March
Monday, March 1
‘Kí ẹ ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, “ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ mọ́.”—2 Kọ́r. 6:17.
Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa mú ká ṣègbọràn sí Jèhófà kódà táwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ọ̀rẹ́ bá ń fúngun mọ́ wa pé ká lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìsìnkú tó ta ko Bíbélì. Wọ́n lè sọ pé a ò nífẹ̀ẹ́ ẹni tó kú náà la ò ṣe fẹ́ lọ́wọ́ nínú ohun táwọn ń ṣe. Wọ́n sì lè sọ pé ìpinnu wa máa bí òkú yẹn nínú, kó sì wá ṣe àwọn ní ìjàǹbá. Ní agbègbè kan ní Caribbean, ọ̀pọ̀ gbà pé téèyàn bá kú, ẹ̀mí rẹ̀ á ṣì máa rìn kiri láti fìyà jẹ àwọn tó fojú pọ́n ọn nígbà tó wà láyé. Ìwé kan sọ pé ẹ̀mí òkú náà tiẹ̀ lè fa ìṣòro fáwọn ará ìlú. Láwọn ilẹ̀ kan ní Áfíríkà, wọ́n sábà máa ń daṣọ bo dígí, wọ́n á sì kọ ojú fọ́tò òkú náà sí ògiri. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn kan gbà pé ẹni tó kú náà ò gbọ́dọ̀ rí àwòrán ara rẹ̀! Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà kò gba àwọn nǹkan yìí gbọ́, torí náà a kì í bá wọn lọ́wọ́ sáwọn àṣà tó ń gbé irọ́ Sátánì lárugẹ.—1 Kọ́r. 10:21, 22. w19.04 16 ¶11-12
Tuesday, March 2
Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.—Mát. 7:12.
Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láwọn ìlànà táá jẹ́ kí wọ́n máa hùwà tó tọ́ sáwọn míì. Àpẹẹrẹ kan ni ti Ìlànà Pàtàkì tí àwọn kan máa ń pè ní Òfin Oníwúrà. Gbogbo wa la fẹ́ káwọn èèyàn hùwà tó dáa sí wa. Torí náà, ó yẹ káwa náà máa hùwà tó dáa sí wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á yá wọn lára láti ṣe bákan náà sí wa. Táwọn èèyàn bá hùwà àìdáa sí wa ńkọ́? Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ Jèhófà, pẹ̀lú ìdánilójú pé á ‘dájọ́ bó ṣe tọ́ fún àwọn tí wọ́n ń ké pè é tọ̀sántòru.’ (Lúùkù 18:6, 7) Ọ̀rọ̀ yìí fini lọ́kàn balẹ̀ torí ó jẹ́ ká mọ̀ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ó rí gbogbo àdánwò tá à ń kojú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó sì máa gbèjà wa lásìkò tó tọ́ lójú rẹ̀. (2 Tẹs. 1:6) Tá a bá ń fi àwọn ìlànà tí Jésù fi kọ́ni sílò, àá máa hùwà tó dáa sáwọn èèyàn. Táwọn èèyàn bá sì hùwà àìdáa sí wa nínú ayé Èṣù yìí, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ torí ó dá wa lójú pé Jèhófà máa gbèjà wa. w19.05 5 ¶18-19
Wednesday, March 3
Kí ẹ ṣe tán nígbà gbogbo láti gbèjà ara yín níwájú gbogbo ẹni tó bá béèrè ìdí tí ẹ fi ní ìrètí yìí, àmọ́ kí ẹ máa fi ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Pét. 3:15.
Ṣé ọ̀dọ́ tó ń lọ sílé ìwé ni ẹ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo ọmọ kíláàsì rẹ ló gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́. Ó lè wù ẹ́ pé kó o sọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, àmọ́ kó o má mọ bó o ṣe máa ṣàlàyé. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé o gbọ́dọ̀ ṣèwádìí nìyẹn. Á dáa kó o ní àwọn nǹkan méjì yìí lọ́kàn bó o ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́: (1) o fẹ́ jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ló dá gbogbo nǹkan àti (2) o fẹ́ mọ bó o ṣe lè fi Bíbélì ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́. (Róòmù 1:20) Kó o tó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí náà, bi ara rẹ pé, ‘Kí nìdí táwọn ọmọ kíláàsì mi fi gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́?’ Lẹ́yìn ìyẹn, fara balẹ̀ ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Wàá wá rí i pé kò le tó bó o ṣe rò. Ìdí sì ni pé nǹkan táwọn kan gbọ́ lẹ́nu àwọn tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ló jẹ́ kí wọ́n gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́. Tó o bá ti rí kókó kan tàbí méjì tó o lè lò, ó dájú pé wàá lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn tó fẹ́ gbọ́.—Kól. 4:6. w19.05 29 ¶13
Thursday, March 4
Bí ìyá ṣe ń tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni màá máa tù yín nínú.—Àìsá. 66:13.
Nígbà tí wòlíì Èlíjà gbọ́ pé wọ́n fẹ́ pa òun, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá a, ó sì sá lọ kódà ó ronú pé á dáa kóun kú. Jèhófà wá rán áńgẹ́lì alágbára kan láti tù ú nínú, áńgẹ́lì náà sì pèsè ohun tí Èlíjà nílò. Ó gbé oúnjẹ tó gbóná fẹlifẹli wá fún Èlíjà, ó sì rọ̀ ọ́ pé kó jẹun. (1 Ọba 19:5-8) Àkọsílẹ̀ yẹn jẹ́ ká mọ òótọ́ pàtàkì kan: Ìyẹn ni pé kò dìgbà tá a bá ṣe nǹkan ńlá fún ẹnì kan ká tó lè tù ú nínú. Nígbà míì, ó lè jẹ́ ohun kékeré kan tá a ṣe ló máa ṣe ẹni náà láǹfààní. A lè se oúnjẹ fún un, ká fún un lẹ́bùn kan, ká fi káàdì ránṣẹ́ sí i tàbí ká bá a ṣiṣẹ́ ilé, èyí á jẹ́ kó mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun, ọ̀rọ̀ òun sì jẹ wá lógún. Tá ò bá tiẹ̀ mọ ohun tá a lè sọ láti tu ẹni náà nínú, ó dájú pé a lè ràn án lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà yìí. Jèhófà fún wòlíì náà lókun lọ́nà ìyanu kó lè rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn títí dé Òkè Hórébù. Ọkàn ẹ̀ balẹ̀ níbẹ̀ torí ó gbà pé àwọn tó fẹ́ gbẹ̀mí òun kò ní lè rí òun mú níbẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú èyí? Tá a bá fẹ́ pèsè ìtùnú fún ẹni tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé, ó yẹ ká kọ́kọ́ mára tù ú, ká sì fi í lọ́kàn balẹ̀ nílé rẹ̀ tàbí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. w19.05 16 ¶11; 17 ¶13-14
Friday, March 5
Ilẹ̀ náà máa pohùn réré ẹkún, . . . ìdílé Nátánì lọ́tọ̀.—Sek. 12:12.
Ká sọ pé ò ń ka orí kejìlá ìwé Sekaráyà tó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú Mèsáyà. (Sek. 12:10) Ní ẹsẹ kejìlá (12), ó sọ pé “ìdílé Nátánì” máa ṣọ̀fọ̀ Mèsáyà. Dípò kó o kàn gbójú fo gbólóhùn yẹn, o lè bi ara rẹ pé: ‘Kí ló pa ìdílé Nátánì pọ̀ mọ́ ti Mèsáyà?’ Ìyẹn máa gba pé kó o ṣèwádìí díẹ̀. Atọ́ka ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ máa gbé ẹ lọ sí 2 Sámúẹ́lì 5:13, 14 tó sọ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ọba Dáfídì ni Nátánì. Atọ́ka ẹsẹ Bíbélì kejì tún máa gbé ẹ lọ sí Lúùkù 3:23, 31, níbi tí Bíbélì ti sọ pé àtọmọdọ́mọ Nátánì ni Jésù nípasẹ̀ Màríà. Ohun tó o rí lè yà ẹ́ lẹ́nu. O mọ̀ pé Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì. (Mát. 22:42) Àmọ́ ọmọkùnrin tí Dáfídì ní lé ní ogún (20). Ṣé kò wá yà ẹ́ lẹ́nu pé Sekaráyà dìídì mẹ́nu kan Nátánì pé ó máa ṣọ̀fọ̀ Jésù? w19.05 30 ¶17
Saturday, March 6
Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.—Róòmù 12:2.
Kí ló yẹ ká ṣe? Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, a ò ní ṣiyèméjì rárá nípa àwọn òtítọ́ tá a ti kọ́ nínú Bíbélì. Á sì túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlànà Jèhófà ló yẹ ká máa tẹ̀ lé. Ìyẹn á jẹ́ ká dà bí igi tí gbòǹgbò rẹ̀ fìdí múlẹ̀ dáadáa, àá sì “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Kól. 2:6, 7) Àwa fúnra wa la máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, kò sí ẹlòmíì tó lè bá wa ṣe é. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú wa. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ó ṣe pàtàkì ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo, ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa lẹ́mìí mímọ́ rẹ̀. Bákan náà, ká máa ṣàṣàrò, ká sì máa ṣàyẹ̀wò ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká yan àwọn èèyàn gidi lọ́rẹ̀ẹ́, ìyẹn àwọn táá mú ká máa ronú ká sì máa hùwà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ayé Sátánì kò ní kéèràn ràn wá, àá sì borí “àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga tí kò bá ìmọ̀ Ọlọ́run mu.”—2 Kọ́r. 10:5. w19.06 13 ¶17-18
Sunday, March 7
Ìjọsìn tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run àti Baba wa nìyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ aláìlóbìí àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.—Jém. 1:27.
Bí Rúùtù ṣe dúró ti Náómì, bẹ́ẹ̀ náà ló yẹ ká dúró ti àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ká sì máa bá a lọ láti tù wọ́n nínú. (Rúùtù 1:16, 17) Paula sọ pé: “Lẹ́yìn tí ọkọ mi kú, àwọn ará gbárùkù tì mí gan-an. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn èèyàn gbọ́kàn kúrò lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi, wọ́n sì ń bá ìgbésí ayé wọn lọ. Bó ti wù kó rí, ìgbésí ayé mi ti yí pa dà, mi ò sì lè yí ọwọ́ aago pa dà sẹ́yìn mọ́. Mo ti wá rí i pé ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an táwọn ará bá mọ̀ pé ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣì nílò ìtùnú kódà lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún bá ti kọjá.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé bí nǹkan ṣe ń rí lára kálukú yàtọ̀ síra. Àwọn kan máa ń tètè gbé nǹkan kúrò lára. Àmọ́, ìgbà gbogbo làwọn míì máa ń rántí ẹnì kejì wọn tó kú pàápàá tí wọ́n bá ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n sábà máa ń ṣe pa pọ̀. Báwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe nígbà tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹ̀ wọ́n yàtọ̀ síra. Torí náà, ká rántí pé ara iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa ni pé ká máa tu àwọn tó pàdánù ọkọ tàbí aya wọn nínú, ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́. w19.06 24 ¶16
Monday, March 8
Màá fi ìbonu bo ẹnu mi ní gbogbo ìgbà tí ẹni burúkú bá wà níwájú mi.—Sm. 39:1.
Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, ó yẹ ká mọ “ìgbà dídákẹ́.” (Oníw. 3:7) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìsọfúnni tó yẹ ká pa mọ́ láṣìírí bọ́ sọ́wọ́ àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, orúkọ àwọn ará, àwọn ibi tá a ti ń ṣèpàdé, ọ̀nà tá à ń gbà wàásù àti bá a ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà. A ò ní fún aṣojú ìjọba èyíkéyìí láwọn ìsọfúnni yìí, bẹ́ẹ̀ sì la ò ní fún àwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wa lórílẹ̀-èdè tá à ń gbé tàbí lórílẹ̀-èdè míì. Tá a bá jẹ́ káwọn ìsọfúnni yìí bọ́ sọ́wọ́ àwọn míì, ṣe là ń fi ẹ̀mí àwọn ará wa sínú ewu. Ká má ṣe jẹ́ kí èdèkòyédè tàbí àìgbọ́ra-ẹni-yé fa ìpínyà láàárín wa. Sátánì mọ̀ pé tí kò bá sí ìṣọ̀kan nínú ilé kan, ilé náà kò ní lè dúró. (Máàkù 3:24, 25) Bó ṣe máa kẹ̀yìn wa síra ló ń wá, kò níṣẹ́ míì. Ó mọ̀ pé tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, dípò ká ṣe ara wa ní òṣùṣù ọwọ̀ ká sì kọjú ìjà sí òun ńṣe làá máa bá ara wa jà. Kódà, àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa gba èṣù láyè. Torí náà, tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa, a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun da àárín wa rú, àá sì wà níṣọ̀kan.—Kól. 3:13, 14. w19.07 11-12 ¶14-16
Tuesday, March 9
[Ó] yẹ kí ẹrú Olúwa . . . máa hùwà jẹ́jẹ́ sí gbogbo èèyàn, kí ó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni.—2 Tím. 2:24.
Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe ohun tá a bá àwọn èèyàn sọ ló máa ń mú kí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, bí kò ṣe ọ̀nà tá a gbà bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n máa ń mọrírì bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wọn, tá à ń gba tiwọn rò, tá a sì ń sọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání. Yàtọ̀ síyẹn, a kì í fipá mú wọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la máa ń sapá láti mọ èrò wọn nípa ẹ̀sìn, ká sì gba tiwọn rò. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ ni Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó ń bá àwọn Júù sọ̀rọ̀. Àmọ́ nígbà tó ń bá àwọn Gíríìkì onímọ̀ ọgbọ́n orí sọ̀rọ̀ ní Áréópágù, kò tọ́ka sí Bíbélì ní tààràtà. (Ìṣe 17:2, 3, 22-31) Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù? Tá a bá pàdé ẹnì kan tí kò gba Bíbélì gbọ́, á dáa ká má ṣe mẹ́nu kan Bíbélì ní tààràtà nínú ìjíròrò wa pẹ̀lú rẹ̀. Tó o bá kíyè sí i pé ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ kò fẹ́ káwọn míì rí i pé òun ń ka Bíbélì, á dáa kó o ka Bíbélì fún un látinú fóònù rẹ. w19.07 21 ¶5-6
Wednesday, March 10
Kí ẹ rí i pé ẹ ò jẹ́ kí ọkàn yín fà sí àwọn ọlọ́run míì, kí ẹ wá yà bàrá lọ sìn wọ́n.—Diu. 11:16.
Sátánì fọgbọ́n tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ kí wọ́n lè bọ̀rìṣà, ó mọ̀ pé oúnjẹ ṣe pàtàkì, ohun tó sì fi dẹkùn mú wọn nìyẹn. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ó di dandan kí wọ́n yí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń dáko pa dà. Ìdí sì ni pé nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì, omi tó wá látinú Odò Náílì ni wọ́n fi ń bomi rin oko wọn. Àmọ́ ní Ilẹ̀ Ìlérí, ó dìgbà tí òjò bá rọ̀, tí ìrì sì sẹ̀ kí irúgbìn wọn tó lè rómi mu. (Diu. 11:10-15; Àìsá. 18:4, 5) Torí náà, ó pọn dandan fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti kọ́ ọ̀nà tuntun tí wọ́n á máa gbà dáko. Kí nìdí tí Jèhófà fi kìlọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bọ̀rìṣà nígbà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n á ṣe máa dáko ló ń bá wọn sọ? Jèhófà mọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fẹ́ yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọn ká, kí wọ́n lè kọ́ bí wọ́n ṣe ń dáko lágbègbè yẹn. Òrìṣà Báálì làwọn àgbẹ̀ tó wà nílẹ̀ Kénáánì ń bọ, wọ́n sì gbà pé òun ló ni ojú ọ̀run, tó sì ń fúnni ní òjò.—Nọ́ń. 25:3, 5; Oníd. 2:13; 1 Ọba 18:18. w19.06 3 ¶4-6
Thursday, March 11
Ohun tí mò ń gbà ládùúrà ni pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ pọ̀ gidigidi.—Fílí. 1:9.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Sílà, Lúùkù àti Tímótì dé sílùú Fílípì, wọ́n wàásù fún àwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn arákùnrin mẹ́rin tó nítara yìí ló mú kí wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ nílùú yẹn. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé arábìnrin ọ̀làwọ́ kan tó ń jẹ́ Lìdíà làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni yẹn ti ń pàdé pọ̀. (Ìṣe 16:40) Kò pẹ́ tí wọ́n dá ìjọ náà sílẹ̀ ni Èṣù gbé ìṣe rẹ̀ dé. Ó mú káwọn ọ̀tá òtítọ́ gbé àtakò dìde, wọn ò sì fẹ́ kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn yòókù rẹ̀ wàásù nílùú yẹn mọ́. Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, wọ́n ti fàṣẹ ọba mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà, wọ́n fi ọ̀pá lù wọ́n, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni, wọ́n sì fún wọn níṣìírí. Ẹ̀yìn náà ni Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Tímótì fi ìlú náà sílẹ̀, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí Lúùkù ní tiẹ̀ dúró síbẹ̀. Báwo ni nǹkan ṣe rí fáwọn ará tó wà níjọ tuntun yẹn? Ẹ̀mí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run láìfi àtakò pè. (Fílí. 2:12) Ẹ wá rídìí tí inú Pọ́ọ̀lù fi dùn sí wọn gan-an! w19.08 8 ¶1-2
Friday, March 12
Ẹni tó yá nǹkan . . . ni ẹrú ẹni tó yá a ní nǹkan.—Òwe 22:7.
Ṣé o ṣí lọ síbòmíì lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Ó máa ń náni lówó gan-an téèyàn bá ṣípò pa dà, téèyàn ò bá sì ṣọ́ra ó lè tọrùn bọ gbèsè. Tó ò bá fẹ́ tọrùn bọ gbèsè, má ṣe jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ra nǹkan àwìn, má sì yáwó láìnídìí. (Òwe 22:3) Tí ìṣòro bá yọjú, bóyá tẹ́nì kan nínú ìdílé rẹ ń ṣàìsàn, ẹ lè má mọ iye tẹ́ ẹ máa yá lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ yíjú sí Jèhófà, kẹ́ ẹ gbàdúrà, kẹ́ ẹ sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i pé kó ràn yín lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Jèhófà máa gbọ́ àdúrà yín, á mú kẹ́ ẹ ní àlàáfíà tó máa “ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín,” èyí á sì jẹ́ kẹ́ ẹ lè fara balẹ̀ ronú kẹ́ ẹ tó ṣèpinnu èyíkéyìí. (Fílí. 4:6, 7; 1 Pét. 5:7) Má ṣe fàwọn ọ̀rẹ́ gidi sílẹ̀. Sọ ìrírí rẹ àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ, pàápàá àwọn tẹ́ ẹ ti jọ ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rí. Torí pé ipò yín jọra, ẹ̀ẹ́ lè jọ fún ara yín níṣìírí. (Oníw. 4:9, 10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti ṣípò pa dà, o ṣì lè máa bá àwọn tó o fi sílẹ̀ ṣọ̀rẹ́. w19.08 22 ¶9-10
Saturday, March 13
Wọ́n sì kó wọn jọ sí . . . Amágẹ́dọ́nì.—Ìfi. 16:16.
Kí nìdí tí Jèhófà fi mẹ́nu kan Mẹ́gídò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ogun ọjọ́ ńlá rẹ̀? Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ ogun làwọn èèyàn jà ní Mẹ́gídò àti Àfonífojì Jésírẹ́lì tó wà nítòsí Mẹ́gídò. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jèhófà dìídì ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà mú kí Bárákì ṣẹ́gun Sísérà, ìyẹn olórí àwọn ọmọ ogun Kénáánì “létí omi Mẹ́gídò.” Bárákì àti Dèbórà tó jẹ́ wòlíì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe mú kí wọ́n ṣẹ́gun lọ́nà ìyanu. Lára ohun tí wọ́n kọ lórin ni pé: “Àwọn ìràwọ̀ jà láti ọ̀run; wọ́n bá Sísérà jà. . . . Jẹ́ kí gbogbo ọ̀tá rẹ ṣègbé, Jèhófà, àmọ́ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ dà bí oòrùn tó ń yọ nínú ògo rẹ̀.” (Oníd. 5:19-21, 31) Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jèhófà máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ run pátápátá, á sì dá ẹ̀mí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí. Àmọ́, ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà nínú ogun Amágẹ́dọ́nì àtèyí tí Bárákì jà. Àwọn èèyàn Ọlọ́run kò ní jà nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Kódà, wọn ò ní ní ohun ìjà kankan débi tí wọ́n á dira ogun! Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ‘máa lágbára tí wọ́n bá fara balẹ̀, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé’ Jèhófà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ tó wà lọ́run.—Àìsá. 30:15; Ìfi. 19:11-15. w19.09 9 ¶4-5
Sunday, March 14
Ẹ wá sọ́dọ̀ mi.—Mát. 11:28.
Ọ̀nà kan tá a lè gbà “wá sọ́dọ̀” Jésù ni pé ká kọ́ gbogbo ohun tá a lè kọ́ nípa rẹ̀, ìyẹn àwọn ohun tó ṣe àtohun tó sọ. (Lúùkù 1:1-4) Kò sẹ́ni tó lè ṣèyẹn fún wa, àwa fúnra wa la máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀. A tún lè lọ “sọ́dọ̀” Jésù tá a bá pinnu láti ṣèrìbọmi tá a sì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ọ̀nà míì tá a lè gbà lọ “sọ́dọ̀” Jésù ni pé ká tọ àwọn alàgbà lọ kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. Àwọn “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” yìí ni Jésù ń lò láti bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀. (Éfé. 4:7, 8, 11; Jòh. 21:16; 1 Pét. 5:1-3) Àwa la gbọ́dọ̀ lọ bá wọn, ó ṣe tán, kò sí báwọn alàgbà ṣe lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wa tàbí ohun tá a nílò. Ẹ gbọ́ ohun tí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Julian sọ, ó ní: ‘Mo ní kí wọ́n wá ràn mí lọ́wọ́. Kí n má tàn yín, mo gbádùn ìbẹ̀wò yẹn, kò sóhun tí mo lè fi wé.’ Bíi tàwọn alàgbà méjì tó bẹ Julian wò, àwọn alàgbà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ “èrò inú Kristi,” ìyẹn ni pé, ká lóye bí Kristi ṣe ń ronú àti bó ṣe ń hùwà, ká sì fara wé e. (1 Kọ́r. 2:16; 1 Pét. 2:21) Ká sòótọ́, kò sí ẹ̀bùn tá a lè fi wé irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀. w19.09 21 ¶4-5
Monday, March 15
Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kò sí lára ọ̀wọ́ yìí.—Jòh. 10:16.
Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí, síbẹ̀ tí wọn ò sí lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) náà. Àpẹẹrẹ kan ni Jòhánù Arinibọmi. (Mát. 11:11) Àpẹẹrẹ míì ni Dáfídì. (Ìṣe 2:34) Àwọn olóòótọ́ yìí àti ọ̀pọ̀ àwọn míì ni Jèhófà máa jí dìde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Gbogbo wọn pátá títí kan àwọn ogunlọ́gọ̀ náà máa láǹfààní láti fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, àwọn sì fi ara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Jèhófà máa kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn jọ látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ níṣọ̀kan. Yálà ọ̀run là ń lọ tàbí ayé la máa wà, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wà lára ogunlọ́gọ̀ tó jẹ́ ara “àgùntàn mìíràn.” Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, Jèhófà máa mú kí ìpọ́njú ńlá tó sọ tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀, á sì pa àwọn ìjọba ayé yìí run títí kan àwọn ẹ̀sìn tó ń fayé ni àwọn èèyàn lára. Ẹ wo àǹfààní àgbàyanu táwọn ogunlọ́gọ̀ náà máa ní, wọ́n á máa sin Jèhófà títí láé lórí ilẹ̀ ayé!—Ìfi. 7:14. w19.09 31 ¶18-19
Tuesday, March 16
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn tó ń fini ṣẹlẹ́yà máa wá, wọ́n á máa fini ṣẹlẹ́yà.—2 Pét. 3:3.
Bí ètò Sátánì ṣe ń lọ sópin, a mọ̀ pé a máa kojú àwọn àdánwò tó lágbára táá fi hàn bóyá a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn túbọ̀ máa fi wá ṣẹlẹ́yà lásìkò yẹn. Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí wọ́n sì fi máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a kì í ṣe ara wọn, a ò sì dá sí ohunkóhun tí wọ́n ń ṣe. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá jẹ́ adúróṣinṣin báyìí, kó lè rọrùn fún wa láti jẹ́ adúróṣinṣin nígbà ìpọ́njú ńlá. Lásìkò ìpọ́njú ńlá, ìyípadà máa wáyé sí àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwa èèyàn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé. Tó bá di àkókò kan, àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé máa lọ sọ́run kí wọ́n lè kópa nínú ogun Amágẹ́dọ́nì. (Mát. 24:31; Ìfi. 2:26, 27) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ò ní sí pẹ̀lú wa mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, ogunlọ́gọ̀ èèyàn ìyẹn àwa èèyàn Jèhófà ṣì máa wà létòlétò. Àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n lára àwọn àgùntàn mìíràn lá máa múpò iwájú. A gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin, ká máa ti àwọn arákùnrin yìí lẹ́yìn, ká sì máa tẹ̀ lé gbogbo ìtọ́ni tí Jèhófà ń gbẹnu wọn fún wa. Ìyẹn ló máa jẹ́ ká là á já! w19.10 17 ¶13-14
Wednesday, March 17
Ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ . . . Ibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí.—Rúùtù 1:16, 17.
Obìnrin olóòótọ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni Náómì. Àmọ́ lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì kú, ìdààmú ọkàn bá a débi tó fi sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n má pe òun ní Náómì mọ́, “Márà” tó túmọ̀ sí “Ìkorò” ni kí wọ́n máa pe òun. (Rúùtù 1:3, 5, 20, àlàyé ìsàlẹ̀, 21) Ṣùgbọ́n Rúùtù tó jẹ́ ìyàwó ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dúró tì í ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira yẹn. Yàtọ̀ sí pé Rúùtù ṣe àwọn ohun pàtó láti ràn án lọ́wọ́, ó tún máa ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un. Rúùtù lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára láti jẹ́ kí Náómì mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Tí ẹnì kan nínú ìjọ bá pàdánù ọkọ tàbí aya rẹ̀, ó ṣe pàtàkì ká dúró ti irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ṣe làwọn tọkọtaya dà bí igi méjì tí wọ́n jọ hù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, gbòǹgbò wọn á máa lọ́ mọ́ra. Tí wọ́n bá hú ọ̀kan nínú wọn tó sì kú, ó máa ṣàkóbá fún ìkejì gan-an. Lọ́nà kan náà, tí ọkọ tàbí aya ẹnì kan bá kú, ó máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an, ó sì lè má lọ bọ̀rọ̀. w19.06 23 ¶12-13
Thursday, March 18
Àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.—Jém. 1:14.
Kì í ṣe irú eré ìnàjú tá à ń wò nìkan ló yẹ ká kíyè sí, ó tún yẹ ká kíyè sí iye àkókò tá à ń lò nídìí ẹ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, iye àkókò tá à ń lò nídìí eré ìnàjú máa pọ̀ ju èyí tá a fi ń jọ́sìn Jèhófà lọ. Àkọ́kọ́, mọ iye wákàtí tó ò ń lò nídìí ẹ̀. O ò ṣe gbìyànjú láti mọ iye àkókò tó o lò nídìí ẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ kan? Kọ iye wákàtí tó o lò nídìí tẹlifíṣọ̀n, Íńtánẹ́ẹ̀tì àti iye àkókò tó o lò nídìí géèmù sílẹ̀. Tíwọ náà bá rí i pé ọ̀pọ̀ wákàtí lò ń lò, gbìyànjú àbá yìí wò. Ṣe àkọsílẹ̀ bí wàá ṣe máa lo àkókò rẹ, àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà ni kó o fi sípò àkọ́kọ́, ẹ̀yìn ìyẹn ni kó o wá pinnu iye àkókò tó o fẹ́ máa lò nídìí eré ìnàjú. Lẹ́yìn náà, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó o pinnu yìí. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá ní ọ̀pọ̀ àkókò àti okun tí wàá fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn ìdílé, tí wàá sì fi lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí. Yàtọ̀ síyẹn, wàá túbọ̀ gbádùn eré ìnàjú, torí o mọ̀ pé o ti fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́. w19.10 30 ¶14, 16; 31 ¶17
Friday, March 19
Ó ń wù mí láti ṣe ohun tó dára, àmọ́ mi ò ní agbára láti ṣe é.—Róòmù 7:18.
Ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Kọ́ríńtì ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn ará ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà ń jìyà, wọn ò sì lówó lọ́wọ́, wọ́n pinnu pé àwọn á ran àwọn ará yẹn lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 16:1; 2 Kọ́r. 8:6) Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé àwọn ará Kọ́ríńtì ò tíì ṣe ohun tí wọ́n ní àwọn fẹ́ ṣe. Torí náà, owó tí wọ́n fẹ́ dá ò ní lè bá tàwọn ìjọ yòókù lọ sí Jerúsálẹ́mù torí wọn ò dá a lásìkò. (2 Kọ́r. 9:4, 5) Ìpinnu tó dáa làwọn ará Kọ́ríńtì ṣe, Pọ́ọ̀lù sì gbóríyìn fún wọn torí ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n ní àti bó ṣe ń wù wọ́n láti ran àwọn ará wọn lọ́wọ́. Àmọ́, ó tún gbà wọ́n nímọ̀ràn pé kí wọ́n parí ohun tí wọ́n bẹ̀rẹ̀, ó ṣe tán àwọn kan máa ń sọ pé ìbẹ̀rẹ̀ kì í ṣe oníṣẹ́. (2 Kọ́r. 8:7, 10, 11) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí kọ́ wa pé ó lè ṣòro fáwọn Kristẹni tòótọ́ pàápàá láti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìpinnu tó dáa tí wọ́n ṣe. Kí nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé aláìpé ni wá, a sì máa ń fi nǹkan falẹ̀ nígbà míì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ohun tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe ohun tá a pinnu.—Oníw. 9:11. w19.11 26-27 ¶3-5
Saturday, March 20
Ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́.—Éfé. 6:16.
Bí apata ńlá ṣe máa ń dáàbò bo ọmọ ogun, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ rẹ ṣe máa dáàbò bò ẹ́ lọ́wọ́ ìṣekúṣe, ìwà ipá àtàwọn ìwàkiwà míì tó kúnnú ayé èṣù yìí. Ogun tẹ̀mí làwa Kristẹni ń jà, àwọn ẹ̀mí burúkú la sì ń bá jà. (Éfé. 6:10-12) Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o wà ní sẹpẹ́ nígbà tí àdánwò ìgbàgbọ́ bá dé? Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò kó o lè mọ̀ bóyá irú ẹni tí Jèhófà fẹ́ kó o jẹ́ ni o jẹ́. (Héb. 4:12) Bíbélì sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.” (Òwe 3:5, 6) Pẹ̀lú ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, wá ronú nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ lẹ́nu àìpẹ́ yìí àtohun tó o ṣe nípa ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o níṣòro ìṣúnná owó tó le gan-an? Ṣé o sì rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe nínú Hébérù 13:5 pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé”? Ǹjẹ́ ìlérí yẹn mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ò ń ṣe ohun tó yẹ láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ dúró digbí. w19.11 14 ¶1, 4
Sunday, March 21
Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.—Sm. 127:3.
Ó ṣe pàtàkì kí ìyá àti bàbá máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa tọ́ wọn sọ́nà. Torí náà, tí tọkọtaya bá wẹ́ ọmọ jọ láàárín ọdún mélòó kan péré, ó lè ṣòro fún wọn láti wáyè fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ náà. Àwọn tọkọtaya tó wẹ́ ọmọ jọ gbà pé kò rọrùn rárá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló lè rẹ ìyá bẹ́ẹ̀, kó sì máa kanra. Ṣérú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kó nira fún un láti ráyè kẹ́kọ̀ọ́, láti gbàdúrà tàbí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé? Ìṣòro míì lèyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ nípàdé, kì í sábà rọrùn fáwọn ìyá ọlọ́mọ láti gbádùn ìpàdé. Àmọ́ ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ kò ní dá iṣẹ́ náà dá a yálà nílé tàbí nípàdé. Bí àpẹẹrẹ, irú ọkọ bẹ́ẹ̀ máa ń ran ìyàwó ẹ̀ lọ́wọ́ nínú ilé. Ó máa ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé, ó sì máa ń rí i pé ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọ gbádùn ìṣètò náà. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń bá ìdílé rẹ̀ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí déédéé. w19.12 24 ¶8
Monday, March 22
Júbílì ni ọdún àádọ́ta (50) náà yóò jẹ́ fún yín.—Léf. 25:11.
Àǹfààní wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí nínú ètò Júbílì tí Jèhófà ṣe? Ẹ jẹ́ ká sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan jẹ gbèsè, ó wá di dandan pé kó ta ilẹ̀ rẹ̀ kó lè san gbèsè tó jẹ. Tó bá di ọdún Júbílì, wọ́n gbọ́dọ̀ dá ilẹ̀ náà pa dà fún un. Nípa bẹ́ẹ̀, á ṣeé ṣe fún ẹni tó ni ilẹ̀ náà láti “pa dà sídìí ohun ìní rẹ̀,” á sì rí ogún fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà míì sì rèé, nǹkan lè nira fún ẹnì kan débi tó fi máa ta ọmọ rẹ̀ tàbí ara rẹ̀, á sì di ẹrú ẹni tó jẹ ní gbèsè. Tó bá di ọdún Júbílì, ẹrú náà máa “pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀.” (Léf. 25:10) Torí náà, kò sí pé ẹnì kan ń fi gbogbo ayé rẹ̀ sìnrú fún ẹlòmíì láìnírètí! Bákan náà, Jèhófà sọ pé: “Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ tòṣì, torí ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ọ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún.” (Diu. 15:4) Ẹ wo bíyẹn ṣe yàtọ̀ pátápátá sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí, táwọn olówó ń lówó sí i, táwọn òtòṣì sì túbọ̀ ń tòṣì! w19.12 8-9 ¶3-4
Tuesday, March 23
Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn mi yọ̀.—Òwe 27:11.
Nígbà tí Jésù wà nínú àdánwò, ó gbàdúrà sí Jèhófà pẹ̀lú “ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé.” (Héb. 5:7) Àdúrà tó gbà yẹn fi hàn pé tọkàntọkàn ló fi múra tán láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Lójú Jèhófà, àdúrà tí Jésù gbà dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn. Ìgbésí ayé Jésù látòkèdélẹ̀ múnú Jèhófà dùn gan-an, ó sì dá Jèhófà láre pé Òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. A lè fara wé Jésù tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa, tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Tá a bá kojú àdánwò, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntara pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. A mọ̀ pé Jèhófà ò ní gbọ́ àdúrà wa tá a bá ń ṣe ohun tó kórìíra. Àmọ́ tá a bá ń fi ìlànà rẹ̀ sílò láyé wa, ó dá wa lójú pé àdúrà wa máa dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn lójú Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, bá a ṣe jẹ́ onígbọràn tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin máa múnú Jèhófà Baba wa dùn. w19.11 21-22 ¶7-8
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 9) Lúùkù 19:29-44
Wednesday, March 24
Ní tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye?—Mát. 24:45.
Lọ́dún 1919, Jésù yan ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró, ó sì fi wọ́n ṣe “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Ẹrú yìí ló ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, òun náà ló sì ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi “ní àkókò tó yẹ.” Sátánì àti ayé búburú yìí ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dá iṣẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà dúró. Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà lára ẹrú yìí, wọn ò bá má rí iṣẹ́ náà ṣe. Láìka ti ogun àgbáyé méjì tó wáyé, bí wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni tó lé kenkà sí wọn, tọ́rọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n wọn, ẹrú yìí kò dẹ́kun àtimáa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fáwa ọmọlẹ́yìn Kristi. Ẹ wo bí oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú yìí ń pèsè ṣe pọ̀ tó lónìí ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900), bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn kì í díye lé e! Kò sí àlàyé míì, ìtìlẹyìn Ọlọ́run ló mú kó ṣeé ṣe. Àpẹẹrẹ míì tó fi hàn pé Jèhófà ń ti ẹrú náà lẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù. Ní báyìí, à ń wàásù ìhìn rere náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”—Mát. 24:14. w19.11 24 ¶15-16
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 10) Lúùkù 19:45-48; Mátíù 21:18, 19; 21:12, 13
Thursday, March 25
A ṣojúure sí [Kristi] torí pé ó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.—Héb. 5:7.
Lọ́dọọdún ní Ọjọ́ Ètùtù àlùfáà àgbà máa ní láti kọ́kọ́ sun tùràrí kó tó lè rú ẹbọ sí Jèhófà, torí ìyẹn ló máa jẹ́ kó rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà nígbà tó bá rú ẹbọ. Nígbà tí Jésù wà láyé, kó tó di pé ó fi ara rẹ̀ rúbọ, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an, kódà ohun náà ṣe pàtàkì ju ìgbàlà wa lọ. Kí ni nǹkan náà? Ó gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀, kó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i torí pé ìyẹn lá jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ tó fẹ́ rú. Ìgbọràn Jésù máa fi hàn pé ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà gbé ìgbésí ayé wa ni pé ká ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ó sì tún máa jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Ní gbogbo ọjọ́ tí Jésù lò láyé, ó ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dojú kọ ìdẹwò àti àdánwò, ó jẹ́ onígbọràn sí Baba rẹ̀ láìkù síbì kan.—Fílí. 2:8. w19.11 21 ¶6-7
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 11) Lúùkù 20:1-47
Friday, March 26
Ẹ̀yin lẹ ti dúró tì mí nígbà àdánwò.—Lúùkù 22:28.
Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀rẹ́ gidi làwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jẹ́ fún un nígbà dídùn àti nígbà kíkan. (Òwe 18:24) Jésù mọyì àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí gan-an. Ó ṣe tán, àwọn àbúrò rẹ̀ ò gbà á gbọ́. (Jòh. 7:3-5) Kódà ìgbà kan wà táwọn mọ̀lẹ́bí Jésù sọ pé orí rẹ̀ ti yí. (Máàkù 3:21) Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì ò ronú bẹ́ẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní fún wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbà kan wà táwọn àpọ́sítélì ṣe ohun tó dun Jésù, síbẹ̀ àwọn nǹkan rere tí wọ́n ṣe ló gbájú mọ́, ó sì mọyì bí wọ́n ṣe nígbàgbọ́ nínú òun. (Mát. 26:40; Máàkù 10:13, 14; Jòh. 6:66-69) Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kí wọ́n tó pa á, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi.” (Jòh. 15:15) Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rẹ́ Jésù fún un níṣìírí. w19.04 11 ¶11-12
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 12) Lúùkù 22:1-6; Máàkù 14:1, 2, 10, 11
Ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi
Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
Saturday, March 27
Ẹ̀mí fúnra rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé ọmọ Ọlọ́run ni wá.—Róòmù 8:16.
Báwo lẹnì kan ṣe máa mọ̀ pé Jèhófà ti fi ẹ̀mí yan òun tàbí pé ẹni àmì òróró lòun? Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tí Jèhófà “pè láti jẹ́ ẹni mímọ́” nílùú Róòmù. Láfikún sí ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní, ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ìsìnrú tó ń múni pa dà sínú ìbẹ̀rù lẹ gbà, ẹ̀mí ìsọdọmọ lẹ gbà, ẹ̀mí tó ń mú ká ké jáde pé: ‘Ábà, Bàbá!’ ” (Róòmù 1:7; 8:15) Torí náà, ẹ̀mí mímọ́ ni Jèhófà lò láti mú kó ṣe kedere sáwọn ẹni àmì òróró pé ọ̀run ni wọ́n ń lọ. (1 Tẹs. 2:12) Jèhófà máa ń mú kó ṣe kedere láìsí tàbí ṣùgbọ́n sí àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró pé òun ti fi ẹ̀mí yàn wọ́n láti lọ sí ọ̀run. (1 Jòh. 2:20, 27) Wọn ò nílò kẹ́nì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún wọn kí wọ́n tó mọ̀ pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan àwọn. w20.01 22 ¶7-8
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 13) Lúùkù 22:7-13; Máàkù 14:12-16 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 14) Lúùkù 22:14-65
Sunday, March 28
Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.—Jòh. 15:13.
Orí ìpìlẹ̀ tó lágbára ni a gbé “òfin Kristi” kà, ìyẹn sì ni ìfẹ́. (Gál. 6:2) Ìfẹ́ ló mú kí Jésù ṣe gbogbo ohun tó ṣe. Ìfẹ́ ló máa ń mú kéèyàn káàánú àwọn míì tàbí kéèyàn ṣe àwọn míì lóore. Torí pé Jésù káàánú àwọn èèyàn, ó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó mú àwọn tó ń ṣàìsàn lára dá, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó sì jí àwọn òkú dìde. (Mát. 14:14; 15:32-38; Máàkù 6:34; Lúùkù 7:11-15) Jésù fi ire àwọn èèyàn ṣáájú tiẹ̀. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn nígbà tó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. A lè fara wé Jésù tá a bá ń fi ire àwọn míì ṣáájú tiwa. A tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń káàánú àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Tó bá jẹ́ pé àánú àwọn èèyàn ló ń mú ká máa wàásù ká sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, á jẹ́ pé òfin Kristi là ń tẹ̀ lé yẹn. w19.05 4 ¶8-10
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 14) Lúùkù 22:66-71
Monday, March 29
[Jèhófà] rán mi láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú . . . , láti mú kí àwọn tí wọ́n tẹ̀ rẹ́ máa lọ lómìnira.—Lúùkù 4:18.
Jésù mú káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀kọ́ èké làwọn aṣáájú ìsìn wọn fi ń kọ́ wọn. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ọ̀pọ̀ Júù ni wọ́n fipá mú láti gba ẹ̀kọ́ èké gbọ́, tí wọ́n sì ń lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Òfin Ọlọ́run mu. (Mát. 5:31-37; 15:1-11) Afọ́jú lásán-làsàn ni àwọn tó pera wọn ní afinimọ̀nà yẹn. Kí nìdí? Torí pé wọ́n kọ Jésù ní Mèsáyà, tí wọn ò sì gbà pé kó tọ́ àwọn sọ́nà, inú òkùnkùn biribiri ni wọ́n wà, wọn ò sì ní rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Jòh. 9:1, 14-16, 35-41) Torí pé Jésù kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́, tó sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, ó ṣeé ṣe fáwọn oníwà pẹ̀lẹ́ láti ní òmìnira nípa tẹ̀mí. (Máàkù 1:22; 2:23–3:5) Jésù dá aráyé sílẹ̀ lómìnira bó ṣe mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. Àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, tó sì ń hàn nínú ìgbésí ayé wọn ló máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.—Héb. 10:12-18. w19.12 10 ¶8; 11 ¶10-11
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 15) Mátíù 27:62-66
Tuesday, March 30
A fi ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí gbé èdìdì lé yín nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ yìí jẹ́ àmì ìdánilójú ogún tí à ń retí.—Éfé. 1:13, 14.
Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kó dá gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lójú pé òun ti yàn wọ́n. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ni “àmì ìdánilójú [ìyẹn ẹ̀jẹ́ tàbí ìlérí]” tí Jèhófà fún wọn láti mú kó dá wọn lójú pé ọ̀run ni wọ́n máa gbé títí láé kì í ṣe ayé yìí. (2 Kọ́r. 1:21, 22) Tí Kristẹni kan bá di ẹni àmì òróró, ṣé ó ti dájú nìyẹn pé ó máa lọ sọ́run? Rárá. Ó dá Kristẹni bẹ́ẹ̀ lójú pé Jèhófà ti yan òun láti lọ sọ́run. Àmọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ túbọ̀ ṣe gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe, kí pípè àti yíyàn yín lè dá yín lójú, torí tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ẹ ò ní kùnà láé.” (2 Pét. 1:10) Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti yan Kristẹni ẹni àmì òróró kan láti lọ sọ́run, tí Kristẹni náà bá jẹ́ olóòótọ́ dópin nìkan ló tó lè rí èrè náà gbà.—Fílí. 3:12-14; Héb. 3:1; Ìfi. 2:10. w20.01 21-22 ¶5-6
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 16) Lúùkù 24:1-12
Wednesday, March 31
Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni, àmọ́ ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.—Òwe 12:18.
Dípò káwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta tù ú nínú kí wọ́n sì fàánú hàn sí i, ṣe ni wọ́n bẹnu àtẹ́ lù ú. Ìdí sì ni pé wọn ò lóye ohun tó fa ìṣòro ẹ̀, torí náà wọ́n dá a lẹ́bi, wọ́n sì sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i. Kí ló yẹ ká ṣe ká má bàa dà bí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù yìí? Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà nìkan ló mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó fa ìṣòro tẹ́nì kan ń kojú àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká jẹ́ aláàánú, ká sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹni náà dáadáa. Àmọ́ kì í ṣèyẹn nìkan, ó tún yẹ ká sapá ká lè mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀. Ìgbà yẹn la máa tó lóye ohun tẹ́ni náà ń kojú, àá sì lè ràn án lọ́wọ́. Tá a bá jẹ́ aláàánú, a ò ní máa sọ ìṣòro àwọn ará wa kiri fáwọn míì. Ẹni tó ń ṣòfófó kì í gbé ìjọ ró, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa ń tú ìjọ ká. (Òwe 20:19; Róòmù 14:19) Ó máa ń sọ̀rọ̀ láìronú, ọ̀rọ̀ ẹ̀ sì máa dá kún ìṣòro ẹni tó ní ìdààmú ọkàn. (Éfé. 4:31, 32) Ẹ wo bó ṣe máa dáa tó pé ibi tẹ́nì kan dáa sí là ń wò, ká sì ronú ohun tá a lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́ kó lè fara da ìṣòro ẹ̀. w19.06 21-22 ¶8-9