November
Monday, November 1
Ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.—Fílí. 2:3.
Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn táwọn èèyàn kà sí ọlọ́gbọ́n nínú ayé máa ń bẹnu àtẹ́ lu ohun tí Bíbélì sọ nípa ojú tó yẹ ká fi máa wo ara wa. Wọ́n gbà pé sùẹ̀gbẹ̀ lẹni tó bá ń ronú pé àwọn míì sàn ju òun lọ àti pé wọ́n máa rẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ. Àmọ́, báwo ni nǹkan ṣe rí fáwọn tó ń gbéra ga? Ṣé àwọn onímọtara-ẹni-nìkan máa ń láyọ̀? Ṣé ayọ̀ máa ń wà nínú ìdílé wọn, ṣé wọ́n sì láwọn ọ̀rẹ́ gidi? Ṣé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run? Látinú ohun tíwọ fúnra rẹ ti rí, èwo lo gbà pé ó sàn jù, ṣé ọgbọ́n táyé ń gbé lárugẹ ni àbí ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì? (1 Kọ́r. 3:19) Àwọn tó ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táyé ń gbé lárugẹ dà bí ẹni tí kò mọ̀nà tó wá ń béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ ẹni tó ti sọnù, àfàìmọ̀ káwọn méjèèjì má bára wọn nínú igbó. Jésù sọ nípa àwọn tí wọ́n kà sí “ọlọ́gbọ́n” nígbà yẹn lọ́hùn-ún pé: “Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n. Tí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa já sí.” (Mát. 15:14) Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ìwà òmùgọ̀ gbáà ni ọgbọ́n ayé yìí! w19.05 24-25 ¶14-16
Tuesday, November 2
Wọ́n sì máa kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ.—Mát. 24:31.
Lẹ́nu ọ̀pọ̀ ọdún àìpẹ́ yìí, ńṣe ni iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi ń pọ̀ sí i. Ṣó yẹ ká máa dara wa láàmú nítorí èyí? Rárá. “Jèhófà mọ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀.” (2 Tím. 2:19) Àwọn arákùnrin tó ń ka iye àwọn tó ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ kì í ṣe Jèhófà, torí náà wọn ò lè mọ àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró lóòótọ́. Ìdí sì ni pé àwọn tí wọ́n rò pé ẹni àmì òróró làwọn àmọ́ tí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró wà lára àwọn tí wọ́n kà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí wọ́n ti máa ń jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà tẹ́lẹ̀ kò jẹ ẹ́ mọ́ nígbà tó yá. Àwọn míì lè ní ìṣòro ọpọlọ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí wọ́n sì máa rò pé àwọn wà lára àwọn tó máa bá Kristi jọba lọ́run. Ó ṣe kedere pé a ò mọ iye àwọn ẹni àmì òróró tó kù láyé báyìí. Àwọn ẹni àmì òróró máa wà ní ọ̀pọ̀ ibi lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Jésù bá dé láti kó wọn lọ sọ́run. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹni àmì òróró díẹ̀ máa ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 12:17) Àmọ́, kò sọ iye àwọn tó máa ṣẹ́ kù nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀. w20.01 29-30 ¶11-13
Wednesday, November 3
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.—Jòh. 3:16.
Jésù ṣe àkàwé kan nípa ọmọ onínàákúnàá ká lè mọ bí ìfẹ́ tí Baba wa ọ̀run ní fún wa ṣe jinlẹ̀ tó. (Lúùkù 15:11-32) Bàbá inú àkàwé yẹn gbà pé ọmọ òun ṣì máa pa dà wálé lọ́jọ́ kan. Lọ́jọ́ tí ọmọ náà pa dà, tayọ̀tayọ̀ ni bàbá rẹ̀ fi gbà á. Torí náà, tó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé o ṣi ẹsẹ̀ gbé àmọ́ tó o ronú pìwà dà tọkàntọkàn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Baba rẹ ọ̀run ṣe tán láti gbà ẹ́ pa dà. Baba wa ọ̀run máa ṣàtúnṣe gbogbo ohun tí Ádámù bà jẹ́. Lẹ́yìn tí Ádámù ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà pinnu pé òun máa gba àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) lára aráyé ṣọmọ, wọ́n á sì di ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù lọ́run. Nínú ayé tuntun, Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí máa ran àwọn tó jẹ́ onígbọràn lọ́wọ́ láti di pípé. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pegedé nínú àdánwò ìkẹyìn, Jèhófà máa fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ wo bí inú Baba wa ọ̀run ṣe máa dùn tó nígbà tí ayé yìí bá kún fún àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ti di pípé! Ó dájú pé àsìkò yẹn máa lárinrin gan-an! w20.02 6-7 ¶17-19
Thursday, November 4
Ẹ máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú yín.—Éfé. 4:23.
Ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bi ara ẹ̀ pé, ‘Ṣé àwọn ìyípadà tí mò ń ṣe dénú mi àbí ojú ayé lásán ni mò ń ṣe?’ Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì gan-an, ó sì yẹ ká wá ìdáhùn sí i. Ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 12:43-45 jẹ́ ká rí kókó pàtàkì kan, ìyẹn ni pé ká gbé èròkerò kúrò lọ́kàn nìkan ò tó, a tún gbọ́dọ̀ fi èrò tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu kún ọkàn wa. Àmọ́ ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn yí èrò rẹ̀ tàbí irú ẹni tó jẹ́ nínú pa dà? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ . . . gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfé. 4:24) Torí náà, ó ṣeé ṣe kéèyàn yí irú ẹni tó jẹ́ nínú pa dà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. Ó kọjá ká kàn gbé èròkerò kúrò lọ́kàn tàbí ká kàn sọ pé a ò ní hùwà burúkú mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gba pé ká yí “agbára tó ń darí ìrònú” wa pa dà. Ìyẹn béèrè pé ká ṣe ìyípadà nínú ohun tí ọkàn wa ń fà sí, bá a ṣe ń ronú àtohun tó ń sún wa ṣe nǹkan. Kì í ṣe ohun tá a máa ṣe lẹ́ẹ̀kan tá a sì máa dúró, ohun tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbà gbogbo ni. w19.06 9-10 ¶6-7
Friday, November 5
A máa pa ìlú yìí run.—Jẹ́n. 19:13.
Jèhófà fàánú hàn sí Lọ́ọ̀tì nígbà tó rán àwọn áńgẹ́lì láti gba òun àti ìdílé rẹ̀ là. Àmọ́ ṣe ni Lọ́ọ̀tì “ń lọ́ra ṣáá.” Làwọn áńgẹ́lì náà bá gbá ọwọ́ rẹ̀ mú, wọ́n sì mú òun àti ìdílé rẹ̀ jáde nílùú náà. (Jẹ́n. 19:15, 16) Wọ́n wá sọ fún un pé kó sá lọ sí agbègbè olókè. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí Lọ́ọ̀tì sọ? Ó sọ fáwọn áńgẹ́lì náà pé kí wọ́n jẹ́ kí òun lọ sí ìlú kan tó wà nítòsí. (Jẹ́n. 19:17-20) Síbẹ̀, Jèhófà mú sùúrù fún un, ó sì gbà á láyè láti lọ sí ìlú náà. Nígbà tó yá, ẹ̀rù àwọn tó ń gbé ìlú yẹn ba Lọ́ọ̀tì, ló bá forí lé agbègbè olókè, ìyẹn ibi tí Jèhófà sọ fún un pé kó lọ tẹ́lẹ̀. (Jẹ́n. 19:30) Àbí ẹ ò rí i pé Jèhófà mú sùúrù fún Lọ́ọ̀tì gan-an! Bíi ti Lọ́ọ̀tì, àwọn ará kan lè ṣèpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu, kíyẹn sì kó wọn síṣòro. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan, kí ló yẹ ká ṣe? Ó lè ṣe wá bíi pé ká fọ̀rọ̀ gún un lára, ká sì jẹ́ kó mọ̀ pé ohun téèyàn bá gbìn ló máa ká, òótọ́ sì nìyẹn. (Gál. 6:7) Àmọ́ dípò ká ṣe bẹ́ẹ̀, á dáa ká ràn án lọ́wọ́ bí Jèhófà ṣe ran Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. w19.06 20-21 ¶3-5
Saturday, November 6
Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.—Héb. 13:6.
Ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọ̀tá wa ni pé táwọn bá fòfin de ìjọsìn wa, ẹ̀rù á bà wá, a ò sì ní jọ́sìn Jèhófà mọ́. Láfikún sí ìfòfindè, wọ́n tún lè tan irọ́ kálẹ̀ nípa wa, kí wọ́n rán àwọn agbófinró láti wá gbọn ilé wa yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́, wọ́n lè fẹ̀sùn kàn wá kí wọ́n sì gbé wa lọ sílé ẹjọ́. Kódà wọ́n lè ju àwọn kan lára wa sẹ́wọ̀n. Èrò wọn ni pé báwọn ṣe ju díẹ̀ lára wa sẹ́wọ̀n yẹn máa mú kí ẹ̀rù ba àwa tó kù. Tá a bá jẹ́ kí wọ́n kó wa láyà jẹ, a lè fọwọ́ ara wa dá ìjọsìn Jèhófà dúró. Ó sì dájú pé a ò ní fẹ́ dà bí àwọn tí Bíbélì sọ nínú Léfítíkù 26:36, 37. Torí náà, ká má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù mú ká dẹwọ́ tàbí ṣíwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà. Ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá ká má sì gbọ̀n jìnnìjìnnì. (Àìsá. 28:16) Ká bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn rẹ̀, kò sí ìjọba náà láyé yìí táá mú ká ṣíwọ́ sísin Jèhófà, bó ti wù kí ìjọba náà lágbára tó. Inúnibíni lè dẹ́rù bani, àmọ́ ó tún lè ṣe wá láǹfààní. Lọ́nà wo? Ó lè mú ká túbọ̀ máa fìtara jọ́sìn Jèhófà ká sì pinnu pé a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. w19.07 9-10 ¶6-7
Sunday, November 7
Wàásù ọ̀rọ̀ náà.—2 Tím. 4:2.
Tó ò bá tiẹ̀ tíì rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, má jẹ́ kó sú ẹ. Máa rántí pé Jésù fi iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn wé iṣẹ́ ẹja pípa. Àwọn apẹja máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n tó rí ẹja pa. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń wà lórí omi ní gbogbo òru mọ́jú, kódà nígbà míì wọ́n máa ń wakọ̀ lọ sọ́nà jíjìn kí wọ́n tó rí ẹja pa. (Lúùkù 5:5) Lọ́nà kan náà, àwọn kan tó ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí bíi tàwọn apẹja, wọ́n máa ń lọ síbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láwọn àsìkò tó yàtọ̀ síra. Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kàn. Àwọn tó ń sapá gan-an láti wá àwọn ẹni yíyẹ sábà máa ń rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Ṣé ìwọ náà lè lọ wàásù lásìkò tó ṣeé ṣe kó o rí àwọn èèyàn tàbí níbi táá ti rọrùn láti bá wọn sọ̀rọ̀? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe sùúrù pẹ̀lú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ìdí kan ni pé kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nìkan la ṣe ń kọ́ wọn. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ Jèhófà tó jẹ́ Òǹṣèwé Bíbélì, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. w19.07 18-19 ¶14-15
Monday, November 8
Mò . . . ń gbàgbé àwọn ohun tí mo fi sílẹ̀ sẹ́yìn.—Fílí. 3:13.
Àwọn kan ṣì máa ń dá ara wọn lẹ́bi torí àwọn àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, ìyẹn sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí, o ò ṣe dìídì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà Jésù? Tá a bá ṣèwádìí nípa ìràpadà náà, tá a ronú jinlẹ̀, tá a sì gbàdúrà nípa ẹ̀, ó ṣeé ṣe kọ́kàn wa balẹ̀. Ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká máa dá ara wa lẹ́bi ṣáá fún ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà ti dárí ẹ̀ jì wá. Ẹ jẹ́ ká tún wo ohun míì tá a kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Àwọn kan lè ti fiṣẹ́ olówó ńlá sílẹ̀ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé a lè gbàgbé àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn, ká má sì máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe ká kó jọ ká sọ pé a ò fiṣẹ́ náà sílẹ̀? (Nọ́ń. 11:4-6; Oníw. 7:10) Lára ‘àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn’ ni àwọn àṣeyọrí tàbí àwọn àdánwò tá a ti fara dà sẹ́yìn. Òótọ́ ni pé tá a bá ń ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà bù kún wa àti bó ṣe ràn wá lọ́wọ́, àá túbọ̀ sún mọ́ Baba wa ọ̀run. Àmọ́, kò yẹ ká ronú pé èyí tá a ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà náà ti tó.—1 Kọ́r. 15:58. w19.08 3 ¶5-6
Tuesday, November 9
Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.—1 Tẹs. 5:17.
Ibi yòówù ká wà, kò sígbà tá a yíjú sí Baba wa ọ̀run tí kò ráyè tiwa. Ọwọ́ rẹ̀ kò dí jù láti tẹ́tí sí wa, ìgbà gbogbo ló ṣeé bá sọ̀rọ̀, ó sì ṣe tán láti gbọ́ wa. Tá a bá mọ̀ pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà wa, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ wa máa dà bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nítorí ó ń gbọ́ ohùn mi.” (Sm. 116:1) Kì í ṣe pé Baba wa ọ̀run ń gbọ́ àdúrà wa nìkan, ó tún máa ń dáhùn wọn. Àpọ́sítélì Jòhánù fi dá wa lójú pé: “Tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.” (1 Jòh. 5:14, 15) Àmọ́ o, Jèhófà lè má dáhùn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́. Ìdí sì ni pé ó mọ ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù, torí náà ó lè má fún wa lóhun tá a fẹ́ gan-an, ó sì lè gba pé ká mú sùúrù dìgbà tó bá tó àsìkò lójú rẹ̀. (2 Kọ́r. 12:7-9) Jèhófà ń pèsè ohun tá a nílò. Gbogbo ohun tó yẹ kí Baba ṣe ni Jèhófà ń ṣe. (1 Tím. 5:8) Ó ń fún àwa ọmọ rẹ̀ láwọn nǹkan tó ń gbé ẹ̀mí wa ró. Kò fẹ́ ká máa ṣàníyàn nípa oúnjẹ, aṣọ tàbí ilé tá a máa gbé. (Mát. 6:32, 33; 7:11) Torí pé Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa, ó ti ṣètò gbogbo ohun tó máa mú kí ọjọ́ ọ̀la wa ládùn kó sì lóyin. w20.02 5 ¶10-12
Wednesday, November 10
Wọ́n á . . . di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.—Jòh. 10:16.
Kì í ṣe gbogbo àwọn tó nírètí láti lọ sọ́run ló para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45-47) Bó ṣe rí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìwọ̀nba àwọn arákùnrin ni Jèhófà àti Jésù ń lò láti bọ́ tàbí kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni Jèhófà lò láti kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Bákan náà lónìí, ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró ni Jèhófà gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa fún àwọn èèyàn òun ní “oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ.” Jèhófà ti pinnu láti fún èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ti pinnu láti fún àwọn mélòó kan tó máa bá Jésù jọba ní ìyè ti ọ̀run. Gbogbo wa pátá ni Jèhófà máa fún lérè, yálà àwọn tí Bíbélì pè ní “Júù” tàbí àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” náà. Òfin kan náà ló ní kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé, ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí òun jálẹ̀ ìgbésí ayé wa. (Sek. 8:23) Gbogbo wa gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa sìn ín ká sì wà níṣọ̀kan. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ. Bí òpin ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa sin Jèhófà nìṣó, ká sì máa tẹ̀ lé Kristi gẹ́gẹ́ bí “agbo kan.” w20.01 31 ¶15-16
Thursday, November 11
Tí a bá rí ẹnikẹ́ni tí kò ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà , a máa lè jèrè wọn . . . láìsọ ohunkóhun, torí pé wọ́n fojú rí ìwà mímọ́ yín pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀.—1 Pét. 3:1, 2.
A ò lè fipá mú àwọn mọ̀lẹ́bí wa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́, a lè gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n fetí sí ìwàásù, kí wọ́n sì ronú nípa ohun tí wọ́n gbọ́. (2 Tím. 3:14, 15) Máa hùwà tó dáa kó o lè yí wọn lọ́kàn pa dà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn máa ń kíyè sí ìwà wa ju ohun tá à ń sọ lọ. Má jẹ́ kó sú ẹ. Jèhófà ti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa. Bíbélì sọ pé “léraléra” ni Jèhófà ń fún àwọn èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere kí wọ́n lè jèrè ìyè. (Jer. 44:4) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó má jáwọ́ nínú sísọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó máa gba ara rẹ̀ àtàwọn tó ń fetí sí i là. (1 Tím. 4:16) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa, a fẹ́ kí wọ́n mọ òtítọ́. w19.08 14 ¶2; 16-17 ¶8-9
Friday, November 12
Ìbáwí tí a fúnni níta sàn ju ìfẹ́ tí a fi pa mọ́ lọ.—Òwe 27:5.
Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ó gba ìgboyà kẹ́nì kan tó lè fún wa nímọ̀ràn torí àṣìṣe wa. Tó bá sì rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àṣìṣe náà ti kọjá ohun tá a rò. Ó lè kọ́kọ́ ṣe wá bíi pé ká má gba ìbáwí náà. A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí ẹni náà tàbí ká máa bínú torí bó ṣe gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀. Àmọ́ tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a máa sapá láti ní èrò tó tọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà. Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń mọyì ìbáwí tí wọ́n bá fún un. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí: Ká sọ pé o ti kí ọ̀pọ̀ àwọn ará lẹ́yìn ìpàdé, lẹnì kan bá fà ẹ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì rọra sọ fún ẹ pé oúnjẹ ti há sí ẹ léyín. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ó dájú pé ojú máa tì ẹ́, ó tiẹ̀ lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ó yẹ kẹ́nì kan ti sọ fún ẹ tẹ́lẹ̀. Síbẹ̀, ṣé inú ẹ ò ní dùn pé ẹni náà sọ fún ẹ? Lọ́nà kan náà, ṣé kò yẹ ká mọyì ẹni tó lo ìgboyà, tó sì bá wa wí lásìkò tó tọ́. Ṣe ló yẹ ká mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, dípò ká sọ ọ́ di ọ̀tá.—Òwe 27:6; Gál. 4:16. w19.09 5 ¶11-12
Saturday, November 13
Ọmọ mi, pa àṣẹ bàbá rẹ mọ́, má sì pa ẹ̀kọ́ ìyá rẹ tì.—Òwe 6:20.
Iṣẹ́ pàtàkì ni Jèhófà gbé fún ẹ̀yin ìyá, ó sì fún yín láṣẹ déwọ̀n àyè kan lórí àwọn ọmọ yín. Kódà, ipa kékeré kọ́ ni ìyá máa ń ní lórí ọmọ, àwọn ọmọ ò sì ní gbàgbé ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ lọ́dọ̀ ìyá wọn. (Òwe 22:6) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan díẹ̀ tẹ́ ẹ lè kọ́ lára Màríà ìyá Jésù. Màríà mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, ó sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Ó múra tán láti fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn máa yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà. (Lúùkù 1:35-38, 46-55) Ẹ̀yin ìyá, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ lè kọ́ lára Màríà. Àkọ́kọ́, ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ẹ sì ń gbàdúrà láyè ara yín kí àjọṣe tí ẹ̀yin fúnra yín ní pẹ̀lú Jèhófà lè túbọ̀ lágbára. Ìkejì, ẹ múra tán láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ kẹ́ ẹ lè múnú Jèhófà dùn. w19.09 18 ¶17-19
Sunday, November 14
Wò ó! . . . ogunlọ́gọ̀ èèyàn.—Ìfi. 7:9.
Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran àgbàyanu kan. Nínú ìran náà, áńgẹ́lì kan sọ fáwọn áńgẹ́lì mẹ́rin míì pé kí wọ́n má tíì tú atẹ́gùn ìpọ́njú ńlá tí wọ́n dì mú sílẹ̀ títí dìgbà tí wọ́n á fi gbé èdìdì lé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan. (Ìfi. 7:1-3) Àwùjọ àwọn tí wọ́n máa gbé èdìdì lé yìí ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa jọba pẹ̀lú Jésù lọ́run. (Lúùkù 12:32; Ìfi. 7:4) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jòhánù wá mẹ́nu kan àwùjọ míì, wọ́n pọ̀ débi tó fi pariwo pé: “Wò ó!” tó fi hàn pé ohun tó rí yà á lẹ́nu gan-an. Kí ni Jòhánù rí? Ó rí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn, tí èèyàn kankan kò lè ka iye wọn, wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìfi. 7:9-14) Ẹ wo bí inú Jòhánù ṣe máa dùn tó nígbà tó mọ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn á máa ṣe ìjọsìn tòótọ́! Kò sí àní-àní pé ìran yẹn máa mú kí ìgbàgbọ́ Jòhánù túbọ̀ lágbára. Tó bá rí bẹ́ẹ̀ fún un, mélòómélòó àwa tá à ń gbé lásìkò tí ìran náà ń ní ìmúṣẹ! Àsìkò wa yìí ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ń rọ́ wá sínú ètò Ọlọ́run, ìyẹn àwọn tó nírètí àtila ìpọ́njú ńlá já sínú ayé tuntun kí wọ́n sì wà láàyè títí láé. w19.09 26 ¶2-3
Monday, November 15
Ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn, . . . wọn ò sì ní yè bọ́ lọ́nàkọnà.—1 Tẹs. 5:3.
Lọ́jọ́ kan, àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè máa kéde pé “àlàáfíà àti ààbò” tí wọ́n ti ń fojú sọ́nà fún tipẹ́tipẹ́ ti dé báyìí. Wọ́n tiẹ̀ lè sọ pé ìsinsìnyí gan-an ni àlàáfíà ṣẹ̀ṣẹ̀ jọba láyé. Wọ́n máa fẹ́ ká gbà pé àwọn ti rí ojútùú sí gbogbo ìṣòro tó ń bá aráyé fínra. Ó mà ṣé o, wọn ò mọ̀ pé àwọn ò ní lè ṣe nǹkan kan sóhun tó máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e. “Bábílónì Ńlá” máa pa run! (Ìfi. 17:5, 15-18) “Ọlọ́run [máa] fi sí ọkàn wọn láti ṣe ohun tí òun fẹ́.” Kí ni Ọlọ́run fẹ́? Ó fẹ́ pa àpapọ̀ àwọn ìsìn èké ayé yìí run títí kan Kristẹndọm. Ọlọ́run máa fi ohun tó fẹ́ ṣe sínú ọkàn “ìwo mẹ́wàá” ti “ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” náà. Ìwo mẹ́wàá náà dúró fún gbogbo ìjọba ayé tó ń ti “ẹranko” yìí lẹ́yìn, ìyẹn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. (Ìfi. 17:3, 11-13; 18:8) Nígbà táwọn ìjọba ayé bá gbéjà ko ẹ̀sìn èké, ìyẹn á fi hàn pé ìpọ́njú ńlá ti bẹ̀rẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa wáyé lójijì, á sì lágbára gan-an débi pé kò sẹ́ni tí kò ní mọ̀ ọ́n lára. w19.10 14 ¶1, 3
Tuesday, November 16
Díótíréfè tó fẹ́ fi ara rẹ̀ ṣe olórí láàárín wọn, kì í fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ohunkóhun tí a bá sọ.—3 Jòh. 9.
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Díótíréfè ṣe ìlara àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ. Bíbélì sọ pé ó fẹ́ “fi ara rẹ̀ ṣe olórí” láàárín àwọn ará, ìyẹn sì mú kó máa sọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù àtàwọn míì tó ń múpò iwájú láìdáa. (3 Jòh. 10) Òótọ́ ni pé kò sẹ́nì kankan lára wa tó máa ṣe bíi ti Díótíréfè, síbẹ̀ tá ò bá ṣọ́ra a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara àwọn ará tó ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù wá, pàápàá tá a bá ronú pé àwa náà kúnjú ìwọ̀n tàbí pé a lè ṣe é jù wọ́n lọ. Ìlara dà bí ewéko búburú. Tó bá ti ta gbòǹgbò lọ́kàn èèyàn, ó máa ń ṣòro fà tu. Lára ohun tó ń fa ìlara ni kéèyàn máa jowú, kó máa gbéra ga, kó sì jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Ńṣe ni ìlara máa ń paná ànímọ́ rere, kì í jẹ́ kéèyàn fi ìfẹ́, àánú àti ìgbatẹnirò hàn. Gbàrà tá a bá ti kíyè sí i pé a fẹ́ máa ṣe ìlara ni ká ti fà á tu kúrò lọ́kàn wa. w20.02 15 ¶6-7
Wednesday, November 17
A fi ẹ̀gún kan sínú ara mi.—2 Kọ́r. 12:7.
Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé òun láwọn ìṣòro kan tó ń bá òun fínra. Ó sọ pé ìṣòro náà dà bí ìgbà tí “áńgẹ́lì Sátánì” ń ‘gbá òun ní àbàrá’ (‘lu òun’ àlàyé ìsàlẹ̀). Ó lè má jẹ́ Sátánì tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ gangan ló fa ìṣòro Pọ́ọ̀lù bí ẹni pé àwọn ló ki ẹ̀gún sínú ara ẹ̀. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà táwọn ẹ̀mí burúkú yìí rí i pé ó níṣòro tó dà bí “ẹ̀gún,” ṣe ni wọ́n mú kó túbọ̀ nira fún un bíi pé wọ́n ń gbá ẹ̀gún náà wọnú sí i. Kí ni Pọ́ọ̀lù wá ṣe? Ohun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ ni pé kí Jèhófà bá òun yọ “ẹ̀gún” náà kúrò pátápátá. Ó sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀mẹta ni mo bẹ Olúwa [Jèhófà] . . . kó lè kúrò lára mi.” Láìka gbogbo àdúrà tí Pọ́ọ̀lù gbà, ẹ̀gún ọ̀hún ò mà kúrò níbẹ̀. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà ẹ̀ ni? Rárá o. Ó dáhùn ẹ̀, lóòótọ́ Jèhófà ò mú ìṣòro náà kúrò, àmọ́ ó fún un lágbára kó lè fara dà á. Jèhófà fi dá a lójú pé: “À ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” (2 Kọ́r. 12:8, 9) Torí pé Jèhófà ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ gan-an, ó láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ọkàn ẹ̀ sì balẹ̀!—Fílí. 4:4-7. w19.11 9 ¶4-5
Thursday, November 18
Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo.—Náh. 1:2.
Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun sì ni Olùfúnni-Ní-Ìyè wa. (Ìfi. 4:11) Àmọ́ ìṣòro kan wà tó dojú kọ wá. Lóòótọ́ a lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un, síbẹ̀ àwọn nǹkan kan wà tó lè dí wa lọ́wọ́ àtimáa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ máa jọ́sìn Jèhófà nìkan, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú. A ò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun gba ipò àkọ́kọ́ nínú ọkàn wa. (Ẹ́kís. 34:14) A ní ìdí tó pọ̀ tá a fi ń jọ́sìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kọ́ nípa Jèhófà, a sì ti wá mọyì àwọn ànímọ́ rẹ̀. A mọ àwọn nǹkan tó fẹ́ àtàwọn nǹkan tó kórìíra, àwa náà sì fara mọ́ ọn. A mọ ohun tó ní lọ́kàn fáwa èèyàn, pé ká wà láàyè títí láé ká sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tá a fi ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Bákan náà, a mọyì àǹfààní tó fún wa láti jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Sm. 25:14) Ká sòótọ́, gbogbo nǹkan tá à ń kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.—Jém. 4:8. w19.10 26 ¶1-3
Friday, November 19
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.—Òwe 17:17.
Oríṣiríṣi nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa. Bí àpẹẹrẹ, àjálù máa ń ṣàdédé wáyé, nígbà míì sì rèé ó lè jẹ́ pé àwọn èèyàn ló fà á. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn kan lára wa lè gba àwọn ará yìí sílé, àwọn míì sì lè fún wọn lówó. Àmọ́ ohun kan wà tí gbogbo wa lè ṣe, a lè bẹ Jèhófà pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá gbọ́ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan rẹ̀wẹ̀sì, a lè má mọ ohun tá a máa ṣe tàbí ohun tá a máa sọ fún wọn. Síbẹ̀ àwọn nǹkan míì wà tá a lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a lè wáyè lọ rí ọ̀rẹ́ wa yẹn. Ká fara balẹ̀ tẹ́tí sí i bó ṣe ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. A sì tún lè ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tá a fẹ́ràn fún un láti tù ú nínú. (Àìsá. 50:4) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o dúró ti ọ̀rẹ́ rẹ nígbà ìṣòro. Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká pinnu pé a máa mú àwọn ará wa lọ́rẹ̀ẹ́, a ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun da àárín wa rú. Kódà, títí láéláé làá máa bára wa ṣọ̀rẹ́! w19.11 7 ¶18-19
Saturday, November 20
Òfin ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tí ẹnì kan bá mú wá fún Jèhófà nìyí.—Léf. 7:11.
Ìfẹ́ tí ọmọ Ísírẹ́lì kan ní fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ló mú kó fínnúfíndọ̀ rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀. Ẹni tó rú ẹbọ yìí, ìdílé rẹ̀ àtàwọn àlùfáà máa jẹ lára ẹran tó fi rúbọ náà. Àmọ́, àwọn apá kan wà lára ẹran náà tó jẹ́ ti Jèhófà nìkan. Apá wo nìyẹn? Ọ̀rá ni Jèhófà kà sí pàtàkì jù lára ẹran. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn apá míì bíi kíndìnrín ṣe pàtàkì sí òun. (Léf. 3:6, 12, 14-16) Ẹ wá rídìí tí inú Jèhófà fi máa ń dùn tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá fínnúfíndọ̀ fi ọ̀rá àtàwọn apá pàtàkì míì rúbọ sí i. Ọmọ Ísírẹ́lì tó fi àwọn nǹkan yìí rúbọ fi hàn pé ohun tó dára jù lọ lòun fún Jèhófà. Lọ́nà kan náà, Jésù fínnúfíndọ̀ fi ohun tó dára jù lọ rúbọ sí Jèhófà ní ti pé ó sin Jèhófà tọkàntara torí ìfẹ́ tó ní fún un. (Jòh. 14:31) Inú Jésù máa ń dùn gan-an láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ̀ dénúdénú. (Sm. 40:8) Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé Jésù sin òun tọkàntọkàn! w19.11 22-23 ¶9-10
Sunday, November 21
Ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá. Ohun mímọ́ ló jẹ́ fún Jèhófà.—Ẹ́kís. 31:15.
Bíbélì sọ pé lẹ́yìn “ọjọ́” mẹ́fà tí Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá àwọn nǹkan tó wà láyé, ó dáwọ́ dúró. (Jẹ́n. 2:2) Àmọ́ ohun kan ni pé Ọlọ́run fẹ́ràn àtimáa ṣiṣẹ́, kódà Bíbélì sọ pé ó ṣì “ń ṣiṣẹ́.” (Jòh. 5:17) Ètò tí Ọlọ́run ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa sinmi ní gbogbo ọjọ́ Sábáàtì jọra pẹ̀lú ọjọ́ keje tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé Jèhófà fi sinmi. Ọlọ́run sọ pé àmì ni Sábáàtì jẹ́ láàárín òun àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kís. 31:12-14) Kì í ṣe àwọn àgbàlagbà nìkan ni kò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́, ó kan àwọn ọmọdé àtàwọn ẹrú, kódà ó kan àwọn ẹran ọ̀sìn pàápàá. (Ẹ́kís. 20:10) Ètò yìí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn náà láti túbọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run. Àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà yẹn ti àṣejù bọ̀ ọ́. Wọ́n sọ pé kò bófin mu bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe já ọkà jẹ nínú oko àti bí Jésù ṣe wo àwọn èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Máàkù 2:23-27; 3:2-5) Èrò tí wọ́n ní yẹn ta ko èrò Ọlọ́run, Jésù sì mú kíyẹn ṣe kedere sáwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. w19.12 3-4 ¶8-9
Monday, November 22
Ẹ máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ.—Éfé. 5:1.
Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ lá ṣe rọrùn fún wa láti fìwà jọ ọ́. Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé: “Ẹní bíni làá jọ.” Dáfídì mọ Baba rẹ̀ ọ̀run gan-an, ó sì fìwà jọ ọ́, kódà ó hàn nínú bó ṣe bá àwọn míì lò. Dáfídì ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn sì mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Kódà, òun ni Jèhófà sábà máa ń tọ́ka sí láti fi díwọ̀n bóyá ọba kan ṣe dáadáa tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Ọba 15:11; 2 Ọba 14:1-3) Kí lèyí kọ́ wa? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé ká máa “fara wé Ọlọ́run.” Tá a bá fìwà jọ Jèhófà nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe, ńṣe là ń fi hàn pé ọmọ rẹ̀ ni wá. (Éfé. 4:24) Títí ayé làá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Oníw. 3:11) Àmọ́, kéèyàn kó ìmọ̀ jọ tàbí kéèyàn rọ́ ìmọ̀ ságbárí kọ́ ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe ohun téèyàn fi ìmọ̀ náà ṣe. Ohun tó dáa jù lọ ni pé ká máa fi ohun tà à ń kọ́ ṣèwàhù, ká máa sapá láti fìwà jọ Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á túbọ̀ sún mọ́ wa, àárín àwa àtiẹ̀ á sì túbọ̀ gún régé. (Jém. 4:8) Ó fi dá wa lójú nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun ò ní fàwọn tó mọ òun sílẹ̀ láé. w19.12 20 ¶20; 21 ¶21, 23
Tuesday, November 23
Ọkàn ń tanni jẹ ju ohunkóhun lọ.—Jer. 17:9.
Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àmọ́ Jósẹ́fù ló nífẹ̀ẹ́ jù. Báwo ló ṣe rí lára àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù pé àbúrò wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ni bàbá wọn fẹ́ràn jù? Kò dùn mọ́ wọn nínú, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara rẹ̀, ìyẹn sì mú kí wọ́n kórìíra ẹ̀. Torí náà, wọ́n tà á sóko ẹrú wọ́n sì pa irọ́ fún bàbá wọn pé ẹranko ti pa ààyò ọmọ rẹ̀ jẹ. Ìlara tí wọ́n ṣe yìí mú kí àlàáfíà tó wà ní ìdílé wọn bà jẹ́, wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá bàbá wọn. (Jẹ́n. 37:3, 4, 27-34) Ìlara wà lára “àwọn iṣẹ́ ti ara” tó léwu tó sì lè mú kéèyàn má jogún Ìjọba Ọlọ́run. (Gál. 5:19-21) Ìlara kì í bímọọre, ohun tó sábà máa ń yọrí sí ni ìkórìíra, wàhálà àti inú fùfù. Àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù yìí jẹ́ ká rí i pé ìlara lè ba àjọṣe àti àlàáfíà tó wà nínú ìdílé jẹ́. Òótọ́ ni pé kò sẹ́nì kankan nínú wa tó máa fẹ́ ṣe bíi tàwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù láé, àmọ́ ká rántí pé aláìpé ni gbogbo wa, ọkàn wa sì lè tàn wá jẹ. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń ṣe wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi pé ká ṣe ìlara àwọn míì. w20.02 14 ¶1-3
Wednesday, November 24
Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.—Fílí. 2:3.
Lọ́jọ́ kan, Jèhófà mú lára ẹ̀mí mímọ́ tó wà lára Mósè, ó sì fún àwùjọ àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì tó wà níbi àgọ́ ìpàdé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Mósè gbọ́ pé ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn àgbààgbà méjì kan tí wọn ò wá síbi àgọ́ ìpàdé náà, wọ́n sì ń ṣe bíi wòlíì. Kí ni Mósè ṣe nígbà tí Jóṣúà sọ fún un pé kó pa wọ́n lẹ́nu mọ́? Mósè kò ṣe ìlara àwọn méjì náà, kò sì bínú pé Jèhófà fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bá wọn yọ̀. (Nọ́ń. 11:24-29) Kí ni àpẹẹrẹ Mósè yìí kọ́ wa? Ṣé alàgbà ni ẹ́? Ǹjẹ́ wọ́n ti sọ fún ẹ rí pé kó o dá ẹlòmíì nínú ìjọ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa bójú tó iṣẹ́ tó o gbádùn láti máa ṣe? Tó o bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Mósè, o ò ní ronú pé ẹni tí wọ́n ní kó o dá lẹ́kọ̀ọ́ máa gbaṣẹ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ẹ á dùn, á sì yá ẹ lára láti dá onítọ̀hún lẹ́kọ̀ọ́ débi pé tó bá yá, á lè bójú tó iṣẹ́ náà dáadáa. w20.02 15 ¶9; 17 ¶10-11
Thursday, November 25
Àníyàn inú ọkàn máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mú kó túra ká.—Òwe 12:25.
Èèyàn lè ní ẹ̀dùn ọkàn tó bá ń ṣàìsàn. Ọkàn wa lè gbọgbẹ́ torí pé ara wa ò yá tàbí torí pé a ò lè dá ṣe nǹkan kan láìjẹ́ pé àwọn míì ràn wá lọ́wọ́. Àwọn míì tiẹ̀ lè má mọ̀ pé à ń ṣàìsàn, síbẹ̀ kí ojú máa tì wá nítorí pé agbára wa ti dín kù, a ò sì lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Láwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ń gbé wa ró, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀nà wo ló ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Tó o bá wo inú Bíbélì, wàá rí i pé àìmọye ìgbà ni Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ rere tó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa láìka ti àìsàn tó ń ṣe wá sí. (Sm. 31:19; 41:3) Jèhófà máa tipasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú kó o borí ẹ̀dùn ọkàn tó o ní, kó o sì fara da àìsàn tó ń ṣe ẹ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ ohun tó ń ṣe ẹ́ àti bó ṣe rí lára ẹ. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro rẹ. Lẹ́yìn náà, ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó o lè rí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ láti tù ẹ́ nínú. Ní pàtàkì, máa ronú lórí àwọn ẹsẹ tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn rẹ̀, ó sì mọyì wa gan-an. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé adúrótini nígbà ìṣòro ni Jèhófà, kì í sì í fàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.—Sm. 84:11. w20.01 15-16 ¶9-10; 17 ¶12
Friday, November 26
Má ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú, àpẹẹrẹ rere ni kí o máa tẹ̀ lé.—3 Jòh. 11.
Ísákì ní ọrọ̀ gan-an, ìyẹn sì mú kí àwọn Filísínì máa ṣe ìlara rẹ̀. (Jẹ́n. 26:12-14) Kódà, wọ́n dí àwọn kànga tó ti máa ń fa omi fún àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀. (Jẹ́n. 26:15, 16, 27) Bíi tàwọn Filísínì, àwọn kan máa ń ṣe ìlara àwọn míì nítorí pé wọ́n ní nǹkan jù wọ́n lọ. Yàtọ̀ sí pé wọ́n fẹ́ ní ohun táwọn míì ní, wọ́n tún fẹ́ kóhun táwọn yẹn ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe ìlara Jésù nítorí pé àwọn èèyàn mọyì Jésù, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Mát. 7:28, 29) Aṣojú Ọlọ́run ni Jésù, òtítọ́ ló sì fi ń kọ́ni. Síbẹ̀, ńṣe ni àwọn aṣáájú ìsìn yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa, tí wọ́n sì ń bà á lórúkọ jẹ́. (Máàkù 15:10; Jòh. 11:47, 48; 12:12, 13, 19) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ yìí? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé ká rí i dájú pé a ò ṣe ìlara àwọn tí àwọn ará nífẹ̀ẹ́ torí àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká fara wé wọn.—1 Kọ́r. 11:1. w20.02 15 ¶4-5
Saturday, November 27
Kí wọ́n pa onítọ̀hún.—Ẹ́sít. 4:11.
Jẹ́ ká sọ pé ilẹ̀ Páṣíà lò ń gbé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (2,500) ọdún sẹ́yìn, o sì fẹ́ bá kábíyèsí ìlú yín sọ ọ̀rọ̀ kan. Àmọ́ o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbàṣẹ kó o tó lè bá ọba sọ̀rọ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ikú lo fi ń ṣeré yẹn! A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ò dà bí ọba Páṣíà yẹn! Kò sígbà tá a fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ tí kì í ráyè fún wa. Kódà ó fẹ́ ká máa wá sọ́dọ̀ òun, ká sì máa bá òun sọ̀rọ̀ nígbàkigbà tá a bá fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá, òun ni Olódùmarè, ó sì tún jẹ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ, ó fẹ́ ká máa pe òun ní “Baba” tá a bá fẹ́ bá òun sọ̀rọ̀. (Mát. 6:9) Ẹ ò rí i pé ìyẹn tuni lára gan-an, ó sì múnú wa dùn pé ojú Baba ni Jèhófà fẹ́ ká fi máa wo òun! Ó tọ́, ó sì yẹ ká máa pe Jèhófà ní “Baba,” ó ṣe tán òun ló dá wa. (Sm. 36:9) Torí pé òun ni Baba wa, ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí i. Tá a bá ń ṣe ohun tó fẹ́, ó máa rọ̀jò ìbùkún lé wa lórí. (Héb. 12:9) Lára ìbùkún náà ni ìyè àìnípẹ̀kun yálà lórí ilẹ̀ ayé tàbí lókè ọ̀run. w20.02 2 ¶1-3
Sunday, November 28
Ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19.
Ohun tá a fẹ́ ni pé kí akẹ́kọ̀ọ́ wa máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (Éfé. 4:13) Tẹ́nì kan bá gbà pé ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àǹfààní tó máa rí nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ló wà lọ́kàn ẹ̀. Àmọ́, bí òye rẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i, á bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á sì máa ronú ọ̀nà tóun lè gbà ran àwọn míì lọ́wọ́, títí kan àwọn tó wà nínú ìjọ. (Mát. 22:37-39) Tó bá tó àsìkò, ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kó mọ̀ pé gbogbo wa la láǹfààní láti fowó ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ ohun tó yẹ kó ṣe tó bá níṣòro. Jẹ́ ká sọ pé akẹ́kọ̀ọ́ rẹ tó ti di akéde aláìṣèrìbọmi sọ fún ẹ pé ẹnì kan nínú ìjọ ṣẹ òun. Dípò tí wàá fi gbè sẹ́yìn èyíkéyìí nínú wọn, o ò ṣe ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Ó lè pinnu pé òun á dárí ji ẹni náà kó sì gbọ́rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Tí kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè lọ yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí pẹ̀lú onítọ̀hún, á sì tipa bẹ́ẹ̀ “jèrè arákùnrin” rẹ̀. (Fi wé Mátíù 18:15.) Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè mọ ohun tó máa sọ àti bó ṣe máa sọ ọ́. w20.01 5-6 ¶14-15
Monday, November 29
Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ; mi ò bo àṣìṣe mi mọ́lẹ̀. . . . O sì dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.—Sm. 32:5.
A lè fi hàn pé a mọyì ìdáríjì Jèhófà tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá, tá a gbà pé kó bá wa wí, tá a sì sa gbogbo ipá wa ká má bàa tún ẹ̀ṣẹ̀ náà dá. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ẹ wo bó ṣe fini lọ́kàn balẹ̀ tó pé “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là”! (Sm. 34:18) Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ṣe ń parí lọ, ńṣe làwọn ohun tó ń fa àníyàn á máa pọ̀ sí i. Tó o bá ń ṣàníyàn tàbí tó o ní ìdààmú ọkàn, tètè yíjú sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó o kà. Kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí Hánà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Ọba Dáfídì ṣe nígbà tí wọ́n ní ìdààmú ọkàn. Bẹ Jèhófà Baba rẹ ọ̀run pé kó jẹ́ kó o mọ ohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè. (Sm. 139:23) Jẹ́ kó bá ẹ gbé ẹrù ìnira rẹ, pàápàá èyí tí agbára rẹ ò ká. Tó o bá ṣe àwọn nǹkan yìí, ìwọ náà á lè sọ bíi ti onísáàmù tó kọrin sí Jèhófà pé: “Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”—Sm. 94:19. w20.02 24 ¶17; 25 ¶20-21
Tuesday, November 30
Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.—2 Tím. 3:16.
Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti “mí sí” àwọn tó kọ Bíbélì. Tá a bá ka Bíbélì, tá a sì ronú jinlẹ̀ nípa ohun tá a kà, ìyẹn á mú káwọn ìtọ́ni Ọlọ́run wọnú ọkàn wa. Àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run mí sí yẹn á wá jẹ́ ká máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Héb. 4:12) Àmọ́, tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣiṣẹ́ lára wa fàlàlà, a gbọ́dọ̀ ṣètò àkókò wa ká lè máa ka Bíbélì déédéé, ká sì máa ronú jinlẹ̀ nípa ohun tá a kà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń darí wa. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ará. (Sm. 22:22) Afẹ́fẹ́ Jèhófà ń fẹ́ láwọn ìpàdé wa torí pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà wà níbẹ̀. (Ìfi. 2:29) A máa ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà nípàdé, a tún máa ń kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arákùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ yàn máa ń fún wa láwọn ìtọ́ni tá a gbé karí Bíbélì. Torí náà, tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣiṣẹ́ lára wa fàlàlà, a gbọ́dọ̀ máa múra ìpàdé sílẹ̀, ká sì máa kópa níbẹ̀. w19.11 11 ¶13-14