May
Tuesday, May 1
A . . . tẹ àwọn ọmọ Ámónì lórí ba.—Oníd. 11:33.
Jẹ́fútà mọ̀ pé àfi kí Ọlọ́run ti òun lẹ́yìn kóun tó lè gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ámónì. Torí náà, ó ṣèlérí fún Jèhófà pé tó bá jẹ́ kí òun ṣẹ́gun, tí òun sì pa dà sílé ní ayọ̀ àti àlàáfíà, òun á fi ẹni tó bá kọ́kọ́ jáde wá pàdé òun láti inú ilé òun rú “ọrẹ ẹbọ sísun” sí Ọlọ́run. (Oníd. 11:30, 31) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Jèhófà kórìíra fífi èèyàn rúbọ, torí náà, a mọ̀ pé kì í ṣe pé Jẹ́fútà fẹ́ pa èèyàn fi rúbọ ní ti gidi. (Diu. 18:9, 10) Nínú Òfin Mósè, ọrẹ ẹbọ sísun ni ẹ̀bùn pàtàkì téèyàn fún Jèhófà pátápátá. Torí náà, ohun tí Jẹ́fútà ní lọ́kàn ni pé ẹni tóun máa fi fún Jèhófà á máa sìn nínú àgọ́ ìjọsìn jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Jẹ́fútà, ó sì mú kó ṣẹ́gun. (Oníd. 11:32) Nígbà tí Jẹ́fútà togun dé, ọmọbìnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n lẹni àkọ́kọ́ tó jáde wá pàdé rẹ̀, òun sì lọmọ kan ṣoṣo tó bí! Ṣé Jẹ́fútà á wá lè mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ báyìí? w16.04 1:11-13
Wednesday, May 2
Wọ́n ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.—Neh. 8:8.
Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ ìjọ ló ka ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Báwo ló ṣe rí lára rẹ nígbà tá à ń jíròrò àwọn ànímọ́ Jèhófà, tó o sì tún gbọ́ báwọn ará ṣe ń sọ bó ṣe rí lára wọn? Ó dájú pé ṣe nìyẹn mú kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Láwọn ìpàdé ìjọ, a túbọ̀ máa ń lóye Bíbélì nípa títẹ́tí sí àwọn àsọyé, Bíbélì kíkà àti wíwo àwọn àṣefihàn. Àwọn ìpàdé tá à ń ṣe, irú bí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ń kọ́ wa pé ká máa fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù. (1 Tẹs. 4:9, 10) Bí àpẹẹrẹ, ṣó o ti wà níbi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ kan rí tó o sì wá rí i pé ó yẹ kó o ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, pé ó yẹ kó o túbọ̀ mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i tàbí pé o gbọ́dọ̀ dárí ji arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan tó ṣẹ̀ ọ́? Ìpàdé tá a máa ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ máa ń kọ́ wa láwọn ọ̀nà tá a lè gbà wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.—Mát. 28:19, 20. w16.04 3:4, 5
Thursday, May 3
Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa. —Róòmù 15:4.
Ṣé o ti fìgbà kan rí ronú lórí àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n ní aáwọ̀ láàárín ara wọn? Àwọn àpẹẹrẹ kan wà nínú àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì. Kéènì pa Ébẹ́lì (Jẹ́n. 4:3-8); Lámékì pa ọ̀dọ́kùnrin kan torí pé ó gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́ (Jẹ́n. 4:23); aáwọ̀ wà láàárín àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ábúráhámù (Ábúrámù) àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn Lọ́ọ̀tì (Jẹ́n. 13:5-7); Hágárì fi Sárà (Sáráì) ṣẹ̀sín, Sárà náà sì tún bínú sí Ábúráhámù (Jẹ́n. 16:3-6); Íṣímáẹ́lì ń bá gbogbo èèyàn jà, gbogbo èèyàn sì ń bá òun náà jà. (Jẹ́n. 16:12) Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ̀rọ̀ nípa àwọn aáwọ̀ tó wáyé yìí? Ìdí ni pé ó máa jẹ́ kí àwa èèyàn aláìpé rí ìdí tó fi yẹ ká máa bára wa gbé ní àlàáfíà. Ó tún jẹ́ ká mọ báa ṣe lè máa wá àlàáfíà. Tá a bá kà nípa bí àwọn èèyàn bíi tiwa ṣe yanjú aáwọ̀, ìyẹn máa jẹ́ káwa náà mọ ohun tó yẹ ká ṣe. A máa mọ ohun tí ìsapá wọn yọrí sí, àwa náà á sì lè fi ohun tí wọ́n ṣe yẹn yanjú àwọn ìṣòro kan tá à ń dojú kọ nígbèésí ayé wa. Gbogbo èyí máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tí kò yẹ ká ṣe táwa náà bá ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. w16.05 1:1, 2
Friday, May 4
A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. —Máàkù 13:10.
Ọ̀nà wo ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà wàásù ìhìn rere? Wọ́n máa ń wá àwọn èèyàn lọ síbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí wọn, yálà ní ìta gbangba tàbí nínú ilé wọn. Iṣẹ́ ìwàásù náà gba pé kí wọ́n máa wá àwọn ẹni yíyẹ rí láti ilé dé ilé. (Mát. 10:11; Lúùkù 8:1; Ìṣe 5:42; 20:20) Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà wàásù yìí fi hàn pé wọn kì í ṣojúsàájú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́? Àwọn nìkan ló ń wàásù pé Jésù ti di Ọba, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso látọdún 1914. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jésù fún wọn, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù yẹn ni wọ́n kà sí pàtàkì jù. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́sìn, ìyẹn Pillars of Faith—American Congregations and Their Partners sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò jẹ́ gbàgbé pé olórí iṣẹ́ àwọn ni láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa òpin tó ń bọ̀ àti ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè rí ìgbàlà.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń polongo ìhìn rere náà, ọ̀nà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà ṣe é làwọn náà sì ń gbà ṣe é. w16.05 2:10, 12
Saturday, May 5
Ìwọ yóò . . . rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.—Òwe 2:5.
Tá a bá ń ṣèpinnu tó bá èrò Jèhófà mu, àárín àwa àti Jèhófà á túbọ̀ gún régé. (Ják. 4:8) Àá rójú rere rẹ̀, á sì máa bù kún wa. Èyí á mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Baba wa ọ̀run máa lágbára sí i. Torí náà, ká jẹ́ kí àwọn ìlànà àti òfin tó wà nínú Bíbélì máa darí àwọn ìpinnu tá à ń ṣe, àá tipa bẹ́ẹ̀ máa ṣe ohun tó bá èrò Ọlọ́run mu. Òótọ́ kan ni pé títí láé làá máa róhun tuntun kọ́ nípa Jèhófà. (Jóòbù 26:14) Àmọ́, tá a bá sapá gidigidi nísinsìnyí, àá ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye táá jẹ́ ká máa ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. (Òwe 2:1-5) Àwọn èèyàn lè gbà pé ohun kan dáa lónìí, àmọ́ kó dọ̀la kó má wúlò mọ́. Àmọ́ ti Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀, onísáàmù náà rán wa létí pé: “Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ète Jèhófà yóò dúró; ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ ń bẹ láti ìran kan tẹ̀ lé ìran mìíràn.” (Sm. 33:11) Ó ṣe kedere nígbà náà pé a lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu tá a bá ń jẹ́ kí Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ orísun ọgbọ́n, máa darí èrò àti ìṣe wa. w16.05 3:17
Sunday, May 6
Ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.—1 Sám. 16:7.
Ó ṣe kedere pé Jèhófà lágbára láti mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, a sì mọ̀ pé òun fúnra rẹ̀ ló ń pinnu ẹni tó máa fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Torí náà, kò yẹ ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, yálà àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tàbí àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ. (Jòh. 6:44) Tá a bá gbà pé Jèhófà ni Amọ̀kòkò wa lóòótọ́, ó máa hàn nínú bá a ṣe ń hùwà sáwọn ará wa. (Aísá. 64:8) Ó yẹ ká bi ara wa pé, Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lèmi náà fi ń wò wọ́n, pé Jèhófà ò tíì mọ wọ́n tán, ó ṣì ń mọ wọ́n lọ́wọ́? Ó mọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú, ó sì mọ irú ẹni tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa jẹ́ bí òun ṣe ń mọ wá nìṣó. Torí náà, Jèhófà kì í wo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, ibi tá a dáa sí àti bá a ṣe máa rí nígbà tó bá mọ wá tán ló máa ń wò. (Sm. 130:3) Ẹ jẹ́ ká fìwà jọ Jèhófà, ká máa wo ibi táwọn ará wa dáa sí. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, á dáa ká máa bá Amọ̀kòkò wa ṣiṣẹ́. Lọ́nà wo? Ká máa ti àwọn ará wa lẹ́yìn bí wọ́n ti ń sapá láti túbọ̀ fìwà jọ Ọlọ́run wa. (1 Tẹs. 5:14, 15) Àwọn alàgbà la retí pé kó múpò iwájú nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀, torí pé “ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” ni wọ́n.—Éfé. 4:8, 11-13. w16.06 1:4-6
Monday, May 7
Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú. —1 Kọ́r. 10:12.
Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe máa ń mú ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rere míì tó para pọ̀ jẹ́ èso tẹ̀mí. (Gál. 5:22, 23) Àwa náà kúkú mọ̀ pé, bá a ṣe ń hùwà tó yẹ Kristẹni lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó ń buyì kún ọ̀rọ̀ wa, ó sì wà lára ohun tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn tẹ́tí sọ́rọ̀ wa. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì wàásù fún obìnrin kan, àmọ́ obìnrin yẹn sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wọn, síbẹ̀ àwọn méjèèjì ò gbin. Lẹ́yìn tí wọ́n lọ, obìnrin náà da ọ̀rọ̀ yẹn rò, ó rí i pé ohun tóun ṣe ò dáa, ló bá kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Díẹ̀ lára ohun tó kọ rèé: “Ẹ jọ̀ọ́ ẹ bá mi bẹ àwọn méjì tó wá wàásù fún mi, èèyàn jẹ́jẹ́ ni wọ́n, wọ́n sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ìwà àìlójútì gbáà ni mo hù, mo sì jọ ara mi lójú. Ohun tí mo ṣe kò bọ́gbọ́n mu rárá, káwọn èèyàn wá wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún mi, kí n sì lé wọn bí ẹni lé ajá, ó kù díẹ̀ káàtó.” Ẹ gbọ́ ná, ká ní ńṣe làwọn ará yẹn tiẹ̀ bínú díẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ṣé obìnrin yìí á lè kọ irú ohun tó kọ yẹn? Kò dájú pé á ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé lóòótọ́ ni iṣẹ́ ìwàásù ń ṣe wá láǹfààní, àwa nìkan sì kọ́, ó tún ń ṣàǹfààní fáwọn tá à ń wàásù fún. w16.06 2:12, 13
Tuesday, May 8
Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.—Mát. 22:39.
Gbogbo wa la jẹ́ aláìpé. (Róòmù 5:12, 19) Torí náà, àwọn kan nínú ìjọ lè sọ ohun kan tàbí ṣe ohun tó máa dùn wá nígbà míì. Irú àwọn àkókò yìí la máa ń mọ̀ bóyá lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Kí la máa ṣe tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ní àwọn ọmọkùnrin méjì tí kò ka òfin Jèhófà sí. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin Élì jẹ́ aláìdára fún ohunkóhun; wọn kò ka Jèhófà sí.” (1 Sám. 2:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ pàtàkì ni Élì ń ṣe láti gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ, síbẹ̀ ìwà burúkú làwọn ọmọ rẹ̀ ń hù. Kàkà kí Élì bá wọn wí, ńṣe ló gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún wọn. Torí náà, Ọlọ́run dá gbogbo ilé Élì lẹ́jọ́. (1 Sám. 3:10-14) Nígbà tó yá, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ò láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà mọ́. Ká sọ pé ìgbà ayé Élì ni ìwọ náà gbáyé, kí lo máa ṣe bó o ṣe rí i tí Élì ń gbójú fo ìwà burúkú táwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ń hù? Ṣé wàá jẹ́ kíyẹn bí ẹ nínú débi tí wàá fi fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀? w16.06 4:5, 6
Wednesday, May 9
Gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.—Mát. 6:33.
Kí nìdí tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí,” ìyẹn àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé. Jèhófà mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nílò, kódà kí àwa fúnra wa tó mọ̀ pé a máa nílò wọn. Jèhófà mọ̀ pé a nílò oúnjẹ, aṣọ àti ilé. (Fílí. 4:19) Ó mọ àwọn aṣọ wa tí kò ní pẹ́ gbó. Ó mọ irú oúnjẹ tá a nílò àti irú ilé tó máa tu àwa àti ìdílé wa lára. Ó dájú pé Jèhófà máa bójú tó gbogbo àwọn nǹkan tá a nílò ní ti gidi. Tá a bá ṣe ohun tó yẹ ká ṣe, tá à ń fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, Jèhófà máa pèsè ohun rere fún wa. Tá a bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, a máa jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn, ìyẹn “oúnjẹ,” “aṣọ àti ilé.”—1 Tím. 6:6-8. w16.07 1:17, 18
Thursday, May 10
Nígbà tí àwa jẹ́ ọ̀tá, a mú wa padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ikú Ọmọ rẹ̀.—Róòmù 5:10.
Ikú Ọmọ rẹ̀ yìí ló mú kí àárín àwa àti Jèhófà pa dà gún régé. Pọ́ọ̀lù so ọ̀rọ̀ náà mọ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, ó sọ pé: “Nísinsìnyí tí a ti polongo wa [ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Kristi] ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́, ẹ jẹ́ kí a máa gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi, ẹni tí àwa pẹ̀lú tipasẹ̀ rẹ̀ rí ọ̀nà ìwọlé wa nípa ìgbàgbọ́ sínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí nínú èyí tí àwa dúró nísinsìnyí.” (Róòmù 5:1, 2) Ẹ ò rí i pé ìbùkún yẹn ga! Torí pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí wa sí, a kì í ṣe olódodo. Àmọ́ wòlíì Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé tó bá di àkókò òpin, “àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró máa “mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo.” (Dán. 12:3) Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ sì rí torí pé nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù táwọn ẹni àmì òróró ń ṣe àti bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ti mú kí Jèhófà máa fojú olódodo wo ẹgbàágbèje àwọn “àgùntàn mìíràn.” (Jòh. 10:16) Àmọ́ o, kì í ṣe mímọ́ ṣe wọn, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ló mú kí èyí ṣeé ṣe.—Róòmù 3:23, 24. w16.07 3:10, 11
Friday, May 11
Wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.—Jẹ́n. 6:2.
Torí pé Ọlọ́run ò dá àwọn áńgẹ́lì pé kí wọ́n máa láya, àdàmọ̀dì ọmọ tí Bíbélì pè ní Néfílímù ni wọ́n bí jọ. Yàtọ̀ síyẹn, “ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́n. 6:1-5) Ọlọ́run fi àkúnya omi pa àwọn èèyàn búburú run nígbà ayé Nóà. Nígbà yẹn, ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu títí kan ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ló gba àwọn èèyàn náà lọ́kàn. Ó burú débi pé wọn ò kọbi ara sí bí “Nóà oníwàásù òdodo” ṣe ń kìlọ̀ fún wọn pé ayé yẹn máa tó pa run. (2 Pét. 2:5) Jésù wá fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn wé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tiwa. (Mát. 24:37-39) Lónìí, à ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé ká lè jẹ́rìí fún gbogbo èèyàn kí òpin tó dé, àmọ́ ọ̀pọ̀ ni kì í fẹ́ gbọ́. Kò yẹ ká jẹ́ kí ohunkóhun gbà wá lọ́kàn, ì báà jẹ́ ọ̀rọ̀ ìdílé, ìgbéyàwó tàbí ọmọ títọ́. Tá a bá wà lójúfò, àá máa fi sọ́kàn pé ọjọ́ Jèhófà ò ní pẹ́ dé. w16.08 1:8, 9
Saturday, May 12
Àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù. Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn tí wọ́n ní aya dà bí ẹni pé wọn kò ní, . . . àti àwọn tí ń lo ayé bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.—1 Kọ́r. 7:29-31.
Torí pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé yìí, à ń kojú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1-5) Tá a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ayé búburú yìí ò ní kó èèràn ràn wá. Nínú ẹ̀kọ́ ojúmọ́ wa tòní, Pọ́ọ̀lù ò sọ pé káwọn tó ti ṣègbéyàwó pa ẹnì kejì wọn tì o, ohun tó ń sọ ni pé kí wọ́n máa fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ torí pé àkókò tó ṣẹ́ kù ti dín kù. (Mát. 6:33) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àkókò tó le gan-an là ń gbé, tí ọ̀pọ̀ ìdílé sì ń tú ká, síbẹ̀ ìgbéyàwó wa lè ládùn kó sì lóyin. Táwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni bá ń bá ètò Ọlọ́run rìn, tí wọ́n ń fi ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa darí wọn, wọn ò ní tú “ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀” ká.—Máàkù 10:9. w16.08 2:17, 18
Sunday, May 13
Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.—1 Pét. 5:2.
Ojoojúmọ́ ló túbọ̀ ń ṣe kedere sí i pé a nílò àwọn alàgbà nínú ìjọ. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè di alàgbà lọ́jọ́ iwájú. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí Tímótì, ó ní: “Àwọn nǹkan tí ìwọ sì ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ìtìlẹyìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlẹ́rìí, nǹkan wọ̀nyí ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́, tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” (2 Tím. 2:1, 2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dá Tímótì lẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Ọ̀nà kan náà yìí ni Tímótì wá ń lò láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti láwọn ìgbà míì. (2 Tím. 3:10-12) Pọ́ọ̀lù ò sọ pé Tímótì á kọ́ béèyàn ṣe ń ṣe nǹkan láyè ara rẹ̀. Rárá, ṣe lòun àti Tímótì jọ máa ń ṣe nǹkan. (Ìṣe 16:1-5) Àwọn alàgbà máa ń fara wé Pọ́ọ̀lù, wọ́n máa ń mú àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó kúnjú ìwọ̀n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Àwọn alàgbà ń tipa bẹ́ẹ̀ mú káwọn arákùnrin yìí rí i pé ẹni tó bá máa di alàgbà nínú ìjọ gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́, kó mọ̀ọ̀yàn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kó máa ní sùúrù, kó sì nífẹ̀ẹ́. Táwọn alàgbà bá ń bá àwọn ìránṣẹ́ ìṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣiṣẹ́ lọ́nà yìí, wọ́n á lè tóótun láti di “olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run” lọ́jọ́ iwájú. w16.08 4:16, 17
Monday, May 14
Kí ọwọ́ rẹ má [ṣe] rọ jọwọrọ. —Sef. 3:16.
Tí Bíbélì bá sọ pé ọwọ́ ẹnì kan rọ jọwọrọ, ó sábà máa ń túmọ̀ sí pé onítọ̀hún rẹ̀wẹ̀sì, nǹkan tojú sú u tàbí pé ó sọ̀rètí nù. (2 Kíró. 15:7; Héb. 12:12) Àwọn nǹkan yìí lè máyé súni. Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro làwa èèyàn ń kojú nínú ayé Èṣù yìí, àwọn ìṣòro náà máa ń mú kéèyàn ṣàníyàn, kéèyàn sì rẹ̀wẹ̀sì. A lè fi àníyàn téèyàn máa ń ní wé ìdákọ̀ró tí kì í jẹ́ kí ọkọ̀ ojú omi kúrò lójú kan. (Òwe 12:25) Kí ló máa ń fa àníyàn? Ó lè jẹ́ pé èèyàn wa kan ṣaláìsí, tàbí ara wa ò fi bẹ́ẹ̀ le, ó lè jẹ́ ìṣòro àtijẹ àtimu torí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀, ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ń ta kò wá torí pé à ń sin Jèhófà. Àwọn ìṣòro yìí lè mú kí nǹkan tojú súni, ó sì máa ń tánni lókun. Kódà, ó lè mú kéèyàn má láyọ̀ mọ́. Àmọ́ o, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Aísá. 41:10, 13. w16.09 1:2, 4
Tuesday, May 15
Èmi yóò sáré àní ní ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ.—Sm. 119:32.
Ìṣòro táwọn kan ń bá pò ó ni bí wọ́n ṣe máa borí kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Ńṣe làwọn míì ń sapá gan-an kí wọ́n lè máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bóyá ìṣòro tó ò ń fara dà ni àìsàn, tàbí kẹ̀, ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sẹ́ni tó rí tìẹ rò. A ò sì ní gbàgbé pé kò rọrùn fáwọn míì láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n. Yálà ó ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀ tàbí kò tíì pẹ́, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ máa jà fitafita kí ohunkóhun má bàa dí wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ó sì dájú pé Ọlọ́run máa san wá lẹ́san tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Tó o bá ń gbàdúrà, ẹ̀mí Ọlọ́run máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, wàá lè lókun táá jẹ́ kó o lè ṣe ohun tínú Jèhófà dùn sì, ó sì máa bù kún rẹ. Lẹ́yìn náà, ṣe ohun tó bá àdúrà rẹ mu. Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, máa wáyè láti dá kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé.—Sm. 119:32. w16.09 2:10, 11
Wednesday, May 16
Ìgbàgbọ́ ni . . . ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.—Héb. 11:1.
Ǹjẹ́ ẹnì kan ti sọ fún ẹ rí pé òun gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ torí pé ẹ̀rí wà nínú sáyẹ́ǹsì pé òótọ́ ni, ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, àfi kéèyàn ṣáà ti gbà á gbọ́? Ohun táwọn kan gbà gbọ́ nìyẹn. Àmọ́ ohun kan rèé tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Yálà ẹfolúṣọ̀n lẹnì kan gbà tàbí Ọlọ́run, déwọ̀n àyè kan ó kan ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Kò sẹ́nì kan nínú wa tó rí Ọlọ́run rí, bẹ́ẹ̀ la ò sí níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn nǹkan. (Jòh. 1:18) Bákan náà ni kò sí ẹnì kankan láyé yìí, títí kan àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó lè sọ pé òun rí aláǹgbá tó di àmọ̀tẹ́kùn tàbí ọ̀nì tó di erin. (Jóòbù 38:1, 4) Torí náà, ó gba pé kí gbogbo wa gbé ẹ̀rí tó wà nílẹ̀ wò, ká ronú lé e lórí ká sì dórí ìpinnu. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, ó sọ pé: “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre.”—Róòmù 1:20. w16.09 4:4
Thursday, May 17
Ẹ má gbàgbé aájò àlejò. —Héb. 13:2.
Jèhófà fìfẹ́ ṣe àwọn ètò kan táá mú kí nǹkan rọrùn fún àwọn àjèjì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ṣètò pé kí wọ́n máa pèéṣẹ́ nínú oko àwọn míì. (Léf. 19:9, 10) Jèhófà ò fi dandan lé e pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì, ṣe ló rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ro tàwọn èèyàn náà mọ́ tiwọn. (Ẹ́kís. 23:9) Ó ṣe tán, àwọn náà mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá jẹ́ àjèjì nílẹ̀ ibòmíì. Ilẹ̀ Íjíbítì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé kó tó di pé àwọn èèyàn náà sọ wọ́n dẹrú. Kódà ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ará Íjíbítì ò ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì séèyàn, torí wọ́n gbà pé àwọn dáa jù wọ́n lọ àti pé ẹ̀sìn wọn ò nítumọ̀. (Jẹ́n. 43:32; 46:34; Ẹ́kís. 1:11-14) Ojú pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gan-an nígbà yẹn, àmọ́ ní báyìí tí wọ́n ti wà nílẹ̀ tiwọn, Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n fojú pọ́n àwọn àjèjì tó wà láàárín wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ kí wọ́n kà wọ́n sí “ọmọ ìbílẹ̀” wọn. (Léf. 19:33, 34) Ó dájú pé bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì láyé ìgbà yẹn náà ló ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn lóde òní, pàápàá jù lọ àwọn tó ń wá sípàdé wa. (Diu. 10:17-19; Mál. 3:5, 6) Tá a bá mọ àwọn ìṣòro táwọn àjèjì máa ń ní, àá máa fìfẹ́ hàn sí wọn, àá sì máa gba tiwọn rò. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ gbédè ibi tí wọ́n wà, àwọn èèyàn sì máa ń fojú pa wọ́n rẹ́.—1 Pét. 3:8. w16.10 1:3-5
Friday, May 18
Gẹ́gẹ́ bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.—Ják. 2:26.
Lẹ́tà tí Jákọ́bù kọ ṣàlàyé pé ìgbàgbọ́ kọjá kéèyàn kàn gba nǹkan gbọ́, èèyàn gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ tì í. Jákọ́bù wá sọ pé: “Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí láìsí àwọn iṣẹ́, èmi yóò sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ mi.” (Ják. 2:18) Jákọ́bù tún jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín kéèyàn kàn gba nǹkan gbọ́ àti kéèyàn lo ìgbàgbọ́. Ó ṣe tán, àwọn ẹ̀mí èṣù náà gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ wọn ò nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Dípò kí wọ́n lo ìgbàgbọ́, ṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n á ṣe dí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́. (Ják. 2:19, 20) Àmọ́ nígbà tí Jákọ́bù máa sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù, ó sọ pé: “A kò ha polongo Ábúráhámù baba wa ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́ lẹ́yìn tí ó ti fi Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ? Ẹ̀yin rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àti nípa àwọn iṣẹ́ rẹ̀ a sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé.” (Ják. 2:21-23) Kó lè túbọ̀ ṣe kedere pé a gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wa lẹ́yìn, Jákọ́bù sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹ̀kọ́ ojúmọ́ wa tòní. w16.10 4:8
Saturday, May 19
Àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn.—Oníw. 3:11.
Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti jẹ́ ká mọ̀ nípa àgbáálá ayé wa, àwọn nǹkan tí wọ́n ṣàwárí sì ti ṣe wá láǹfààní gan-an. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìbéèrè làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè dáhùn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ nípa sánmà ò lè sọ bí àgbáálá ayé yìí ṣe wà tàbí ìdí tó fi jẹ́ pé orí ilẹ̀ ayé là ń gbé tí kì í ṣe ibòmíì. Bákan náà, àwọn èèyàn kárí ayé ò lè sọ ìdí tó fi máa ń wù wá pé ká máa wà láàyè nìṣó. Àmọ́, kí nìdí tí wọn ò fi lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì yìí? Ọ̀kan lára ohun tó fà á ni pé ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn míì kò fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé Ọlọ́run wà, ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ni wọ́n ń gbé lárugẹ. Àmọ́, Jèhófà ti fi Bíbélì dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn níbi gbogbo. Gbogbo wa là ń jàǹfààní àwọn òfin ìṣẹ̀dá tí kì í yí pa dà tí Jèhófà gbé kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn oníṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná, àwọn awakọ̀ òfuurufú, àwọn púlọ́ńbà, àwọn ẹnjiníà àtàwọn dókítà máa ń jàǹfààní àwọn òfin yìí kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ wọn. w16.11 2:4, 5
Sunday, May 20
Nípasẹ̀ [Ọlọ́run] ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.—Ìṣe 17:28.
Tá a bá ní ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún gbogbo ohun tó ti ṣe fún wa, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Òun ló fún wa lẹ́mìí, ó sì ń dá wa sí. Ó tún fún wa ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ìyẹn Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bíi tàwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà, àwa náà gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì a sì fọwọ́ pàtàkì mú un. (1 Tẹs. 2:13) Bíbélì ti mú ká sún mọ́ Jèhófà, òun náà sì ti sún mọ́ wa. (Ják. 4:8) Àǹfààní ńlá ni Baba wa ọ̀run fún wa bó ṣe mú ká wà nínú ètò rẹ̀. A sì mọyì àwọn ìbùkún tá à ń rí gbà. Onísáàmù náà sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nígbà tó kọrin pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere: Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sm. 136:1) Ìgbà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] ni ọ̀rọ̀ náà “inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” fara hàn nínú ìwé Sáàmù 136. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ yẹn máa ṣẹ sí wa lára torí a máa wà láàyè títí láé! w16.11 3:18, 19
Monday, May 21
Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.—Róòmù 5:12.
Léraléra la lo ẹsẹ yẹn nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bó o ṣe ń lo ìwé yìí láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ àtàwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ó ṣeé ṣe kó o ka Róòmù 5:12 tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé nínú orí kẹta. Ó ṣeé ṣe kó o tún kà á tẹ́ ẹ bá ńjíròrò nípa ìràpadà ní orí karùn-ún àti nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò nípa ipò tí àwọn òkú wà ní orí kẹfà. Àmọ́, ǹjẹ́ o ti ronú nípa bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe kan àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà, ìwà rẹ àti ọjọ́ ọ̀la rẹ? Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ojoojúmọ́ la sì máa ń ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, ọkàn wa balẹ̀ pé Ọlọ́run máa ń rántí pé erùpẹ̀ ni wá, ó sì ń fàánú hàn sí wa. (Sm. 103:13, 14) Nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù gbà, ó ní ká máa bẹ Jèhófà pé: “Dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.” (Lúùkù 11:2-4) Torí náà, kò yẹ ká tún máa banú jẹ́ lórí àwọn àṣìṣe tí Ọlọ́run ti dárí ẹ̀ jì wá. Síbẹ̀, ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ń ronú nípa ohun tó ń mú kí Ọlọ́run dárí jì wá. w16.12 1:1-3
Tuesday, May 22
Awọn tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara gbé èrò inú wọn ka àwọn ohun ti ẹran ara.—Róòmù 8:5.
Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà káwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù ronú nípa ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì jù lọ. Ṣé kì í ṣe pé “àwọn ohun ti ẹran ara” ló gbà wọ́n lọ́kàn jù? Ó yẹ káwa náà ronú nípa ohun tá a kà sí pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa. Kí la nífẹ̀ẹ́ sí jù, kí lọ̀rọ̀ wa sábà máa ń dá lé? Kí là ń fi ìgbésí ayé wa lé? Ohun táwọn míì kúndùn àtimáa ṣe ni pé kí wọ́n máa gbádùn oríṣiríṣi wáìnì, kí wọ́n máa ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́, kí wọ́n wọ aṣọ aláràbarà, kí wọ́n ṣòwò táá mú èrè rẹpẹtẹ wọlé, kí wọ́n máa gbafẹ́ kiri àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ omi di ọtí wáìnì, Pọ́ọ̀lù náà sì ní kí Tímótì máa mu “wáìnì díẹ̀.” (1 Tím. 5:23; Jòh. 2:3-11) Àmọ́ ṣé ọjọ́ kan ò lè lọ kí Jésù àti Pọ́ọ̀lù má sọ̀rọ̀ ọtí, ṣé ohun tí wọ́n sì fi ń ṣayọ̀ nìyẹn? Ṣé nǹkan tó máa ń wù wọ́n ṣáá nìyẹn, tí wọn ò sì rí nǹkan míì sọ àfi ọ̀rọ̀ wáìnì? Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀. Àwa ńkọ́? Kí ló máa ń wù wá jù? w16.12 2:5, 10, 11
Wednesday, May 23
Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.—Héb. 13:5.
A ti wá rí bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe bá ohun tí Jésù sọ mu pé tá a bá wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run á bù kún wa. (Mát. 6:33) Ìgbà kan wà tí àpọ́sítélì Pétérù bi Jésù pé: “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kí ni yóò wà fún wa ní ti gidi?” (Mát. 19:27) Dípò tí Jésù fi máa bá Pétérù wí pé ó ṣe béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀, ṣe ló fi dá òun àtàwọn yòókù lójú pé Ọlọ́run máa san wọ́n lẹ́san gbogbo ohun tí wọ́n yááfì. Àwọn àpọ́sítélì yẹn àtàwọn míì máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, wọ́n á gbádùn àwọn ìbùkún míì. Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi yóò rí gbà ní ìlọ́po-ìlọ́po sí i, yóò sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mát. 19:29) Ìbùkún táwọn ọmọ ẹ̀yìn á rí gbà máa ju gbogbo ohun tí wọ́n yááfì lọ. Kí lèèyàn lè fi sílẹ̀ tàbí yááfì torí Ìjọba Ọlọ́run tó lè dà bí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ bàbá, ìyá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò àtàwọn ọmọ téèyàn á rí nínú ètò Jèhófà? w16.12 4:4, 5
Thursday, May 24
Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí. —Héb. 11:1.
Tọkàntara làwa Kristẹni fi ń retí ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ṣe fún wa. Yálà ẹni àmì òróró ni wá tàbí a wà lára àwọn “àgùntàn mìíràn,” gbogbo wa pátá là ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, táá sì sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (Jòh. 10:16; Mát. 6:9, 10) Kò sí ìrètí míì tó lè múnú ẹni dùn bí èyí. A tún ń fayọ̀ retí ìgbà tí Jèhófà máa mú ká wà láàyè títí láé, yálà ní ọ̀run tàbí láyé. (2 Pét. 3:13) Ní báyìí ná, inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀. Àwọn èèyàn inú ayé náà máa ń fojú sọ́nà fún àwọn nǹkan kan, àmọ́ kò dá wọn lójú pé ọwọ́ wọn á tẹ nǹkan ọ̀hún. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń retí pé lọ́jọ́ kan, àwọn á jẹ. Àmọ́ wọ́n gbà pé èyí-jẹ èyí-ò-jẹ lọ̀rọ̀ tẹ́tẹ́ títa. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìgbàgbọ́ táwa Kristẹni ní jẹ́ “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú” nípa àwọn ohun tí a ń retí. w16.10 3:1, 2
Friday, May 25
Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìrànṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. —1 Pét. 4:10.
Torí pé Jèhófà jẹ́ onínúure, ó fún wa lẹ́bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ànímọ́ tó yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ sì ni agbára wa ò rí bákan náà. Ó fẹ́ ká máa fàwọn nǹkan yìí bọlá fún òun, ká sì máa fi ṣe àwọn míì láǹfààní. (Róòmù 12:4-8) Àǹfààní ńlá ni Jèhófà fi dá wa lọ́lá yìí, ó sì yẹ ká mọyì wọn ká sì máa lò wọ́n bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Àmọ́ o, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ojú kan náà la máa wà títí lọ, nǹkan lè yí pa dà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù. Níbẹ̀rẹ̀, òun nìkan ló wà pẹ̀lú Jèhófà. (Òwe 8:22) Nígbà yẹn, ó bá Jèhófà ṣiṣẹ́ láti dá àwọn áńgẹ́lì, ayé àti ọ̀run àtàwa èèyàn nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Kól. 1:16) Nígbà tó sì yá, Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé. Ìgbà kan wà tó jẹ́ ọmọ jòjòló, lẹ́yìn náà ó di géńdé. (Fílí. 2:7) Lẹ́yìn tí Jésù ti fara rẹ̀ rúbọ, ó pa dà sọ́run, ó sì di Ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914. (Héb. 2:9) Nǹkan máa tún yí pa dà fún Jésù. Ìdí sì ni pé, lẹ́yìn tí ẹgbẹ̀rún ọdún tó fi máa ṣàkóso bá parí, á gbé ìjọba náà pa dà fún Jèhófà, kí “Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”—1 Kọ́r. 15:28. w17.01 3:11, 12
Saturday, May 26
Lónìí yìí, ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín.—Joṣ. 24:15.
Obìnrin kan fẹ́ kí ọ̀rẹ́ òun gba òun nímọ̀ràn nípa ìpinnu kan tó fẹ́ ṣe, ó wá sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Má wulẹ̀ jẹ́ kí n da ọpọlọ mi láàmú, ohun tí màá ṣe ni kó o sọ fún mi. Ohun tó pé mi nìyẹn.” Lédè míì, obìnrin yẹn gbà pé á dáa kí wọ́n sọ ohun tí òun máa ṣe dípò kó lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa, ìyẹn òmìnira. Ìwọ ńkọ́? Ṣé ìwọ lo máa ń pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe àbí o máa ń fẹ́ káwọn míì ṣèpinnu fún ẹ? Kí ló túmọ̀ sí pé a ní òmìnira? Ọjọ́ pẹ́ tẹ́nu àwọn èèyàn ò ti kò lórí ọ̀rọ̀ pé èèyàn ní òmìnira. Àwọn kan sọ pé àwa èèyàn ò lómìnira èyíkéyìí torí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ti kádàrá gbogbo ohun tá a máa ṣe láyé. Àwọn míì sì sọ pé káwọn tó lè gbà pé a ní òmìnira ó dìgbà táwa èèyàn bá lè ṣe ohun tó wù wá láìsí pé ẹnì kan ń yẹ̀ wá lọ́wọ́ wò. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, tá a bá máa lóye ọ̀rọ̀ náà, á dáa ká wo ohun tí Bíbélì sọ. Kí nìdí? Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló dá wa tó sì fún wa lómìnira ká lè fara balẹ̀ yan ohun tá a fẹ́ ṣe. w17.01 2:1, 2
Sunday, May 27
Sólómọ́nì ọmọkùnrin mi jẹ́ ọ̀dọ́, ó sì ṣe ẹlẹgẹ́ . . . Nítorí náà, [màá] ṣe ìpèsèsílẹ̀ fún un.—1 Kíró. 22:5.
Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì ronú pé Sólómọ́nì kò ní lè bójú tó iṣẹ́ ńlá náà. Ó ṣe tán, tẹ́ńpìlì náà máa jẹ́ “ọlọ́lá ńlá lọ́nà títa yọ ré kọjá.” Sólómọ́nì ní tiẹ̀ ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, kò sì fi bẹ́ẹ̀ nírìírí. Síbẹ̀, Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà á ran Sólómọ́nì lọ́wọ́ kíṣẹ́ náà lè di ṣíṣe. Torí náà, Dáfídì pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó lè ṣe, ó sì kó àwọn ohun èlò tí wọ́n máa lò jọ rẹpẹtẹ. Kò yẹ káwọn tó ti dàgbà banú jẹ́ tó bá di pé kí wọ́n gbé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kí nǹkan tẹ̀ síwájú tí wọ́n bá kọ́ àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí kí wọ́n lè bójú tó iṣẹ́. Ó yẹ kínú àwọn àgbàlagbà máa dùn bí wọ́n ṣe ń rí i táwọn tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń bójú tó iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run. w17.01 5:8, 9
Monday, May 28
Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí.—Jẹ́n. 3:15.
Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa fọ́ orí ejò náà yán-án yán, á sì palẹ̀ gbogbo ọ̀tẹ̀ Sátánì mọ́ pátápátá. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ bí Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó. Kété lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi ló bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ níbi gbogbo tó dé. (Lúùkù 4:43) Nígbà tó ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ìdágbére kó tó pa dà sọ́run, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹ́rìí òun “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:6-8) Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe máa mú káwọn èèyàn kárí ayé mọ̀ nípa ìràpadà, á sì jẹ́ kí wọ́n di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Lónìí, à ń fi hàn pé a jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run bá a ṣe ń ran àwọn arákùnrin Kristi lọ́wọ́ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run níbi gbogbo láyé.—Mát. 24:14; 25:40. w17.02 2:7, 8
Tuesday, May 29
[Kristi] fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì.—Éfé. 4:11.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbìmọ̀ olùdarí ló ń bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ láwọn ìjọ tó wà nígbà yẹn, wọ́n gbà pé Jésù ni Aṣáájú àwọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tí í ṣe orí, Kristi.” (Éfé. 4:15) Dípò tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn á fi máa fi orúkọ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì pe ara wọn, Bíbélì sọ pé ‘a tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni.’ (Ìṣe 11:26) Lóòótọ́ Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará pé kí wọ́n máa “di àwọn àṣà àfilénilọ́wọ́ mú ṣinṣin,” ìyẹn àwọn àṣà tó bá Ìwé Mímọ́ mu táwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tó ń múpò iwájú fi lélẹ̀. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù fi kún un: “Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin [títí kan àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ olùdarí] ni Kristi; . . . ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 11:2, 3) Ó ṣe kedere pé Jésù Kristi tá a ṣe lógo ló ń darí ìjọ, òun alára sì wà lábẹ́ ìdarí Jèhófà tó jẹ́ Orí ohun gbogbo. w17.02 4:7
Wednesday, May 30
Kí a ka àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ yẹ fún ọlá ìlọ́po méjì. —1 Tím. 5:17.
Tó bá ti mọ́ wa lára láti máa bọlá fáwọn míì, a ò ní máa ro tara wa nìkan. Kò ní jẹ́ ká jọ ara wa lójú táwọn èèyàn bá ń bọlá fún wa. Bákan náà, á jẹ́ ká máa fara wé ètò Jèhófà tó bá di pé ká bọlá fáwọn èèyàn. Ètò Jèhófà kì í bọlá fáwọn èèyàn kọjá bó ṣe yẹ yálà Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n àbí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, kò ní jẹ́ ká ṣìwà hù tí ẹnì kan tá à ń bọlá fún bá ṣe ohun tó dùn wá. Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa bọlá fúnni bó ṣe yẹ ni pé àá máa múnú Jèhófà dùn. A jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run torí pé ohun tó fẹ́ ká ṣe là ń ṣe. Èyí sì ń mú kí Jèhófà fún ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣáátá rẹ̀ lésì. (Òwe 27:11) Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bọlá fúnni. A mà dúpẹ́ o pé a mọ bá a ṣe lè máa bọlá fúnni lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. w17.03 1:13, 20, 21
Thursday, May 31
[Jèhóṣáfátì ṣe] ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà. —2 Kíró. 20:32.
Bíi ti bàbá rẹ̀, Ásà, Jèhóṣáfátì rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà pé kí wọ́n wá Jèhófà. Ó ṣètò àwọn ọmọ Léfì àtàwọn míì pé kí wọ́n máa fi “ìwé òfin Jèhófà” kọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà. (2 Kíró. 17:7-10) Ó tiẹ̀ tún lọ sáwọn ẹkùn olókè ńlá Éfúráímù, tó wà ní àgbègbè ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá, kó lè mú àwọn èèyàn ibẹ̀ “padà wá sọ́dọ̀ Jèhófà.” (2 Kíró. 19:4) Gbogbo wa la lè kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ṣètò rẹ̀ lásìkò wa yìí. Ṣó o máa ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lóṣooṣu láti kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣó o sì ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá sin Ọlọ́run? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, tó o sì ń bẹ Jèhófà pé kó bù kún ìsapá rẹ, wàá rẹ́ni tí wàá máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣó o máa ń fọ̀rọ̀ náà sádùúrà? Ṣé wàá ṣe gbogbo ohun tó bá gbà, bó bá tiẹ̀ gba pé kó o yááfì lára àkókò ìsinmi rẹ? Bíi ti Jèhóṣáfátì tó lọ sí àgbègbè Éfúráímù kó lè ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, àwa náà lè ṣèrànwọ́ fáwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ kí wọ́n lè pa dà máa ṣe déédéé. w17.03 3:10, 11