Àṣà Burúkú
Àwọn àṣà burúkú wo ló yẹ káwa Kristẹni máa yẹra fún?
Àbẹ̀tẹ́lẹ̀
Ẹk 23:8; Sm 26:9, 10; Owe 17:23
Tún wo Di 10:17; 16:19; Sm 15:1, 5
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
1Sa 8:1-5—Dípò káwọn ọmọ wòlíì Sámúẹ́lì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere bàbá wọn, ńṣe ni wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po
Ne 6:10-13—Àwọn ọ̀tá gba Ṣemáyà pé kó lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké kó lè dẹ́rù ba Gómìnà Nehemáyà, kí iṣẹ́ Jèhófà lè dúró
Àjẹkì
Tún wo Lk 21:34, 35
Àríyá aláriwo
Àwòrán Ìṣekúṣe
Wo “Àwòrán Ìṣekúṣe”
Fífi ọ̀rọ̀ dídùn pọ́nni
Job 32:21, 22; Sm 5:9; 12:2, 3; Owe 26:24-28; 29:5
Tún wo Owe 28:23; 1Tẹ 2:3-6
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Lk 18:18, 19—Jésù ò fẹ́ kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ dídùn pọ́n òun
Iṣe 12:21-23—Ọba Hẹ́rọ́dù Ágírípà kú torí pé ó gbà kí wọ́n pé òun ní ọlọ́run
Fífọ́nnu
Wo “Fífọ́nnu”
Ìbánidíje
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mk 9:33-37; 10:35-45—Léraléra ni Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wí torí pé wọ́n máa ń bára wọn jiyàn lórí ẹni tó jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn
3Jo 9, 10—Díótíréfè fẹ́ “fi ara rẹ̀ ṣe olórí láàárín” àwọn ará
Ìbọ̀rìṣà
Wo “Ìbọ̀rìṣà”
Ìfiniṣẹ̀sín
Tún wo Owe 17:5; 22:10; 2Pe 3:3, 4
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
2Kr 36:15-21—Ọlọ́run fìyà jẹ àwọn èèyàn ẹ̀ tó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ torí pé wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́
Job 12:4; 17:2; 21:3; 34:7—Àwọn èèyàn ń fi Jóòbù ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tó ń dojú kọ àdánwò tó le gan-an
Ìjà
Wo “Ìjà”
Ìlọ́nilọ́wọ́gbà
Sm 62:10; 1Kọ 5:10, 11; 6:9, 10
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jer 22:11-17—Jèhófà fìyà jẹ Ọba Ṣálúmù (Jèhóáhásì) torí pé ó jẹ́ alọ́nilọ́wọ́gbà, ó sì tún dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an
Lk 19:2, 8—Sákéù tó jẹ́ olórí àwọn agbowó orí máa ń fipá gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn, àmọ́ ó ronú pìwà dà, ó sì ṣèlérí pé òun máa dá àwọn owó náà pa dà
Iṣe 24:26, 27—Gómìnà Fẹ́líìsì ń retí pé kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún òun ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò fún un
Ìmutípara; ọtí àmujù
Owe 20:1; 23:20, 29-35; 1Kọ 5:11; 6:9, 10
Tún wo Ef 5:18; 1Ti 3:8; Tit 2:3; 1Pe 4:3
Tún wo “Ọtí Mímu”
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jẹ 9:20-25—Hámù àti Kénáánì ọmọ ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an torí pé Nóà mutí yó
Da 5:1-6, 30—Ọba Bẹliṣásárì kú, ìjọba ẹ̀ sì dópin torí pé ó pẹ̀gàn Jèhófà nígbà tó mutí yó
Ìpànìyàn
Tún wo Mt 5:21, 22; Mk 7:21
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jẹ 4:4-16—Dípò kí Kéènì gba ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fún un, ńṣe ló pa arákùnrin ẹ̀ Ébẹ́lì tó jẹ́ olódodo
1Ọb 21:1-26; 2Ọb 9:26—Torí pé Ọba Áhábù àti Ayaba Jésíbẹ́lì jẹ́ olójú kòkòrò tí wọ́n sì tún burú gan-an, wọ́n pa Nábótì àtàwọn ọmọ ẹ̀
Ìpínyà; ẹ̀ya ìsìn
Irọ́; bíbanijẹ́
Wo “Irọ́”
Irọ́; kéèyàn máa tanni jẹ
Wo “Irọ́”
Ìwà àìnítìjú; ìwà àìmọ́; ìṣekúṣe; àgbèrè
Wo “Ìṣekúṣe”
Kéèyàn máa fa wàhálà; ìwà ipá
Tún wo 1Ti 3:2, 3; Tit 1:7
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Ẹk 21:22-27—Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá hùwà ipá, tó sì ṣe ẹlòmíì léṣe tàbí tó pààyàn
Kéèyàn máa halẹ̀ mọ́ àwọn míì
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Iṣe 4:15-21—Ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù torí wọn ò fẹ́ kí wọ́n máa wàásù mọ́
Kéèyàn máa kùn tàbí ráhùn
Tún wo Nọ 11:1
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Nọ 14:1-11, 26-30—Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kùn sí Mósè àti Áárónì, àmọ́ lójú Jèhófà, òun gangan ni wọ́n ń kùn sí
Jo 6:41-69—Àwọn Júù kùn sí Jésù; àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sì fi í sílẹ̀
Lílo ẹ̀jẹ̀ lọ́nà tí kò bá òfin Ọlọ́run mu
Jẹ 9:4; Di 12:16, 23; Iṣe 15:28, 29
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
1Sa 14:32-34—Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà torí wọ́n jẹ ẹran láì da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀
Olè
Wo “Olè”
Ọ̀rọ̀ èébú
Tún wo Ẹk 22:28; Onw 10:20; Jud 8
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
2Sa 16:5-8; 1Ọb 2:8, 9, 44, 46—Ṣíméì pẹ̀gàn ẹni àmì òróró Jèhófà, ó sì jìyà ẹ̀