Ẹyẹ Penguin: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda John R. Peiniger
Friday
“Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù”—1 Kọ́ríńtì 13:4
Àárọ̀
- 9:20 Fídíò Orin 
- 9:30 Orin No. 66 àti Àdúrà 
- 9:40 Ọ̀RỌ̀ ALÁGA: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa “Ní Sùúrù”? (Jémíìsì 5:7, 8; Kólósè 1:9-11; 3:12) 
- 10:10 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: “Ohun Gbogbo Ni Àkókò Wà Fún” - • Máa Ronú Nípa Bí Jèhófà Ṣe Máa Ń Fara Balẹ̀ Ṣe Nǹkan (Oníwàásù 3:1-8, 11) 
- • Ó Máa Ń Gba Àkókò Káwa Àtẹnì Kan Tó Di Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́ (Òwe 17:17) 
- • Ó Máa Ń Gba Àkókò Kí Òtítọ́ Tó Jinlẹ̀ Lọ́kàn Èèyàn (Máàkù 4:26-29) 
- • Ó Máa Ń Gba Àkókò Kọ́wọ́ Wa Tó Lè Tẹ Àfojúsùn Wa (Oníwàásù 11:4, 6) 
 
- 11:05 Orin 143 àti Ìfilọ̀ 
- 11:15 BÍBÉLÌ KÍKÀ BÍ ẸNI ṢE ERÉ ÌTÀN: Dáfídì Fi Sùúrù Dúró De Jèhófà (1 Sámúẹ́lì 24:2-15; 25:1-35; 26:2-12; Sáàmù 37:1-7) 
- 11:45 Ṣé O Mọyì Bí Sùúrù Ọlọ́run Ṣe Pọ̀ Tó? (Róòmù 2:4, 6, 7; 2 Pétérù 3:8, 9; Ìfihàn 11:18) 
- 12:15 Orin 147 àti Àkókò Ìsinmi 
Ọ̀sán
- 1:35 Fídíò Orin 
- 1:45 Orin 17 
- 1:50 Máa Ṣe Sùúrù Bíi ti Jésù (Hébérù 12:2, 3) 
- 2:10 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn tí Jèhófà Bù Kún Torí Pé Wọ́n Ní Sùúrù - • Ábúráhámù àti Sérà (Hébérù 6:12) 
- • Jósẹ́fù (Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9) 
- • Jóòbù (Jémíìsì 5:11) 
- • Módékáì àti Ẹ́sítà (Ẹ́sítà 4:11-16) 
- • Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì (Lúùkù 1:6, 7) 
- • Pọ́ọ̀lù (Ìṣe 14:21, 22) 
 
- 3:10 Orin 11 àti Ìfilọ̀ 
- 3:20 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: Àwọn Nǹkan tí Jèhófà Dá Kọ́ Wa Pé Ó Máa Ń Ṣe Nǹkan Lásìkò - • Àwọn Ewéko (Mátíù 24:32, 33) 
- • Àwọn Ẹ̀dá Inú Òkun (2 Kọ́ríńtì 6:2) 
- • Àwọn Ẹyẹ (Jeremáyà 8:7) 
- • Àwọn Kòkòrò (Òwe 6:6-8; 1 Kọ́ríńtì 9:26) 
- • Àwọn Ẹranko (Oníwàásù 4:6; Fílípì 1:9, 10) 
 
- 4:20 “Ẹ Ò Mọ Ọjọ́ Tàbí Wákàtí Náà” (Mátíù 24:36; 25:13, 46) 
- 4:55 Orin 27 àti Àdúrà Ìparí