Jèhófà
Orúkọ ẹ̀
A gbà pé orúkọ náà Jèhófà túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di”
Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà máa ń sọ ara ẹ̀ dà tàbí tó máa ń ṣe kó lè bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ àti pé òun ni Ọlọ́run tòótọ́?
Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo èèyàn máa ṣègbọràn sí Jèhófà?
Díẹ̀ lára àwọn orúkọ oyè Jèhófà
Àpáta—Di 32:4; Ais 26:4
Baba—Mt 6:9; Jo 5:21
Ẹni Gíga Jù Lọ—Jẹ 14:18-22; Sm 7:17
Olódùmarè—Jẹ 17:1; Ifi 19:6
Olùkọ́ Atóbilọ́lá—Ais 30:20
Olúwa Ọba Aláṣẹ—Ais 25:8; Emọ 3:7
Ọba ayérayé—1Ti 1:17; Ifi 15:3
Ọba Ọlọ́lá—Heb 1:3; 8:1
Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun—1Sa 1:11
Díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Jèhófà tó ṣàrà ọ̀tọ̀
Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé òun jẹ́ mímọ́, kí ló sì yẹ kí èyí mú káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe?
Ẹk 28:36; Le 19:2; 2Kọ 7:1; 1Pe 1:13-16
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Ais 6:1-8—Nínú ìran kan tí Jèhófà fi han wòlíì Àìsáyà nígbà kan, ó rí bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́ tó. Èyí mú kó rí ara ẹ̀ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, áńgẹ́lì kan jẹ́ kó mọ̀ pé èèyàn aláìpé ṣì lè jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run
Ro 6:12-23; 12:1, 2—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà àti bá a ṣe lè máa rìn “lọ́nà ìjẹ́mímọ́”
Báwo ni agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó, àwọn ọ̀nà wo ló sì ń gbà lo agbára ẹ̀?
Ẹk 15:3-6; 2Kr 16:9; Ais 40:22, 25, 26, 28-31
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Di 8:12-18—Wòlíì Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Jèhófà lo agbára ẹ̀ láti fún wọn ní gbogbo ohun rere tí wọ́n ní
1Ọb 19:9-14—Jèhófà fi agbára ńlá ẹ̀ han wòlíì Èlíjà kó lè fún un níṣìírí
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìdájọ́ Jèhófà ló dáa jù?
Di 32:4; Job 34:10; 37:23; Sm 37:28; Ais 33:22
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Di 24:16-22—Òfin Mósè jẹ́ ká rí i kedere pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo, onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú
2Kr 19:4-7—Ọba Jèhóṣáfátì sọ fáwọn onídàájọ́ pé kí wọ́n máa rántí pé Jèhófà ni wọ́n ń ṣojú fún nígbà tí wọ́n bá ń dájọ́, kì í ṣe èèyàn
Kí ló fi hàn pé Jèhófà ló gbọ́n jù?
Sm 104:24; Owe 2:1-8; Jer 10:12; Ro 11:33; 16:27
Tún wo Sm 139:14; Jer 17:10
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
1Ọb 4:29-34—Jèhófà fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n tó ju ti gbogbo àwọn tí wọ́n jọ gbé ayé lọ
Lk 11:31; Jo 7:14-18—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n Jésù ga gan-an ju ti Sólómọ́nì lọ, ó fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bó ṣe sọ fáwọn èèyàn pé Ọlọ́run ló fún òun ní ọgbọ́n
Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an?
Jo 3:16; Ro 8:32; 1Jo 4:8-10, 19
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 10:29-31—Jésù lo àpẹẹrẹ ológoṣẹ́ láti jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a sì ṣeyebíye gan-an lójú ẹ̀
Mk 1:9-11—Jèhófà bá Ọmọ ẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run, ó sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, òun sì tẹ́wọ́ gbà á. Ó yẹ káwọn òbí máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, torí pé ọkàn àwọn ọmọ máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá gbọ́ irú ọ̀rọ̀ yìí
Àwọn ànímọ́ míì wo ni Jèhófà tún ní tó mú ká nífẹ̀ẹ́ ẹ̀? Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ míì tó fani mọ́ra tí Jèhófà ní. Bí àpẹẹrẹ . . .
Adúróṣinṣin ni—Ifi 15:4
Aláàánú ni—Ẹk 34:6
Aláyọ̀ ni—1Ti 1:11
Iyì rẹ̀ kò láfiwé—Sm 8:1; 148:13
Kì í yí pa dà; ó ṣeé gbára lé—Mal 3:6; Jem 1:17
Ojú ẹ̀ ń rí gbogbo nǹkan—2Kr 16:9; Owe 15:3
Olódodo ni—Sm 7:9
Ológo ni—Ifi 4:1-6
Olójú àánú ni—Ais 49:15; 63:9; Sek 2:8
Onínúure ni—Lk 6:35; Ro 2:4
Onírẹ̀lẹ̀ ni—Sm 18:35
Ó ní sùúrù—Ais 30:18; 2Pe 3:9
Ó ti wà láti ayébáyé; kò ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sì ní òpin—Sm 90:2; 93:2
Ọ̀làwọ́ ni—Sm 104:13-15; 145:16
Ọlọ́run àlàáfíà ni—Flp 4:9
Tá a bá mọ Jèhófà dáadáa, kí ni èyí á mú ká ṣe?
Bí Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa sin òun
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kì í retí pé káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ohun tó ju agbára wa lọ?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Di 30:11-14—Òfin tí Jèhófà fi rán wòlíì Mósè sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ṣòro láti pa mọ́
Mt 11:28-30—Jésù fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa mú kára tù wọ́n, torí pé ó fìwà jọ Bàbá ẹ̀ láìkù síbì kan
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà?
Tún wo Jer 20:9; Lk 6:45; Iṣe 4:19, 20
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Sm 104:1, 2, 10-20, 33, 34—Onísáàmù kan yin Jèhófà torí àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀
Sm 148:1-14—Àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà tó kù máa ń yìn ín, ó yẹ káwa náa máa ṣe bẹ́ẹ̀
Báwo ni ìwà àti ìṣe wa ṣe lè mú káwọn èèyàn bọlá fún Jèhófà?
Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà?
Tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nírẹ̀lẹ̀ ?
Tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ka Bíbélì, ká sì máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá à ń kà?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi àwọn nǹkan tá à ń kà nínú Bíbélì sílò?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fi ohunkóhun pa mọ́ fún Jèhófà?
Job 34:22; Owe 28:13; Jer 23:24; 1Ti 5:24, 25
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
2Ọb 5:20-27—Géhásì gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ mọ́lẹ̀, àmọ́ Jèhófà jẹ́ kí wòlíì Èlíṣà mọ ohun tí Géhásì ṣe
Iṣe 5:1-11—Ananáyà àti Sàfírà gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀, àmọ́ Jèhófà tú àṣírí wọn, ó sì fìyà jẹ wọ́n torí pé wọ́n parọ́