Jésù Kristi
Àwọn ọ̀nà pàtàkì wo ni Jèhófà gbà lo Jésù láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ?
Iṣe 4:12; 10:43; 2Kọ 1:20; Flp 2:9, 10
Tún wo Owe 8:22, 23, 30, 31; Jo 1:10; Ifi 3:14
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 16:13-17—Àpọ́sítélì Pétérù mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù àti pé òun ni Kristi tí Ọlọ́run ṣèlérí
Mt 17:1-9—Mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì Jésù rí Jésù nígbà tí Jèhófà yí i pa dà di ológo, wọ́n sì tún gbọ́ tí Jèhófà pè é ní Ọmọ Òun
Àwọn nǹkan wo ló mú kí Jésù yàtọ̀ sí àwọn èèyàn tó kù?
Jo 8:58; 14:9, 10; Kol 1:15-17; 1Pe 2:22
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 21:1-9—Jésù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù, ìyẹn sì mú kí àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà Ọba tí Ọlọ́run ṣèlérí ṣẹ
Heb 7:26-28—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bí ipò Jésù gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà tó ga jù lọ ṣe mú kó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn àlùfáà tó kù
Kí làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ nípa Jésù àti Bàbá rẹ̀?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 4:23, 24—Jésù ṣe ohun tó fi hàn pé òun lágbára ju àwọn ẹ̀mí èṣù lọ àti pé kò sí irú àìsàn tóun ò lè wò sàn
Mt 14:15-21—Lọ́nà ìyanu, Jésù fi búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tébi ń pa
Mt 17:24-27—Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu kan kó lè rí owó táá fi ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn Jèhófà, kó má bàa mú àwọn èèyàn kọsẹ̀
Mk 1:40, 41—Nígbà tí Jésù rí adẹ́tẹ̀ kan, àánú ẹ̀ ṣe é torí náà ó wo adẹ́tẹ̀ náà sàn. Èyí jẹ́ ká rí i pé ó wu Jésù láti wo àwọn aláìsàn sàn
Mk 4:36-41—Jésù mú kí ìjì líle kan rọlẹ̀, èyí sì fi hàn pé Bàbá rẹ̀ tí fún un láṣẹ lórí ìjì àtàwọn nǹkan míì tó lè fa àjálù
Jo 11:11-15, 31-45—Jésù sunkún nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú. Lẹ́yìn ìyẹn, ó jí Lásárù dìde, èyí sì fi hàn pé ó kórìíra ikú àti ìbànújẹ́ tó máa ń fà fáwọn téèyàn wọn kú
Kí ni ẹ̀kọ́ Jésù dá lé?
Àwọn ìwà àti ìṣe tó fani mọ́ra wo ni Jésù ní nígbà tó wà láyé? Wo bó ṣe fi hàn pé òun jẹ́ . . .
Ẹni tó ṣeé sún mọ́—Mt 13:2; Mk 10:13-16; Lk 7:36-50
Ẹni tó máa ń gba tẹni rò; aláàánú—Mk 5:25-34; Lk 7:11-15
Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn—Jo 13:1; 14:31; 15:13; 1Jo 3:16
Onígboyà—Mt 4:2-11; Jo 2:13-17; 18:1-6
Onígbọràn—Lk 2:40, 51, 52; Heb 5:8
Onírẹ̀lẹ̀—Mt 11:29; 20:28; Jo 13:1-5; Flp 2:7, 8
Ọlọ́gbọ́n—Mt 12:42; 13:54; Kol 2:3
Kí nìdí tí Jésù fi gbà láti kú, báwo ni ikú ẹ̀ sì ṣe ṣe wá láǹfààní?
Kí nìdí tó fi yẹ kínú wa máa dùn pé Jésù ti ń jọba lọ́run?
Sm 72:12-14; Da 2:44; 7:13, 14; Ifi 12:9, 10
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Sm 45:2-7, 16, 17—Sáàmù yìí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ti yan Ọba kan tó máa ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá, tó sì máa ṣàkóso pẹ̀lú òtítọ́, ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo
Ais 11:1-10—Nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso ayé, ó máa sọ ayé di Párádísè, àlàáfíà sì máa wà níbi gbogbo