ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es21 ojú ìwé 88-97
  • September

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • September
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Wednesday, September 1
  • Thursday, September 2
  • Friday, September 3
  • Saturday, September 4
  • Sunday, September 5
  • Monday, September 6
  • Tuesday, September 7
  • Wednesday, September 8
  • Thursday, September 9
  • Friday, September 10
  • Saturday, September 11
  • Sunday, September 12
  • Monday, September 13
  • Tuesday, September 14
  • Wednesday, September 15
  • Thursday, September 16
  • Friday, September 17
  • Saturday, September 18
  • Sunday, September 19
  • Monday, September 20
  • Tuesday, September 21
  • Wednesday, September 22
  • Thursday, September 23
  • Friday, September 24
  • Saturday, September 25
  • Sunday, September 26
  • Monday, September 27
  • Tuesday, September 28
  • Wednesday, September 29
  • Thursday, September 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2021
es21 ojú ìwé 88-97

September

Wednesday, September 1

Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di báyìí, èmi náà ṣì ń ṣiṣẹ́.​—Jòh. 5:17.

Ṣé bí Jèhófà àti Jésù kò ṣe fiṣẹ́ ṣeré yìí wá túmọ̀ sí pé àwa náà ò gbọ́dọ̀ sinmi? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Kì í rẹ Jèhófà, torí náà kò nílò ìsinmi báwa èèyàn ṣe máa ń sinmi. Bó ti wù kó rí, Bíbélì sọ pé lẹ́yìn tí Jèhófà dá ọ̀run àti ayé, ‘ó sinmi, ara sì tù ú.’ (Ẹ́kís. 31:17) Ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ ni pé Jèhófà dáwọ́ dúró díẹ̀ kó lè fara balẹ̀ wo àwọn nǹkan tó dá, ìyẹn sì múnú rẹ̀ dùn. Jésù náà ṣiṣẹ́ kára nígbà tó wà láyé, síbẹ̀ ó wáyè láti sinmi, òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì jọ gbádùn ara wọn. (Mát. 14:13; Lúùkù 7:34) Bíbélì rọ àwa èèyàn Jèhófà pé ká fọwọ́ gidi mú iṣẹ́. Òṣìṣẹ́ kára làwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́, a ò gbọ́dọ̀ ya ọ̀lẹ. (Òwe 15:19) Ó ṣeé ṣe kó o jẹ́ onídìílé, tó o sì ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó ìdílé rẹ. Bákan náà, torí pé o jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, o mọ̀ pé o tún ní ojúṣe láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bó ti wù kó rí, ó ṣe pàtàkì pé kó o máa wáyè sinmi dáadáa. w19.12 2 ¶2; 3 ¶4-5

Thursday, September 2

Kristi . . . jìyà torí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.​—1 Pét. 2:21.

Má ṣe máa ròyìn ohun táwọn ẹ̀mí èṣù ń ṣe. Àpẹẹrẹ Jésù ló yẹ ká tẹ̀ lé nínú ọ̀rọ̀ yìí. Kí Jésù tó wá sáyé, kò sóhun tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń ṣe tí kò mọ̀. Àmọ́ kì í ṣe ìròyìn nípa wọn ló ń sọ fáwọn èèyàn. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Jésù, kì í ṣe agbẹnusọ fún Sátánì. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fara wé Jésù, ká má ṣe máa ròyìn ohun táwọn ẹ̀mí èṣù ń ṣe. Ṣe ló yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa fi hàn pé ‘ohun rere ló ń gbé wa lọ́kàn,’ ìyẹn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 45:1) Má ṣe bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Nínú ayé burúkú yìí, kò sí kí nǹkan burúkú má ṣẹlẹ̀. Ìjàǹbá, àìsàn àti ikú lè ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, àmọ́ kò yẹ ká máa ronú pé àwọn ẹ̀mí èṣù ló fà á. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé “ìgbà àti èèṣì” lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. (Oníw. 9:11) Bákan náà, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà lágbára ju àwọn ẹ̀mí èṣù lọ fíìfíì. w19.04 23-24 ¶13-14

Friday, September 3

Àwọn aláṣẹ tó wà ni a gbé sí àwọn ipò wọn tó ní ààlà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.​—Róòmù 13:1.

Ṣé àwọn alàgbà máa ń tẹ̀ lé òfin ìjọba tó ní kí wọ́n fi ẹ̀sùn bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe tó ìjọba létí? Bẹ́ẹ̀ ni. Láwọn ilẹ̀ tírú òfin bẹ́ẹ̀ bá wà, àwọn alàgbà máa ń pa òfin ìjọba mọ́, wọ́n á sì rí i pé ọ̀rọ̀ náà dé etí ìjọba. Irú òfin ìjọba bẹ́ẹ̀ kò ta ko òfin Ọlọ́run rárá. (Ìṣe 5:​28, 29) Torí náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ táwọn alàgbà bá gbọ́ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ẹnì kan pé ó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, wọ́n á pe ẹ̀ka ọ́fíìsì láìjáfara kí wọ́n lè mọ ohun tí wọ́n á ṣe kọ́rọ̀ náà lè dé etí ìjọba. Àwọn alàgbà máa sọ fún òbí àti ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe, títí kan àwọn tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà pé wọ́n lè fọ̀rọ̀ ẹni tó bá ọmọ náà ṣèṣekúṣe tó ìjọba létí. Lẹ́yìn tí wọ́n bá fẹjọ́ sùn lọ́dọ̀ ìjọba, ọ̀rọ̀ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í jà ràn-ìn nílùú. Ká sọ pé ará ìjọ lẹni tó hùwà burúkú yìí, ṣó yẹ kí Kristẹni tó lọ fẹjọ́ sùn lọ́dọ̀ ìjọba ronú pé òun ti kẹ́gàn bá orúkọ Jèhófà? Rárá ni ìdáhùn. Ìdí sì ni pé ẹni tó hùwà burúkú yìí ló kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, kì í ṣe ẹni tó fọ̀rọ̀ náà tó ìjọba létí. w19.05 10 ¶13-14

Saturday, September 4

Ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.​—1 Kọ́r. 3:19.

Bíbélì sọ pé káwọn tọkọtaya máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, kí wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn. Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, kí wọ́n má sì jẹ́ kí ohunkóhun yà wọ́n. Ó sọ pé: ‘Ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, wọ́n á sì di ara kan.’ (Jẹ́n. 2:24) Àmọ́ ojú táwọn èèyàn ayé fi ń wo ìgbéyàwó yàtọ̀ síyẹn. Wọ́n gbà pé ohun tó bá wu kálukú ni kó ṣe láìfi ti ẹnì kejì pè. Bí àpẹẹrẹ, ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀ sọ pé: “Níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, àwọn tọkọtaya sábà máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á wà pa pọ̀ ‘níwọ̀n ìgbà táwọn bá fi jọ wà láàyè.’ Àmọ́ àwọn kan ti sọ ẹ̀jẹ́ náà di nǹkan míì, wọ́n máa ń sọ pé àwọn á wà pa pọ̀ ‘níwọ̀n ìgbà táwọn bá fi jọ nífẹ̀ẹ́ ara àwọn.’ ” Irú èrò yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ ìdílé tú ká, ó sì ti fa ọgbẹ́ ọkàn tí kì í jinná bọ̀rọ̀ fáwọn míì. Kò sí àní-àní pé, ohun tí ọgbọ́n ayé fi ń kọ́ni nípa ìgbéyàwó kò bọ́gbọ́n mu rárá àti rárá. w19.05 23 ¶12

Sunday, September 5

Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín.​—Róòmù 12:2.

Pọ́ọ̀lù kíyè sí i pé àwọn Kristẹni kan ti fàyè gba èròkerò àti ọgbọ́n orí èèyàn tó kúnnú ayé Sátánì, ìdí nìyẹn tó fi kọ̀wé sí wọn. (Éfé. 4:​17-19) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni yẹn lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Sátánì tó jẹ́ ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ń wá bó ṣe máa mú ká kẹ̀yìn sí Jèhófà, onírúurú ọgbọ́n ló sì ń dá. Bí àpẹẹrẹ, tó bá kíyè sí pé a lẹ́mìí ìgbéraga tàbí pé a fẹ́ di gbajúmọ̀, ó lè lò ó láti dẹkùn mú wa. Ó sì tún lè lo àṣà ìbílẹ̀ wa, bá a ṣe kàwé tó àti ibi tá a gbé dàgbà láti mú ká máa ronú bíi tiẹ̀. Ṣé ó ṣeé ṣe láti fa àwọn nǹkan tó ti “fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” tu lọ́kàn wa? (2 Kọ́r. 10:4) Ẹ kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, ó ní: “À ń borí àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga tí kò bá ìmọ̀ Ọlọ́run mu, a sì ń mú gbogbo ìrònú lẹ́rú kí ó lè ṣègbọràn sí Kristi.” (2 Kọ́r. 10:5) Ó ṣe kedere nígbà náà pé lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, a lè borí èrò tí kò tọ́ ká sì yí ìwà wa pa dà. w19.06 8 ¶1-3

Monday, September 6

Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi. Mo ti fi Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ṣe ibi ààbò mi.​—Sm. 73:28.

Lóòótọ́ ìṣòro dé bá Hánà, Dáfídì àti onísáàmù kan, àmọ́ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta gbára lé Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n gbàdúrà sí i taratara nípa ìṣòro tí wọ́n ní. Wọ́n tú ọkàn wọn jáde sí Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ kó mọ bí ìṣòro náà ṣe rí lára wọn. Láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n ní sí, wọn ò yé lọ sílé Jèhófà láti jọ́sìn. (1 Sám. 1:​9, 10; Sm. 55:22; 73:17; 122:1) Jèhófà fi hàn pé òun mọ bí nǹkan ṣe rí lára ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó sì gbọ́ àdúrà wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà mú kí ọkàn Hánà balẹ̀. (1 Sám. 1:18) Dáfídì ní tiẹ̀ sọ pé: “Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.” (Sm. 34:19) Onísáàmù yẹn sì sọ pé Jèhófà ti “di ọwọ́ ọ̀tún [òun] mú,” ó sì ń fìfẹ́ tọ́ òun sọ́nà. (Sm. 73:​23, 24) Kí la rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ yìí? Nígbà míì, àwọn ìṣòro lè pin wá lẹ́mìí, kí wọ́n sì kó ìdààmú ọkàn bá wa. Àmọ́, a lè fara dà á tá a bá ń ṣàṣàrò nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́, tá à ń gbàdúrà sí i láìjẹ́ kó sú wa, tá a sì ń pa àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ mọ́.​—Sm. 143:​1, 4-8. w19.06 17 ¶14-15

Tuesday, September 7

Tí ẹ bá tiẹ̀ jìyà nítorí òdodo, inú yín máa dùn.​—1 Pét. 3:14.

Má ṣe jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn ń sọ tàbí tí wọ́n ń ṣe mú kójú tì ẹ́ láti sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. (Míkà 4:5) Ronú nípa ohun táwọn àpọ́sítélì ṣe ní Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn táwọn alátakò pa Jésù. Wọ́n mọ̀ pé àwọn aṣáájú ìsìn Júù kórìíra àwọn. (Ìṣe 5:​17, 18, 27, 28) Láìfi ìyẹn pè, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń lọ sí tẹ́ńpìlì àtàwọn ibi térò pọ̀ sí, wọ́n ń wàásù, wọ́n sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn Jésù làwọn. (Ìṣe 5:42) Wọn ò jẹ́ kẹ́rù bà wọ́n débi tí wọ́n á fi dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró. Àwa náà lè borí ìbẹ̀rù èèyàn tá a bá ń wàásù, tá a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, yálà ní ibiṣẹ́, níléèwé tàbí ládùúgbò wa. (Ìṣe 4:29; Róòmù 1:16) Kí nìdí tí inú àwọn àpọ́sítélì fi ń dùn? Inú wọn ń dùn torí wọ́n mọ ìdí táwọn èèyàn fi kórìíra wọn, wọ́n sì ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù. (Lúùkù 6:23; Ìṣe 5:41; 1 Pét. 2:​19-21) Tá a bá ń fi sọ́kàn pé torí à ń ṣe ohun tó tọ́ làwọn èèyàn fi kórìíra wa, a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ láé. w19.07 7 ¶19-20

Wednesday, September 8

Ó bófin mu láti ṣe ohun tó dáa ní Sábáàtì.​—Mát. 12:12.

Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pa Sábáàtì mọ́ torí pé Júù ni wọ́n, wọ́n sì wà lábẹ́ Òfin Mósè. Àwọn ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe fi hàn pé òfin yẹn ò ní kéèyàn má fojú àánú hàn, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé kí wọ́n má ran àwọn míì lọ́wọ́. (Mát. 12:​9-11) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé èèyàn ò rú òfin Sábáàtì téèyàn bá ṣe rere fáwọn míì tàbí tó ran àwọn míì lọ́wọ́. Àwọn nǹkan tí Jésù ṣe fi hàn pé ó lóye ìdí tí Jèhófà fi ṣòfin Sábáàtì. Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì, ó ṣeé ṣe fún wọn láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Nínú ìdílé tí Jésù dàgbà sí, ó dájú pé nǹkan tẹ̀mí ni wọ́n máa ń ṣe lọ́jọ́ Sábáàtì. Èyí ṣe kedere nínú àkọsílẹ̀ nípa Jésù nígbà tó wà ní Násárẹ́tì tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “[Jésù] wọnú sínágọ́gù, ó sì dìde dúró láti kàwé, bó ṣe máa ń ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì.” (Lúùkù 4:​15-19) Bákan náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò fi Sábáàtì ṣeré rárá, kódà wọ́n dúró kí Sábáàtì parí kí wọ́n tó parí èròjà tí wọ́n fẹ́ fi bójú tó òkú Jésù tó wà nínú ibojì.​—Lúùkù 23:​55, 56. w19.12 4 ¶10

Thursday, September 9

Ẹ ò nírètí.​—Éfé. 2:12.

Gbogbo àwa Kristẹni pátá ló ń lọ́wọ́ nínú wíwá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. A lè fi iṣẹ́ ìwàásù wé àwọn tó ń wá ọmọ kan tó sọ nù. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń wá ọmọ ọdún mẹ́ta kan tó sọ nù. Àwọn èèyàn bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ló wá ọmọ náà kiri. Lẹ́yìn ogún (20) wákàtí tí ọmọ náà ti sọ nù, ọ̀kan lára àwọn tó ń wá a rí i nínú oko àgbàdo kan. Ọkùnrin yẹn ò jẹ́ kí wọ́n kan sárá sí òun pé òun lòun wá ọmọ náà rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Ẹnì kan kì í jẹ́ àwa dé, gbogbo wa pátá la jẹ́ kó ṣeé ṣe.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló dà bí ọmọ yẹn torí pé wọn ò mọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọn ò nírètí, torí náà wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá à ń wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ju mílíọ̀nù mẹ́jọ lọ. Nínú ìjọ tó o wà, o lè má ní ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn kan nínú ìjọ rẹ lè ní àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú ìjọ rẹ bá kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ tó sì ṣèrìbọmi, ó yẹ kí inú gbogbo wa dùn torí àjọṣe gbogbo wa ni. w19.07 16-17 ¶9-10

Friday, September 10

Mò ń sapá kí ọwọ́ mi lè tẹ èrè.​—Fílí. 3:14.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn ará Fílípì létí pé wọ́n gbọ́dọ̀ fara dà á dópin. Ìdí ni pé nǹkan ò rọrùn rárá fáwọn ará ìjọ yẹn látìgbà tí wọ́n ti dá ìjọ náà sílẹ̀. Báwo ni ìjọ náà ṣe bẹ̀rẹ̀? Nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sí Fílípì lẹ́yìn tí ẹ̀mí mímọ́ ní kí wọ́n “sọdá wá sí Makedóníà.” (Ìṣe 16:9) Níbẹ̀, wọ́n pàdé obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà. Obìnrin yìí ń “fetí sílẹ̀, Jèhófà sì ṣí ọkàn rẹ̀ sílẹ̀” láti gbọ́ ìhìn rere. (Ìṣe 16:14) Kò pẹ́ lẹ́yìn náà lòun àtàwọn ará ilé rẹ̀ ṣèrìbọmi. Àmọ́ Èṣù tún gbé ìṣe ẹ̀ dé, ṣe làwọn ọkùnrin ìlú yẹn wọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sọ́dọ̀ àwọn adájọ́, wọ́n sì parọ́ mọ́ wọn pé wọ́n ń da ìlú rú. Torí náà, wọ́n na Pọ́ọ̀lù àti Sílà, wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì ní kí wọ́n fi ìlú àwọn sílẹ̀. (Ìṣe 16:​16-40) Ṣé wọ́n wá tìtorí ìyẹn sọ pé àwọn ò ní wàásù mọ́? Ká má rí i! Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà níjọ tuntun yìí ńkọ́, kí làwọn ṣe? Inú wa dùn pé wọ́n fara dà á! Kò sí àní-àní pé àpẹẹrẹ àtàtà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi lélẹ̀ ló mú káwọn náà lè fara dà á. w19.08 2 ¶1-2

Saturday, September 11

Kí èso òdodo . . . kún inú yín.​—Fílí. 1:11.

Ó dájú pé ọ̀kan lára “èso òdodo” ni ìfẹ́ fún Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Ohun míì tún ni pé ká máa wàásù fáwọn míì nípa Jésù àti ìrètí ológo tá a ní. Torí náà, à ń so “èso òdodo” tá a bá ń lo ara wa tokuntokun lẹ́nu iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù yìí, ìyẹn iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:​18-20) Ipò yòówù ká wà, a ṣì lè tàn bí ìmọ́lẹ̀. Láwọn ipò kan, ohun tó dà bí ìdíwọ́ tẹ́lẹ̀ lè wá ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti wàásù. Àpẹẹrẹ kan ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àtìmọ́lé ló wà nílùú Róòmù nígbà tó kọ̀wé sáwọn ará Fílípì. Síbẹ̀, ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é kò ní kó má wàásù fáwọn ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ ọ àtàwọn tó wá kí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù wà ní àtìmọ́lé, ó fìtara wàásù, ìyẹn sì mú káwọn ará túbọ̀ nígboyà láti máa sọ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.”​—Fílí. 1:​12-14; 4:22. w19.08 12 ¶15-16

Sunday, September 12

Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kó lè gbé yín ga ní àkókò tó yẹ.​—1 Pét. 5:6.

Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ni pé ó máa ń múnú Jèhófà dùn. Ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ sì jẹ́ kí èyí ṣe kedere nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Nígbà tí ìwé “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn” orí kẹta, ìpínrọ̀ kẹtàlélógún (23) ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Pétérù, ó sọ pé: “Bíi májèlé ni ìgbéraga rí. Ohun tó máa ń yọrí sí kì í dáa. Ànímọ́ kan tó lè mú kí ẹ̀bùn yòówù tẹ́nì kan ní dìdàkudà mọ́ ọn lára níwájú Ọlọ́run ni. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìrẹ̀lẹ̀ lè mú kí ẹni tí ò tiẹ̀ já mọ́ nǹkan kan di ẹni tó máa wúlò fún Jèhófà. . . . Inú Ọlọ́run wa á dùn láti san ọ́ lẹ́san rere bó o bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.” Kò sí àní-àní pé ohun tó dáa jù tá a lè ṣe ni pé ká múnú Jèhófà dùn. (Òwe 23:15) Yàtọ̀ sí pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń múnú Jèhófà dùn, ó tún máa ń ṣe wá láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ káwọn míì sún mọ́ wa. Kí ohun tá a sọ yìí lè túbọ̀ ṣe kedere, wò ó báyìí ná: Irú èèyàn wo ni wàá fẹ́ mú lọ́rẹ̀ẹ́? Ṣé agbéraga ni àbí onírẹ̀lẹ̀?​—Mát. 7:12. w19.09 4 ¶8-9

Monday, September 13

Jèhófà kórìíra gbogbo ẹni tó ń gbéra ga.​—Òwe 16:5.

Àwọn alàgbà máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn. Wọn kì í gbéra ga, kàkà bẹ́ẹ̀, ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni wọ́n fi ń mú ìjọ. (1 Tẹs. 2:​7, 8) Torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, wọ́n sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n máa ń kíyè sí bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Andrew tó jẹ́ alàgbà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Àwọn ará sábà máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà tó jẹ́ onínúure tó sì kóni mọ́ra. Ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn ará láti tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n bá fún wọn.” Arákùnrin Tony tóun náà ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí sọ pé: “Mo máa ń sapá láti fi ohun tó wà nínú Fílípì 2:3 sílò, torí náà mo máa ń rán ara mi létí pé àwọn míì sàn jù mí lọ. Ìyẹn ni kì í jẹ́ kí n máa ṣe bí ọ̀gá lé àwọn ará lórí.” Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bí Jèhófà náà ṣe lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, ó máa ń rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kó lè “gbé aláìní dìde látinú eruku.” (Sm. 18:35; 113:​6, 7) Àní sẹ́, Jèhófà kórìíra àwọn agbéraga àtàwọn tó jọ ara wọn lójú. w19.09 16-17 ¶11-12

Tuesday, September 14

Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín.​—Mát. 11:29.

Láti lè rí ìtura lábẹ́ àjàgà Jésù, a gbọ́dọ̀ máa fojú tó tọ́ wo nǹkan. Ká rántí pé iṣẹ́ Jèhófà là ń ṣe, a sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ náà bí Jèhófà ṣe fẹ́. Òṣìṣẹ́ ni wá, Jèhófà sì ni Ọ̀gá wa. (Lúùkù 17:10) Tá a bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe wù wá, àjàgà náà á nira fún wa. Lọ́wọ́ kejì, tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, àá borí ìṣòro èyíkéyìí tó lè yọjú, àá sì gbé nǹkan ribiribi ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Ohun kan tó dájú ni pé, kò sẹ́ni tó lè dí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́! (Róòmù 8:31; 1 Jòh. 4:4) Ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa fògo fún Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn tó jẹ́ pé ojúkòkòrò àti ìmọtara-ẹni-nìkan ló mú kí wọ́n máa tẹ̀ lé Jésù dẹni tí kò láyọ̀ mọ́, ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, ṣe ni wọ́n pa Jésù tì. (Jòh. 6:​25-27, 51, 60, 66; Fílí. 3:​18, 19) Lọ́wọ́ kejì, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wọn ò pa Jésù tì, wọ́n fayọ̀ sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì nírètí pé àwọn máa bá Jésù Kristi jọba ní ọ̀run. Bíi tiwọn, tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti ọmọnìkejì wa ló mú ká fi ara wa sábẹ́ àjàgà Jésù, àá máa láyọ̀. w19.09 20 ¶1; 24-25 ¶19-20

Wednesday, September 15

Ẹ ó mọ òtítọ́, òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.​—Jòh. 8:32.

Ronú nípa òmìnira tó o ní torí pé o ò gba ẹ̀kọ́ èké gbọ́, o ò sì lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Ẹ wo bí inú wa ṣe ń dùn pé a ní irú òmìnira bẹ́ẹ̀! O ṣì máa gbádùn òmìnira tó ju èyí tó ò ń gbádùn báyìí lọ. Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, Jésù máa pa gbogbo ìsìn èké àtàwọn alákòóso burúkú run. Bákan náà, Ọlọ́run máa dáàbò bo “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín, á sì rọ̀jò ìbùkún lé wọn lórí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 7:​9, 14) Ọlọ́run máa jí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn dìde, wọ́n á sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (Ìṣe 24:15) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣàkóso máa mú kí aráyé ní ìlera pípé, kí wọ́n sì ní àjọṣe tó túbọ̀ dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Àsìkò yẹn máa dà bí ọdún Júbílì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe. Gbogbo èèyàn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn á ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n á sì ti di pípé. w19.12 12-13 ¶14-16

Thursday, September 16

Bánábà ràn án lọ́wọ́.​—Ìṣe 9:27.

Ọkùnrin ọ̀làwọ́ kan wà nínú ìjọ Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni. Jósẹ́fù lorúkọ ọkùnrin yìí (wọ́n tún ń pè é ní Bánábà), ó sì yọ̀ǹda pé kí Jèhófà lo òun. (Ìṣe 4:​36, 37) Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di onígbàgbọ́, kò rọrùn fáwọn ará láti sún mọ́ ọn torí pé ó ti máa ń ṣenúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run. Àmọ́ torí pé ara Bánábà yá mọ́ọ̀yàn, ó sún mọ́ Sọ́ọ̀lù, ó sì ràn án lọ́wọ́. (Ìṣe 9:​21, 26-28) Nígbà tó yá, àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù rí i pé ó yẹ káwọn fún àwọn ará tó wà ní iyànníyàn Áńtíókù ti Síríà níṣìírí. Ǹjẹ́ ẹ mọ ẹni tí wọ́n rán lọ síbẹ̀? Bánábà ni! Ẹni tó sì yẹ kí wọ́n rán nìyẹn. Nígbà tó dé ọ̀hún, ó “bẹ̀rẹ̀ sí í fún gbogbo wọn ní ìṣírí láti máa fi gbogbo ọkàn wọn ṣègbọràn sí Olúwa.” (Ìṣe 11:​22-24) Bákan náà lónìí, Jèhófà lè sọ wá di “ọmọ ìtùnú” fáwọn ará wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú ká tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú. Ó lè mú ká ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣàìsàn tàbí tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì ká sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, ó sì lè jẹ́ orí fóònù làá ti tù wọ́n nínú. Ṣé wàá jẹ́ kí Jèhófà lò ẹ́ bó ṣe lo Bánábà?​—1 Tẹs. 5:14. w19.10 22 ¶8

Friday, September 17

Ẹni tó bá ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini ń wá ìfẹ́, àmọ́ ẹni tó bá ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ṣáá ń tú ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká.​—Òwe 17:9.

Tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa, kì í ṣe ibi tí wọ́n dáa sí nìkan la máa ń rí, a tún máa ń rí ibi tí wọ́n kù díẹ̀ káàtó sí. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tírú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀? Ká sòótọ́, a ò lè retí pé káwọn ará wa má ṣàṣìṣe. Torí náà, tá a bá ní ọ̀rẹ́ kan, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe kí àárín wa má bàa dà rú. Tí ọ̀rẹ́ wa bá ṣàṣìṣe, ó yẹ ká fún un ní ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́ láì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, síbẹ̀ ká ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. (Sm. 141:5) Tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn wá, á dáa ká dárí jì wọ́n. Tá a bá sì ti dárí jì wọ́n, ká gbàgbé ẹ̀, ká má sì mẹ́nu kàn án mọ́. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ibi táwọn ará wa dáa sí ló yẹ ká gbájú mọ́, dípò ibi tí wọ́n kù sí torí pé àkókò tí nǹkan nira gan-an là ń gbé yìí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, okùn ọ̀rẹ́ wa á túbọ̀ lágbára, ká má sì gbàgbé pé a máa nílò àwọn ọ̀rẹ́ pàtàkì yẹn nígbà ìpọ́njú ńlá. w19.11 6 ¶13, 16

Saturday, September 18

Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.​—Mát. 28:​19, 20.

Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ ká sa gbogbo ipá wa ká lè ‘sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn, ká sì máa kọ́ wọn pé kí wọ́n pa gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ fún wa mọ́.’ A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n fara wọn sábẹ́ Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. Ìyẹn máa gba pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sọ òtítọ́ di tiwọn. Lédè míì, kí wọ́n máa fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò, kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Ìyẹn nìkan ló máa jẹ́ kí wọ́n la ọjọ́ Jèhófà já. (1 Pét. 3:21) Ohun tó kù kí ayé búburú yìí dópin kò sì tó nǹkan mọ́. Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ ká fi àkókò ṣòfò, ká wá máa pààrà ọ̀dọ̀ àwọn tí kò ṣe tán láti di ọmọlẹ́yìn Kristi. (1 Kọ́r. 9:26) Iṣẹ́ wa ti di kánjúkánjú báyìí! Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì wà tó yẹ ká wàásù fún, torí náà ẹ jẹ́ ká wá irú wọn lọ kó tó pẹ́ jù. w19.10 11-12 ¶14-15

Sunday, September 19

Kó . . . fi tùràrí sínú iná níwájú Jèhófà.​—Léf. 16:13.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kóra jọ lọ́dọọdún ní Ọjọ́ Ètùtù, wọ́n sì máa ń fi ẹran rúbọ. Àwọn ẹbọ yẹn máa ń rán wọn létí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n àti pé wọ́n nílò ìdáríjì. Àmọ́, àlùfáà àgbà ní ohun pàtàkì kan tó máa ṣe, ó máa rọra da tùràrí mímọ́ náà sínú ẹyin iná, gbogbo iyàrá náà sì máa kún fún òórùn dídùn. Kí la sì lè rí kọ́ nínú ìyẹn? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fi àdúrà wọn wé tùràrí. (Sm. 141:2; Ìfi. 5:8) Nígbà tí àlùfáà àgbà bá fẹ́ lọ sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ láti sun tùràrí, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá fẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ẹni ńlá ni Jèhófà, ó sì yẹ ká bọ̀wọ̀ fún un gan-an. A mọyì pé Ẹlẹ́dàá wa gbà káwa èèyàn lásán-làsàn sún mọ́ òun, ká sì bá òun sọ̀rọ̀ bí ọmọ ṣe máa ń bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀. (Jém. 4:8) Kódà, ó gbà pé ọ̀rẹ́ òun ni wá! (Sm. 25:14) A mọyì àǹfààní ńlá tí Jèhófà fún wa yìí, torí náà a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa bà á nínú jẹ́. w19.11 20-21 ¶3-5

Monday, September 20

Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn lo fi ọgbọ́n ṣe. Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe.​—Sm. 104:24.

Ọwọ́ wo lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń mú iṣẹ́ lágbègbè tó o wà? Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣe làwọn èèyàn ń ṣiṣẹ́ kára tí wọ́n sì ń lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí iṣẹ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àwọn tó máa ń ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó kì í fi bẹ́ẹ̀ sinmi, wọn kì í ráyè gbọ́ ti ìdílé wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run. (Oníw. 2:23) Ní tàwọn míì, wọn ò fẹ́ṣẹ́ ṣe rárá, téèyàn bá sì bi wọ́n, àwáwí ni wọ́n á máa ṣe. (Òwe 26:​13, 14) Tá a bá fi ojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo iṣẹ́ wò ó, àá rí i pé ó yàtọ̀ pátápátá sí ojú tí aráyé fi ń wò ó. Kò sí àní-àní pé Jèhófà kì í fiṣẹ́ ṣeré. Jésù mú kí kókó yìí ṣe kedere nígbà tó sọ pé: “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di báyìí, èmi náà ṣì ń ṣiṣẹ́.” (Jòh. 5:17) Ẹ gbọ́ ná, mélòó la fẹ́ kà nínú àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣẹ̀dá? Ṣé ti àìmọye àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run ni ká sọ ni àbí ti àgbáálá ayé yìí tó lọ salalu? w19.12 2 ¶1-2

Tuesday, September 21

Mo ti rí Dáfídì . . . ẹni tí ọkàn mi fẹ́.​—Ìṣe 13:22.

Kí ni Dáfídì ṣe tí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Dáfídì túbọ̀ mọ Jèhófà bó ṣe ń wo ohun tí Jèhófà dá. Nígbà tí Dáfídì wà lọ́mọdé, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń wà níta bó ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àsìkò yẹn ló fi máa ń ṣàṣàrò nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Bí àpẹẹrẹ, bí Dáfídì ṣe ń wòkè lálẹ́, ó dájú pé ó máa rí i tí ojú ọ̀run tẹ́ rẹrẹ tó sì kún fún àìmọye ìràwọ̀. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́, àwọn ohun tó rí máa jẹ́ kó túbọ̀ mọ Ẹlẹ́dàá àtàwọn ànímọ́ rẹ̀. (Sm. 19:​1, 2) Nígbà tí Dáfídì ronú nípa ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà gbà dá àwa èèyàn, ó rí i pé ọgbọ́n Jèhófà kò láfiwé. (Sm. 139:14) Ní gbogbo ìgbà tí Dáfídì bá ń ronú àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà dá, ó máa ń rí i pé òun ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Sm. 139:6) Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Dáfídì? Bó o ṣe ń sùn tó ò ń jí lójoojúmọ́, máa ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá, ìyẹn àwọn ewéko àtàwọn ẹranko títí kan ọ̀nà àrà tó gbà dá àwa èèyàn. Ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n jẹ́ kó o mọ̀ nípa Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́, ṣe ni wàá túbọ̀ máa mọ Baba rẹ ọ̀run. (Róòmù 1:20) Nípa bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tó o ní fún un á máa jinlẹ̀ sí i lójoojúmọ́. w19.12 19-20 ¶15-17

Wednesday, September 22

Ìgbàgbọ́ mú kí Mósè kọ̀ kí wọ́n máa pe òun ní ọmọ ọmọbìnrin Fáráò nígbà tó dàgbà.​—Héb. 11:24.

Mósè pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn. Nígbà tí Mósè wà lẹ́ni ogójì (40) ọdún, ó yàn láti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ìyẹn àwọn Hébérù dípò táwọn èèyàn á fi mọ̀ ọ́n sí “ọmọ ọmọbìnrin Fáráò.” Ipò pàtàkì ni Mósè wà tẹ́lẹ̀ nílẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ ó pa ìyẹn tì, ó sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹrú. Ó mọ̀ pé ohun tóun ṣe yẹn máa bí Ọba Fáráò nínú, bẹ́ẹ̀ sì rèé òrìṣà àkúnlẹ̀bọ làwọn ará Íjíbítì ka Fáráò sí. Ẹ ò rí i pé ìgbàgbọ́ tó lágbára ni Mósè ní! Kò sí àní-àní pé Mósè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ìyẹn ló sì mú kó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Òwe 3:5) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Mósè? Bíi ti Mósè, ohun pàtàkì kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣèpinnu lé lórí, ohun náà ni pé: Ṣé Jèhófà la máa sìn, ṣé a sì máa dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀? Ká tó lè sin Jèhófà, ó lè gba pé ká yááfì àwọn nǹkan kan, ó sì ṣeé ṣe káwọn tí ò mọ Jèhófà kórìíra wa. Àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Baba wa ọ̀run, kò ní fi wá sílẹ̀ láé! w19.12 17 ¶5-6

Thursday, September 23

Jèhófà Ọlọ́run fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ọkùnrin, ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀.​—Jẹ́n. 2:7.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé erùpẹ̀ ni Jèhófà fi dá àwa èèyàn, kò fojú eruku lásán-làsàn wò wá. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mélòó kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé a ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Ó dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, lédè míì lọ́nà tá a fi lè gbé àwọn ànímọ́ rẹ̀ yọ. (Jẹ́n. 1:27) Lọ́nà yìí, ó mú ká yàtọ̀ pátápátá sáwọn nǹkan míì tó dá, ó sì fi wá jọba lórí àwọn ẹranko, ẹyẹ, ẹja àtàwọn nǹkan míì tó dá sáyé. (Sm. 8:​4-8) Kódà lẹ́yìn tí Ádámù ṣàìgbọràn, Jèhófà ṣì fi hàn pé òun ò fọ̀rọ̀ wa ṣeré. Ó fi hàn pé òun mọyì wa, òun sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an nígbà tó yọ̀ǹda Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n pé kó kú torí ẹ̀ṣẹ̀ wa. (1 Jòh. 4:​9, 10) Ìràpadà tí Jésù san yìí ni Jèhófà máa wò mọ́ aráyé lára táá sì mú kó jí àwọn tó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù dìde, ìyẹn “àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo.” (Ìṣe 24:15) Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi dá wa lójú pé Jèhófà mọ àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra, bí àìlera, àìrówóná àti hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó. Síbẹ̀, ó mọyì wa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.​—Ìṣe 10:​34, 35. w20.01 15 ¶5-6

Friday, September 24

Má yọjú sí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀.​—1 Tẹs. 4:11.

Ìrètí táwọn ẹni àmì òróró ní kì í ṣe ogún ìdílé. Ọlọ́run ló ń fún èèyàn ní ẹ̀mí mímọ́. (1 Tẹs. 2:12) Torí náà, kò yẹ ká máa béèrè àwọn ìbéèrè tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ ká máa béèrè lọ́wọ́ ìyàwó ẹni àmì òróró kan pé báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ̀ tó bá ń rántí pé òun máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé tí ọkọ rẹ̀ sì máa wà lọ́run. Ó ṣe tán, ó dá wa lójú pé nínú ayé tuntun, Jèhófà máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.” (Sm. 145:16) A máa dáàbò bo ara wa tá a bá ń fojú tó tọ́ wo àwọn ẹni àmì òróró, tí a kì í wò wọ́n bí ẹni pé wọ́n ṣe pàtàkì ju àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó kù lọ. Lọ́nà wo? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹni àmì òróró kan lè di aláìṣòótọ́. (Mát. 25:​10-12; 2 Pét. 2:​20, 21) Àmọ́, tí a kì í bá “kan sáárá” sáwọn èèyàn, a ò ní sọ ẹnikẹ́ni di ọlọ́run wa, yálà ẹni àmì òróró ni tàbí ẹnì kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa tàbí ẹni tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́tipẹ́ pàápàá. (Júùdù 16, àlàyé ìsàlẹ̀) Tírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá wá lọ di aláìṣòótọ́ tàbí tí wọ́n fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà ò ní wọmi, a ò sì ní pa ìjọsìn Jèhófà tì. w20.01 29 ¶9-10

Saturday, September 25

Ẹ máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ.​—Éfé. 5:1.

Torí pé “àyànfẹ́ ọmọ” Jèhófà ni wá, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fara wé e. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, tá à ń ṣenúure sí wọn tá a sì ń dárí jì wọ́n. Táwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá rí ìwà rere tá à ń hù, ó lè mú kí wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (1 Pét. 2:12) Ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni fara wé Jèhófà nínú ọwọ́ tí wọ́n fi ń mú àwọn ọmọ wọn. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ náà á fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Ojú kì í tì wá láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà a sì máa ń jẹ́ káwọn míì mọ̀ ọ́n. Ó máa ń ṣe wá bíi ti Ọba Dáfídì tó sọ pé: “Èmi yóò máa fi Jèhófà yangàn.” (Sm. 34:2) Àmọ́ tá a bá jẹ́ onítìjú ńkọ́? Báwo la ṣe lè borí ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi sọ́kàn pé bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn míì ń múnú rẹ̀ dùn ó sì ń ṣe àwọn tá à ń wàásù fún láǹfààní. Jèhófà máa fún wa nígboyà tá a nílò. Ó máa fún wa nígboyà bó ṣe fún àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.​—1 Tẹs. 2:2. w20.02 11 ¶12-13

Sunday, September 26

Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . .  di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.​—Mát. 28:19.

Ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló ń tẹ̀ síwájú tí wọ́n sì ń ṣèrìbọmi. Àmọ́, àwọn kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ déédéé ò ṣe tán láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Wọ́n ń gbádùn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ wọn, àmọ́ wọn ò tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n á ṣèrìbọmi. Tó o bá lẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó dájú pé wàá fẹ́ kó máa fi ohun tó ń kọ́ sílò, wàá sì fẹ́ kó di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn jọ́sìn òun torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun. Torí náà, a máa fẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lóye pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún. A fẹ́ kí wọ́n mọ Jèhófà ní “bàbá àwọn ọmọ aláìníbaba àti ẹni tó ń dáàbò bo àwọn opó.” (Sm. 68:5) Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ṣe túbọ̀ ń mọyì ìfẹ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni òtítọ́ á máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Torí náà, jẹ́ kí wọ́n lóye pé Baba wa ọ̀run fẹ́ kí wọ́n jogún ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ọwọ́ wọn lè tẹ èrè náà. w20.01 3 ¶7-8

Monday, September 27

Nígbà tí mo gbọ́ nípa ìfẹ́ rẹ, inú mi dùn gan-an.​—Fílém. 7.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ìyẹn mú kó gbà pé òun nílò ìtùnú, ó sì mọyì ẹ̀ nígbà tí wọ́n tù ú nínú. Kò yọ ara ẹ̀ lẹ́nu pé àwọn kan lè máa fojú tẹ́ńbẹ́lú òun torí pé àwọn míì ran òun lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. (Kól. 4:​7-11) Táwa náà bá jẹ́ káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa mọ̀ pé a nílò ìṣírí, inú wọn á dùn láti gbé wa ró, wọ́n á sì tì wá lẹ́yìn. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé òun lè rí ìtùnú nínú Ìwé Mímọ́. (Róòmù 15:4) Ó sì tún mọ̀ pé á fún òun ní ọgbọ́n tóun lè fi rán ìṣòro yòówù kó dé bá òun. (2 Tím. 3:​15, 16) Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì nílùú Róòmù, ó mọ̀ pé wọ́n máa tó pa òun. Ó ní kí Tímótì tètè wá sọ́dọ̀ òun kó sì bá òun mú “àwọn àkájọ ìwé” bọ̀. (2 Tím. 4:​6, 7, 9, 13) Kí nìdí? Ìdí ni pé Pọ́ọ̀lù fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àkájọ ìwé náà torí pé wọ́n jẹ́ apá kan lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Táwa náà bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé bíi ti Pọ́ọ̀lù, Jèhófà máa fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù wá nínú, láìka ìṣòro yòówù kó máa bá wa fínra. w20.02 23-24 ¶14-15

Tuesday, September 28

Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.​—Mát. 7:1.

Ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu Élífásì, Bílídádì àti Sófárì fi hàn pé kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa ran Jóòbù lọ́wọ́ ni wọ́n ń rò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó gbà wọ́n lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa fi hàn pé èèyàn burúkú ni Jóòbù. Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí wọ́n sọ tó jóòótọ́, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú ohun tí wọ́n sọ nípa Jóòbù àti Jèhófà ló jẹ́ kìkìdá irọ́, kò sì fìfẹ́ hàn. Wọ́n dá Jóòbù lẹ́bi, wọ́n sì sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i. (Jóòbù 32:​1-3) Báwo lọ̀rọ̀ wọn ṣe rí lára Jèhófà? Jèhófà bínú gidigidi sáwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òmùgọ̀ ni wọ́n, ó sì ní kí wọ́n bẹ Jóòbù kó lè gbàdúrà fún wọn. (Jóòbù 42:​7-9) Àwọn ẹ̀kọ́ mélòó kan wà tá a lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ burúkú àwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn. Àkọ́kọ́, kò yẹ ká máa dá àwọn ará wa lẹ́jọ́. (Mát. 7:​2-5) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa fara balẹ̀ gbọ́ wọn, ká má sì já lu ọ̀rọ̀ wọn. Ìgbà yẹn la máa lóye ohun tó ń ṣe wọ́n. (1 Pét. 3:8) Ìkejì, tá a bá máa sọ̀rọ̀, ká rí i dájú pé ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára ló jáde lẹ́nu wa, ó sì jẹ́ òótọ́ látòkèdélẹ̀. (Éfé. 4:25) Ẹ̀kọ́ kẹta ni pé ká máa fi sọ́kàn pé Jèhófà ń kíyè sí ọ̀rọ̀ tá à ń sọ sáwọn míì. w20.03 22-23 ¶15-16

Wednesday, September 29

Ẹ máa gbàdúrà ní gbogbo ìgbà.​—Éfé. 6:18.

Lọ́pọ̀ ìgbà, bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làwa náà á túbọ̀ máa mọ̀ ọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àánú Jèhófà túbọ̀ ń ṣe kedere sí wa bó ṣe ń darí wa sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tí wọ́n sì fẹ́ di ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jòh. 6:44; Ìṣe 13:48) À ń rí agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní bá a ṣe ń kíyè sí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n ń jáwọ́ nínú àwọn ìwà wọn àtijọ́ tí wọ́n sì ń hùwà tó yẹ Kristẹni. (Kól. 3:​9, 10) Bákan náà, à ń rí bí Ọlọ́run ṣe ń mú sùúrù fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa nítorí pé léraléra ló ń rán wa lọ sọ́dọ̀ wọn ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n bàa lè rí ìgbàlà. (Róòmù 10:​13-15) Yálà ó ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà tàbí kò tíì pẹ́, ẹ má ṣe jẹ́ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ni pé ká máa gbàdúrà sí i. Àárín àwọn ọ̀rẹ́ méjì máa túbọ̀ gún régé tí wọ́n bá ń bára wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Torí náà, máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé, máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un láìbẹ̀rù. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àárín ìwọ àtiẹ̀ á túbọ̀ gún régé. w19.12 19 ¶11, 13-14

Thursday, September 30

A ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.​—1 Jòh. 2:12.

Ìyẹn mà tuni lára o! Torí pé Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa mú gbogbo aburú tí Sátánì àti ayé burúkú yìí ti fà fún wa kúrò. (Àìsá. 65:17; 1 Jòh. 3:8; Ìfi. 21:​3, 4) Ó dájú pé ìrètí tó ń fọkàn ẹni balẹ̀ nìyẹn! Yàtọ̀ síyẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa ò rọrùn, síbẹ̀ ó wà pẹ̀lú wa, ó sì ń fún wa lókun tá a nílò ká lè ṣiṣẹ́ náà láṣeyanjú nínú ayé burúkú yìí. (Mát. 28:​19, 20) Kò sí àní-àní pé ìyẹn ń fún wa nígboyà! Ká sòótọ́, ó ṣe pàtàkì ká ní ìtura, ìrètí àti ìgboyà ká tó lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ bó o tiẹ̀ ń kojú àwọn ìṣòro tó lékenkà? Máa fara wé Jésù. Lọ́nà wo? Àkọ́kọ́, máa gbàdúrà nígbà gbogbo. Ìkejì, máa ṣègbọràn sí Jèhófà kó o sì máa fìtara wàásù tí kò bá tiẹ̀ rọrùn. Ìkẹta, jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àlàáfíà Ọlọ́run á máa ṣọ́ ọkàn rẹ. (Fílí. 4:​6, 7) Bíi ti Jésù, ìwọ náà á borí ìṣòro èyíkéyìí tó lè dé bá ẹ.​—Jòh. 16:33. w19.04 13 ¶16-17

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́