Òdodo
Ta lẹni kan ṣoṣo tó lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jẹ 18:23-33—Jèhófà jẹ́ kí Ábúráhámù mọ̀ pé Onídàájọ́ òdodo lòun
Sm 72:1-4, 12-14—Ọlọ́run mí sí onísáàmù yìí láti yin Mèsáyà Ọba, ẹni tó jẹ́ olódodo bíi ti Ọlọ́run
Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, àǹfààní wo la máa rí?
Sm 37:25, 29; Jem 5:16; 1Pe 3:12
Tún wo Sm 35:24; Ais 26:9; Ro 1:17
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Job 37:22-24—Élíhù yin Jèhófà torí pé ó jẹ́ olódodo, títóbi rẹ̀ sì máa ń mú káwọn èèyàn rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un látọkàn wá
Sm 89:13-17—Onísáàmù yìí yin Jèhófà torí pé òdodo ló fi ń ṣàkóso
Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn wá òdodo Ọlọ́run?
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló yẹ kó mú ká máa hùwà tó dáa, kì í ṣe torí pé a fẹ́ gbayì lójú àwọn èèyàn?
Mt 6:1; 23:27, 28; Lk 16:14, 15; Ro 10:10
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 5:20; 15:7-9—Jésù sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n jẹ́ olódodo, àmọ́ kì í ṣe bíi tàwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí torí pé alágàbàgebè ni wọ́n
Lk 18:9-14—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ káwọn tó máa ń ṣe òdodo àṣelékè, tí wọ́n sì máa ń wo àwọn míì bíi pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan rí i pé ó yẹ kí wọ́n ṣàtúnṣe