Ogun
Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ogun ń jà lọ́pọ̀ ibi lásìkò tá a wà yìí?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Da 11:40—Jèhófà mú kí wòlíì Dáníẹ́lì rí ìran kan nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí, nínú ìran náà, ó rí i pé àwọn orílẹ̀-èdè alágbára méjì ń bára wọn díje, wọ́n sì ń figa gbága
Ifi 6:1-4—Àpọ́sítélì Jòhánù rí ẹṣin aláwọ̀ iná kan tó ń ṣàpẹẹrẹ ogun, ẹni tó jókòó sórí ẹṣin náà sì ní àṣẹ “láti mú àlàáfíà kúrò ní ayé”