Ìjọsìn
Tá ni ẹnì kan ṣoṣo tó yẹ ká máa jọ́sìn?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 4:8-10—Sátánì sọ pé tí Jésù bá lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, òun á fún un ní gbogbo ìjọba ayé; àmọ́ Jésù ò gbà, torí pé kò fẹ́ jọ́sìn ẹlòmíì, àfi Jèhófà nìkan ṣoṣo
Ifi 19:9, 10—Áńgẹ́lì alágbára kan kò gbà kí Jòhánù jọ́sìn òun
Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa jọ́sìn òun?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Ais 1:10-17—Torí pé àwọn èèyàn Jèhófà kan ya aláìgbọràn, Jèhófà ò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn ojú ayé tí wọ́n ń ṣe, kódà ó kórìíra ẹ̀
Mt 15:1-11—Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ò fẹ́ ká máa tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn nínú ìjọsìn wa, kàkà bẹ́ẹ̀ àṣẹ Ọlọ́run ló yẹ ká máa tẹ̀ lé
Tó bá ṣeé ṣe, àwọn wo ló yẹ ká jọ máa jọ́sìn Jèhófà?
Tún wo Sm 133:1-3
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Iṣe 2:40-42—Tí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ bá pàdé, wọ́n máa ń gbàdúrà pa pọ̀, wọ́n máa ń fún ara wọn níṣìírí, wọ́n sì tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ látinú Ìwé Mímọ́
1Kọ 14:26-40—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó yẹ káwọn ìpàdé ìjọ wà létòlétò, ká máa gba ìṣírí níbẹ̀, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀
Kí ló yẹ ká máa ṣe kí Jèhófà lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Heb 11:6—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé tá a bá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́
Jem 2:14-17, 24-26—Jémíìsì àbúrò Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ kún ìgbàgbọ́ wa, torí pé ńṣe ni ìgbàgbọ́ máa ń jẹ́ ká ṣe ohun tó tọ́