August
Tuesday, August 1
Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?—Jẹ́n. 18:25.
Àjọṣe tí Ábúráhámù ní pẹ̀lú Jèhófà ń lágbára sí i torí pé gbogbo ìgbà ni Ábúráhámù máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà. Ábúráhámù gbà pé kò sóhun tóun ò lè bá Jèhófà sọ, ó tiẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ nígbà tí ohun kan ń dùn ún lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ọkàn Ábúráhámù ò balẹ̀ nígbà tí Jèhófà sọ pé òun máa pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run. Kí ló fà á? Ẹ̀rù ń bà á kí àwọn èèyàn rere má lọ bá ìparun náà lọ. Ó sì ṣeé ṣe kí ọkàn rẹ̀ má balẹ̀ torí Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tóun àti ìdílé rẹ̀ ń gbé nílùú Sódómù. Ábúráhámù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé,” torí náà, ó bá Jèhófà sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nípa ohun tó ń dùn ún lọ́kàn. Jèhófà mú sùúrù fún ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere sí i pé aláàánú lòun. Jèhófà jẹ́ kó yé e pé bí òun bá tiẹ̀ fẹ́ mú ìdájọ́ wá, òun á wá àwọn èèyàn rere kóun lè gbà wọ́n là. (Jẹ́n. 18:22-33) Kò sí àní-àní pé gbogbo ohun tí Ábúráhámù kọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ni kò jẹ́ kí àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà yingin. w16.02 1:11, 12
Wednesday, August 2
Kí Jèhófà fúnra rẹ̀ wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín ọmọ mi àti ọmọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.—1 Sám. 20:42.
Inú wa máa ń dùn tá a bá rí àwọn adúróṣinṣin. Àmọ́, ṣé torí pé Jónátánì jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì nìkan la fi fẹ́ràn rẹ̀? Rárá, ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé Jónátánì ni bó ṣe máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Ìdí ẹ̀ sì nìyẹn tí Jónátánì fi jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì tí kò sì jowú rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì máa jọba dípò rẹ̀. Kódà, Jónátánì ran Dáfídì lọ́wọ́ kó lè gbára lé Jèhófà. Àwọn méjèèjì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, wọn ò sì dalẹ̀ ara wọn. Àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn tó wà nínú ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn ará nínú ìjọ. (1 Tẹs. 2:10, 11) Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ó ṣe tán, òun ló dá wa. (Ìṣí. 4:11) A máa ń láyọ̀, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àmọ́, a mọ̀ pé ó ṣì yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run kódà láwọn ìgbà tí nǹkan ò bá rọgbọ. w16.02 3:3, 4
Thursday, August 3
Dáníẹ́lì pinnu ní ọkàn-àyà rẹ̀ pé òun kì yóò sọ ara òun di eléèérí.—Dán. 1:8.
Ọ̀dọ́ kan tó dàgbà dénú ò ní máa ṣiyè méjì nípa ohun tó gbà gbọ́, kódà nígbà tí nǹkan bá le koko. Kò ní máa ṣe bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kó wá dé iléèwé kó máa ṣohun táyé ń fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ṣe ohun tó tọ́ bí wọ́n bá dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò. (Éfé. 4:14, 15) A kì í mọ̀ ọ́n rìn kórí má mì. Tọmọdé tàgbà wa ló máa ń ṣàṣìṣe. (Oníw. 7:20) Àmọ́, tó o bá fẹ́ ṣèrìbọmi, á dáa kó o ronú jinlẹ̀ dáadáa kó o lè mọ̀ bóyá o ti ṣe tán láti ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Jèhófà. O lè bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà ní gbogbo ìgbà?’ Ronú nípa ohun tó o ṣe nígbà tẹ́nì kan dán ìgbàgbọ́ rẹ wò kẹ́yìn. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ẹ láti pinnu ohun tó yẹ kó o ṣe? Bí àpẹẹrẹ, Dáníẹ́lì ò gbéra ga torí ẹ̀bùn tó ní. Ìwọ náà ńkọ́? Kí lo máa ṣe bí ẹnì kan bá gbà ẹ́ níyànjú pé kó o lo ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ tó o ní nínú ayé Sátánì? Bí ohun tó sọ yẹn bá mú kó wù ẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe?—Éfé. 5:17. w16.03 1:7-9
Friday, August 4
Ọjọ́ wọnnì yóò jẹ́ àwọn ọjọ́ ìpọ́njú irúfẹ́ èyí ti kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá títí di àkókò yẹn.—Máàkù 13:19.
“Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí, ìpọ́njú ńlá tí ò tíì sírú ẹ̀ rí sì máa tó bẹ̀rẹ̀. (2 Tím. 3:1) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run, ó ti lé wọn jù sáyé, wàhálà ńlá sì nìyẹn fà bá aráyé. (Ìṣí. 12:9, 12) Ohun mìíràn sì tún ni pé à ń pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká wàásù fáwọn èèyàn jákèjádò ayé ní èdè tó pọ̀ sí i! Kí Ọlọ́run lè bù kún wa, a gbọ́dọ̀ máa fiyè sí gbogbo ìtọ́ni tí Ọlọ́run ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fún wa. Tó bá ti mọ́ wa lára láti máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yẹn nísinsìnyí, á rọrùn fún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tá ó máa rí gbà nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí Jèhófà máa pa ayé búburú tí Sátánì ń darí yìí run. (Mát. 24:21) Lẹ́yìn ìyẹn, a tún máa nílò àwọn ìtọ́ni tuntun tá ó máa tẹ̀ lé nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. w16.03 4:16, 18
Saturday, August 5
Àwọn eéṣú jáde wá . . . láti inú èéfín náà.—Ìṣí. 9:3.
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àpọ́sítélì Jòhánù rí àwọn áńgẹ́lì méje kan nínú ìran tí wọ́n ń fun kàkàkí. Nígbà tí áńgẹ́lì karùn-ún fun kàkàkí rẹ̀, Jòhánù rí “ìràwọ̀ kan tí ó ti jábọ́ láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé.” “Ìràwọ̀” yẹn fi kọ́kọ́rọ́ kan ṣí kòtò jíjìn kan tó ṣókùnkùn biribiri. Èéfín ńlá kan ló kọ́kọ́ rú jáde látinú kòtò náà, lẹ́yìn náà ni ọ̀wọ́ àwọn eéṣú wá jáde wá látinú èéfín náà. Dípò tí àwọn eéṣú yìí ì bá fi bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àwọn igi tàbí àwọn ewéko run, àwọn èèyàn tí “kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn” ni wọ́n ya bò. (Ìṣí. 9:1-4) Jòhánù mọ̀ pé ọṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn eéṣú máa ń ṣe; wọ́n ti pitú nílẹ̀ Íjíbítì nígbà ayé Mósè. (Ẹ́kís. 10:12-15) Àwọn eéṣú tí Jòhánù rí dúró fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ń kéde ìdájọ́ Ọlọ́run sórí ìsìn èké. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé náà sì ti dara pọ̀ mọ́ wọn láti máa wàásù. Iṣẹ́ ìwàásù yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ìsìn èké sílẹ̀, ó sì ti dá wọn sílẹ̀ kúrò lóko ẹrú Sátánì. w16.03 3:3
Sunday, August 6
La ojú mi, kí n lè máa wo àwọn ohun àgbàyanu láti inú òfin rẹ.—Sm. 119:18.
Tí alàgbà kan bá fẹ́ mọ bí arákùnrin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ Ìjọba náà darí èrò àti ìṣe rẹ̀ tó, ó lè bi í pé, ‘Báwo ni bó o ṣe ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà ṣe ti yí ọ̀nà tó o gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ pa dà?’ Ìbéèrè yẹn lè jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó gbámúṣé nípa ìdí tí a fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa tọkàntọkàn. (Máàkù 12:29, 30) Ní ìparí ọ̀rọ̀ wọn, alàgbà náà lè gbàdúrà, kó sì bẹ Jèhófà pé kó fún arákùnrin náà ní ẹ̀mí mímọ́ tó nílò kó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu ìdálẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Bí arákùnrin náà ṣe ń gbọ́ tí alàgbà náà ń gbàdúrà látọkàn wá nítorí rẹ̀ máa fún un níṣìírí gan-an ni. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, alàgbà náà lè jíròrò àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì kan tó máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà rí ìdí tó fi yẹ kóun múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́, kóun ṣeé gbára lé, kóun sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (1 Ọba 19:19-21; Neh. 7:2; 13:13; Ìṣe 18:24-26) Ó ṣe pàtàkì pé kí akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìwà yẹn bó ṣe ṣe pàtàkì pé kí àgbẹ̀ fi ajílẹ̀ sílẹ̀ tó fẹ́ fi dáko. Wọ́n máa jẹ́ kó tètè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, wọ́n á sì jẹ́ kí ‘ojú rẹ̀ là’ sí “àwọn ohun àgbàyanu” tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. w15 4/15 2:3, 4
Monday, August 7
Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run.—Ják. 4:8.
Tá a bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá a sọ̀rọ̀ déédéé. Báwo lo ṣe lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, kó o sì tún gbọ́ ohun tó ń bá ẹ sọ? Ọ̀nà tó o lè gbà bá Jèhófà sọ̀rọ̀ ni kó o máa gbàdúrà sí i déédéé. (Sm. 142:2) O sì ń jẹ́ kí Jèhófà bá ẹ sọ̀rọ̀ tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó o sì ń ṣàṣàrò lé e lórí déédéé. (Aísá. 30:20, 21) Tí àdúrà rẹ bá ṣe pàtó, ìdáhùn Jèhófà sí àdúrà rẹ á ṣe kedere sí ẹ, kódà bí kò tiẹ̀ hàn sójú táyé. Bí o bá sì ṣe ń rí i tí Jèhófà ń dáhùn àdúrà rẹ ni á túbọ̀ máa jẹ́ ẹni gidi sí ẹ. Bákan náà, bí o ṣe túbọ̀ ń sọ ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn fún Jèhófà, á máa sún mọ́ ẹ sí i. Gbogbo ọjọ́ ayé wa ló yẹ ká máa sapá láti mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i. Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run sún mọ́ wa, a gbọ́dọ̀ máa sapá láti sún mọ́ ọn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá Ọlọ́run wa sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo nípa gbígbàdúrà sí i, ká sì máa tẹ́tí sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àjọṣe àwa àti Jèhófà á máa lágbára sí i, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú àwọn ìṣòro wa. w15 4/15 3:3, 14, 16
Tuesday, August 8
Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.—1 Pét. 5:8.
Ẹ ò rí i pé àpèjúwe tí ẹsẹ ojúmọ́ tòní lò yìí bá Sátánì àti ìwà ìkà rẹ̀ mu gan-an! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ti wà níkàáwọ́ Sátánì, ó ṣì ń wá àwọn èèyàn tó máa pa jẹ. Ohun tó wà lọ́kàn Sátánì ni bó ṣe máa pa àwọn èèyàn Jèhófà jẹ. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ inúnibíni tí wọ́n ṣe sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní títí di ìsinsìnyí fi hàn pé ìkà ni Sátánì. Kìnnìún tí ebi ń pa kì í ṣàánú ẹran tó fẹ́ pa jẹ. Kì í ṣàánú ẹran náà kó tó pa á, bẹ́ẹ̀ sì ni inú rẹ̀ kì í bà jẹ́ lẹ́yìn tó bá ti pa á. Lọ́nà kan náà, Sátánì kì í ṣàánú àwọn tó fẹ́ pa jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ọ̀pọ̀ ìgbà tí Sátánì Èṣù máa ń lúgọ de àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí wọ́n á fi dẹ́ṣẹ̀, irú bí ìwà wọ̀bìà àti ìṣekúṣe. Nígbà tó o bá kà nípa aburú tó dé bá Símírì oníṣekúṣe àti Géhásì olójúkòkòrò, ǹjẹ́ o kì í “rí” bí kìnnìún tó ń bú ramúramù yẹn ṣe ń ju ìrù tí inú rẹ̀ sì ń dùn torí pé ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ ohun tó ń wá?—Núm. 25:6-8, 14, 15; 2 Ọba 5:20-27. w15 5/15 1:8, 9
Wednesday, August 9
Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.—Ják. 4:7.
Báwo la ṣe lè bá Sátánì jà ká sì borí? Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nípasẹ̀ ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ ó fi jèrè ọkàn yín.” (Lúùkù 21:19) Kò sí ìpalára tí ẹ̀dá èèyàn kan lè ṣe sí wa tó máa kọjá àtúnṣe. Kò sẹ́ni tó lè ba àárín àwa àti Ọlọ́run jẹ́ àyàfi tá a bá fàyè gbà á. (Róòmù 8:38, 39) Kódà bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá tiẹ̀ kù, ìyẹn ò fi hàn pé Sátánì ti jáwé olúborí, torí pé Jèhófà á rí i pé òun jí wọn dìde! (Jòh. 5:28, 29) Àmọ́ ọjọ́ iwájú Sátánì kò ní dáa rárá. Lẹ́yìn tí ayé búburú yìí bá ti pa run, Jésù máa fi Sátánì sẹ́wọ̀n fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún. (Ìṣí. 20:1-3) Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Jésù, a máa ‘tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀’ fúngbà díẹ̀ láti gbìyànjú ìkẹyìn bóyá á lè ṣi aráyé tó ti di pípé lọ́nà. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù máa pa Èṣù run. (Ìṣí. 20:7-10) Ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Sátánì, àmọ́ ó dájú pé mìmì kan kò ní mì ọ́! Torí náà, gbéjà ko Sátánì, dúró gbọin nínú ìgbàgbọ́. (1 Pét. 5:9) Ó dájú pé o lè bá Sátánì jà, kó o sì borí! w15 5/15 2:1, 18
Thursday, August 10
Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.—Òwe 22:3.
Afọgbọ́nhùwà mọ̀ pé ìrònú èèyàn lè dà bí iná. Téèyàn bá lo iná bó ṣe yẹ, ó máa ń wúlò, bí àpẹẹrẹ a lè fi iná se oúnjẹ. Àmọ́, iná lè fa jàǹbá tá ò bá lò ó lọ́nà tó tọ́, ó lè jó ilé kan run, kó sì pa àwọn tó wà níbẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ronú lọ́nà tó tọ́, èyí lè jẹ́ ká fìwà jọ Jèhófà. Àmọ́ o, tá a bá ń ro èrò tí kò tọ́, ó lè pa wá lára. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa ronú lórí ohun tó lè múni dẹ́ṣẹ̀, èyí lè sún wa débi tá a fi máa ṣe ohun tá à ń rò lọ́kàn. Àní sẹ́, èrò tí kò tọ́ lè pa àjọṣe àwa àti Jèhófà lára! (Ják. 1:14, 15) Jésù kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe máa ro ohun tó lè mú kí ọkàn wa fà sí ìṣekúṣe. Ó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Mát. 5:28. w15 5/15 4:11, 12, 14
Friday, August 11
Ohun tí mo . . . ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.—Òwe 8:31.
Jálẹ̀ gbogbo iṣẹ́ ìwàásù Jésù, àwọn ẹ̀rí tó ṣe kedere wà tó fi hàn pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ìran èèyàn dénúdénú. Nígbà kan, ó rí ohun kan tó ṣe é láàánú gan-an. (Máàkù 1:39, 40) Ọkùnrin kan wà níwájú rẹ̀ tó ní àrùn kan tó ń lé àwọn èèyàn sá, ìyẹn àrùn ẹ̀tẹ̀. Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn jẹ́rìí sí i pé àìsàn ọkùnrin náà ti burú gan-an, ó sọ pé ọkùnrin náà “kún fún ẹ̀tẹ̀.” (Lúùkù 5:12) “Nígbà tí ó tajú kán rí Jésù, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́, ó wí pé: ‘Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.’ ” Ọkùnrin yẹn mọ̀ dájú pé Jésù lágbára tó fi lè wo òun sàn, àmọ́ ohun tó fẹ́ mọ̀ ni pé, ṣé ó wu Jésù kó wo òun sàn? Kí ni Jésù máa ṣe sí ohun tí ọkùnrin yìí ń fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún? Jésù na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó fi kan adẹ́tẹ̀ náà, ó sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ó fẹ́ ṣèrànwọ́ àti pé ó káàánú ọkùnrin náà, ó sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Lẹ́yìn náà, “ẹ̀tẹ̀ náà sì pòórá kúrò lára rẹ̀.” (Lúùkù 5:13) Láìsí àní-àní, Jésù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an.—Lúùkù 5:17. w15 6/15 2:3-5
Saturday, August 12
Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ . . . gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.—Òwe 18:1.
Tá a bá lo ìgboyà tá a sì rẹ ara wa sílẹ̀, tí a wá ní kí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ yẹ̀ wá wo, kó sì sọ irú èèyàn tá a jẹ́ gan-an fún wa, èyí ò ní jẹ́ ká máa rò pé ó tọ́ láti gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èyíkéyìí láyè. (Héb. 3:12, 13) Tá a bá sọ ibi tá a kù sí fún Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ tó sì tóótun nípa tẹ̀mí, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn àbààwọ́n kan tèèyàn kì í sábà kíyè sí. Èyí sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó ṣe pàtàkì táá jẹ́ ká lè dúró nínú ìfẹ́ Jèhófà. Àwọn alàgbà kúnjú ìwọ̀n láti ràn wá lọ́wọ́. (Ják. 5:13-15) Ó ṣe pàtàkì pé ká wá ìrànlọ́wọ́ pàápàá tó bá jẹ́ pé wíwo àwọn ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ló gbé èròkerò sí wa lọ́kàn. Tá ò bá tètè wá ìrànlọ́wọ́, ńṣe ni ewu tí èrò tí kò mọ́ máa ń fà máa túbọ̀ lágbára sí i, ‘nígbà tí ó bá sì lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀’ tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn míì, táá sì kẹ́gàn bá orúkọ Jèhófà. Bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣé pinnu láti wà nínú ìjọ Kristẹni kí wọ́n sì máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ti jẹ́ kí wọ́n lè gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n fún wọn lọ́nà ìfẹ́.—Ják. 1:15; Sm. 141:5; Héb. 12:5, 6. w15 6/15 3:15-17
Sunday, August 13
Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé, ojú yóò ti àwọn wòlíì, olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọ tẹ́lẹ̀; wọn kì yóò sì wọ ẹ̀wù oyè ti a fi irun ṣe fún ète títannijẹ.—Sek. 13:4.
Ṣé ìgbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run náà ni gbogbo àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn èké máa pa run? Bóyá ni. Àwọn kan lára àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì á jáwọ́ nínú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe, wọ́n á sì sẹ́ pé àwọn ò dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀sìn èké yẹn rí. (Sek. 13:5, 6) Báwo ni nǹkan á ṣe rí fún àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà yẹn? Jésù ṣàlàyé pé: “Ní ti tòótọ́, láìjẹ́ pé a ké ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là; ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́, a óò ké ọjọ́ wọnnì kúrú.” (Mát. 24:22) Ní ọdún 66 Sànmánì Kristẹni, a “ké” ìpọ́njú náà “kúrú.” Èyí mú kí “àwọn àyànfẹ́,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró, sá kúrò nínú ìlú náà àti ní gbogbo àyíká rẹ̀. Bákan náà, a máa “ké” apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ “kúrú” nítorí “àwọn àyànfẹ́.” Jèhófà ò ní gba “ìwo mẹ́wàá” tó ṣàpẹẹrẹ gbogbo agbára òṣèlú náà láyè láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run run. (Ìṣí. 17:16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdádúró díẹ̀ máa wà. w15 7/15 2:5,6
Monday, August 14
Adẹniwò náà dé.—Mát. 4:3.
Ó kù sọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan, yálà a máa gbà kí Sátánì mú wa wá sínú ìdẹwò tàbí a ò ní gbà. (Mát. 6:13; Ják. 1:13-15) Ní ti Jésù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mu láti kọ ìdẹwò kọ̀ọ̀kan tí Sátánì Èṣù gbé síwájú rẹ̀. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àmọ́ Sátánì ò jáwọ́ o. Ó dúró “títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀.” (Lúùkù 4:13) Síbẹ̀, Jésù ń bá a nìṣó láti máa dènà gbogbo ìsapá Sátánì láti mú kó di aláìṣòótọ́. Àmọ́ ṣá o, Sátánì ń dá gbogbo ọgbọ́n kó lè dẹkùn mú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, kò sì yọ ìwọ náà sílẹ̀. Torí àríyànjiyàn tó ń lọ lọ́wọ́ lórí ipò Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, Jèhófà fàyè gba Adẹniwò náà pé kó lo ayé yìí láti fi dẹ wá wò. Ọlọ́run kọ́ ló ń mú wa wá sínú ìdẹwò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fọkàn tán wa, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ o, torí pé Jèhófà fún wa lómìnira láti yan òun tó wù wá, kì í dédé yọ wá ká máa bàa kó sínú ìdẹwò. A ní láti ṣe ohun méjì kan. Àkọ́kọ́ ni pé ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Ìkejì sì ni pé ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo. w15 6/15 5:13, 14
Tuesday, August 15
Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—2 Kọ́r. 6:3.
Àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn kí wọ́n lè ronú lọ́nà tó tọ́ kó má di pé wọ́n á máa dá sí àwọn awuyewuye tó bá ń ṣẹlẹ̀. (Róòmù 14:19) Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Arábìnrin Mirjeta yẹ̀ wò. Orílẹ̀-èdè tó ń jẹ́ Yugoslavia tẹ́lẹ̀ ni arábìnrin yìí ti wá. Láti kékeré ni wọ́n ti kọ́ ọ pé kó kórìíra àwọn tó wá láti ìlú Serbia. Nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú àti pé Sátánì ló ń fa ìṣòro láàárín ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó sapá láti borí gbígbé orílẹ̀-èdè rẹ̀ ga ju òmíràn lọ. Síbẹ̀, nígbà tí àwọn ẹ̀yà kan ń jà ní àdúgbò tí Mirjeta ń gbé, ìkórìíra tó máa ń ní tẹ́lẹ̀ tún pa dà wá sọ́kàn rẹ̀, ìyẹn wá jẹ́ kó ṣòro fún un láti wàásù fún àwọn tó wá láti ìlú Serbia. Àmọ́, ó mọ̀ pé òun ò kàn lè fọwọ́ lẹ́rán, kí òun sì máa retí pé kí ìkórìíra náà kúrò lọ́kàn òun. Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kí òun lè borí ìkórìíra tó wà lọ́kàn òun. Ó sọ pé: “Mo ti rí i pé pípa ọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn mi ni ohun tó tíì ràn mí lọ́wọ́ jù lọ. Tí mo bá wà lóde ẹ̀rí, mo máa ń gbìyànjú láti fìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà, ẹ̀mí ìkórìíra tó wà lọ́kàn mi sì di àfẹ́kù.” w15 7/15 3:11-13
Wednesday, August 16
Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.—2 Kíró. 16:9.
Wo àpẹẹrẹ Jèhóṣáfátì Ọba Júúdà. Nígbà kan, Jèhóṣáfátì hùwà tí kò bọ́gbọ́n mu. Ó bá Áhábù Ọba Ísírẹ́lì lọ sógun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn irínwó [400] wòlíì èké fi dá Áhábù Ọba burúkú lójú pé ó máa ṣẹ́gun, Mikáyà tó jẹ́ wòlìí tòótọ́ fún Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣẹ́gun rẹ̀. Áhábù kú sójú ogun, díẹ̀ ló sì kù kí wọ́n pa Jèhóṣáfátì náà. Nígbà tó pa dà dé Jerúsálẹ́mù, Jéhù bá a wí torí pé ó bá Áhábù da nǹkan pọ̀. Síbẹ̀, Jéhù, ọmọ Hánáánì aríran sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “A rí àwọn ohun rere pẹ̀lú rẹ.” (2 Kíró. 18:4, 5, 18-22, 33, 34; 19:1-3) Òótọ́ ni pé Jèhóṣáfátì hùwà òmùgọ̀, àmọ́ Jèhófà rí gbogbo ohun rere tó ti ṣe. (2 Kíró. 17:3-10) Àkọsílẹ̀ yìí rán wa létí pé bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa kò ní yẹ̀ tá a bá ń fi tọkàntọkàn wá a. w15 8/15 1:8, 9
Thursday, August 17
[Sọ fún wọn] láti máa ṣe rere, . . . kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.—1 Tím. 6:18, 19.
Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ nísinsìnyí láti gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé à ń gbèrò láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì. Báwo la ṣe máa múra sílẹ̀ fún ìṣípòpadà náà? A lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè àwọn tó ń gbé níbẹ̀. Ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá kọ́ èdè àwọn tó ń gbé níbẹ̀ àti àṣà ìbílẹ̀ wọn, ká sì tún fi oúnjẹ wọn kọ́ra. Dé ìwọ̀n àyè kan, á máa ṣe wá bíi pé a ti ń gbé ní orílẹ̀-èdè náà. Ó ṣe tán, ohun tá ó máa ṣe tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbébẹ̀ nìyẹn. Bákan náà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi bá ó ṣe máa gbé nínú ayé tuntun kọ́ra báyìí bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Àwọn kan ò fẹ́ wà lábẹ́ ẹnikẹ́ni, tinú wọn ni wọ́n sì máa ń fẹ́ ṣe, àmọ́ kí ló ti jẹ́ àbájáde rẹ̀? Bí àwọn èèyàn ṣe kọ̀ láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ti yọrí sí ìyà, òṣì àti ìbànújẹ́. (Jer. 10:23) À ń retí ìgbà tí gbogbo èèyàn máa gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso àti pé ìfẹ́ ló fi ń ṣàkóso. w15 8/15 3:4, 5
Friday, August 18
Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.—2 Kọ́r. 6:14.
Ó túbọ̀ ṣe pàtàkì pé kí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni tó sì fẹ́ ṣègbéyàwó ṣọ́ àwọn tó ń bá kẹ́gbẹ́. Bíbélì gba àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó nímọ̀ràn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ “kìkì nínú Olúwa,” ìyẹn ni pé olùjọ́sìn Jèhófà tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tó ti ṣèrìbọmi, tó sì ń fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ fẹ́. (1 Kọ́r. 7:39) Bí àwọn Kristẹni tòótọ́ bá ń fẹ́ ará bíi tiwọn, wọ́n á máa ní àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, èyí á sì jẹ́ kí wọ́n lè pa ìwà títọ́ wọn mọ́. Jèhófà mọ ohun tó máa ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láǹfààní jù lọ, kò sì yé tipasẹ̀ ètò rẹ̀ sọ ojú tó fi ń wo ìgbéyàwó fún wa. Kíyè sí àṣẹ kedere tó pa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí Jèhófà ń gbẹnu Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn orílẹ̀-èdè tí kò sin Ọlọ́run tó yí wọn ká, ó sọ pé: “Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ bá wọn dána. . . . Nítorí òun yóò yí ọmọ rẹ padà láti má ṣe tọ̀ mí lẹ́yìn.”—Diu. 7:3, 4. w15 8/15 4:12, 13
Saturday, August 19
Kí ẹ lè máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù, kí ẹ lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n, kí ẹ má sì máa mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀.—Fílí. 1:10.
Báwo la ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa? Àwọn ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ ni pé ká máa ka Bíbélì déédéé, ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a bá kà, ká sì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká lè máa fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò. Kì í wulẹ̀ ṣe kéèyàn ní ìmọ̀ orí lásán nípa Jèhófà tàbí kó mọ àwọn ìlànà rẹ̀ là ń sọ o! Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ ká túbọ̀ máa lóye irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an, ká lóye àwọn ànímọ́ rẹ̀, ká sì mọ àwọn ohun tó fẹ́ àtèyí tí kò fẹ́. Lọ́nà yìí, ẹ̀rí ọkàn wa á jẹ́ ká tètè máa mọ ohun tó tọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run àti ohun tí kò tọ́ lójú rẹ̀. Èyí á wá mú ká máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Àmọ́, tá ò bá lóye ìdí tí ẹ̀rí ọkàn ará kan fi fàyè gbà á láti ṣe ìpinnu lórí ọ̀rọ̀ kan tó kàn án gbọ̀ngbọ̀n, kò yẹ ká yára dá irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́jọ́ tàbí ká rọ̀ ọ́ títí tó fi máa yí èrò rẹ̀ pa dà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ṣì jẹ́ “aláìlera,” ó sì ní láti túbọ̀ kọ́ ọ, tàbí kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kì í fàyè gbà.—1 Kọ́r. 8:11, 12. w15 9/15 2:4, 8, 10
Sunday, August 20
Ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.—Sm. 115:16.
Ilẹ̀ ayé wa yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá. Tiẹ̀ rò ó wò ná, nínú àìlóǹkà pílánẹ́ẹ̀tì tó wà lágbàáyé, kì í ṣe pé Jèhófà dá ayé ká lè gbé inú rẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ó dá a kó lè jẹ́ ibi tó tuni lára, tó lẹ́wà tí kò sì léwu láti gbé! (Aísá. 45:18) Gbogbo èyí ń fi bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó hàn. (Jóòbù 38:4, 7; Sm. 8:3-5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹlẹ́wà ni Jèhófà fún wa, ó mọ̀ pé ká tó lè láyọ̀ ká sì ní ìtẹ́lọ́rùn, a nílò ju àwọn ohun tara lọ. Bí ọmọ kan bá mọ̀ pé àwọn òbí òun nífẹ̀ẹ́ òun wọ́n sì ń tọ́jú òun, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀. Jèhófà dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa ó sì ń tọ́jú wa. (Jẹ́n. 1:27) Láfikún síyẹn, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mát. 5:3) Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, torí náà ó “ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa” nípa tara àti nípa tẹ̀mí.—1 Tím. 6:17; Sm. 145:16. w15 9/15 4:6, 7
Monday, August 21
Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.—Òwe 14:12.
Onísáàmù náà ní ohun tó tọ́ lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Dúró de Ọlọ́run, nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára. Ìwọ Ọlọ́run mi, àní ọkàn mi ń bọ́hùn nínú mi. Ìdí nìyẹn tí mo fi rántí rẹ.” (Sm. 42:5, 6) Onísáàmù yìí mà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an o! Ṣé ìwọ náà ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà, ṣé o sì máa ń gbẹ́kẹ̀ lé Baba wa ọ̀run? Kódà, bó o bá tiẹ̀ dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ìdí ṣì lè wà fún ẹ láti túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e níbàámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ fún wa. Ó ní: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Jèhófà ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa, nípa báyìí ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa nípa bá a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòh. 4:19) Ẹ jẹ́ ká máa fi àpẹẹrẹ ìfẹ́ títayọ yìí sọ́kàn nígbà gbogbo. Ká sì máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ‘pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú wa àti pẹ̀lú gbogbo okun wa.’—Máàkù 12:30. w15 9/15 5:17-19
Tuesday, August 22
Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.—Joṣ. 24:15.
Bá a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ tiwa náà á máa lágbára sí i. Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa náà ti kọ́ bá a ṣe lè ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jèhófà, a sì ń fìgboyà wàásù níbi gbogbo. (Ìṣe 4:17-20; 13:46) Bá a ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbèésí ayé wa àti bó ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i. Bó ṣe rí fún Kálébù àti Jóṣúà nìyẹn. Wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà nígbà tí wọ́n lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́, bí Jèhófà ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn náà, ìgbàgbọ́ wọn ń lágbára sí i. Abájọ tí Jóṣúà fi fi ìdánilójú sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín.” Ó tún sọ pé: “Wàyí o, ẹ bẹ̀rù Jèhófà, kí ẹ sì máa sìn ín ní àìlálèébù àti ní òtítọ́.” (Jóṣ. 23:14; 24:14) Tá a bá tọ́ Jèhófà wò, a óò rí i pé ẹni rere ni, àwa náà á sì ní irú ìdánilójú tí Jóṣúà ní.—Sm. 34:8. w15 10/15 2:10, 11
Wednesday, August 23
Ẹ́sírà fúnra rẹ̀ ti múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀.—Ẹ́sírà 7:10.
Ṣé o máa ń ṣe àkọsílẹ̀ tó o bá ń tẹ́tí sí àsọyé, tó o bá wà ní àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè? Tó o bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó o kọ sílẹ̀ yìí, wàá lè máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tó o ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Bákan náà, a lè ṣàṣàrò lórí àwọn ìwé ìròyìn wa irú bí Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àtàwọn ìtẹ̀jáde tuntun tá à ń rí gbà láwọn àpéjọ wa. Tó o bá ń ka Ìwé Ọdọọdún wa, máa dúró díẹ̀ kó o lè fẹ̀sọ̀ ronú lórí ìrírí tó o kà, ìrírí náà á sì wọ̀ ẹ́ lọ́kàn. O lè fàlà sábẹ́ àwọn kókó pàtàkì tàbí kó o kọ ọ̀rọ̀ tó máa wúlò fún ẹ sí etí ìwé náà. Àwọn àkọsílẹ̀ náà máa wúlò tó o bá ń múra sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò, ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tàbí àsọyé tó o máa sọ lọ́jọ́ iwájú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, tó o bá ń dúró díẹ̀ láti ṣàṣàrò bó o ṣe ń ka àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, àwọn ohun tó ò ń kà á túbọ̀ yé ẹ sí i wàá sì lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn ohun rere tó ò ń kọ́. w15 10/15 4:9, 10
Thursday, August 24
Jésù sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n àti ní ìdàgbàsókè ti ara-ìyára àti ní níní ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.—Lúùkù 2:52.
Ọ̀kan lára ọjọ́ tínú àwọn òbí máa ń dùn jù lọ ni ọjọ́ tí ọmọ wọ́n ṣèrìbọmi. Arábìnrin Berenice táwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣèrìbọmi kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sọ pé: “Tá a bá rántí báwọn ọmọ wa ṣe ṣèrìbọmi ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, inú wa máa ń dùn gan-an. Ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé àwọn ọmọ wa pinnu láti sin Jèhófà. Àmọ́, a mọ̀ pé àwọn ọmọ wa máa kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro bí wọ́n ti ń dàgbà.” Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ní ìmọ̀ nípa ìdàgbàsókè àwọn ọmọdé gbà pé tọ́mọ kan bá ti ń dàgbà, iṣẹ́ ńlá ló já lé ọmọ náà àtàwọn òbí rẹ̀ léjìká. Ó wá sọ pé: “Ó yẹ káwọn òbí mọ̀ pé tọ́mọ kan bá ti ń bàlágà, kì í tún ṣọmọdé mọ́, kí wọ́n má sì rò pé àwọn ọmọ náà ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ọmọ náà ti lè dá ronú kí wọ́n sì ṣe nǹkan fúnra wọn, nǹkan tàwọn èèyàn bá ṣe sí wọn lè dùn wọn tàbí kó múnú wọn dùn àti pé àwọn ọmọ náà á fẹ́ máa wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọ́n lọ́pọ̀ ìgbà.” Àsìkò táwọn ọmọ rẹ wà lọ́dọ̀ọ́ gan-an ni wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í pinnu àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n sì lè pinnu pé àwọn á ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí i. Bíi ti Jésù, àwọn ọmọ rẹ lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà bí wọ́n ṣe ń dàgbà. w15 11/15 2:1, 2
Friday, August 25
Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.Mát. 6:10.
Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn Ìjọba Mèsáyà fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. Jèhófà ti fi ìjọba yìí sí ìkáwọ́ Ọmọ rẹ̀, Ọmọ rẹ̀ yìí nífẹ̀ẹ́ aráyé, òun ló sì kúnjú ìwọ̀n láti ṣàkóso. (Òwe 8:31) Nígbà tí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó máa bá Jésù jọba lókè ọ̀run yìí bá jíǹde, wọ́n á gbé gbogbo ìrírí tí wọ́n ti ni nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé lọ sọ́run. (Ìṣí. 14:1) Ìjọba Ọlọ́run ni lájorí ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù Jésù, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà fún un àti àwọn ìbùkún tó máa mú wá. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ìgbà wíwàníhìn-ín Kristi lọ́dún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀. Láti ìgbà yẹn ni ìkójọ àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó máa bá Jésù jọba lókè ọ̀run ti bẹ̀rẹ̀, bákan náà sì ni ìkójọ àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó máa la òpin ètò àwọn nǹkan yìí já, bọ́ sínú ayé tuntun.—Ìṣí. 7:9, 13, 14. w15 11/15 3:16, 18
Saturday, August 26
Jọ̀wọ́, gbọ́, èmi alára yóò sì sọ̀rọ̀.—Jóòbù 42:4.
Àpọ́sítélì Jòhánù pe ẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá ní “Ọ̀rọ̀ náà,” ó sì tún pè é ní “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Jòh. 1:1; Ìṣí. 3:14) Jèhófà Ọlọ́run máa ń sọ èrò rẹ̀ àtohun tó fẹ́ ṣe fún àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ yìí. (Jòh. 1:14, 17; Kól. 1:15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ‘ahọ́n àwọn áńgẹ́lì,’ ìyẹn èdè tí wọ́n ń sọ lọ́run tó sì jinlẹ̀ ju èyí táwa èèyàn ń sọ lọ. (1 Kọ́r. 13:1) Kò sóhun tí Jèhófà ò mọ̀ nípa gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó dá sọ́run àti àwa èèyàn tó dá sórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa gbàdúrà sí Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan náà lédè tí kálukú wọn ń sọ. Bó sì ṣe ń tẹ́tí sí àdúrà ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn yìí, bẹ́ẹ̀ láá tún máa bá àwọn áńgẹ́lì sọ̀rọ̀ táá sì máa fún wọn ní ìtọ́ni. Gbogbo èyí fi hàn pé èrò Ọlọ́run, èdè rẹ̀ àti ọ̀nà tó ń gbà sọ̀rọ̀ gbọ́dọ̀ ga ju tèèyàn lọ fíìfíì. (Aísá. 55:8, 9) Ó ṣe kedere nígbà náà pé tí Jèhófà bá fẹ́ bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀, àfi kó mú kí ohun tó ń sọ rọrùn kó bàa lè yé wa. w15 12/15 1:1, 2
Sunday, August 27
Ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.—Aísá. 11:9.
Bíbélì ò pọ̀ láwọn ilẹ̀ kan, ó sì tún wọ́n gan-an. Torí náà, pé àwọn kan tiẹ̀ rí Bíbélì yìí gbà tọ́pẹ́ ó ju ọpẹ́ lọ. Ìròyìn kan tá a gbọ́ láti orílẹ̀-èdè Rùwáńdà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn táwọn ará ti ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látọjọ́ yìí ni òye ò tíì fi bẹ́ẹ̀ yé torí wọn ò ní Bíbélì. Owó wọn ò ká èyí tí wọ́n ń tà ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó yí wọn ká. Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan ò yé wọn dáadáa, ìyẹn ò sì jẹ́ kí wọ́n tètè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́.” Àmọ́, nǹkan yí pa dà nígbà tí ètò Ọlọ́run mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè wọn. Ìdílé ọlọ́mọ mẹ́rin kan lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé a rí Bíbélì yìí gbà, a sì tún dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye. A ò rí já jẹ, torí náà, kò sówó tá a lè fi ra Bíbélì fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé wa. Àmọ́ kálukú wa ló ti ní Bíbélì tiẹ̀ báyìí. Ojoojúmọ́ là ń ka Bíbélì náà ká lè máa fìyẹn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.” w15 12/15 2:15, 16
Monday, August 28
Jèhófà, fi ojú rere hàn sí mi. Mú ọkàn mi lára dá, nítorí pé mo ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.—Sm. 41:4.
Ó lè jẹ́ pé ìgbà tí ara Dáfídì ò yá, tí Ábúsálómù sì fẹ́ gba ìjọba mọ́ ọn lọ́wọ́ ni Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ibí yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti dárí ji Dáfídì, Dáfídì ò gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà àti ohun tó yọrí sí. (2 Sám. 12:7-14) Síbẹ̀, ó dá Dáfídì lójú pé Ọlọ́run máa dá òun sí. Kò sọ pé kí Ọlọ́run wo òun sàn lọ́nà ìyanu. Ọ̀nà kan náà tí Jèhófà máa gbà ran ‘ẹni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀’ lọ́wọ́ ni Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó gbà ran òun lọ́wọ́. Lára ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì ni pé Ọlọ́run “yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi.” (Sm. 41:3) Torí pé Ọlọ́run ti dárí ji Dáfídì, ó lè bẹ Ọlọ́run pé kó tu òun nínú, kó sì ti òun lẹ́yìn, kí ara òun lè tètè kọ́fẹ pa dà. (Sm. 103:3) Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. w15 12/15 4:8, 9
Tuesday, August 29
Ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, ẹ̀mí tí ń mú kí a ké jáde pé: “Ábà, Baba!”—Róòmù 8:15.
Àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ò nílò kẹ́nì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ fún wọn pé Ọlọ́run ti yàn wọ́n. Jèhófà ló ń mú kó dá wọn lójú. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: ‘Ẹ ní ìfòróróyàn láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́ náà; gbogbo yín ní ìmọ̀. Ní tiyín, ìfòróróyàn tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ dúró nínú yín, ẹ kò sì nílò ẹnikẹ́ni láti máa kọ́ yín; ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ìfòróróyàn náà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti ń kọ́ yín nípa ohun gbogbo, tí ó sì jẹ́ òótọ́, tí kì í sì í ṣe irọ́, àti pé gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ yín, ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ (1 Jòh. 2:20, 27) Àwọn ẹni àmì òróró náà ní láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà bíi tàwa tó kù. Àmọ́, kò dìgbà tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún wọn kí wọ́n tó mọ̀ pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan àwọn. Jèhófà fúnra rẹ̀ ti fi ẹ̀rí tó lágbára jù lọ, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, mú kó ṣe kedere sí wọn pé ẹni àmì òróró ni wọ́n! w16.01 3:9, 10
Wednesday, August 30
Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí.—Héb. 13:5.
Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àwọn nǹkan tá a ní á tẹ́ wa lọ́rùn. Báwo nìyẹn ṣe lè mú ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa? Tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn, àá máa rántí pé àwọn ará wa ṣe pàtàkì ju owó tàbí àwọn nǹkan míì lọ. (1 Tím. 6:6-8) A ò ní máa ṣàríwísí àwọn ará wa tàbí ká máa ráhùn torí bí ipò nǹkan ṣe rí fún wa. A ò sì ní máa jowú àwọn ará wa tàbí ká wá di oníwọra. Àmọ́ tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn, àá jẹ́ ọ̀làwọ́. (1 Tím. 6:17-19) Yàtọ̀ síyẹn, ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Jèhófà ń fún wa nígboyà láti fara da àwọn àdánwò tó le koko. (Héb. 13:6) Ìgboyà yìí ló sì máa jẹ́ ká ní ẹ̀mí pé nǹkan á dáa, àá máa fún àwọn ará wa níṣìírí, àá sì máa tù wọ́n nínú. (1 Tẹs. 5:14, 15) Kódà, nígbà ìpọ́njú ńlá pàápàá, a lè nígboyà torí a mọ̀ pé ìdáǹdè wa kù sí dẹ̀dẹ̀.—Lúùkù 21:25-28. w16.01 1:16, 17
Thursday, August 31
Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.—2 Tím. 2:19.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ńṣe ni iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi ń dín kù. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ṣe ni iye wọn ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Ṣó yẹ ká máa dara wa láàmú nítorí èyí? Rárá. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tí kò fi yẹ kíyẹn kó ìdààmú ọkàn bá wa. Àwọn arákùnrin tó ń ka iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi kì í ṣe Jèhófà, torí náà wọn ò lè mọ àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró lóòótọ́. Torí náà, àwọn tí wọ́n rò pé ẹni àmì òróró làwọn àmọ́ tí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró wà lára àwọn tó ń jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí wọ́n ti máa ń jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà tẹ́lẹ̀ kò jẹ ẹ́ mọ́ nígbà tó yá. Àwọn kan lè ní ìṣòro ọpọlọ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí wọ́n sì máa rò pé àwọn wà lára àwọn tó máa bá Kristi jọba lọ́run. Ó ṣe kedere pé a ò mọ iye àwọn ẹni àmì òróró tó kù láyé báyìí. Bíbélì kò sì sọ iye àwọn tó máa ṣẹ́ kù nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀. w16.01 4:12-14