ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es18 ojú ìwé 88-97
  • September

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • September
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Saturday, September 1
  • Sunday, September 2
  • Monday, September 3
  • Tuesday, September 4
  • Wednesday, September 5
  • Thursday, September 6
  • Friday, September 7
  • Saturday, September 8
  • Sunday, September 9
  • Monday, September 10
  • Tuesday, September 11
  • Wednesday, September 12
  • Thursday, September 13
  • Friday, September 14
  • Saturday, September 15
  • Sunday, September 16
  • Monday, September 17
  • Tuesday, September 18
  • Wednesday, September 19
  • Thursday, September 20
  • Friday, September 21
  • Saturday, September 22
  • Sunday, September 23
  • Monday, September 24
  • Tuesday, September 25
  • Wednesday, September 26
  • Thursday, September 27
  • Friday, September 28
  • Saturday, September 29
  • Sunday, September 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
es18 ojú ìwé 88-97

September

Saturday, September 1

Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré.​—Ják. 1:4.

Ọ̀nà tí Bíbélì gbà lo ìfaradà jẹ́ ká mọ̀ pé ó kọjá kéèyàn kàn máa forí ti nǹkan tàbí kéèyàn máa fàyà rán ìṣòro. Ó tún kan èrò wa nípa àwọn àdánwò tá à ń kojú àti ojú tá a fi ń wo àwọn àdánwò náà. Ìfaradà máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìgboyà, ó máa ń jẹ́ kéèyàn ní sùúrù, kì í sì í jẹ́ kéèyàn bọ́hùn nígbà ìṣòro. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ìfaradà máa ń mú ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, kì í sì í jẹ́ ká bọ́hùn nígbà ìṣòro. Ó máa ń jẹ́ ká ṣọkàn akin kódà nígbà tá a bá dojú kọ àwọn àdánwò tí ń pinni lẹ́mìí. Ó máa jẹ́ ká borí àwọn àdánwò náà, àá sì lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tá à ń lé dípò ká máa ronú ṣáá nípa ohun tá à ń fàyà rán. Ìfẹ́ ló ń mú káwa Kristẹni máa fara dà á. (1 Kọ́r. 13:​4, 7) Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà ló mú ká máa fara da ohunkóhun tó bá fàyè gbà. (Lúùkù 22:​41, 42) Ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará wa ló ń mú ká máa fara da àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. (1 Pét. 4:8) Ìfẹ́ tá a ní sí ọkọ tàbí aya wa ló ń mú ká máa fara da “ìpọ́njú” irú èyí tí àwọn tọkọtaya tí ilé wọn tòrò pàápàá máa ń ní, á sì mú kí àjọṣe wa túbọ̀ dán mọ́rán.​—1 Kọ́r. 7:28. w16.04 2:​3, 4

Sunday, September 2

Kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.​—Héb. 10:​24, 25.

Lẹ́yìn ìpàdé tó wáyé nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, àwọn Kristẹni ṣì máa ń pà dé pọ̀ déédéé láti jọ́sìn Jèhófà. Wọn ‘kì í kọ ìpéjọpọ̀ ara wọn sílẹ̀.’ Kódà nígbà tí ìjọba ilẹ̀ Róòmù àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ṣe inúnibíni sí wọn, wọn ò yé pé jọ pọ̀ láti jọ́sìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wọn, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè máa jọ́sìn pa pọ̀. Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọrírì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa pé jọ pọ̀, wọ́n sì máa ń gbádùn rẹ̀. Arákùnrin George Gangas tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí fún ohun tó lé ní ọdún méjìlélógún [22] sọ pé: “Ní tèmi, kò sóhun tó dùn bíi kéèyàn máa wà pẹ̀lú àwọn ará nípàdé, ó sì máa ń mórí mi wú. Gbogbo ohun tó wù mí láyé mi ni pé kí n ṣáà máa lọ sípàdé.” Ṣé bí ìjọsìn Jèhófà ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè máa wà nípàdé pẹ̀lú àwọn ará, kódà bí ò bá tiẹ̀ rọrùn. Jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé bó ṣe rí lára Dáfídì Ọba ló rí lára ìwọ náà, nígbà tó sọ pé: “Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ ibùgbé ilé rẹ.”​—Sm. 26:8. w16.04 3:​16-18

Monday, September 3

Kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ.​—Mát. 5:24.

Tó o bá gbọ́ pé ohun tó o ṣe tàbí ohun tó o sọ bí ẹnì kan nínú, kí lo yẹ kó o ṣe? Kọ́kọ́ lọ bá arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀ ná. Má sì gbàgbé ohun tó o fẹ́ torí ẹ̀ lọ. Kì í ṣe torí kó o lè di ẹ̀bi rù ú lo ṣe fẹ́ lọ bá a, ṣe ni kó o bẹ̀ ẹ́ pé kó má bínú kí ẹ sì yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa. Àpẹẹrẹ kan ni ti Ábúráhámù àti ìbátan rẹ̀ Lọ́ọ̀tì. Àwọn méjèèjì ní ẹran ọ̀sìn, àmọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ń bá ara wọn jà lórí ilẹ̀ táwọn ẹran náà ń jẹ̀ sí. Torí pé Ábúráhámù ò fẹ́ wàhálà, ó ní kí Lọ́ọ̀tì kọ́kọ́ mú apá ibi tóun àti ìdílé rẹ̀ máa wà. (Jẹ́n. 13:​1, 2, 5-9) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere ló fi lélẹ̀ fún wa! Bí wọ́n ṣe máa wà lálàáfíà ni Ábúráhámù ń wá, kì í ṣe bó ṣe máa tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Ṣé ó wá jìyà ohun tó ṣe yẹn? Rárá. Kété lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, Jèhófà ṣèlérí ìbùkún rẹpẹtẹ fún Ábúráhámù. (Jẹ́n. 13:​14-17) Ọlọ́run ò ní jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jìyà àjẹgbé torí pé wọ́n tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ láti fìfẹ́ yanjú aáwọ̀. w16.05 1:​11, 12

Tuesday, September 4

Ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.​—Éfé. 5:17.

Nínú Bíbélì, Jèhófà ti fún wa láwọn òfin pàtó kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ka àwọn nǹkan kan léèwọ̀ fún wa, irú bí ìṣekúṣe, ìbọ̀rìṣà, olè jíjà àti ìmutípara. (1 Kọ́r. 6:​9, 10) Jésù Kristi tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run náà pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:​19, 20) Kò sí àní-àní pé àwọn òfin tí Ọlọ́run fún wa àtàwọn àṣẹ tó pa fún wa ń dáàbò bò wá. Torí pé à ń pa àwọn òfin àti àṣẹ Ọlọ́run mọ́, a lẹ́nu ọ̀rọ̀ láwùjọ, a ní ìlera tó dáa, ìdílé wa sì túbọ̀ ń láyọ̀. Èyí tó tiẹ̀ wá ṣe pàtàkì jù ni pé à ń rójú rere Jèhófà, ó sì ń bù kún wa torí pé à ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ nígbà gbogbo títí kan àṣẹ tó pa fún wa pé ká máa wàásù. w16.05 3:1

Wednesday, September 5

Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà.​—Róòmù 12:2.

Tá a bá ń tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, tá a sì ń mú èrò wa bá èrò Jèhófà mu bó ṣe wà nínú Bíbélì, àá túbọ̀ máa fìwà jọ Jèhófà lọ́rọ̀, lérò àti ní ìṣe. (Lúùkù 11:13; Gál. 5:​22, 23) Àmọ́ síbẹ̀ náà, a ṣì gbọ́dọ̀ máa sapá láti máa fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò, kó má di pé ṣe la kàn ṣáà ń ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ kan náà nígbà gbogbo. (Òwe 4:23) Tó ò bá tètè ní àwọn ànímọ́ tí Jèhófà fẹ́, ó yẹ kó o máa rántí pé irú ìtẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀ máa ń gba àkókò. A ò lè ní gbogbo àwọn ànímọ́ yẹn lẹ́ẹ̀kan náà. Ó máa gba pé ká ní sùúrù bá a ṣe ń sapá láti jẹ́ kí Bíbélì tún ìgbésí ayé wa ṣe. Níbẹ̀rẹ̀, ó lè gba pé ká kọ́ ara wa láti máa ṣe ohun tó bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu. Bí èrò àti ìṣe wa ṣe ń bá ti Jèhófà mu bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, á wá rọrùn fún wa láti máa ronú lọ́nà tó yẹ ká sì máa hùwà tó yẹ Kristẹni.​—Sm. 37:31; Òwe 23:12; Gál. 5:​16, 17. w16.05 4:​14, 16

Thursday, September 6

Inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.​—Sm. 1:2.

Lásìkò wa yìí, Jèhófà ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ìjọ Kristẹni láti mọ wá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á mọ wá tá a bá ń kà á bíi pé àwa gan-an ni wọ́n kọ ọ́ fún, tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, tá a sì ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti fi ohun tá a kà sílò. Dáfídì sọ pé, “Mo rántí rẹ lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú gbọọrọ mi, mo ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní àwọn ìṣọ́ òru.” (Sm. 63:6) Ó tún sọ pé: “Èmi yóò fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹni tí ó ti fún mi ní ìmọ̀ràn. Ní ti tòótọ́, kíndìnrín mi ti tọ́ mi sọ́nà ní òru.” (Sm. 16:7) Ó ṣe kedere pé Dáfídì jẹ́ kí ìmọ̀ràn Ọlọ́run wọ òun lọ́kàn ṣinṣin, ó jẹ́ kó yí bí òun ṣe ń ronú àti ojú tí òun fi ń wo nǹkan pa dà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ràn náà lè nira. (2 Sám. 12:​1-13) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Dáfídì jẹ́ tó bá di pé kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àtẹni tó ń fi ara rẹ̀ sábẹ́ àkóso Ọlọ́run! Ṣé ìwọ náà máa ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣé o sì ń jẹ́ kó wọnú ọkàn rẹ ṣinṣin? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé o lè túbọ̀ fi kún ìsapá rẹ?​—Sm. 1:3. w16.06 1:11

Friday, September 7

Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya.​—Oníw. 7:9.

A gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé ó ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún táwa èèyàn ti jẹ́ aláìpé. Èèyàn aláìpé ò sì lè má ṣàṣìṣe. Torí náà, kò bọ́gbọ́n mu ká máa rétí pé káwọn tá a jọ ń sin Jèhófà jẹ́ ẹni pípé, àti pé kò yẹ kí wọ́n ṣàṣìṣe. Bákan náà, kò yẹ ká jẹ́ kí àṣìṣe wọn paná ayọ̀ tá à ń rí bá a ṣe wà lára àwọn èèyàn Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Kò sì ní dáa tá a bá lọ jẹ́ kí àṣìṣe wọn mú wa kọsẹ̀, ká wá torí ìyẹn fi ètò Jèhófà sílẹ̀. Tíyẹn bá lọ ṣẹlẹ̀ sí wa pẹ́nrẹ́n, a máa pàdánù àǹfààní tá a ní láti máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run báyìí, àá sì tún pàdánù àǹfààní láti wà nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Kí ayọ̀ tá a ní má bàa dín kù, kí ìrètí wa sì fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó yẹ ká máa rántí ìlérí tó ń mọ́kàn yọ̀ tí Jèhófà ṣe, ó ní: “Kíyè sí i, èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísá. 65:17; 2 Pét. 3:13) Torí náà, má ṣe jẹ́ kí àṣìṣe àwọn míì mú kó o pàdánù àwọn ìbùkún yìí. w16.06 4:​13, 14

Saturday, September 8

Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.​—Diu. 6:4.

Tá a bá sọ pé Jèhófà jẹ́ “ọ̀kan ṣoṣo,” ó túmọ̀ sí pé kò yí pa dà, irú ẹni tó jẹ́ lánàá náà ni lónìí. Bọ́rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, A-wí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà. Ó jẹ́ olóòótọ́, adúróṣinṣin, kò sì yí pa dà. Ó ṣèlérí fún Ábúráhámù pé àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa jogún Ilẹ̀ Ìlérí, ó sì ṣe àwọn ohun àgbàyanu láti mú ìlérí yẹn ṣẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irinwó ó lé ọgbọ̀n [430] ọdún kọjá lẹ́yìn tí Ọlọ́run ṣe ìlérí yẹn, síbẹ̀ Ọlọ́run mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Jẹ́n. 12:​1, 2, 7; Ẹ́kís. 12:​40, 41) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹnì kan náà ni mí. Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run kankan tí a ṣẹ̀dá, àti lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan tí ó ṣì wà nìṣó.” Kó lè fi dá wọn lójú pé òun kò yí pa dà, Jèhófà fi kún un pé: “Ní gbogbo ìgbà, Ẹnì kan náà ni mí.” (Aísá. 43:​10, 13; 44:6; 48:12) Ẹ ò rí i pé ohun iyì gbáà ló jẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti fún àwa náà lónìí pé a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run tí kì í yí pa dà, tó sì ṣeé gbára lé!​—Mál. 3:6; Ják. 1:17. w16.06 3:​6, 7

Sunday, September 9

Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.​—Máàkù 13:33.

Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lónìí ló ní àwọn aṣọ́bodè, wọ́n sì máa ń lo kámẹ́rà àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì láti ṣọ́ ohun tó ń lọ. Wọ́n máa ń ṣọ́ àwọn tó bá fẹ́ pẹ́ ọ̀nà wọ̀lú àtàwọn ọ̀tá tó bá fẹ́ ṣe wọ́n ní jàǹbá. Àmọ́, àwọn nǹkan téèyàn lè fojú rí àtàwọn èèyàn tó bá fẹ́ kógun wọ̀lú nìkan láwọn aṣọ́bodè àtàwọn kámẹ́rà yìí lè rí. Wọn ò mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi ń ṣàkóso àtàwọn ohun tó ń ṣe, àti bó ṣe máa tó ṣèdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè. (Aísá. 9:​6, 7; 56:10; Dán. 2:44) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá wà lójúfò nípa tẹ̀mí, tá a sì ń ṣọ́nà, a máa wà ní ìmúratán nígbàkigbà tọ́jọ́ ìdájọ́ yìí bá dé. (Sm. 130:6) Bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ètò yìí, ó lè túbọ̀ ṣòro láti wà lójúfò. Àdánù gbáà ló máa jẹ́ tá a bá lọ sùn nípa tẹ̀mí! w16.07 2:​2, 9, 10

Monday, September 10

Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [Ọlọ́run] tí ó sì wà fún mi kò já sí asán. ​—1 Kọ́r. 15:10.

Pọ́ọ̀lù mọ̀ dáadáa pé kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe òun ni Ọlọ́run fi ṣàánú òun lọ́nà gíga bẹ́ẹ̀, ó sì mọ̀ pé òun ò lẹ́tọ̀ọ́ sí i torí pé òun ti fìyà jẹ àwọn Kristẹni rí. Nígbà tó kù díẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù máa kú, ó kọ̀wé sí Tímótì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, pé: “Mo kún fún ìmoore sí Kristi Jésù Olúwa wa, ẹni tí ó fi agbára fún mi, nítorí tí ó kà mí sí olùṣòtítọ́ nípa yíyan iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lé mi lọ́wọ́.” (1 Tím. 1:​12-14) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wo ló ní lọ́kàn? Pọ́ọ̀lù sọ ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní nínú fún àwọn alàgbà tó wà ní ìjọ Éfésù, ó ní: “Èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan kan tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:24) Àwa Kristẹni òde òní lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Ó fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sóun kò “já sí asán.” w16.07 4:​1-3

Tuesday, September 11

Èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn.​—Míkà 7:7.

Jèhófà máa ń dúró ti àwọn tó ń fòótọ́ inú sìn ín, kì í fi wọ́n sílẹ̀ rárá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè fẹ́ kí wọ́n ní sùúrù kọ́wọ́ wọn tó tẹ àǹfààní tí wọ́n ń fẹ́, ó sì lè má tètè yí ipò tí kò rọgbọ fún wọn pa dà. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé ó máa bímọ, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún ni ọkùnrin olóòótọ́ yìí fi ní sùúrù, tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò sì yingin. (Héb. 6:​12-15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún kọjá kí Ábúráhámù tó bí Ísákì, síbẹ̀ kò sọ̀rètí nù, Jèhófà náà ò sì já a kulẹ̀. (Jẹ́n. 15:​3, 4; 21:5) Kì í rọrùn fáwa èèyàn láti mú sùúrù. (Òwe 13:12) Tá a bá ń dààmú ṣáá lórí ohun tá à ń lé àmọ́ tọ́wọ́ wa ò tíì tẹ̀, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Torí náà, á dáa ká máa fàkókò wa ronú lórí bá a ṣe lè sunwọ̀n sí i nínú ìjọsìn wa. Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, àá ní ọgbọ́n, òye, ìmọ̀, àá tún láròjinlẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì torí pé ojoojúmọ́ là ń ṣe àwọn ìpinnu tó kan eré ìnàjú tá a yàn láàyò, ìmúra wa, bá a ṣe ń náwó àti bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì. Tá a bá ń fi ohun tá à ń kọ́ nínú Bíbélì sílò, àá ṣe àwọn ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn. w16.08 3:​9-11

Wednesday, September 12

Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín.​—Fílí. 2:13.

Jèhófà ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì àtàwọn ará Etiópíà, ó sì tún fún Nehemáyà àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ lágbára láti parí ògiri Jerúsálẹ́mù. Á fún àwa náà lókun láti borí àníyàn, á sì tún ràn wá lọ́wọ́ nígbà táwọn èèyàn bá ta kò wá tàbí nígbà tí wọ́n bá kọtí ikún sí iṣẹ́ ìwàásù wa. Ìrànwọ́ yìí á mú ká lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. (1 Pét. 5:10) A ò retí pé kí Jèhófà ṣe iṣẹ́ ìyanu fún wa, àwa náà lóhun tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Lára ẹ̀ ni pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká máa múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ ká sì máa pésẹ̀ síbẹ̀ déédéé, ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká má fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gba àwọn nǹkan míì láyè láti dí wa lọ́wọ́ ṣíṣe àwọn nǹkan tá a sọ tán yìí, torí pé àwọn nǹkan yẹn ni Jèhófà ń lò láti fún wa lókun àti ìṣírí. Tó o bá kíyè sí i pé o ti ń dẹwọ́ nínú èyíkéyìí lára àwọn ohun tá a sọ yìí, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí i pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà á jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́, á sì mú kó o ṣe bẹ́ẹ̀. w16.09 1:12

Thursday, September 13

Nítorí ìgbòdekan àgbèrè, kí olúkúlùkù ọkùnrin ní aya tirẹ̀, kí olúkúlùkù obìnrin sì ní ọkọ tirẹ̀. ​—1 Kọ́r. 7:2.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó dáa téèyàn bá wà láìlọ́kọ tàbí láìláya. Síbẹ̀, ó sọ ohun tó wà lókè yìí. Ó tún sọ pé: “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá ní ìkóra-ẹni-níjàánu, kí wọ́n gbéyàwó, nítorí ó sàn láti gbéyàwó ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara ẹni gbiná.” Lóòótọ́, téèyàn bá ṣègbéyàwó, á lè yẹra fáwọn ìwà tí kò bójú mu, bíi kó máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ tàbí kó lọ ṣèṣekúṣe. Àmọ́, ó tún ṣe pàtàkì kéèyàn wò ó bóyá òun dàgbà tó ẹni tó ń ṣègbéyàwó torí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń hùwà lọ́nà àìbẹ́tọ̀ọ́mu sí ipò wúńdíá òun, bí onítọ̀hún bá ti ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe, tí èyí sì jẹ́ ọ̀nà tí ó yẹ kí ó gbà ṣẹlẹ̀, kí ó ṣe ohun tí ó fẹ́; kò dẹ́ṣẹ̀. Kí wọ́n gbéyàwó.” (1 Kọ́r. 7:​9, 36; 1 Tím. 4:​1-3) Síbẹ̀, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni lọ ṣègbéyàwó torí àwọn ìmọ̀lára téèyàn máa ń ní nígbà ọ̀dọ́. Ẹni náà lè má tíì dàgbà tó láti bójú tó àwọn ojúṣe táwọn tó ti ṣègbeyàwó máa ń ní. w16.08 1:17

Friday, September 14

Lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.​—2 Kọ́r. 6:4.

“Ohun tí ó fara hàn sí ojú” ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń pinnu irú ẹni tá a jẹ́. (1 Sám. 16:7) Ìdí nìyẹn tí àwa tá a jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run fi gbà pé ìmúra kì í ṣe ọ̀rọ̀ ká wọ ohun tó kàn wù wá. Torí pé àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé, a kì í wọ àwọn aṣọ tó fún mọ́ra pinpin, tó ṣí ara sílẹ̀ tàbí tó lè mú káwọn èèyàn máa ro èròkerò nípa wa. Bákan náà, a ò ní máa wọ àwọn aṣọ tí kò bo àwọn ibi kọ́lọ́fín ara tàbí tó gbé àwọn ibi kọ́lọ́fín ara yọ. Kò yẹ ká múra lọ́nà táá máa kọ àwọn míì lóminú tàbí táá mú kí wọ́n máa gbójú sẹ́gbẹ̀ẹ́ nígbà tí wọ́n bá rí wa. Tá a bá wọṣọ tó yẹ ọmọlúàbí, tí aṣọ wá mọ́, tó sì bójú mu, àwọn èèyàn máa yẹ́ wa sí, wọ́n á sì bọ̀wọ̀ fún wa, èyí tiẹ̀ lè mú káwọn náà wá sin Jèhófà. Bákan náà, tí ìmúra wa bá bójú mu, àwọn èèyàn á fojú tó tọ́ wo ètò Ọlọ́run tá à ń ṣojú fún. Èyí sì lè mú kó yá wọn lára láti gbọ́ ìwàásù wa. w16.09 3:​5, 6

Saturday, September 15

Jẹ́ afòyebánilò, . . . máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.​—Títù 3:2.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, má ṣe ronú pé o mọ ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́. Àwọn kan sọ pé àwọn gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, síbẹ̀ wọ́n tún gbà pé Ọlọ́run wà. Èrò wọn ni pé ẹfolúṣọ̀n ni Ọlọ́run lò láti dá àwọn nǹkan. Àwọn míì sì gbà pé ẹfolúṣọ̀n ní láti jóòótọ́ torí pé bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wọn ò ní máa fi kọ́ni níléèwé. Ìwàkiwà tó kúnnú ìsìn ló mú káwọn míì gbà pé kò sí Ọlọ́run. Torí náà, kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé, á dáa kó o kọ́kọ́ bi ẹni náà ní ìbéèrè táá jẹ́ kó o mọ ohun tó gbà gbọ́. Tó o bá fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ, ó ṣeé ṣe kóun náà fetí sí ẹ. Tẹ́nì kan bá ń ta kò ẹ́ pé kì í ṣe Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan, o lè fọgbọ́n lo ìbéèrè láti mú kẹ́ni náà ṣàlàyé ara rẹ̀. Ní kó ṣàlàyé báwọn nǹkan ṣe dáyé tó bá dá a lójú pé kò sí Ẹlẹ́dàá. Òótọ́ kan ni pé tí ohun tó kọ́kọ́ dáyé kò bá ní pa run, ó di dandan kó mú irú ara rẹ̀ jáde. Ògbógi kan nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé “Àwámáridìí làwọn nǹkan tó yí wa ká, títí kan àwọn nǹkan kéékèèké.” w16.09 4:​12, 13

Sunday, September 16

Wọn kò jẹ́ tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà kankan, kí ọwọ́ wọn lè tẹ àjíǹde tí ó sàn jù. ​—Héb. 11:35.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ àwọn tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn, síbẹ̀ wọ́n sọ Nábótì àti Sekaráyà lókùúta pa torí pé wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. (1 Ọba 21:​3, 15; 2 Kíró. 24:​20, 21) Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò “tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀,” ìyẹn ni pé wọ́n yàn láti fẹ̀mí wọn wewu dípò kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run, èyí sì mú kí “wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,” kí ‘wọ́n sì dá ipá iná dúró’ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Héb. 11:​33, 34; Dán. 3:​16-18, 20, 28; 6:​13, 16, 21-23) Wòlíì Mikáyà àti Jeremáyà fara da “ìfiṣẹlẹ́yà . . . àti ẹ̀wọ̀n” torí ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn míì bí Èlíjà “rìn káàkiri nínú àwọn aṣálẹ̀ àti àwọn òkè ńlá àti àwọn hòrò àti àwọn ihò inú ilẹ̀.” Gbogbo wọn ló fara dà á torí pé wọ́n ní “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí [wọ́n] ń retí.”​—Héb. 11:​1, 36-38; 1 Ọba 18:13; 22:​24-27; Jer. 20:​1, 2; 28:​10, 11; 32:2. w16.10 3:​10, 11

Monday, September 17

Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.​—Fílí. 2:3.

Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣojúure sáwọn àjèjì tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ni pé ká kí wọn tẹ̀rín tọ̀yàyà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ojú máa ń ti àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ìlú onílùú, wọ́n sì sábà máa ń dá wà. Torí pé ibi tí wọ́n dàgbà sí yàtọ̀ àti pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rẹ́ni fojú jọ báyìí, ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò tẹ́gbẹ́. Torí náà, á dáa kó jẹ́ àwa la máa kọ́kọ́ sún mọ́ wọn, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Tí èdè ẹni yẹn bá wà lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Language, o lè fi kọ́ bí wàá ṣe kí ẹni náà lédè rẹ̀. (Fílí. 2:4) Ojú lè máa tì wá tàbí kó má fi bẹ́ẹ̀ yá wa lára láti bá àwọn tí kì í ṣe ọmọ ìlú wa sọ̀rọ̀. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o sọ nǹkan kan fún wọn nípa ara rẹ. O lè wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ fi jọra, àti pé àṣà kọ̀ọ̀kan ló ní dáadáa tiẹ̀. w16.10 1:​13, 14

Tuesday, September 18

Àgbèrè ni a ròyìn láàárín yín, irúfẹ́ àgbèrè tí kò tilẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. ​—1 Kọ́r. 5:1.

Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, à ń fi hàn pé a fẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Kọ́ríńtì nígbà yẹn. Pọ́ọ̀lù fi ìtara wàásù níbẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn “ẹni mímọ́” bíi tiẹ̀ tó wà níbẹ̀. (1 Kọ́r. 1:​1, 2) Ó dájú pé kò ní rọrùn fún un láti yanjú ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe tí wọ́n fàyè gbà nínú ìjọ yẹn. Pọ́ọ̀lù sọ pé káwọn alàgbà fa ọkùnrin oníṣekúṣe náà lé Sátánì lọ́wọ́, ìyẹn ni pé kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Kí ìjọ lè wà ní mímọ́, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ mú oníwà àìtọ́ náà kúrò láàárín wọn torí ó lè kó bá àwọn míì tó wà nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:​5-7, 12) Tí ẹnì kan bá hùwà àìtọ́, tí kò sì ronú pìwà dà, táwọn alàgbà bá yọ ẹni náà lẹ́gbẹ́, ó yẹ ká fara mọ́ ìpinnu tí wọ́n ṣe. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìjọ á wà ní mímọ́, ẹni náà sì lè wá yí pa dà kó sì tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà. w16.11 2:14

Wednesday, September 19

Bí ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí bá wà tí ẹ ní fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́.​—Ìṣe 13:15.

Àwọn èèyàn máa ń sọ pé, yinniyinni, kẹ́ni lè ṣèmíì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Rubén fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ tó ti máa ń ṣe mí bíi pé mi ò wúlò. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, èmi àti alàgbà kan jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Alàgbà náà kíyè sí i pé inú mi ò dùn. Ó wá bi mí pé kí ló ṣẹlẹ̀, mo sọ tọkàn mi fún un, ó sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi. Lẹ́yìn náà, ó rán mi létí àwọn nǹkan dáadáa tí mo ti ń ṣe látọjọ́ yìí wá. Ó tún fi ọ̀rọ̀ Jésù tù mí nínú, pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa níye lórí ju ọ̀pọ̀ ẹyẹ ológoṣẹ́ lọ. Kò sígbà tí mo rántí ẹsẹ Bíbélì yìí, tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kì í wọ̀ mí lọ́kàn. Ọ̀rọ̀ tí alàgbà yẹn sọ mú kí ara mi túbọ̀ yá gágá.” (Mát. 10:31) Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Bíbélì tẹnu mọ́ ọn pé ká máa gba ara wa níyànjú tàbí ká máa fún ara wa níṣìírí déédéé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní gbígba ara yín níyànjú lẹ́nì kìíní-kejì lójoojúmọ́, . . . kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ẹnikẹ́ni nínú yín di aláyà líle.” (Héb. 3:13) Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ti fún ẹ níṣìírí rí, tí ìṣírí náà sì gbé ẹ ró, ìwọ náà á gbà pé ó ṣe pàtàkì ká máa fún àwọn míì níṣìírí. w16.11 1:​2, 3

Thursday, September 20

Àwọn ènìyàn yóò . . . dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.​—Ìṣe 20:30.

Lásìkò tí Kọnsitatáìnì abọ̀rìṣà di Olú Ọba Róòmù lọ́dún 313 Sànmánì Kristẹni, wọ́n ṣe òfin pé ẹ̀sìn Kristẹni ìgbà yẹn ni ìjọba fọwọ́ sí bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti di apẹ̀yìndà. Nínú ìpàdé kan tí wọ́n jọ ṣe nílùú Niséà, Kọnsitatáìnì lé àlùfáà kan tí wọ́n ń pè ní Arius jáde nípàdé náà, ó sì lé e kúrò nílùú torí pé àlùfáà náà kọ̀ láti gbà pé Jésù ni Ọlọ́run. Nígbà tó yá, Theodosius Kìíní (tó jẹ́ Olú Ọba Róòmù lọ́dún 379 sí 395 Sànmánì Kristẹni), sọ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó jẹ́ ayédèrú Kristẹni di ìsìn tí ìjọba Róòmù fọwọ́ sí pé káwọn èèyàn máa ṣe. Àwọn òpìtàn tiẹ̀ sọ pé àsìkò yẹn ni ìlú Róòmù tó jẹ́ abọ̀rìṣà sọ ara wọn di onísìn Kristẹni. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, lásìkò tá à ń sọ yìí, àwọn Kristẹni tó ti di apẹ̀yìndà dara pọ̀ mọ́ àwọn abọ̀rìṣà tó wà lábẹ́ àkóso Ìjọba Róòmù, wọ́n wá jọ para pọ̀ di apá kan Bábílónì Ńlá. Bó ti wù kó rí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mélòó kan wà tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa jọ́sìn Ọlọ́run.​—Mát. 13:​24, 25, 37-39. w16.11 4:​8, 9

Friday, September 21

Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.​—1 Pét. 5:7.

Àsìkò tó le gan-an là ń gbé yìí. Sátánì Èṣù ń bínú burúkú burúkú, ó sì ń “rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pét. 5:8; Ìṣí. 12:17) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà náà máa ń ṣàníyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó ṣe tán, àwọn ìgbà kan wà táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ náà ṣàníyàn. Àpẹẹrẹ kan ni ti Ọba Dáfídì. (Sm. 13:2) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní “àníyàn fún gbogbo àwọn ìjọ.” (2 Kọ́r. 11:28) Torí náà, kí la lè ṣe tí àníyàn bá bò wá mọ́lẹ̀? Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láyé àtijọ́, ó sì dájú pé á ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè rí ìtura lọ́wọ́ àníyàn tàbí àwọn ìṣòro tá a ní. Báwo la ṣe lè rí ìtura yìí gbà? Ká máa gbàdúrà tọkàntọkàn, ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa ṣàṣàrò lé e, ká jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, àti ká máa sọ bí nǹkan ṣe ń ṣe wá fún àwọn tó ṣeé finú hàn. w16.12 3:​1, 2

Saturday, September 22

Òpin nǹkan wọnnì ikú ni. ​—Róòmù 6:21.

Àwọn èèyàn Jèhófà ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tí wọ́n ń hù kí wọ́n tó mọ Jèhófà. Wọ́n ti wá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ìwà kan “tí ń tì [wọ́n] lójú nísinsìnyí,” ni wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀, àwọn ìwà yìí sì lè yọrí sí ikú. (Róòmù 6:21) Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti yí pa dà. Àwọn ará Kọ́ríńtì náà ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn pé, tẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ abọ̀rìṣà, olè, ọ̀mùtípara, wọ́n ń ṣe panṣágà, ọkùnrin ń bá ọkùnrin lò pọ̀, obìnrin ń bá obìnrin lò pọ̀, wọ́n sì ń hu àwọn ìwàkiwà míì. Síbẹ̀, Ọlọ́run ‘wẹ̀ wọ́n mọ́,’ ó sì ‘sọ wọ́n di mímọ́.’ (1 Kọ́r. 6:​9-11) Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan ní ìjọ Róòmù náà ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀, ìyẹn ló mú kí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn pé kí wọ́n ‘má ṣe máa bá a lọ ní jíjọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ bí àwọn ohun ìjà àìṣòdodo, ṣùgbọ́n kí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún Ọlọ́run bí àwọn tí ó wà láàyè láti inú òkú, àti àwọn ẹ̀yà ara wọn pẹ̀lú fún Ọlọ́run bí àwọn ohun ìjà òdodo.’ (Róòmù 6:13) Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé tí wọ́n bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wọ́n á máa jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. w16.12 1:13

Sunday, September 23

Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.​—Sm. 37:3.

Jèhófà fi ọ̀pọ̀ nǹkan jíǹkí àwa èèyàn. Ó fún wa lágbára láti ronú ká lè yanjú ìṣòro ká sì wéèwé ohun tá a máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. (Òwe 2:11) Ó tún fún wa lágbára láti ṣe ohun tá a wéèwé, ká sì rí i pé a ṣàṣeyọrí. (Fílí. 2:13) Yàtọ̀ síyẹn, ó fún wa ní ẹ̀rí ọkàn tó ń jẹ́ ká mọ ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Ẹ̀rí ọkàn yìí ló máa ń kìlọ̀ fún wa tá a bá fẹ́ ṣìwà hù, ó sì máa ń dá wa lẹ́bi ká lè ṣàtúnṣe tá a bá ṣàṣìṣe. (Róòmù 2:15) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà rọ̀ wá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká máa lo ẹ̀bùn tó fún wa lọ́nà tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” Ó tún rọ̀ wá pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.” (Òwe 21:5; Oníw. 9:10) Bákan náà, Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì rọ̀ wá pé: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” Ó tún sọ pé: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Gál. 6:10; 1 Pét. 4:10) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jèhófà fẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múnú ara wa àtàwọn míì dùn. w17.01 1:​1, 2

Monday, September 24

Nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá. ​—1 Kọ́r. 10:11.

Àìgbọràn Ádámù àti Éfà ló mú káwọn àtọmọdọ́mọ wọn jogún àìpé àti ikú. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n. A rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí nínú bí Jèhófà ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò. Jèhófà gbẹnu Mósè sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n yàn bóyá àwọn á jẹ́ àkànṣe dúkìá òun tàbí wọn ò ní fẹ́ bẹ́ẹ̀. (Ẹ́kís. 19:​3-6) Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe? Wọ́n gbà láti ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà béèrè kí wọ́n lè di èèyàn rẹ̀, torí náà wọ́n panu pọ̀ sọ pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.” (Ẹ́kís. 19:8) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣi òmìnira wọn lò, wọn ò sì mú ìlérí wọn ṣẹ. Ìkìlọ̀ ni àpẹẹrẹ wọn yìí jẹ́ fún wa pé ká mọyì òmìnira tá a ní, ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ. w17.01 2:9

Tuesday, September 25

Jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn.​—Míkà 6:8.

Nígbà ìṣàkóso Jèróbóámù tó jẹ́ ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà rán wòlíì kan láti ìlú Júdà pé kó lọ kéde ìdájọ́ mímúná fún Ọba Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà yìí. Wòlíì yìí fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an. Jèhófà sì dáàbò bò ó kí Jèróbóámù má bàa pa á. (1 Ọba 13:​1-10) Nígbà tí wòlíì yìí ń pa dà sílé, bàbá àgbàlagbà kan tó wá láti ìlú Bẹ́tẹ́lì pàdé rẹ̀. Bàbá náà sọ pé wòlíì Jèhófà ni òun, ó tan ọ̀dọ́kùnrin yẹn jẹ, ó sì mú kó ṣàìgbọràn sí ìtọ́ni tó ṣe kedere tí Jèhófà fún un pé ‘kò gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní Ísírẹ́lì,’ bákan náà ‘kò gbọ́dọ̀ tún gba ọ̀nà tó gbà lọ pa dà.’ Inú Jèhófà ò dùn sí ohun tí wòlíì yìí ṣe, torí náà bó ṣe ń lọ sílé, kìnnìún kan pàdé rẹ̀, ó sì pa á. (1 Ọba 13:​11-24) Kí nìdí tí wòlíì tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ yìí fi gbà kí bàbá yẹn tan òun jẹ? Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé ṣe ló gbàgbé pé ó yẹ kóun ṣì jẹ́ ‘amẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run òun rìn.’ w17.01 4:​1-3

Wednesday, September 26

Àní mo ti sọ ọ́; èmi yóò mú un wá pẹ̀lú. Mo ti gbé e kalẹ̀, èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.​—Aísá. 46:11.

Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́n. 1:1) Gbólóhùn yìí kò ṣòro lóye, àmọ́ ó kẹnú torí pé àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá pọ̀ gan-an, àwọn nǹkan bí òfuurufú tó tẹ́ rẹrẹ, ìmọ́lẹ̀ àti agbára òòfà. Kódà èyí tá a mọ̀ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá kò ju bíńtín bí orí abẹ́rẹ́ lọ. (Oníw. 3:11) Síbẹ̀, Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé àti fún aráyé. Ó dá àwa èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní àwòrán ara rẹ̀, ó sì dá ayé lọ́nà táá fi dùn ún gbé fún wa. (Jẹ́n. 1:26) Ó fẹ́ ká jẹ́ ọmọ òun, kóun náà sì jẹ́ Baba wa. Bí Bíbélì ṣe sọ ní orí kẹta ìwé Jẹ́nẹ́sísì, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fẹ́ ṣèdíwọ́ fún ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn. (Jẹ́n. 3:​1-7) Síbẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dà bí ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ lásán, kì í ṣe ohun tí kò lè yanjú torí pé kò sẹ́ni náà tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ ohun tó máa ṣe. (Aísá. 46:10; 55:11) Torí náà, ó dá wa lójú pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún wa máa ṣẹ lásìkò tó ní lọ́kàn gẹ́lẹ́! w17.02 1:​1, 2

Thursday, September 27

Ẹni tí ó fi ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ sínú [Mósè] dà?​—Aísá. 63:11.

Nígbà tó jẹ́ pé èèyàn ò lè fojú rí ẹ̀mí mímọ́, báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí Mósè? Ẹ̀mí mímọ́ mú kí Mósè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, ó sì mú kó kéde orúkọ Jèhófà fún Fáráò. (Ẹ́kís. 7:​1-3) Ẹ̀mí mímọ́ tún mú kí Mósè jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́, ọlọ́kàn tútù àti onísùúrù, àwọn ànímọ́ yìí ló sì mú kó lè darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ọ̀rọ̀ náà ṣe kedere pé Jèhófà ló yan Mósè láti jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tó yá, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà fún àwọn ọkùnrin míì tí Jèhófà yàn lágbára kí wọ́n lè darí àwọn èèyàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ‘Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n.’ (Diu. 34:9) “Ẹ̀mí Jèhófà” bà lé Gídíónì. (Oníd. 6:34) Bákan náà, ‘ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lára Dáfídì.’ (1 Sám. 16:13) Gbogbo àwọn ọkùnrin yẹn gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ẹ̀mí mímọ́ náà sì mú kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan àgbàyanu tí wọn ò lè fagbára wọn ṣe.​—Jóṣ. 11:​16, 17; Oníd. 7:​7, 22; 1 Sám. 17:​37, 50. w17.02 3:​3-5

Friday, September 28

Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.​—2 Kọ́r. 1:24.

Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní ti pé ó jẹ́ kí àwọn ará lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti ṣèpinnu fúnra wọn. Àpẹẹrẹ yìí làwọn alàgbà ń tẹ̀ lé lónìí tí wọ́n bá ń gba àwọn ará níyànjú lórí ọ̀rọ̀ ara ẹni. Wọ́n máa ń jẹ́ káwọn ará mọ ohun tí Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde sọ. Síbẹ̀, àwọn alàgbà máa ń kíyè sára kó má lọ di pé àwọn ló ń sọ ìpinnu táwọn ará máa ṣe fún wọn. Ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu torí pé ẹni tó ṣèpinnu ló ni àbájáde ìpinnu tó bá ṣe. Èyí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ẹ̀kọ́ náà sì ni pé a lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó fẹ́ ṣèpinnu nípa jíjẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí ọ̀rọ̀ náà. Síbẹ̀, ká rántí pé ẹ̀tọ́ wọn ni, ojúṣe wọn sì ni láti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Tí wọ́n bá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, á ṣe wọ́n láǹfààní. Ó ṣe kedere nígbà náà pé a ò gbọ́dọ̀ ronú pé a láṣẹ láti ṣèpinnu fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. w17.03 2:11

Saturday, September 29

Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.​—Héb. 13:17.

Ẹrú olóòótọ́ ń lo ìgbàgbọ́ tó lágbára torí pé wọ́n ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń rọ̀ wá pé káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé ìwọ náà wà lára àwọn àgùntàn mìíràn tó ń ti àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí? Wo bí inú rẹ ṣe máa dùn tó nígbà tí Jésù Aṣáájú wa bá sọ pé: “Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, ẹ ti ṣe é fún mi.” (Mát. 25:​34-40) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti pa dà sọ́run, síbẹ̀ kò gbàgbé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Mát. 28:20) Ó mọ bí ẹ̀mí mímọ́, àwọn áńgẹ́lì àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran òun lọ́wọ́ láti múpò iwájú nígbà tó wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà. Torí náà, ó ń lo ẹ̀mí mímọ́, àwọn áńgẹ́lì àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ran ẹrú olóòótọ́ lọ́wọ́. Ẹrú olóòótọ́ yìí ń “tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ.” (Ìṣí. 14:4) Bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ẹrú náà ń fún wa, ó ṣe kedere pé Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wa là ń tẹ̀ lé. Láìpẹ́, Jésù máa ṣamọ̀nà wa wọnú ayé tuntun níbi tá a ti máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìṣí. 7:​14-17) Ó dájú pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn èèyàn tí wọ́n ń pè ní aṣááju lónìí tó lè ṣe irú ìlérí bẹ́ẹ̀! w17.02 4:​17-19

Sunday, September 30

Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.​—Sm. 37:5.

Tá a bá dojú kọ àwọn ìṣòro tó kà wá láyà, ó máa ń yá wa lára láti bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ kí la máa ń ṣe tó bá kan àwọn ìṣòro ojoojúmọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan? Ṣé a kì í gbára lé òye ara wa, ká sì wá bá a ṣe máa dá yanjú ìṣòro náà? Àbí ṣe la máa ń wo inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká lè fi ìlànà inú rẹ̀ sílò, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Jèhófà la gbára lé? Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan nínú ìdílé rẹ lè gbógun tì ẹ́ nígbà míì pé kó o má lọ sípàdé tàbí àpéjọ. O ò ṣe bẹ Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Ká sọ pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ, tí iṣẹ́ míì ò sì tètè yọjú ńkọ́? Ká wá sọ pé ìwọ àti ẹlòmíì tó fẹ́ gbà ẹ́ síṣẹ́ jọ ń sọ̀rọ̀, ṣé wàá lè sọ fún un pé á máa fún ẹ láyè láti lọ sípàdé àárín ọ̀sẹ̀? Ìṣòro yòówù ká ní, ẹ jẹ́ ká máa fi ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sọ́kàn. w17.03 4:6

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́