ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • scl ojú ìwé 60-62
  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
  • Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
scl ojú ìwé 60-62

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé?

Sm 1:1-3; Owe 18:15; 1Ti 4:6; 2Ti 2:15

Tún wo Iṣe 17:11

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Sm 119:97-101—Onísáàmù kan sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run àti pé bóun ṣe ń tẹ̀ lé àwọn òfin náà mú kí ayé òun dáa

    • Da 9:1-3, àlàyé ìsàlẹ̀—Torí pé wòlíì Dáníẹ́lì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ó mọ̀ pé àádọ́rin (70) ọdún táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa lò nígbèkùn Bábílónì máa tó dópin

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó?

Heb 6:1-3; 2Pe 3:18

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Owe 4:18—Bó ṣe jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni ilẹ̀ máa ń mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ Bíbélì túbọ̀ yé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀

    • Mt 24:45-47—Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé òun máa yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” táá jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ túbọ̀ máa yé wa, ká lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí

Kí nìdí tí ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì fi dáa ju èyí tó wà nínú àwọn ìwé míì táwọn èèyàn kọ?

Onw 12:11-13; 1Kọ 3:19; 1Ti 6:20, 21; 2Pe 1:19-21

Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn, àǹfààní wo la máa rí?

Owe 2:4-6; 9:10; Jo 6:45

Tá a bá fẹ́ túbọ̀ lóye ohun tá à ń kọ́, kí ló yẹ ká máa gbàdúrà fún ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Lk 11:13; 1Kọ 2:10; Jem 1:5

Tún wo Sm 119:66

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé gbogbo ohun tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” bá sọ fún wa?

Mt 24:45-47

Tún wo Mt 4:4; 1Ti 4:15

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ní ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì?

Flp 1:9, 10; Kol 1:9, 10

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní ọgbọ́n àti òye?

Owe 4:7; Onw 7:25

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fara balẹ̀ tá a bá ń ka Bíbélì, ká sì máa ronú lórí ohun tá à ń kà?

Joṣ 1:8; Sm 1:2

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa bí ohun tá a kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe kàn wá?

Ro 15:4; 1Kọ 10:11; 2Ti 3:16, 17; Jem 1:22-25

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa bá a ṣe lè fi ohun tá à ń kọ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?

Owe 15:28; 1Pe 3:15

Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, àǹfààní wo la máa rí?

2Pe 1:13; 3:1, 2

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Di 6:6, 7; 11:18-20—Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀rọ̀ òun léraléra

Àǹfààní wo làwọn ìdílé máa rí tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀?

Ef 6:4

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 18:17-19—Jèhófà fẹ́ kí Ábúráhámù kọ́ agbo ilé ẹ̀ kí wọ́n lè máa ṣe ohun tó dáa àti ohun tó tọ́

    • Sm 78:5-7—Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà pàṣẹ pé kí ìran kọ̀ọ̀kan máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jèhófà, káwọn ìran tó ń bọ̀ lè máa bá a nìṣó láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa nípàdé?

Heb 10:25

Tún wo Owe 18:1

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́