ORIN 161
Inú Mi Ń Dùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Rẹ
- 1. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi - Ní inú Odò Jọ́dánì, - Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ - Ni láti ṣe ìfẹ́ Jáà. - Ó borí ìdẹwò Sátánì. - Ó fi ìtara wàásù. - Ó ń láyọ̀ torí pó ń ṣèfẹ́ Jáà. - Èmi náà ti pinnu pé: - (ÈGBÈ) - Màá fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ Baba. - Ẹnu mi yóò máa ròyìn rẹ. - Mò ń láyọ̀ gan-an látọkàn wá, - Bí mo ṣe ń ṣe ìfẹ́ rẹ. - Màá fayé mi sìn ọ́ Baba. - Ìwọ l’Orísun ayọ̀ mi. - Ìfẹ́ tòótọ́ lo ní sí mi. - Títí láé nìyìn rẹ máa - Wà lẹ́nu mi! 
- 2. Bí mo ṣe wá mọ̀ ọ́ Jèhófà, - Ayé mi ti wá dára sí i. - Mo fi gbogbo ayé mi fún ọ. - Tìrẹ ni màá máa ṣe láé. - Mò ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará, - Tí a jọ ń ṣe ìfẹ́ rẹ. - Gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ, - Ni màá kéde fáráyé. - (ÈGBÈ) - Màá fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ Baba. - Ẹnu mi yóò máa ròyìn rẹ. - Mò ń láyọ̀ gan-an látọkàn wá, - Bí mo ṣe ń ṣe ìfẹ́ rẹ. - Màá fayé mi sìn ọ́ Baba. - Ìwọ l’Orísun ayọ̀ mi. - Ìfẹ́ tòótọ́ lo ní sí mi. - Títí láé nìyìn rẹ máa - Wà lẹ́nu mi! - Màá fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ!