe gan-an nìyẹn! A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí owó tàbí àwọn nǹkan tí owó lè rà mú ká kẹ̀yìn sí Jèhófà ọ̀rẹ́ wa. Tá a bá máa ṣẹ́gun Sátánì, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí nǹkan tara gbà wá lọ́kàn.—1 Tím. 6:6-10. w15 5/15 2:12
Saturday, May 13
Bí ẹ̀yà ara kan bá sì ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà.—1 Kọ́r. 12:26.
Kì í sábà rọrùn láti mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíì. A ò mọ onírúurú ìṣòro tó ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn fínra. Bí àpẹẹrẹ, jàǹbá, àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó ti sọ àwọn míì di aláìlera. Ìsoríkọ́ ń kó ìbànújẹ́ bá àwọn kan, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìbẹ̀rù ò jẹ́ káwọn míì gbádùn torí àwọn apániláyà tàbí torí ìwà ipá táwọn kan ti hù sí wọn nígbà kan rí. Síbẹ̀, àwọn míì wà tó jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ tàbí káwọn kan lára ìdílé wọn má sin Jèhófà. Kò sẹ́ni tí kò níṣòro, èyí tó sì pọ̀ jù nínú àwọn ìṣòro yìí ni kò tíì ṣẹlẹ̀ sí wa rí. Tọ́rọ̀ bá rí báyìí, báwo la ṣe lè fìfẹ́ hàn bíi ti Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ ká máa tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ táwọn èèyàn bá ń sọ ìṣòro wọn fún wa títí tá a fi máa lóye bí nǹkan ṣe rí lára wọn déwọ̀n àyè tá a lè lóye rẹ̀ dé. Èyí máa jẹ́ ká lè fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà, ká sì ṣe ohun tá a fi máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Ohun tí ẹnì kan nílò lè yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì, àmọ́ a lè fún wọn níṣìírí nípa tẹ̀mí, ká sì pèsè àwọn ìrànwọ́ míì fún wọn.—Róòmù 12:15; 1 Pét. 3:8. w15 5/15 4:6, 7
Sunday, May 14
Kristi [ni] agbára Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 1:24.
Jèhófà ló fún Jésù ní agbára tó ń lò, torí náà ìdí wà tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run Olódùmarè ní gbogbo ọlá àṣẹ lórí àwọn ohun tó dá. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò. Ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Jèhófà sọ pé: “Ní ọjọ́ méje péré sí i, èmi yóò mú kí òjò rọ̀ sórí ilẹ̀ ayé fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.” (Jẹ́n. 7:4) Bákan náà, ìwé Ẹ́kísódù 14:21 sọ pé: “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú òkun náà padà sẹ́yìn nípa ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn líle.” Ohun tó fara jọ èyí náà ló wà nínú Jónà 1:4, ó ní: “Jèhófà fúnra rẹ̀ sì rán ẹ̀fúùfù ńláǹlà jáde sí òkun, ìjì líle ńláǹlà sì wá wà lórí òkun; àti ní ti ọkọ̀ òkun náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́.” Inú wa dùn láti mọ̀ pé Jèhófà láṣẹ lórí àwọn òkè, òkun, ẹ̀fúùfù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láìsì àní-àní, ọjọ́ ọ̀la ayé wa yìí ń bọ̀ wá dáa láìpẹ́. Ohun ayọ̀ ló jẹ́ láti máa fojú inú wo àkókò tí ìjì líle, àtàwọn nǹkan míì kò ní pa èèyàn mọ́ tàbí kó sọni di aláàbọ̀ ara, torí pé “àgọ́ Ọlọ́run [yóò] wà pẹ̀lú aráyé”! (Ìṣí. 21:3, 4) Ọkàn wa balẹ̀ pé Jésù máa lo agbára Ọlọ́run nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso rẹ̀ láti fi kápá ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn nǹkan míì. w15 6/15 1:15, 16
Monday, May 15
Jẹ́ kí ọ̀nà rẹ jìnnà réré sí ẹ̀gbẹ́ [obìnrin oníṣekúṣe]; má sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀.—Òwe 5:8.
Òwe orí keje sọ ewu tó wà nínú ká máa fojú kéré ìkìlọ̀ yìí, ó sọ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó gbafẹ́ jáde, àmọ́ tó lọ gba ọ̀nà ilé obìnrin aṣẹ́wó kan kọjá. Ó mà ṣe o, wọ́n bá ara wọn ṣèṣekúṣe. Ká ní ó sá fún obìnrin oníṣekúṣe yìí ni, ì bá má ti kó sí wàhálà yìí! (Òwe 7:6-27) Àwa náà lè hùwà láìlo ìfòyemọ̀, tí a bá lọ fi ara wa sínú àwọn ipò tó lè mú kó máa wù wá láti ṣe ìṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan lè gbé ohunkóhun tó wù wọ́n jáde sórí afẹ́fẹ́ ní òru. Tó bá wá jẹ́ pé ìgbà yẹn là ń wá àwọn ètò tí wọ́n ń ṣe lóríṣiríṣi lórí tẹlifíṣọ̀n ńkọ́? Àbí kó jẹ́ pé, ńṣe la kàn ń ṣí ìlujá tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí àwọn ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti àwọn ìkànnì míì tí wọ́n fi ń peni wá wo àwọn àwòrán, orin tàbí fídíò tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ, àbí tó ń fi ìbálòpọ̀ lọni. Tá a bá ṣe èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí, ó ṣeé ṣe ká rí ohun tó lè mú kó máa wù wá láti ṣe ìṣekúṣe, kó sì wá nira fún wa láti jẹ́ oníwà mímọ́. w15 6/15 3:8, 9
Tuesday, May 16
Dárí àwọn gbèsè wa jì wá.—Mát. 6:12.
Kí nìdí tí Jésù fi lo ọ̀rọ̀ náà “gbèsè,” nígbà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀” ló lò nígbà míì tó ń sọ̀rọ̀? (Mát. 6:12; Lúùkù 11:4) Ní ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ ṣàlàyé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin Ọlọ́run mú ká jẹ Ọlọ́run ní gbèsè. . . . Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, Ọlọ́run lè gba ẹ̀mí wa. . . . Ó lè mú àlááfíà rẹ̀ kúrò lára wa, kó sì já gbogbo àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ kúrò. . . . A jẹ ẹ́ ní gbèsè ìfẹ́, ìgbọ́ràn wa ló sì máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀; tí a bá wá dá ẹ̀ṣẹ̀, a ti kùnà láti san gbèsè ìfẹ́ wa fún un nìyẹn, kò sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí a bá ń dá ẹ̀ṣẹ̀.” (1 Jòh. 5:3) Nítorí pé a ní láti máa tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lójoojúmọ́, Ọlọ́run pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù tó jẹ́ ìlànà kan ṣoṣo tó bá òfin mu tí Jèhófà lè fi pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún tí ìràpadà náà ti wáyé, ó yẹ ká mọrírì rẹ̀ bí ẹni pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i gbà lónìí. “Iye owó ìtúnràpadà” tí Jésù san “ṣe iyebíye tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́” tó fi jẹ́ pé kò sí ohunkóhun tí ẹ̀dá èèyàn aláìpé èyíkéyìí lè ṣe fún wa tó lè sún mọ́ àtisan ìràpadà náà.—Sm. 49:7-9; 1 Pét. 1:18, 19. w15 6/ 15 5:9, 10
Wednesday, May 17
Èmi yóò sì ṣe àyè ẹsẹ̀ mi gan-an lógo.—Aísá. 60:13.
Ẹ wo bó ṣe máa ń dùn mọ́ni tó láti lo àwọn ìwé tó wúlò tó sì fani mọ́ra lóde ẹ̀rí! Bá a sì ṣe ń lo àwọn ohun èlò ìgbàlódé bí Ìkànnì jw.org láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn èèyàn níbi gbogbo ń rí i kedere pé Jèhófà fẹ́ láti máa fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tí ọ̀pọ̀ lára wọ́n nílò lójú méjèèjì. Kò yẹ ká gbàgbé ìyípadà tó wáyé tó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé tàbí ká ní àkókò púpọ̀ sí i fún ìdákẹ́kọ̀ọ́. A sì tún mọrírì àwọn ìyípadà tó ti dé bá àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè wa. À ń rí i pé ọdọọdún ni wọ́n ń dáa sí i. Ayọ̀ wa sì tún ń pọ̀ sí i bá a ṣe ń rí ìdálẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i gbà ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run. Ọwọ́ Jèhófà hàn kedere nínú gbogbo ìyípadà tó ń wáyé náà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ń fi kún ẹwà ètò rẹ̀ àti ti Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn báyìí. w15 7/15 1:16, 17
Thursday, May 18
Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ . . . aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.—Lúùkù 10:27.
Tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀, tó ò sì mọ ohun tó yẹ kó o ṣe, ó máa dáa kó o bi ara rẹ pé, ‘Ká ní Jésù ni irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, kí ló máa ṣe?’ Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó gbé láàárín àwọn èèyàn tó wá láti àgbègbè tó yàtọ̀ síra, irú bíi Jùdíà, Gálílì, Samáríà àti àwọn ìlú míì. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbọ́nmi-si-omi-ò-to wà láàárín àwọn èèyàn wọ̀nyí. (Jòh. 4:9) Gbọ́nmi-si-omi-ò-to tún wà láàárín àwọn Farisí àti àwọn Sadusí (Ìṣe 23:6-9); ó wà láàárín àwọn èèyàn àti àwọn agbowó orí (Mát. 9:11); ó sì tún wà láàárín àwọn tó lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn Rábì àti àwọn tí kò lọ. (Jòh. 7:49) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, abẹ́ ìjọba Róòmù ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà, inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í sì í dùn láti rí wọn. Ìwàásù Jésù dá lórí ìsìn tòótọ́, ó sì fi hàn pé ìgbàlà pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn Júù, síbẹ̀ kò sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa dá àríyànjiyàn sílẹ̀. (Jòh. 4:22) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n fẹ́ràn àwọn aládùúgbò wọn gẹ́gẹ́ bí ara wọn. w15 7/15 3:5
Friday, May 19
Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe? Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láàárín àwọn tí ń ràn mí lọ́wọ́.—Sm. 118:6, 7.
Nítorí bí Ọlọ́run ṣe dá àwa èèyàn, a máa ń fìfẹ́ hàn, a sì máa ń fẹ́ káwọn míì nífẹ̀ẹ́ wa. Ó rọrùn láti rẹ̀wẹ̀sì torí àwọn ohun àìròtẹ́lẹ̀ tàbí ìjákulẹ̀, àìsàn, ìṣòro ìṣúnná owó, tàbí tí àwọn èèyàn ò bá fetí sí iṣẹ́ ìwàásù wa. Tá a bá ń ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa mọ́, ó máa dáa ká rántí pé a ṣeyebíye lójú rẹ̀ àti pé kò gbàgbé wa, ó ń “di ọwọ́ ọ̀tún [wa] mú” ó sì ń ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin, ó dájú pé kò ní gbàgbé wa láé. (Aísá. 41:13; 49:15) Arábìnrin Brigitte, tó dá tọ́ ọmọ méjì lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ kú, sọ pé: “Kéèyàn máa tọ́mọ nínú ayé Sátánì yìí jẹ́ ọ̀kan lára ìṣòro tó le jù lọ téèyàn lè dojú kọ, pàápàá òbí tó ń dá tọ́mọ bíi tèmi. Àmọ́, ó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi torí pé kò fi mí sílẹ̀ nígbà ìbànújẹ́ àti ìrora ọkàn, kò sì jẹ́ kí ohun tí mi ò lè mú mọ́ra ṣẹlẹ̀ sí mi.”—1 Kọ́r. 10:13. w15 8/15 1:1-3
Saturday, May 20
Máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà.—Háb. 2:3.
Ọlọ́run sọ fún wòlíì Hábákúkù pé kó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù. Kí Hábákúkù tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ tiẹ̀, àwọn wòlíì míì ti kéde fún ọ̀pọ̀ ọdún pé ìlú náà máa pa run. Ọ̀rọ̀ sì ti burú débi pé ‘ẹni burúkú ti yí olódodo ká, ìdájọ́ òdodo sì ti jáde lọ ní wíwọ́.’ Torí náà, kò yani lẹ́nu pé Hábákúkù béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́?” Jèhófà fi dá wòlíì olóòótọ́ náà lójú pé ìparun tó sọ tẹ́lẹ̀ náà “kì yóò pẹ́.” (Háb. 1:1-4) Ká sọ pé Hábákúkù rẹ̀wẹ̀sì tó sì wá ń ronú pé: ‘Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti ń gbọ́ pé Jerúsálẹ́mù máa pa run. Bó bá máa pẹ́ kí ìparun náà tó dé ńkọ́? Mi ò rò pé ó bọ́gbọ́n mu kí n máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ẹni pé ìlú náà máa pa run lójijì. Àwọn míì ni màá jẹ́ kó ṣèyẹn.’ Bó bá jẹ́ pé nǹkan tí Hábákúkù ń rò lọ́kàn nìyẹn, ì bá ti pàdánù ojúure Jèhófà, ó sì ṣeé ṣe kó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí àwọn ará Bábílónì wá pa Jerúsálẹ́mù run. w15 8/15 2:12, 13
Sunday, May 21
Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.—1 Kọ́r. 15:33.
Kí ìwà rere wa má bàa bà jẹ́, a kò gbọ́dọ̀ máa bá àwọn tó ń hùwà búburú kẹ́gbẹ́. Kì í ṣe àwọn oníwà àìtọ́ tí kì í ṣe Kristẹni nìkan ni kò yẹ ká máa bá kẹ́gbẹ́ o, kò tún yẹ ká máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó pera wọn ní ìránṣẹ́ Jèhófà ṣùgbọ́n tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣàìgbọràn sí àwọn òfin rẹ̀. Bí irú àwọn tó pera wọn ní Kristẹni bẹ́ẹ̀ bá lọ́wọ́ sí ìwà àìtọ́ tó burú jáì tí wọn kò sì ronú pìwà dà, a gbọ́dọ̀ dẹ́kun bíbá wọn kẹ́gbẹ́. (Róòmù 16:17,18) Tá a bá ń bá àwọn tí kì í ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run kẹ́gbẹ́, àá fẹ́ máa ṣe bíi tiwọn, kí wọ́n lè gba tiwa. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn oníṣekúṣe, ó lè máa wu àwa náà pé ká ṣèṣekúṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ nìyẹn, wọ́n sì yọ àwọn kan lára wọn lẹ́gbẹ́ torí pé wọn kò ronú pìwà dà. (1 Kọ́r. 5:11-13) Bí wọn kò bá ronú pìwà dà, ọ̀rọ̀ wọn lè dà bíi ti àwọn tí Pétérù mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.—2 Pét. 2:20-22. w15 8/15 4:4-6
Monday, May 22
Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.—Jòh. 15:14.
Jésù yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láàárín àwọn adúróṣinṣin tí wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, tí wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà. Ṣé àwọn tó ń sin Jèhófà láìyẹsẹ̀ ni ìwọ náà ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Ìwà ọ̀yàyà ẹgbẹ́ àwọn ará wa máa ń mú ká dàgbà dénú. O lè jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń gbìyànjú láti pinnu ohun tó o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe. Wo bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé kó o máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tí wọ́n sì ń pa kún ìṣọ̀kan ìjọ! Láti ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti ń sìn, wọ́n lè ti dojú kọ àwọn ìṣòro kan tàbí kí wọ́n ti borí àwọn ìpèníjà kan tí wọ́n bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè yan ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ irú àwọn arákùnrin àti arábìnrin bẹ́ẹ̀ tó o sì ń bá wọn kẹ́gbẹ́, wàá lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, wàá sì dàgbà dénú.—Héb. 5:14. w15 9/15 1:14, 15
Tuesday, May 23
Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Èṣù] ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. —1 Pét. 5:9.
Jésù gbé ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ró nípasẹ̀ ohun tó sọ àti ohun tó ṣe. (Máàkù 11:20-24) Ó ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù torí pé bá a ṣe ń gbé ìgbàgbọ́ àwọn míì ró, bẹ́ẹ̀ la ó máa fún ìgbàgbọ́ tiwa náà lókun. (Òwe 11:25) Bó o ṣe ń wàásù tó o sì ń kọ́ni, jẹ́ káwọn èèyàn máa rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún àti pé Bíbélì ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí. Máa gbé ìgbàgbọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ ró. Bó o bá rí i pé àwọn kan fẹ́ máa ṣiyè méjì, bóyá tí wọ́n ń ráhùn nípa àwọn arákùnrin tá a yàn sípò, má ṣe tètè pa wọ́n tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, fọgbọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́, kó o sì wá bó o ṣe máa gbé ìgbàgbọ́ wọn ró. (Júúdà 22, 23) Tó o bá wà níléèwé, tí wọ́n sì ń jíròrò ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, fìgboyà sọ ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá. Ipa tí ọ̀rọ̀ rẹ máa ní lórí olùkọ́ rẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà ní kíláàsì lè jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ẹ. Jèhófà ń ràn gbogbo wá lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. (1 Pét. 5:10) Gbogbo ìsapá tá a bá ṣe láti gbé ìgbàgbọ́ wa ró tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ torí pé èrè tó máa tibẹ̀ wá ò láfiwé. w15 9/15 3:20, 21
Wednesday, May 24
Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.—Sm. 19:1.
Lónìí, a ní òye púpọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá àti bó ṣe ń mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Kíkàwé rẹpẹtẹ àti lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga layé ń gbé lárugẹ. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ti rí i pé lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga sábà máa ń mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ àwọn rì, kí ìfẹ́ tí àwọ́n ní fún Ọlọ́run sì jó rẹ̀yìn. Àmọ́ Bíbélì rọ̀ wá pé ká nífẹ̀ẹ́ ìmọ̀ ká sì tún ní ọgbọ́n àti òye. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ká kọ́ bá a ṣe máa lo ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún wa lọ́nà tó máa ṣe àwa àti àwọn míì láǹfààní. (Òwe 4:5-7) “Ìfẹ́” Ọlọ́run ni “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) A máa ń fi ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà hàn nípa fífi gbogbo ọkàn wa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé.—Sm. 66:16, 17. w15 9/15 5:10, 11
Thursday, May 25
Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa.—Róòmù 15:4.
Èlíjà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Bíbélì sọ pé ó ní ìgbàgbọ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jèhófà. Nígbà tí Èlíjà sọ fún Áhábù Ọba pé Jèhófà máa mú ọ̀dá wá, Èlíjà fi ìdánilójú sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, . . . kì yóò sí ìrì tàbí òjò . . . bí kò ṣe nípa àṣẹ ọ̀rọ̀ mi!” (1 Ọba 17:1) Ó dá Èlíjà lójú pé Jèhófà máa pèsè gbogbo ohun tí òun àtàwọn míì nílò lásìkò ọ̀dá náà. (1 Ọba 17:4, 5, 13, 14) Ó gbà pé Jèhófà lè jí ọmọ kan tó ti kú dìde. (1 Ọba 17:21) Ó dá a lójú pé Jèhófà máa fi iná jó ọrẹ ẹbọ rẹ̀ lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì. (1 Ọba 18:24, 37) Nígbà tí àsìkò tó lójú Jèhófà láti fòpin sí ọ̀dá náà, kódà kí Èlíjà tó gbọ́ kíkù òjò kankan, ó sọ fún Áhábù pé: “Gòkè lọ, kí o jẹ, kí o sì mu; nítorí ìró ìkùrìrì eji wọwọ ń bẹ.” (1 Ọba 18:41) Ǹjẹ́ àwọn ohun tí Èlíjà ṣe yìí kò ní mú káwa náà yẹ ara wa wò, ká lè mọ̀ bóyá a ní ìgbàgbọ́ tó lágbára bíi tiẹ̀? w15 10/15 2:4, 5
Friday, May 26
Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí.—1 Tím. 4:15.
Èdè jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Jèhófà ló mú kó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti kọ́ ọ, ká sì máa lò ó. (Sm. 139:14; Ìṣí. 4:11) Síbẹ̀, ọ̀nà pàtàkì míì wà tí ọpọlọ wa gbà ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọlọ́run dá wa ní “àwòrán” ara rẹ̀, ìyẹn ló sì mú ká yàtọ̀ pátápátá sáwọn ẹranko. A ní òmìnira láti pinnu ohun tá a bá fẹ́, a sì lè fi èdè tá a gbọ́ yin Ọlọ́run lógo. (Jẹ́n. 1:27) Ọlọ́run tún fún gbogbo àwọn tó fẹ́ máa bọlá fún un ní ẹ̀bùn àgbàyanu kan, ìyẹn Bíbélì. Odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ ti wà ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [2,800]. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Sm. 40:5; 92:5; 139:17) Nípa bẹ́ẹ̀, wàá máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan “tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” (2 Tím. 3:14-17) Ẹni tó bá ń ṣàṣàrò máa ń pọkàn pọ̀, ó sì máa ń fẹ̀sọ̀ ronú lé nǹkan lórí. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ohun tó dára tàbí ohun tó burú. (Sm. 77:12; Òwe 24:1, 2) Àwọn méjì tó dára jù lọ tá a lè ṣàṣàrò lé lórí ni Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. —Jòh. 17:3. w15 10/15 4:2-4
Saturday, May 27
Bí ọkùnrin èyíkéyìí kò bá mọ agbo ilé ara rẹ̀ bójú tó, báwo ni yóò ṣe bójú tó ìjọ Ọlọ́run?—1 Tím. 3:5.
Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́rọ̀ àti níṣe pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́. (Lúùkù 22:27) Ó kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n máa yááfì àwọn nǹkan nítorí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti nítorí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Tí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ bá ń mú kí ìwọ náà yááfì àwọn nǹkan, àwọn ọmọ rẹ á kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ. Arábìnrin Debbie tó lọ́mọ méjì sọ pé: “Alàgbà ni ọkọ mi, tó bá ń wáyè láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, mi ò kí ń jowú. Mo mọ̀ pé tó bá tó àsìkò láti gbọ́ tiwa, ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.” Arákùnrin Pranas tó jẹ́ ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Nígbà tó yá, inú àwọn ọmọ wa máa ń dùn láti yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ní àpéjọ, kí wọ́n sì tún ṣe àwọn iṣẹ́ míì nínú ètò Ọlọ́run. Inú wọn máa ń dùn yùngbà, wọ́n lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀, wọ́n sì rí i pé àwọn wúlò nínú ètò Ọlọ́run!” Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni gbogbo ìdílé náà ń ṣe báyìí. Tó o bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tó o sì máa ń yááfì nǹkan nítorí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, àwọn ọmọ rẹ á kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ, àwọn náà á sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́. w15 11/15 1:9
Sunday, May 28
Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.—Róòmù 1:20.
Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí wa. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bí àgbáálá ayé wa yìí ti lẹ́wà tó, tó sì tún fẹ̀ lọ salalu. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ló wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀ àti pílánẹ́ẹ̀tì nínú. Nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ayé yìí wà, ọ̀kan lára àwọn ìràwọ̀ tó wà níbẹ̀ ni oòrùn. Láìsí oòrùn, kò ní ṣeé ṣe fún ohun alààyè kankan láti wà lórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá yìí fi hàn pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, wọ́n sì tún jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní, irú bí agbára, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Ọlọ́run dá ayé lọ́nà táá mú kó ṣeé ṣe fún àwọn nǹkan tó dá sínú rẹ̀ láti máa wà láàyè nìṣó. Nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn, ó fi wọ́n sínú Párádísè ẹlẹ́wà kan, ó sì fún wọn ní ọpọlọ àti ara pípé tó máa mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti gbé títí láé. (Ìṣí. 4:11) Síbẹ̀, ó “ń fi oúnjẹ fún gbogbo ẹlẹ́ran ara: Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sm. 136:25. w15 11/15 3:7, 8
Monday, May 29
Mo wà pẹ̀lú yín.—Mat. 28:20.
Láti àwọn ọdún yìí wá, Ọba Ìjọba Ọlọ́run ti fún wa ní àwọn ohun èlò táá mú kó rọrùn fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tá à ń wàásù fún láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àkókò díẹ̀ la fi lo àwọn kan lára àwọn ohun èlò yìí, àwọn míì sì wà lára wọn tá a ṣì ń lò títí di báyìí. Àmọ́, gbogbo ohun èlò yìí ti mú ká di ajíhìnrere tó túbọ̀ já fáfá lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ohun èlò kan tó ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ni káàdì ìjẹ́rìí. Ọdún 1933 làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í lo káàdì náà. Káàdì ìjẹ́rìí náà mú kó rọrùn fáwọn akéde láti wàásù. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń wu àwọn akéde kan láti máa wàásù, àmọ́ ojú máa ń tì wọ́n, wọn ò sì mọ ohun tí wọ́n á sọ. Bẹ́ẹ̀, àwọn akéde míì máa ń fẹ́ sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn fún onílé láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ wọn kì í wọ àwọn onílé lọ́kàn. Ṣùgbọ́n, káàdì ìjẹ́rìí tó ní àṣàyàn ọ̀rọ̀ ṣókí nínú yìí ran gbogbo akéde lọ́wọ́ láti wàásù lọ́nà tó ṣe kedere tí kò sì lọ́jú pọ̀. w15 11/15 5:3-6
Tuesday, May 30
Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà.—Sm. 148:13.
Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì jẹ́ ká rí i pé orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì àti pé ó yẹ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà kí wọ́n sì máa lò ó. (Ẹ́kís. 3:15; Sm. 83:18; Aísá. 42:8; 43:10; Jòh. 17:6, 26; Ìṣe 15:14) Jèhófà Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti lo orúkọ rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. (Ìsí. 38:23) Bí àwọn atúmọ̀ èdè bá wá yọ orúkọ tó fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ yìí kúrò nínú ìtumọ̀ wọn, á jẹ́ pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run nìyẹn, torí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Bíbélì. Ńṣe ni àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé a ò gbọ́dọ̀ yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìgbà ẹgbẹ̀rún méje ó lé igba àti mẹ́rìndínlógún [7,216] ni orúkọ náà fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2013, ìyẹn sì fi ìgbà mẹ́fà lé sí iye ìgbà tó fara hàn nínú ti ọdún 1984. Márùn-ún nínú àwọn ẹsẹ tó ti fara hàn ni 1 Sámúẹ́lì 2:25; 6:3; 10:26; 23:14, 16. Ìdí tá a sì fi dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí àwọn ẹsẹ yìí ni pé wọ́n fara hàn nínú àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú tó ti wà ní èyí tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún kan ṣáájú kí ìwé àwọn Másọ́rẹ́tì lédè Hébérù tó wà. Ibì kan tó kù tá a tún dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí wà nínú Àwọn Onídàájọ́ 19:18, a sì dá a pa dà síbẹ̀ torí ìwádìí tá a ṣe síwájú sí i nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́. w15 12/15 2:5, 6
Wednesday, May 31
Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.—Héb. 13:1.
Àfi ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa nísinsìnyí torí pé ìyẹn ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí tá a lè kojú lọ́jọ́ iwájú. Lónìí, ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa kódà kí ìpọ́njú ńlá tó dé. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń jìyà torí àwọn àjálù bí ìsẹ̀lẹ̀, àkúnya omi, ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ òkun àtàwọn jàǹbá míì. Àwọn ará wa kan sì ń fara da inúnibíni. (Mát. 24:6-9) Àtijẹ àtimu ń le sí i torí pé inú ayé oníwà ìbàjẹ́ là ń gbé. (Ìṣí. 6:5, 6) Síbẹ̀, bí ìṣòro àwọn ará wa bá ṣe ń peléke sí i, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ ká túbọ̀ máa fi hàn bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó. Báwọn èèyàn ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn nínú ayé yìí, ó yẹ kí àwa Kristẹni tòótọ́ máa fìfẹ́ hàn síra wa.—Mát. 24:12. w16.01 1:8, 9