Ohun Tó O Kọ́ Ní Apá 1
Kí ìwọ àti ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:
- Àwọn nǹkan wo ló wù ẹ́ jù nínú àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la? - (Wo Ẹ̀kọ́ 02.) 
- Kí nìdí tó o fi gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì? 
- Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà? - (Wo Ẹ̀kọ́ 04.) 
- Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ni “orísun ìyè.” (Sáàmù 36:9) Ṣó o gbà pé òótọ́ ni? - (Wo Ẹ̀kọ́ 06.) 
- Ka Òwe 3:32. - Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ Ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ? 
- Kí ni Jèhófà ń retí pé káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣe? Ṣó o rò pé ó bọ́gbọ́n mu? 
 
- Ka Sáàmù 62:8. - Àwọn nǹkan wo lo ti torí ẹ̀ gbàdúrà sí Jèhófà? Àwọn nǹkan míì wo lo tún lè bá Jèhófà sọ nínú àdúrà rẹ? 
- Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà? - (Wo Ẹ̀kọ́ 09.) 
 
- Ka Hébérù 10:24, 25. - Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? 
- Ṣó o rò pé ó yẹ kó o máa lọ sípàdé kódà láwọn ìgbà tí kò bá rọrùn? - (Wo Ẹ̀kọ́ 10.) 
 
- Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì déédéé? Ìgbà wo lo máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́? - (Wo Ẹ̀kọ́ 11.) 
- Àwọn nǹkan wo lo gbádùn jù lọ látìgbà tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? 
- Látìgbà tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìṣòro wo lo ti dojú kọ tó lè mú kó o dá ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ dúró? Kí lo lè ṣe kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó? - (Wo Ẹ̀kọ́ 12.)