ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es17 ojú ìwé 118-128
  • December

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • December
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2017
  • Ìsọ̀rí
  • Friday, December 1
  • Saturday, December 2
  • Sunday, December 3
  • Monday, December 4
  • Tuesday, December 5
  • Wednesday, December 6
  • Thursday, December 7
  • Friday, December 8
  • Saturday, December 9
  • Sunday, December 10
  • Monday, December 11
  • Tuesday, December 12
  • Wednesday, December 13
  • Thursday, December 14
  • Friday, December 15
  • Saturday, December 16
  • Sunday, December 17
  • Monday, December 18
  • Tuesday, December 19
  • Wednesday, December 20
  • Thursday, December 21
  • Friday, December 22
  • Saturday, December 23
  • Sunday, December 24
  • Monday, December 25
  • Tuesday, December 26
  • Wednesday, December 27
  • Thursday, December 28
  • Friday, December 29
  • Saturday, December 30
  • Sunday, December 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2017
es17 ojú ìwé 118-128

December

Friday, December 1

Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.​—Sm. 25:14.

Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Bíbélì pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (2 Kíró. 20:7; Aísá. 41:8; Ják. 2:23) Ábúráhámù nìkan ni Bíbélì dìídì pè ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí èèyàn míì tó di ọ̀rẹ́ Jèhófà yàtọ̀ sí Ábúráhámù? Rárá o. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo wa la lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Ìtàn àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí wọ́n bẹ̀rù Jèhófà, tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kún inú Bíbélì. Wọ́n jẹ́ ara “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ wọn. Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ni gbogbo wọn. (Héb. 12:1) Ó ṣe kedere pé ọ̀rẹ́ Jèhófà ni Ábúráhámù, ọ̀rẹ́ Jèhófà sì ni Rúùtù, Hesekáyà àti Màríà náà. Wọ́n wà lára “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀,” táwọn náà láǹfààní láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé irú àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ títayọ bẹ́ẹ̀. (Héb. 6:11, 12) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà títí láé! w16.02 2:1, 2, 19

Saturday, December 2

Èmi sọ kalẹ̀ wá . . . kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.​—Jòh. 6:38.

Ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ kan fi mọ́tò kan ta ẹ́ lọ́rẹ. Ó kó àwọn ìwé mọ́tò náà fún ẹ, ó wá sọ pé: “Ọwọ́ mi ni kọ́kọ́rọ́ mọ́tò náà máa wà. Èmi ni màá sì máa wà á, kì í ṣe ìwọ.” Ojú wo lo máa fi wo ẹ̀bùn tí ọ̀rẹ́ rẹ fún ẹ yìí? Tẹ́nì kan bá ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ohun tó ń sọ fún Ọlọ́run ni pé: “Mo ti fi ayé mi fún ọ. Tìẹ ni mo jẹ́.” Ó lẹ́tọ̀ọ́ kí Jèhófà retí pé kí onítọ̀hún mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Àmọ́, tẹ́ni náà bá wá lọ ń yọ́ ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́, tó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà ńkọ́? Àbí tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá lọ gba iṣẹ́ tó máa gba gbogbo àkókò tó yẹ kó lò lóde ẹ̀rí tàbí tó ń jẹ́ kó pa ìpàdé jẹ lọ́pọ̀ ìgbà ńkọ́? Ó túmọ̀ sí pé ẹni náà ò mú ìlérí tó ṣe fún Jèhófà ṣẹ nìyẹn. Ṣe nìyẹn sì dà bí ìgbà tó di kọ́kọ́rọ́ mọ́tò mọ́wọ́. Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a sọ fún un pé, “Mo ti fi ìgbésí ayé mi fún ọ, kì í tún ṣe tèmi mọ́.” Torí náà, ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe la ó máa ṣe kódà kó jẹ́ ohun tí kò wù wá ṣe. Ìyẹn á sì fi hàn pé àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé nínú ẹ̀kọ́ ojúmọ́ wa tòní. w16.03 1:16, 17

Sunday, December 3

Èmi kí yóò fi ọ́ sílẹ̀.​—2 Ọba 2:2.

Ní nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, wòlíì Èlíjà ní kí Èlíṣà tó jẹ́ ọ̀dọ́ di ìránṣẹ́ òun. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Èlíṣà gbà láti di ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fi ìṣòtítọ́ sin bàbá àgbàlagbà yìí nípa bíbá a ṣe àwọn iṣẹ́ tí kò jọjú. (2 Ọba 3:11) Lẹ́yìn tí Èlíṣà ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́fà, ó gbọ́ pé iṣẹ́ Èlíjà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì máa tó dópin. Èlíjà wá sọ fún alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ tó ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa yìí pé kó má tẹ̀ lé òun mọ́. Àmọ́, Èlíṣà ṣe tán láti dúró ti ọ̀gá rẹ̀ tó bá ṣì ṣeé ṣe. Báwo ni ọ̀dọ́ Kristẹni kan ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíṣà lónìí? Jẹ́ kó máa yá ẹ lára láti gba iṣẹ́ tí wọ́n bá fún ẹ, títí kan àwọn iṣẹ́ tí kò jọjú. Mú olùkọ́ rẹ lọ́rẹ̀ẹ́, kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé o mọyì bó ṣe ń sapá láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máa fi ìṣòtítọ́ bójú tó iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ẹ. Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé, lẹ́yìn tí àwọn alàgbà bá a rí i pé o jẹ́ olóòótọ́ tó o sì ṣeé fọkàn tán ni ọkàn wọn á tó balẹ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n fún ẹ ní àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ.​—Sm. 101:6; 2 Tím. 2:2. w15 4/15 2:13, 14

Monday, December 4

Ó ti búra sí ohun tí ó burú fún ara rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kò yí padà.​—Sm. 15:4.

Jónátánì ni Sọ́ọ̀lù fẹ́ kó di ọba lẹ́yìn òun dípò Dáfídì. (1 Sám. 20:31) Àmọ́, Jónátánì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Kàkà kí Jónátánì jẹ́ onímọtara ẹni nìkan, ó di ọ̀rẹ́ Dáfídì ó sì pa àdéhùn tó ní pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Torí pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, àá máa pa àdéhùn tá a bá ṣe mọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn iṣẹ́ pẹ̀lú ẹnì kan, á máa rí i dájú pé a ṣe ohun tá a ṣèlérí pé a máa ṣe, kódà bí kò bá tiẹ̀ rọrùn pàápàá. Bí nǹkan ò bá lọ bó ṣe yẹ nínú ìgbéyàwó wa ńkọ́? Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí ọkọ wa tàbí ìyàwó wa ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Mál. 2:​13-16) Torí náà, ẹ jẹ́ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn wá. A fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run kódà tá a bá dojú kọ àwọn ìṣòro lílekoko. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa mú ọkàn Jèhófà yọ̀. (Òwe 27:11) Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò jẹ́ ṣe ohun tó máa pa wá lára, ó sì máa tọ́jú wa. w16.02 3:16, 17

Tuesday, December 5

Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un. ​—Aísá. 30:18.

Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ. (Sm. 103:14) Nítorí náà, kò retí pé ká máa dá fara da àwọn ìṣòro wa, àmọ́ ó ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ torí òun ni baba wa. Òótọ́ ni pé, ìgbà míì máa ń wà tó máa ń ṣe wá bíi pé agbára wa ti pin. Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí pé òun kò ní jẹ́ kí ìyà tó ju agbára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ jẹ wọ́n. Ó dájú pé ó máa “ṣe ọ̀nà àbájáde.” (1 Kọ́r. 10:13) Nítorí náà, kò sí àní-àní pé Jèhófà mọ̀ wá lóòótọ́, ó mọ ibi tí agbára wa mọ. Tá ò bá rí ìtura lójú ẹsẹ̀ lẹ́yìn tá a gbàdúrà, ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù, ká máa wojú Ẹni tó mọ ìgbà tó dára jù lọ láti ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ó wu Ọlọ́run gan-an láti ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ ó ń mú sùúrù dìgbà tó dáa jù láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún fífi ojú rere hàn sí yín, nítorí náà, yóò dìde láti fi àánú hàn sí yín. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ [òdodo].” w15 4/15 4:8, 9

Wednesday, December 6

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obìnrin mímọ́ tí wọ́n ní ìrètí nínú Ọlọ́run máa ń ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, ní fífi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ tiwọn.​—1 Pét. 3:5.

Táwọn òbí àtàwọn ọmọ bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn á máa lágbára sí i. Nígbà Ìjọsìn Ìdílé, wọ́n lè jọ múra ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa sọ lóde ẹ̀rí, èyí á sì jẹ́ kí gbogbo wọn wà ní ìmúrasílẹ̀ dáadáa. Bí wọ́n ṣe jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀, tí wọ́n sì rí i pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ló nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì fẹ́ máa múnú rẹ̀ dùn, wọ́n á túbọ̀ ṣera wọn lọ́kan. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè ṣera wọn lọ́kan? Táwọn méjèèjì bá jọ ń sin Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n á ṣera wọn lọ́kan, ayé wọn á sì dùn bí oyin. Ó tún yẹ kí wọ́n máa fìfẹ́ hàn síra wọn, kí wọ́n fìwà jọ àwọn tọkọtaya bí Ábúráhámù àti Sárà, Ísákì àti Rèbékà àti Ẹlikénà àti Hánà. (Jẹ́n. 26:8; 1 Sám. 1:​5, 8) Bí tọkọtaya bá ń ṣe báyìí, wọ́n á ṣera wọn lọ́kan, wọ́n á sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.​—Oníw. 4:12. w16.03 3:12, 13

Thursday, December 7

Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Sátánì], ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.​—1 Pét. 5:9.

Sátánì ń bá àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” jagun. (Jòh. 10:16) Ohun tó wà lọ́kàn Èṣù ni bó ṣe máa pa púpọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ kí sáà àkókò kúkúrú tó ní tó parí. (Ìṣí. 12:​9, 12) Ǹjẹ́ a lè borí Sátánì nínú ìjà yìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Bíbélì sọ pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Ják. 4:⁠7) Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí wọ́n bá gbọ́ pé Sátánì wà. Lérò tiwọn, wọ́n gbà pé inú ìwé, àwọn fíìmù tó ń dẹ́rù bani àtàwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù ni wọ́n ti máa ń sọ ìtàn àròsọ nípa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù. Àwọn èèyàn yẹn gbà pé kò sẹ́ni tí orí ẹ̀ pé tó máa gbà pé àwọn ẹ̀mí búburú wà. Lójú tìẹ, ṣé o rò pé inú Sátánì bà jẹ́ pé àwọn èèyàn gbà pé òun àtàwọn ẹmẹ̀wà òun jẹ́ ẹ̀dá inú ìtàn àròsọ lásán, pé àwọn kì í ṣe ẹni gidi? Kò dájú pé inú rẹ̀ bà jẹ́! Ó ṣe tán, ó rọrùn fún Sátánì láti fọ́ ojú inú àwọn èèyàn tí kò gbà pé ó wà. (2 Kọ́r. 4:⁠4) Bí àwọn èèyàn ṣe ń tan èrò náà kiri pé kò sí Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Sátánì ń gbà tàn àwọn èèyàn jẹ. w15 5/15 2:1, 2

Friday, December 8

[Mósè] ka ẹ̀gàn Kristi sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì; nítorí tí ó tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.​—Héb. 11:26.

Ó dájú pé àwọn tó jẹ́ òbí Mósè gangan ti kọ́ ọ nípa Jèhófà àti bí Jèhófà ṣe pinnu pé òun máa dá àwọn Hébérù nídè kúrò lóko ẹrú tí á sì mú wọn dé Ilẹ̀ Ìlérí. (Jẹ́n. 13:​14, 15; Ẹ́kís. 2:​5-10) Bí Mósè ṣe ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìlérí tí Jèhófà ti ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ńṣe ni ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ó ṣeé ṣe kóun náà ṣe bíi tàwọn èèyàn kan tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, kó máa fọkàn yàwòrán àkókò tí Jèhófà máa dá aráyé nídè lọ́wọ́ ikú. (Jóòbù 14:​14, 15; Héb. 11:​17-19) A lè wá rí ìdí tí Mósè fi wá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run torí bó ṣe fojú àánú hàn sáwọn Hébérù àti sí gbogbo aráyé. Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ló sún Mósè ṣe gbogbo nǹkan tó ṣe jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Diu. 6:​4, 5) Kódà nígbà tí Fáráò ń halẹ̀ mọ́ Mósè pé òun máa pa á, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí Mósè ní sí Ọlọ́run àti bó ṣe máa ń fọkàn yàwòrán ọjọ́ iwájú aláyọ̀ kan mú kó nígboyà bí Fáráò tiẹ̀ ń halẹ̀ ikú mọ́ ọn.​—Ẹ́kís. 10:28, 29. w15 5/15 3:11-13

Saturday, December 9

Wọn kò ní wáìnì kankan.​—Jòh. 2:3.

Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ níbi ìgbéyàwó kan tó wáyé ní ìlú Kánà ti Gálílì. Ó ṣeé ṣe kí iye àwọn tí wọ́n wá síbi ìgbéyàwó náà pọ̀ ju àwọn tí wọ́n pè lọ. Torí náà, wáìnì wọn tán. Màríà ìyá Jésù wà lára àwọn tí wọ́n pè síbi ìgbéyàwó náà. Láìsí àní-àní, Màríà á ti máa ronú lórí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó mọ̀ pé ọmọ náà máa di ẹni tí à ń pè ní “Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Lúùkù 1:​30-32; 2:52) Ǹjẹ́ ó gbà gbọ́ pé àwọn agbára kàn ṣì wà lára Jésù tí kò tíì fara hàn? Ó dájú pé nígbà tí Jésù àti Màríà wà ní Kánà, wọ́n káàánú tọkọtaya tuntun yìí, wọn ò sì fẹ́ kí ojú tì wọ́n. Jésù mọ̀ pé ojúṣe wa ló jẹ́ láti máa ṣe aájò àlejò. Nítorí náà, ó sọ omi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kún àgbá méjì di “wáìnì àtàtà.” (Jòh. 2:​6-11) Ṣé ọ̀ranyàn ni kí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí? Rárá o. Ńṣe ló káàánú àwọn èèyàn, tó sì fìwà ọ̀làwọ́ jọ Baba rẹ̀ ọ̀run. w15 6/15 1:3

Sunday, December 10

Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba náà padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?​—Ìṣe 1:6.

Kó tó di pé Jésù pa dà sókè ọ̀run, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ béèrè ìbéèrè tó wà lókè yìí. Ìdáhùn tí Jésù fún wọn fi hàn pé kò tíì tó àkókò fún wọn láti mọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ náà, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣe 1:​7, 8) Síbẹ̀, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa retí ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé. Torí náà, láti ọjọ́ àwọn àpọ́sítélì ni àwọn Kristẹni ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Nígbà tí àkókò náà tó tí Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí Jésù jẹ́ Ọba rẹ̀, máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso láti ọ̀run, Jèhófà jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ lóye àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan máa wáyé. Lọ́dún 1876, Arákùnrin Charles Taze Russell gbé àpilẹ̀kọ kan jáde nínú ìwé ìròyìn Bible Examiner. Àkòrí àpilẹ̀kọ náà ni, “Àwọn Àkókò Kèfèrí: Ìgbà Wo Ni Wọ́n Dópin?,” èyí sì ń tọ́ka sí ọdún 1914 pé ó jẹ́ ọdún mánigbàgbé. Àpilẹ̀kọ náà jẹ́ ká mọ bí “ìgbà méje” tí Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ ṣe kan “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” tí Jésù sọ.​—Dán. 4:16; Lúùkù 21:24. w15 6/15 4:11, 12

Monday, December 11

Jésù bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.​—Jòh. 11:35.

Ó máa ń dun Jésù wọra tó bá rí i táwọn èèyàn ń kẹ́dùn. Jésù “kérora . . . ó sì dààmú” nígbà tó rí i táwọn èèyàn bara jẹ́ torí ikú Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó mọ̀ pé òun máa jí Lásárù dìde lójú ẹsẹ̀, síbẹ̀ ó ṣì bá àwọn èèyàn kẹ́dùn. (Jòh. 11:​33-36) Ojú ò ti Jésù rárá láti fi bí nǹkan ṣe dùn ún tó hàn. Àwọn èèyàn rí ìfẹ́ tí Jésù ní sí Lásárù àti ìdílé rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìyọ́nú ni Jésù fi hàn bó ṣe lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi jí ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde! (Jòh. 11:​43, 44) Bíbélì sọ pé Jésù ni “àwòrán náà gẹ́lẹ́ ti wíwà [Ẹlẹ́dàá] gan-an.” (Héb. 1:⁠3) Torí náà, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òun àti Baba rẹ̀ múra tán láti mú ìrora tí àìsàn àti ikú máa ń fà kúrò. Èyí kò mọ sórí àjíǹde mélòó kan tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì nìkan. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò . . . jáde wá.”​—Jòh. 5:28, 29. w15 6/15 2:13, 14

Tuesday, December 12

Kí wọ́n gbé orúkọ rẹ lárugẹ.​—Sm. 99:3.

Àwọn onísìn kan ní èrò tí kò tọ̀nà pé táwọn bá ti kúrò láyé táwọn sì lọ sí ọ̀run làwọn máa tó yin Ọlọ́run. Àmọ́, gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ìsinsìnyí ló yẹ ká máa yin Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé níbí. À ń tipa báyìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí ìwé Sáàmù 99:​1-3, 5 sọ̀rọ̀ wọn. Bí sáàmù yẹn ṣe sọ, Mósè, Áárónì àti Sámúẹ́lì kọ́wọ́ ti ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn tòótọ́ nígbà ayé wọn. (Sm. 99:​6, 7) Kí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ arákùnrin Kristi lóde òní tó lọ sí ọ̀run níbi tí wọ́n á ti di àlùfáà tí wọ́n á sì ṣàkóso pẹ̀lú Jésù, wọ́n á ti kọ́kọ́ sìn láìyẹsẹ̀ nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti orí ilẹ̀ ayé. “Àwọn àgùntàn mìíràn” tí wọ́n ti di ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù báyìí ń tì wọ́n lẹ́yìn nígbà gbogbo. (Jòh. 10:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìrètí kan náà ni gbogbo wá ní, a jùmọ̀ ń sin Jèhófà ní ayé, tó jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ Rẹ̀. Àmọ́, ó dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń kọ́wọ́ ti ìjọsìn mímọ́ tí Jèhófà ṣètò rẹ̀?’ w15 7/15 1:4,  5

Wednesday, December 13

Máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà!​—Háb. 2:3.

Láti ìgbà pípẹ́ ni àwọn olùjọ́sìn Jèhófà ti máa ń fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí àwọn wòlíì rẹ̀ láti sọ. Wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò tí Jèhófà máa ṣe lẹ́yìn tí ilẹ̀ Júdà bá ti di ahoro, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.” (Aísá. 30:18) Wòlíì Míkà náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́. Ó wá sọ ohun tó jẹ́ ìpinnu rẹ̀, ó ní: “Jèhófà ni èmi yóò máa wá.” (Míkà 7:⁠7) Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ń fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú Mèsáyà, tàbí Kristi. (Lúùkù 3:15; 1 Pét. 1:​10-12) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní náà ń fojú sọ́nà, torí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ṣì ń ṣẹ. Nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà náà, Jèhófà máa tó fi òpin sí ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn. Ó máa pa àwọn èèyàn búburú run, ó sì máa dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò nínú ayé Sátánì tó máa tó kásẹ̀ nílẹ̀ yìí. (1 Jòh. 5:19) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa wà lójúfò ká sì mọ̀ dájú pé ayé yìí ò ní pẹ́ dópin. w15 8/15 2:1, 2

Thursday, December 14

Ìtara fún ilé rẹ yóò jẹ mí run.​—Jòh. 2:17.

Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn. (Ẹ́kís. 25:⁠8) Nígbà tó yá, wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì fún ìjọsìn Jèhófà. (1 Ọba 8:​27, 29) Lẹ́yìn tí àwọn Júù pa dà dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì, wọ́n máa ń péjọ pọ̀ déédéé nínú sínágọ́gù. (Máàkù 6:2; Jòh. 18:20; Ìṣe 15:21) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń pàdé pọ̀ nínú ilé àwọn ará. (Ìṣe 12:12; 1 Kọ́r. 16:19) Lóde òní, àwọn èèyàn Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì jọ́sìn nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn kárí ayé. Jésù fẹ́ràn tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó sì mọrírì rẹ̀. Èyí rán òǹkọ̀wé Ìhìn Rere kan létí ọ̀rọ̀ onísáàmù náà tá a fà yọ nínú ẹsẹ Bíbélì wà tòní. (Sm. 69:⁠9) Kò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kankan tá a lè pè ní “ilé Jèhófà” bíi ti tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (2 Kíró. 5:13; 33:⁠4) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì ní àwọn ìlànà tó jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká máa lo àwọn ibi ìjọsìn wa lóde òní àti bí a ó ṣe máa ṣe ohun tó fi ọ̀wọ̀ hàn fún un. w15 7/15 4:1, 2

Friday, December 15

Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ.​—Kól. 3:14.

Ṣé a ó lè máa fìfẹ́ bára wa gbé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi? Tó bá ti mọ́ wa lára nísinsìnyí láti máa dárí jini ní fàlàlà tá a bá ní aáwọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan, ó máa rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà yẹn. (Kól. 3:​12, 13) Tá a bá dé inú ayé tuntun, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà ni ọwọ́ wa máa tẹ ohun tá a bá fẹ́ nígbà tá a bá fẹ́ ẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti máa fi ìmọrírì hàn, ká ní ìtẹ́lọ́rùn ní ipòkípò tá a bá wà, ká sì máa jàǹfààní látinú mímọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso àti pé ìfẹ́ ló fi ń ṣàkóso. Ìyẹn á túmọ̀ sí pé ká máa fi àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa nísinsìnyí ṣèwà hù. Tá a bá ń gbé irú ìgbé ayé tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé nígbà yẹn báyìí, àá ní àwọn ànímọ́ tó yẹ ká máa fi ṣèwà hù títí láé. A ó máa sọ ìgbàgbọ́ wa dọ̀tun nínú “ayé tí n bọ̀” torí ó dá wa lójú pé ó máa dé. (Héb. 2:​5, Bíbélì Mímọ́; 11:⁠1) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ó máa fi hàn pé ó wù wá gan-an pé kí òdodo gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Paríparí rẹ̀ ni pé à ń múra sílẹ̀ fún ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. w15 8/15 3:11, 12

Saturday, December 16

Ẹ máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Jésù].​—Kól. 2:6.

Tó o bá ń yẹ èso tó ti gbó wò lórí igbá, wàá rí i pé gbogbo wọn ò rí bákan náà. Síbẹ̀, wàá rí ohun tó máa mú kó o mọ̀ pé wọ́n ti gbó. Bákan náà, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn Kristẹni tó dàgbà dénú fi yàtọ̀ síra, irú bí ìlú tí wọ́n ti wá, bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà, ìlera wọn, ọjọ́ orí wọn àti ìrírí wọn. Ìwà àti àṣà ìbílẹ̀ wọn sì tún lè yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, àwọn ohun kan wà tá a fi ń mọ gbogbo àwọn tó bá dàgbà dénú. Kí làwọn ohun náà? Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa ká lè máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” Nítorí náà, àpẹẹrẹ Jésù ni ìránṣẹ́ Jèhófà tó dàgbà dénú máa ń tẹ̀ lé. (1 Pét. 2:21) Kí ni Jésù sọ pé ó ṣe pàtàkì jù? Ó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn àti èrò inú wa, ká sì tún nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa bí ara wa. (Mát. 22:​37-39) Ohun tí Jésù sọ yìí ni Kristẹni tó dàgbà dénú máa ń ṣe. Ó máa ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ló kà sí pàtàkì jù, ó sì máa ń fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sáwọn èèyàn. w15 9/15 1:3-5

Sunday, December 17

Nípasẹ̀ fífi òtítọ́ hàn kedere, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà olúkúlùkù ẹ̀rí-ọkàn ẹ̀dá ènìyàn níwájú Ọlọ́run.​—2 Kọ́r. 4:2.

Ẹ̀rí ọkàn tó dáa máa ń kìlọ̀ fún wa nípa ìwà tí kò dáa, ó sì tún máa ń sún wa ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú àwọn iṣẹ́ rere tó yẹ ká máa ṣe ni ìwàásù ilé-dé-ilé, ká sì tún máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà. Ẹ̀rí ọkàn Pọ́ọ̀lù sún un láti ṣe bẹ́ẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!” (1 Kọ́r. 9:16) Bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, ẹ̀rí ọkàn wa á máa sọ fún wa pé ohun tó tọ́ là ń ṣe. Bá a sì ṣe ń wàásù ìhìn rere, à ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn àwọn tá à ń wàásù fún. Ẹ̀rí ọkàn wa sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, tá a sì ń sapá láti fi í sílò, ńṣe là ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀bùn iyebíye yìí á máa dárí wa síbi tó tọ́ nínú ìgbésí ayé wa. w15 9/15 2:16, 18

Monday, December 18

Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà.​—Òwe 3:12.

Ìtàn ìgbésí ayé Jósẹ́fù, Mósè àti Dáfídì wà lára àwọn ìtàn tó gùn jù lọ nínú Bíbélì tí àlàyé rẹ̀ sì ṣe kedere. Tá a bá ń kà nípa bí Jèhófà ṣe dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro àti bó ṣe lò wọ́n láti ṣe àwọn ohun ribiribi, àá túbọ̀ rí bí Jèhófà ṣe ń tọ́jú wa tó sì ń fìfẹ́ hàn sí wa. A tún lè rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa nínú ìbáwí tó bá fún wa. Tí Jèhófà bá bá àwọn tó hùwà àìtọ́ wí, tí wọ́n bá fetí sílẹ̀ tí wọ́n sì ronú pìwà dà, ó máa “dárí jì lọ́nà títóbi.” (Aísá. 55:⁠7) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Dáfídì sọ ohun tó wọni lọ́kàn nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jini nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ń dárí gbogbo ìṣìnà rẹ jì, ẹni tí ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn, ẹni tí ń gba ìwàláàyè rẹ padà kúrò nínú kòtò, ẹni tí ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú dé ọ ládé.” (Sm. 103:​3, 4) Ǹjẹ́ kí àwa náà máa gba ìmọ̀ràn Jèhófà, kódà tó bá bá wa wí ká tètè ṣègbọràn, ká sì máa rántí pé ìfẹ́ tí kò láfiwé tó ní sí wa ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀.​—Sm. 30:5. w15 9/15 4:13, 14

Tuesday, December 19

Màríà . . . sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ [Jésù].​—Lúùkù 10:39.

Ńṣe ni Màtá ń sè tó ń sọ̀ kí ara lè tu Jésù. Gbogbo bó sì ṣe ń dá mú tibí tó ń dá mú tọ̀hún múnú bí i torí pé Màríà ò bá a dá sí i. Jésù rí i pé oúnjẹ tí Màtá ń sè ti pọ̀ jù, torí náà ó fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ fún un pé: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀.” Ó wá sọ́ fún un pé oúnjẹ kan ṣoṣo ti tó. Àmọ́, Jésù gbóríyìn fún Màríà, ó sọ pé: “Ní tirẹ̀, Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 10:​38-42) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Màríà lè tètè gbàgbé ohun tó jẹ lọ́jọ́ yẹn, kò jẹ́ gbàgbé bí Jésù ṣe gbóríyìn fún un àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó gbọ́ látẹnu rẹ̀ torí pé ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Lẹ́yìn ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún, àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀.” (Jòh. 11:⁠5) Gbólóhùn yìí fi hàn pé Màtá gba ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Jésù fún un, ó sì sapá láti sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. w15 10/15 3:3, 4

Wednesday, December 20

Kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run.​—2 Kọ́r. 4:7.

A ní ìdí tó pọ̀ láti gbà pé Jèhófà ń lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ àwa èèyàn lónìí. Látìgbàdégbà là ń rí báwọn èèyàn ṣe ń gbàdúrà pé káwọn lè sún mọ́ Ọlọ́run, tí Ọlọ́run sì ń gbọ́ àdúrà wọn. (Sm. 53:⁠2) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Allan ń wàásù láti ilé dé ilé ní erékùṣù kékeré kan ní orílẹ̀-èdè Philippines, ó bá obìnrin kan pàdé. Nígbà tí obìnrin náà rí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Allan sọ pé: “Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, obìnrin náà gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ wá òun rí. Àdúrà rẹ̀ yára gbà débi pé kò lè pa á mọ́ra mọ́, ló bá bú sẹ́kún.” Láàárín ọdún kan, ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti rí i dájú pé òun ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó ti di bárakú bíi mímu sìgá, ìjoògùnyó tàbí wíwo àwọn ohun tó ń mọ́kan ẹni fà sí ìṣekúṣe. Àwọn kan sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ti gbìyànjú láti jáwọ́, àmọ́ pàbó ló já sí. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, ó fún wọn ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n borí àwọn àṣà tó ti di bárakú náà.​—Sm. 37:23, 24. w15 10/15 1:10, 11

Thursday, December 21

[Ra] àkókò tí ó rọgbọ pa dà.​—Éfé. 5:16.

Àwọn kan máa ń jí láàárọ̀ kùtù kí wọ́n lè kàwé, kí wọ́n ṣàṣàrò, kí wọ́n sì gbàdúrà. Àwọn míì sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà oúnjẹ ọ̀sán. Ó lè jẹ́ pé ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ló máa rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí lálẹ́ kó o tó sùn. Àwọn kan fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì láàárọ̀ àti lálẹ́ kí wọ́n tó lọ sùn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń kà á “ní ọ̀sán àti ní òru,” tàbí déédéé. (Jóṣ. 1:⁠8) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká máa lò lára àkókò tá a fi ń ṣe àwọn nǹkan míì láti máa ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé òun máa bù kún gbogbo àwọn tó ń ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ òun tí wọ́n sì ń sapá láti fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò. (Sm. 1:​1-3) Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!” (Lúùkù 11:28) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, tá a bá ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, a jẹ́ ká lè máa bọlá fún Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá tó dá ọpọlọ wa. Kí wá lèyí á yọrí sí? Jèhófà á mú ká láyọ̀ nísinsìnyí a ó sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun òdodo rẹ̀.​—Ják. 1:25; Ìṣí. 1:3. w15 10/15 4: 17, 18

Friday, December 22

Pétérù mú [Jésù] lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí lọ́nà mímúná, pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.”​—Mát. 16:22.

Ohun tó dáa ni àpọ́sítélì Pétérù ní lọ́kàn nígbà tó rọ Jésù pé kó ṣàánú ara rẹ̀ kí wọ́n má bàa pa á. Jésù mọ̀ pé ohun tí Pétérù ń rò yìí ò tọ́ rárá. Kí Jésù lè ran Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù lọ́wọ́, ó fún wọn ní ìkìlọ̀ tó lágbára, ó jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ téèyàn bá kọ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìbùkún téèyàn máa rí gbà tó bá fínnú-fíndọ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mát. 16:​21-27) Ó dájú pé Pétérù rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tí Jésù sọ. (1 Pét. 2:​20, 21) Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o ní òye kó o lè mọ ìgbà tí ọmọ rẹ bá nílò ìrànlọ́wọ́. (Sm. 32:⁠8) Bí àpẹẹrẹ, báwo lo ṣe lè mọ̀ bí ìgbàgbọ́ ọmọ rẹ bá ti ń jó rẹ̀yìn? Ṣó o kíyè sí i pé kò fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́? Ṣó ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ àwọn ará láìdáa? Àbí kì í fẹ́ sọ tinú ẹ̀ mọ́? Èyí wù kó jẹ́, má ṣe yára parí èrò sí pé ọmọ rẹ ti ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù. Síbẹ̀, má ṣe gbójú fo àwọn ohun tó o kíyè sí nípa ọmọ rẹ tàbí kó o wulẹ̀ ronú pé tó bá yá, kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. w15 11/15 2:12, 13

Saturday, December 23

Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. . . . Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.​—Kól. 3:12, 14.

Ojúlówó ìfẹ́ táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ní àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa fi hàn pé àwa là ń ṣe ìjọsìn tòótọ́. Èyí sì bá ohun tí Jésù sọ mu pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:​34, 35) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù hàn gbangba nípasẹ̀ òtítọ́ yìí: Olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ ní ṣíṣe òdodo kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀. Nítorí èyí ni ìhìn iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, pé a ní láti ní ìfẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Jòh. 3:​10, 11) Ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi hàn pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́, àwa sì ni Ọlọ́run ń lò láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà jákèjádò ayé.​—Mát. 24:14. w15 11/15 4:10, 11

Sunday, December 24

Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.​—Òwe 25:11.

Àṣà ìbílẹ̀ àti ẹ̀sìn àwọn èèyàn yàtọ̀ síra, torí náà a gbọ́dọ̀ fòye mọ ìgbà tó tọ́ láti sọ̀rọ̀. Oríṣiríṣi ipò ló lè wáyé, táá gba pé ká ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ lè dùn wá bó tilẹ̀ jẹ́ pé ire wa ló ní lọ́kàn. Ó máa dáa tá a bá lè fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ náà bóyá ó tiẹ̀ tó nǹkan tá a máa fèsì sí. Tó bá wá pọn dandan pé ká sọ̀rọ̀, kò ní bọ́gbọ́n mu kó jẹ́ ìgbà tí inú ń bí wa la máa dá ẹni náà lóhùn torí a lè fìbínú sọ̀rọ̀ sí i. (Òwe 15:28) Bákan náà, ó yẹ ká máa lo òye tá a bá ń bá àwọn ẹbí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ inú Bíbélì. Òótọ́ ni pé a fẹ́ kí wọ́n wá mọ Jèhófà, àmọ́ àfi ká mú sùúrù ká sì fọgbọ́n ṣe é. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó yẹ lásìkò tó tọ́, ìyẹn lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. w15 12/15 3:6, 8, 9

Monday, December 25

Ó ń fún wa ní ìtọ́ni . . . láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú . . . nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.​—Títù 2:12.

Ó yẹ ká lo “ìyèkooro èrò inú” pàápàá tó bá jẹ́ pé a ò lè fi gbogbo ẹnu ṣàlàyé bí wọ́n ṣe máa ṣe àyẹ̀wò kan fún wa tàbí bí wọ́n ṣe máa tọ́jú irú àìsàn kan. Ṣé ẹni tó dábàá irú àyẹ̀wò tàbí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ lè ṣàlàyé tìfun-tẹ̀dọ̀ bí wọ́n ṣe máa ṣe é? Ṣé ìtọ́jú tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni, ṣé àwọn tó mọ̀ nípa àìsàn náà sì gbà pé ìtọ́jú tó dáa ni? (Òwe 22:29) Àbí nǹkan tí ẹni náà kàn rò ló ń sọ ní tiẹ̀? Bóyá ohun tó gbọ́ ni pé ìlú kan tó jìnnà ni wọ́n ti ṣàwárí ẹ̀ tàbí tí wọ́n ti lò ó. Ṣé ohun tí wọ́n sọ yìí ṣeé gbára lé ṣá? Àwọn àyẹ̀wò kan àtàwọn ìtọ́jú kan wà tó la ìbẹ́mìílò lọ. A gbọ́dọ̀ yẹra fún irú àwọn ìtọ́jú yìí torí Jèhófà ti kìlọ̀ fún wa pé ká máà ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn tó ń lo “agbára abàmì” tàbí àwọn abẹ́mìílò.​—Aísá. 1:13; Diu. 18:10-12. w15 12/15 4:16

Tuesday, December 26

A kò tíì gbé ẹnì kan dìde tí ó tóbi ju Jòhánù Oníbatisí lọ; ṣùgbọ́n ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹni tí ó kéré jù nínú ìjọba ọ̀run tóbi jù ú.​—Mát. 11:11.

Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ èèyàn tí Jèhófà fún ní ẹ̀mí mímọ́ àmọ́ tí wọn ò lọ sọ́run wà nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Jòhánù Oníbatisí. Jésù sọ pé kò sí ẹnì kankan tó tóbi ju Jòhánù lọ, àmọ́ ó tún wá sọ pé Jòhánù ò ní bá òun jọba lọ́run. Dáfídì ni ẹlòmíì tí Jèhófà tún fún ní ẹ̀mí mímọ́. (1 Sám. 16:13) Ẹ̀mí mímọ́ mú kó mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà, ó sì tún darí rẹ̀ láti kọ àwọn apá kan lára Ìwé Mímọ́. (Máàkù 12:36) Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Dáfídì “kò gòkè lọ sí ọ̀run.” (Ìṣe 2:34) Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀, àmọ́ kò fi yàn wọ́n láti lọ sọ́run. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé wọn ò pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ délẹ̀délẹ̀ àbí pé wọn ò tẹ́ni tó ń bá Jésù jọba lọ́run? Rárá. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jèhófà máa jí wọn dìde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.​—Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15. w16.01 3:16

Wednesday, December 27

Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.​—Jòh. 10:30.

Bá a ṣe ń bá àwọn tá a nífẹ̀ẹ́ ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ la óò túbọ̀ máa mọ̀ wọ́n sí i. Àá túbọ̀ mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àtàwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Àá mọ àwọn ohun tí wọ́n fi ṣe àfojúsùn wọn àtàwọn ohun tí wọ́n ṣe kọ́wọ́ wọn lè tẹ̀ ẹ́. Àfàìmọ̀ kí Jésù má ti bá Jèhófà ṣiṣẹ́ fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún. Èyí sì mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn lágbára débi pé kò sóhun tó lè da àárín wọn rú. Àwọn méjèèjì mọwọ́ ara wọn gan-an, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan. Jésù bẹ Jèhófà pé kó máa dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. Kí nìdí? Jésù sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́.” (Jòh. 17:11) Bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run, tá a sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ la óò túbọ̀ máa mọ àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí Jèhófà ní. Àá máa rí ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká gbẹ́kẹ̀ lé e ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó ń fún wa. Bá a sì ṣe ń sún mọ́ Ọlọ́run lòun náà á máa sún mọ́ wa. (Ják. 4:⁠8) Bákan náà, àá túbọ̀ sún mọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa torí pé ìṣòro kan náà ni gbogbo wa ń dojú kọ, ohun kan náà ló ń fún gbogbo wa láyọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun sì ni gbogbo wa ń lé. w16.01 5:9, 10

Thursday, December 28

Bá aya arákùnrin ọkọ rẹ pa dà.​—Rúùtù 1:15.

Náómì ti pinnu pé ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ilẹ̀ ìbílẹ̀ òun lòun á pa dà sí. Kí ni Rúùtù á wá ṣe ní tiẹ̀? Àfi kó yáa ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa kó tó lè ṣèpinnu. Ṣé kó pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ẹ̀ nílẹ̀ Móábù ni àbí kó máa bá Náómì ìyá ọkọ rẹ̀ lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù? (Rúùtù 1:​1-8, 14) Ilẹ̀ Móábù làwọn èèyàn Rúùtù ń gbé. Ó lè pa dà sọ́dọ̀ wọn, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀ kí wọ́n sì máa tọ́jú rẹ̀. Kì í kúkú ṣàjèjì wọn, ó gbọ́ èdè wọn dáadáa, ó sì mọ àṣà ilẹ̀ Móábù dunjú. Náómì ò lè fi gbogbo ẹnu sọ bóyá Rúùtù á ní àwọn àǹfààní yìí ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Náómì ò sì lè fọwọ́ sọ̀yà pé òun á rí ọkọ fún Rúùtù tàbí ilé tó máa gbé. Torí náà, Náómì sọ fún un pé kó pa dà sí ilẹ̀ Móábù. Ópà náà ṣáà “ti padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀.” (Rúùtù 1:​9-15) Àmọ́ Rúùtù pinnu pé òun ò ní pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn òun àtàwọn ọlọ́run èké tí wọ́n ń sìn. w16.02 2:4, 5

Friday, December 29

Kí ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?​—Míkà 6:8.

Sọ́ọ̀lù àti àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọmọ ogun rẹ̀ ń wá Dáfídì nínú aginjù Júdà kí wọ́n lè pa á. Àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ kan, Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rí ibi tí Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí. Gbogbo wọn ti sùn lọ fọnfọn, bí Dáfídì àti Ábíṣáì ṣe yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ gba àárín àwọn ọmọ ogun náà kọjá títí wọ́n fi dé ibi tí Sọ́ọ̀lù sùn sí nìyẹn. Ábíṣáì rọra sọ fún Dáfídì pé: “Jẹ́ kí n fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré, èmi kì yóò sì ṣe é sí i lẹ́ẹ̀mejì.” Àmọ́, Dáfídì ò jẹ́ kí Ábíṣáì pa Sọ́ọ̀lù. Dáfídì wá sọ fún Ábíṣáì pé: “Má ṣe run ún, nítorí ta ni ó na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì òróró Jèhófà tí ó sì wà ní aláìmọwọ́-mẹsẹ̀?” Lẹ́yìn náà Dáfídì sọ fún un pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà, láti na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Jèhófà!” (1 Sám. 26:​8-12) Dáfídì mọ bóun ṣe lè fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ó mọ̀ pé ó pọn dandan kóun bọ̀wọ̀ fún Sọ́ọ̀lù, kò sì ronú láti pa á. Kí nìdí? Torí pé Ọlọ́run ti yan Sọ́ọ̀lù láti jẹ́ ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Lónìí, bíi ti àtijọ́, Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ òun jẹ́ adúróṣinṣin sí òun kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún àwọn tí òun ti fi sípò àṣẹ. w16.02 4:1, 2

Saturday, December 30

Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí.​—Sm. 40:8.

Ṣé ọ̀dọ́ ni ẹ́, tó o sì fẹ́ ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó dára jù lọ lo fẹ́ ṣe yẹn. Àmọ́ má ṣe gbàgbé pé, ìrìbọmi gba àròjinlẹ̀. Ìrìbọmi ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ìyẹn ni pé, o ti ṣèlérí fún Jèhófà pé òun ni wàá máa sìn títí láé àti pé bó o ṣe máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ lo kà sí pàtàkì jù lọ. Ìlérí tó o ṣe fún Ọlọ́run yẹn gba àròjinlẹ̀, torí náà kó o tó ṣèrìbọmi, rí i dájú pé ó tọkàn rẹ wá, o ti dàgbà dénú tó láti ṣèpinnu, o sì ti lóye ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Àmọ́, ó lè máa ṣé ẹ bíi pé kó o máà tíì ṣèrìbọmi. Ó sì lè wù ẹ́ kó o ṣèrìbọmi ṣùgbọ́n káwọn òbí ẹ rò pé ó yẹ kó o gbọ́njú díẹ̀ sí i. Kí ló yẹ kó o ṣe? Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́ ní báyìí ná, mú kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i, kó o lè ṣèrìbọmi láìpẹ́. w16.03 2:1, 2

Sunday, December 31

Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.​—2 Kọ́r. 6:14.

Lẹ́yìn táwọn kan ti ṣègbéyàwó ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ọkọ tàbí aya wọn ò sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tọ́rọ̀ bá rí báyìí, irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, wọ́n sì máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti rí i dájú pé okùn ìfẹ́ tó wà láàárín wọn ò já. Èyí lè má fìgbà gbogbo rọrùn. Ṣe ni Sátánì ń gbógun ti ìdílé lónìí. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwọn tọkọtaya tó ń sin Jèhófà ṣera wọn lọ́kan. Bó ti wù kó pẹ́ tó tẹ́ ẹ ti ṣègbéyàwó, máa ronú àwọn ọ̀rọ̀ tó o lè sọ tàbí àwọn ohun tó o lè ṣe táá mú kí ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní síra yín máa lágbára sí i. Tó bá ti pẹ́ tẹ́ ẹ ti ṣègbéyàwó, ẹ lè jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn tí ò tíì pẹ́ tí wọ́n ṣègbéyàwó. Ẹ lè pè wọ́n wá sílé yín nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín. Àpẹẹrẹ rere yín á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bó ti wù kó pẹ́ tó tí tọkọtaya kan ti ń bára wọn bọ̀, wọ́n ṣì gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn síra wọn, kí wọ́n sì ṣera wọn lọ́kan.​—Títù 2:3-7. w16.03 3:14, 15

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́