February
Thursday, February 1
Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.—Jòh. 15:12.
Kí ni ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní fẹ́ ká mọ̀? Bí Jésù ṣe ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ṣàlàyé pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà ju ara wa lọ, ká sì ṣe tán láti kú nítorí wọn tó bá jẹ́ ohun tó gbà nìyẹn. Bíbélì kọ́ wa pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà tí ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn gan-an, díẹ̀ lára ẹ̀ ni: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.” (Mát. 22:39) “Ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pét. 4:8) “Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé.” (1 Kọ́r. 13:8) Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí àtàwọn míì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an, ó sì yẹ ká máa fi hàn sáwọn èèyàn. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìfẹ́ tòótọ́ ti wá, àwọn tó bá fún ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ nìkan, tó sì ṣojúure sí ló máa ń fìfẹ́ hàn sí ara wọn. (1 Jòh. 4:7) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ní ìfẹ́ gidi láàárín ara wọn. Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ti dá àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ mọ̀ torí pé à ń fìfẹ́ gidi hàn láàárín ara wa. w23.03 27-28 ¶5-8
Friday, February 2
A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.—Lúùkù 7:48.
Ṣé ó wù ẹ́ kó o túbọ̀ máa dárí ji àwọn èèyàn? O lè kọ́kọ́ kà nípa àwọn tó dárí ji àwọn èèyàn nínú Bíbélì àtàwọn tí ò ṣe bẹ́ẹ̀, kó o sì ronú lórí ohun tó o kà. Wo àpẹẹrẹ Jésù. Ó máa ń dárí ji àwọn èèyàn fàlàlà. (Lúùkù 7:47) Yàtọ̀ síyẹn, kì í wo àṣìṣe wọn, ibi tí wọ́n dáa sí ló máa ń wò. Àmọ́ àwọn Farisí ò dà bíi Jésù torí wọ́n máa ń “ka àwọn míì sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.” (Lúùkù 18:9) Lẹ́yìn tó o bá ti ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ yẹn, bi ara ẹ pé: ‘Kí ni mo máa ń kíyè sí lára àwọn èèyàn? Ṣé ìwà wọn tó dáa ni mo máa ń wò àbí ìwà wọn tó kù díẹ̀ káàtó?’ Tí kò bá rọrùn fún ẹ láti dárí ji ẹnì kan, kọ àwọn ìwà tó dáa tẹ́ni náà ní sílẹ̀. Lẹ́yìn náà bi ara ẹ pé: ‘Ojú wo ni Jésù fi ń wo ẹni yìí? Ṣé Jésù máa dárí jì í?’ Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti dárí ji ẹni náà. Ó lè kọ́kọ́ ṣòro fún wa láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá. Àmọ́ tá a bá ń sapá tá ò sì jẹ́ kó sú wa, tó bá yá, á rọrùn fún wa láti máa dárí ji àwọn èèyàn. w22.04 23 ¶6
Saturday, February 3
Ó rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti fi [àwọn ìran náà hàn] . . . nípasẹ̀ àwọn àmì.—Ìfi. 1:1.
Èdè àpèjúwe ni ìwé Ìfihàn fi ṣàlàyé àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Ó pe àwọn kan ní ẹranko ẹhànnà. Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù rí “ẹranko kan tó ń jáde látinú òkun, ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje.” (Ìfi. 13:1) Lẹ́yìn ìyẹn, ó rí “ẹranko míì tó ń jáde látinú [ilẹ̀].” Ẹranko yẹn ń sọ̀rọ̀ bíi dírágónì, ó sì mú kí “iná wá láti ọ̀run.” (Ìfi. 13:11-13) Lẹ́yìn náà, ó tún rí ẹranko míì tó yàtọ̀, ìyẹn “ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò,” tí aṣẹ́wó kan jókòó sórí ẹ̀. Àwọn ẹranko ẹhànnà mẹ́ta yìí ṣàpẹẹrẹ àwọn ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká mọ ohun tí wọ́n jẹ́. (Ìfi. 17:1, 3) Ó yẹ ká mọ ìtumọ̀ èdè àpèjúwe tí ìwé Ìfihàn lò. Ọ̀nà tó dáa jù láti gbà mọ̀ wọ́n ni pé kí Bíbélì fúnra ẹ̀ ṣàlàyé. Àwọn ìwé míì nínú Bíbélì ṣàlàyé ọ̀pọ̀ èdè àpèjúwe tí wọ́n lò nínú ìwé Ìfihàn. w22.05 8-9 ¶3-4
Sunday, February 4
Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ . . . nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.—Mát. 22:37.
Ọjọ́ ogbó àti àìlera ò jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́. Tó o bá ti ń rẹ̀wẹ̀sì torí pé o ò lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́, bi ara ẹ pé, ‘Kí ni Jèhófà fẹ́ kí n ṣe?’ Jèhófà fẹ́ kó o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe bí agbára ẹ bá ṣe gbé e tó. Ká sọ pé arábìnrin kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún ti ń rẹ̀wẹ̀sì torí pé kò lè ṣe tó bó ṣe máa ń ṣe nígbà tó lé lẹ́ni ogójì (40) ọdún. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, ó rò pé ohun tóun ń ṣe fún Jèhófà ò tó. Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn lóòótọ́? Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, tí arábìnrin yìí bá lè máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe fún Jèhófà nígbà tó lé lẹ́ni ogójì ọdún, tó sì tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún, ó dájú pé ó ṣì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe fún Jèhófà. Torí náà, tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, Jèhófà máa sọ fún àwa náà pé: “O káre láé!” (Fi wé Mátíù 25:20-23.) Àá máa láyọ̀ tó bá jẹ́ pé ohun tá a lè ṣe la gbájú mọ́ dípò ohun tá ò lè ṣe. w22.04 10 ¶2; 11 ¶4-6
Monday, February 5
Mo rí ìlú mímọ́ náà, Jerúsálẹ́mù Tuntun.—Ìfi. 21:2.
Ìfihàn orí 21 fi àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì wé ìlú kan tó rẹwà, ó pe ìlú náà ní “Jerúsálẹ́mù Tuntun.” Ìlú náà ní òkúta ìpìlẹ̀ méjìlá tí wọ́n kọ “orúkọ méjìlá (12) àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” sí. (Ìfi. 21:10-14; Éfé. 2:20) Kò sí ìlú míì tó dà bí ìlú yìí. Ògidì wúrà ni wọ́n fi ṣe ojú ọ̀nà ẹ̀, ó ní ẹnubodè méjìlá tí wọ́n fi péálì ṣe, oríṣiríṣi òkúta iyebíye ni wọ́n fi ṣe àwọn ìpìlẹ̀ àti ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́, igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìlú náà sì dọ́gba. (Ìfi. 21:15-21) Síbẹ̀, ohun kan wà tí ò sí níbẹ̀! Ẹ gbọ́ ohun tí Jòhánù sọ lẹ́yìn náà, ó ní: “Mi ò rí tẹ́ńpìlì kankan nínú rẹ̀, torí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹ́ńpìlì rẹ̀ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Ìlú náà ò nílò kí oòrùn tàbí òṣùpá tàn sórí rẹ̀, torí ògo Ọlọ́run mú kó mọ́lẹ̀ rekete, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sì ni fìtílà rẹ̀.” (Ìfi. 21:22, 23) Àwọn tó jẹ́ Jerúsálẹ́mù Tuntun náà máa láǹfààní láti máa rí Jèhófà.—Héb. 7:27; Ìfi. 22:3, 4. w22.05 17-18 ¶14-15
Tuesday, February 6
Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà . . . Bí Jèhófà ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.—Kól. 3:13.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, Afúnnilófin àti Onídàájọ́ wa, ó tún jẹ́ Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa. (Sm. 100:3; Àìsá. 33:22) Tá a bá ṣẹ Jèhófà, tá a sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kì í ṣe pé Jèhófà lè dárí jì wá nìkan ni, àmọ́ ó máa ń wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 86:5) Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, torí náà ó gbẹnu wòlíì Àìsáyà sọ pé: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, wọ́n máa di funfun bíi yìnyín.” (Àìsá. 1:18) Torí pé aláìpé ni gbogbo wa, kò sí ká má sọ tàbí ṣe nǹkan tó máa dun àwọn ẹlòmíì. (Jém. 3:2) Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí àárín wa má gún. Ohun tó sì máa jẹ́ kí ìyẹn ṣeé ṣe ni pé ká máa dárí ji ara wa. (Òwe 17:9; 19:11; Mát. 18:21, 22) Tẹ́nì kan bá sọ tàbí ṣe nǹkan kékeré kan tó dùn wá, Jèhófà fẹ́ ká dárí jì í. Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà máa ń dárí jì wá “fàlàlà.”—Àìsá. 55:7. w22.06 8 ¶1-2
Wednesday, February 7
Ẹ . . . máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí ìgbàgbọ́ àti sùúrù mú kí wọ́n jogún àwọn ìlérí náà.—Héb. 6:12.
Kò yẹ ká máa fi ohun tá ò lè ṣe wé ohun táwọn míì lè ṣe, àmọ́ a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, a kì í ṣe ẹni pípé bíi ti Jésù, àmọ́ a lè fìwà jọ ọ́. (1 Pét. 2:21) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, àjọṣe àwa àti Jèhófà á túbọ̀ gún régé. Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin àtobìnrin aláìpé tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ló wà nínú Bíbélì, ó sì yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Àpẹẹrẹ kan ni Ọba Dáfídì tí Jèhófà pè ní “ẹni tí ọkàn mi fẹ́.” (Ìṣe 13:22) Dáfídì ṣe àwọn àṣìṣe ńlá kan. Síbẹ̀, àpẹẹrẹ tó dáa ló jẹ́ fún wa. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò dá ara ẹ̀ láre. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gba ìbáwí líle tí wọ́n fún un, ó sì fi hàn pé òun kábàámọ̀ ohun tóun ṣe. Torí náà, Jèhófà dárí jì í.—Sm. 51:3, 4, 10-12. w22.04 13 ¶11-12
Thursday, February 8
Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.—Jóòbù 2:4.
Bíbélì sọ pé ọ̀tá ni ikú jẹ́. (1 Kọ́r. 15:25, 26) Ẹ̀rù ikú lè máa bà wá tára wa ò bá yá tàbí tí ẹnì kan nínú ìdílé wa bá ń ṣàìsàn tó le. Kí nìdí tí ẹ̀rù ikú fi ń bà wá? Ìdí ni pé Jèhófà ò dá wa pé ká máa kú, ṣe ló fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa títí láé. (Oníw. 3:11) Síbẹ̀, tá a bá fojú tó tọ́ wò ó, tá ò sì bẹ̀rù ikú ju bó ṣe yẹ lọ, ìyẹn á jẹ́ ká máa bójú tó ara wa. Àá máa jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore, àá sì máa ṣe eré ìmárale. Yàtọ̀ síyẹn, àá máa lọ ṣàyẹ̀wò ara wa lọ́dọ̀ àwọn dókítà, àá lo àwọn oògùn tó bá yẹ lásìkò, a ò sì ní máa fi ẹ̀mí ara wa wewu. Sátánì mọ̀ pé a ò fẹ́ kú. Ó sọ pé tá ò bá fẹ́ kú, gbogbo nǹkan la máa yááfì títí kan àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. (Jóòbù 2:5) Ẹ ò rí i pé onírọ́ ni Sátánì! Síbẹ̀, torí pé Sátánì ni “ẹni tó lè fa ikú,” ó máa ń fìyẹn dẹ́rù bà wá ká lè fi Jèhófà sílẹ̀.—Héb. 2:14, 15. w22.06 18 ¶15-16
Friday, February 9
Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ìbínú.—Éfé. 4:26.
Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, ó lè gba pé ká máa pàdé ní àwùjọ kéékèèké. Torí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an ká jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín wa báyìí. Sátánì ni ọ̀tá tó yẹ ká bá jà, kì í ṣe àwọn ará wa. Máa gbójú fo àṣìṣe àwọn ará tàbí kó o tètè yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín yín. (Òwe 19:11) Tẹ́ ẹ bá rí i pé ó yẹ kẹ́ ẹ ran ara yín lọ́wọ́, ẹ tètè ṣe bẹ́ẹ̀. (Títù 3:14) Ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ṣe fún arábìnrin kan tí wọ́n jọ wà láwùjọ iṣẹ́ ìwàásù ṣe gbogbo àwọn tó wà láwùjọ yẹn láǹfààní torí ó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ wà níṣọ̀kan bí ìdílé kan. (Sm. 133:1) Àìmọye àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni wọ́n ń sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè wọn. Wọ́n ti ju àwọn kan sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Torí náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn ará yẹn àtàwọn ìdílé wọn títí kan àwọn ará tí wọ́n lo òmìnira wọn láti lọ bẹ̀ wọ́n wò bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba lè fi ọlọ́pàá mú wọn. Wọ́n máa ń mú ohun táwọn ará tó wà lẹ́wọ̀n nílò lọ fún wọn. Wọ́n máa ń fi Bíbélì tù wọ́n nínú, wọ́n sì máa ń lọ gbèjà wọn nílé ẹjọ́. (Kól. 4:3, 18) Torí náà, máa gbàdúrà fáwọn ará torí iṣẹ́ kékeré kọ́ ni àdúrà ẹ ń ṣe!—2 Tẹs. 3:1, 2; 1 Tím. 2:1, 2. w22.12 26-27 ¶15-16
Saturday, February 10
Ṣé ìwọ tó ń kọ́ ẹlòmíì ti kọ́ ara rẹ?—Róòmù 2:21.
Àwọn ọmọ sábà máa ń fara wé àwọn òbí wọn. Ká sòótọ́, kò sí òbí tó jẹ́ ẹni pípé. (Róòmù 3:23) Síbẹ̀, àwọn òbí tó bá gbọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn. Bàbá kan sọ pé: “Wọ́n dà bíi fóòmù tó máa ń fa nǹkan olómi mu.” Ó tún sọ pé: “Tá ò bá ṣe ohun tá à ń kọ́ wọn, wọ́n á sọ fún wa.” Torí náà, tá a bá fẹ́ káwọn ọmọ wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìfẹ́ táwa náà ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ lágbára, kí wọ́n sì rí i. Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn òbí lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Arákùnrin Andrew tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) sọ pé: “Gbogbo ìgbà làwọn òbí mi máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé àdúrà ṣe pàtàkì gan-an. Alaalẹ́ ni Dádì máa ń gbàdúrà pẹ̀lú mi kódà tí mo bá ti dá gbàdúrà tèmi. . . . Ìyẹn ti mú kó rọrùn fún mi láti máa gbàdúrà sí Jèhófà kí n sì gbà pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ mi ni.” Ẹ̀yin òbí, ẹ máa rántí pé ìfẹ́ tí ẹ ní fún Jèhófà máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ gan-an káwọn náà lè nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. w22.05 28 ¶7-8
Sunday, February 11
Ìrìbọmi . . . ń gbà yín là báyìí.—1 Pét. 3:21.
Ọ̀kan lára ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ká lè ṣèrìbọmi ni pé ká ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa tọkàntọkàn. (Ìṣe 2:37, 38) Tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, á rọrùn fún wa láti yí pa dà pátápátá. Ṣé o ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tínú Jèhófà ò dùn sí, irú bí ìṣekúṣe, lílo tábà, ọ̀rọ̀ èébú àti ìsọkúsọ? (1 Kọ́r. 6:9, 10; 2 Kọ́r. 7:1; Éfé. 4:29) Máa gbìyànjú láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Sọ fún ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn alàgbà ìjọ ẹ pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n tọ́ ẹ sọ́nà. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó o sì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ, sọ fún wọn pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jáwọ́ nínú ìwà tí ò ní jẹ́ kó o ṣèrìbọmi. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa jọ́sìn Jèhófà déédéé. Ara ìjọsìn náà ni pé ká máa lọ sípàdé déédéé, ká sì máa lọ́wọ́ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. (Héb. 10:24, 25) Tó o bá sì ti kúnjú ìwọ̀n láti máa wàásù, máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. w23.03 10-11 ¶14-16
Monday, February 12
Jèhófà Ọlọ́run wá sọ fún ejò náà pé: “Torí ohun tí o ṣe yìí, ègún ni fún ọ.”—Jẹ́n. 3:14.
Àwọn tí àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15 sọ nípa wọn ni: “Ejò” kan àti “ọmọ” ejò náà. Tó bá jẹ́ pé ejò gidi ni ejò náà, ó dájú pé ohun tí Jèhófà sọ ní ọgbà Édẹ́nì kò ní yé e. Torí náà, ẹni tí Ọlọ́run dá lẹ́jọ́ yẹn ní láti jẹ́ ẹ̀dá kan tó gbọ́n. Ta wá ni ejò náà? Ìfihàn 12:9 jẹ́ ká mọ ẹni tí ejò náà jẹ́. Ó sọ pé “ejò àtijọ́ náà” ni Sátánì Èṣù. Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ọmọ,” ó túmọ̀ sí àwọn tó ń ronú, tí wọ́n sì ń hùwà bí ẹnì kan tí wọ́n lè pè ní bàbá wọn. Torí náà, ọmọ ejò náà ni àwọn áńgẹ́lì àtàwọn èèyàn tí wọ́n ń hùwà bíi Sátánì, tí wọ́n sì ń ta ko Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀ lọ́run nígbà ayé Nóà wà lára wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn burúkú tí wọ́n ń hùwà bí Èṣù bàbá wọn wà lára wọn.—Jẹ́n. 6:1, 2; Jòh. 8:44; 1 Jòh. 5:19; Júùdù 6. w22.07 14-15 ¶4-5
Tuesday, February 13
Ẹ máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.—Fílí. 1:10.
Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, ìyà tó jẹ ò sì kéré rárá. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń gba tàwọn ará rò tí wọ́n bá níṣòro, tó sì máa ń ṣàánú wọn. Ìgbà kan wà tí owó tán lọ́wọ́ ẹ̀, ìyẹn sì gba pé kó máa ṣiṣẹ́ kó lè pèsè fún ara ẹ̀ àtàwọn tó wà pẹ̀lú ẹ̀. (Ìṣe 20:34) Iṣẹ́ àgọ́ pípa ni Pọ́ọ̀lù ń ṣe. Nígbà tó dé Kọ́ríńtì, òun pẹ̀lú Ákúílà àti Pírísílà ni wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àgọ́ pípa. Àmọ́ “gbogbo sábáàtì” ló fi máa ń wàásù fáwọn Júù àtàwọn Gíríìkì. Nígbà tí Sílà àti Tímótì tún wá sọ́dọ̀ ẹ̀, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ọwọ́ Pọ́ọ̀lù dí gan-an.” (Ìṣe 18:2-5) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe máa fayé ẹ̀ sin Jèhófà ló ṣe pàtàkì lójú ẹ̀, kò jẹ́ káwọn nǹkan míì gba òun lọ́kàn. Torí pé Pọ́ọ̀lù ò ṣọ̀lẹ tó sì tún ṣiṣẹ́ kára kó lè gbọ́ bùkátà ara ẹ̀, ìyẹn jẹ́ kẹ́nu ẹ̀ gbà á láti fún àwọn ará níṣìírí. Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àníyàn bí wọ́n ṣe máa pèsè fún ìdílé wọn mú kí wọ́n pa “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” tì, ìyẹn gbogbo apá ìjọsìn wọn. w22.08 20 ¶3
Wednesday, February 14
A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.—Máàkù 13:10.
Lónìí, Ọlọ́run fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa wàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀ níbi gbogbo láyé. (1 Tím. 2:3, 4) Iṣẹ́ Jèhófà ni iṣẹ́ yìí, ó sì ṣe pàtàkì gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi ní kí Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n máa bójú tó iṣẹ́ náà. Torí pé Jésù ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù yìí, ó dájú pé kí òpin tó dé, a máa ṣiṣẹ́ náà parí bí Jèhófà ṣe fẹ́. (Mát. 24:14) Kí ló jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀? Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ lórí òkè Gálílì. Ó sọ fún wọn pé: “Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.” Àmọ́ kíyè sí ohun tó sọ tẹ̀ lé e, ó ní: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:18, 19) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ara iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún Jésù ni àṣẹ tó fún un pé kó máa darí iṣẹ́ ìwàásù. Jésù á sì máa darí iṣẹ́ ìwàásù náà títí di àkókò wa yìí. w22.07 8 ¶1, 3; 9 ¶4
Thursday, February 15
Wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀, tí wọ́n á sì jáde wá, àwọn tó ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè.—Jòh. 5:28, 29.
Àwọn olódodo tí wọ́n ṣe rere kí wọ́n tó kú máa ní “àjíǹde ìyè” torí pé orúkọ wọn ti wà nínú ìwé ìyè. Ìyẹn túmọ̀ sí pé àjíǹde “àwọn tó ṣe ohun rere” tí Jòhánù 5:29 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ náà ni àjíǹde “àwọn olódodo” tí Ìṣe 24:15 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Òye tuntun tá a ní yìí bá ohun tó wà nínú Róòmù 6:7 mu. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Ẹni tó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Jèhófà ti pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn olódodo yẹn rẹ́ nígbà tí wọ́n kú, ṣùgbọ́n kò gbàgbé gbogbo iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe. (Héb. 6:10) Àmọ́ àwọn olódodo tá a jí dìde yìí gbọ́dọ̀ máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó tí wọn ò bá fẹ́ kí orúkọ wọn kúrò nínú ìwé ìyè. w22.09 18 ¶13, 15
Friday, February 16
Gbogbo ohun [tí Jèhófà] bá ṣe ló ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.—Sm. 33:4.
Wòlíì Dáníẹ́lì fi hàn pé òun ṣeé fọkàn tán, torí náà àpẹẹrẹ rere ló jẹ́ fún wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Bábílónì mú un nígbèkùn, kò pẹ́ táwọn èèyàn fi rí i pé ó ṣeé fọkàn tán. Àwọn èèyàn túbọ̀ fọkàn tán Dáníẹ́lì nígbà tí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti sọ ìtúmọ̀ àlá Nebukadinésárì ọba Bábílónì. (Dán. 4:20-22, 25) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Dáníẹ́lì tún fi hàn pé òun ṣeé fọkàn tán nígbà tó túmọ̀ ọ̀rọ̀ àjèjì kan tó fara hàn lára ògiri ààfin ọba Bábílónì. (Dán. 5:5, 25-29) Nígbà tó yá, Dáríúsì ará Mídíà àtàwọn ìjòyè ẹ̀ tún kíyè sí i pé “ẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀” wà nínú Dáníẹ́lì. Wọ́n gbà pé Dáníẹ́lì “ṣeé fọkàn tán, kì í fiṣẹ́ ṣeré, kò sì hùwà ìbàjẹ́ rárá.” (Dán. 6:3, 4) Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ẹni tó ṣeé fọkàn tán?’ Táwọn èèyàn bá rí i pé a ṣeé fọkàn tán, wọ́n á yin Jèhófà lógo. w22.09 8-9 ¶2-4
Saturday, February 17
Ẹ máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ.—Éfé. 5:1.
A máa jàǹfààní tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tíì bá ṣẹlẹ̀ ká sọ pé àwọn ilé iṣẹ́ tó ń bá àwọn èèyàn kọ́lé ò ní ìdíwọ̀n pàtó tí wọ́n ń lò, àmọ́ tí kálukú wọn ń ṣe ohun tó wù ú. Jàǹbá ló máa yọrí sí. Tí àwọn dókítà náà ò bá sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà fún ìtọ́jú ara, àwọn aláìsàn lè kú. Torí náà, ó dájú pé ìlànà pàtó kan gbọ́dọ̀ wà táwọn èèyàn á máa tẹ̀ lé kí jàǹbá má bàa ṣẹlẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwọn ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ máa ń dáàbò bò wá. Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀. Ó ṣèlérí fún wọn pé: “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Sm. 37:29) Ẹ wo bí ayé ṣe máa rí tí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà. Gbogbo èèyàn máa wà níṣọ̀kan, àlàáfíà máa wà, inú wa á sì máa dùn. Bí Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa nìyẹn. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú ká nífẹ̀ẹ́ òdodo! w22.08 27-28 ¶6-8
Sunday, February 18
Máa ronú bó ṣe tọ́ nínú ohun gbogbo.—2 Tím. 4:5.
Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tó dùn wá, ó lè jẹ́ kó nira fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀. Báwo la ṣe lè borí irú àwọn ìṣòro yẹn? Ó yẹ ká máa ronú bó ṣe tọ́, ká wà lójúfò, ká sì dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. Tá a bá fẹ́ máa ronú bó ṣe tọ́, a gbọ́dọ̀ fara balẹ̀, ká máa ronú jinlẹ̀, ká sì máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní máa fi bí nǹkan ṣe rí lára wa hùwà. Ẹnì kan lára àwọn alábòójútó lè ṣe nǹkan tí ò dáa sí ẹ, arákùnrin náà lè má mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó ṣe yẹn. (Róòmù 3:23; Jém. 3:2) Síbẹ̀, ohun tó ṣe yẹn lè múnú bí ẹ gan-an. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé, ‘Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló ń darí ètò yìí lóòótọ́, kò yẹ kí arákùnrin yìí hu irú ìwà báyìí sí mi.’ Ohun tí Sátánì sì fẹ́ ká máa rò gan-an nìyẹn. (2 Kọ́r. 2:11) Irú èrò bẹ́ẹ̀ lè mú ká fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká ṣọ́ra ká má bàa di àwọn èèyàn sínú. w22.11 20 ¶1, 3; 21 ¶4
Monday, February 19
Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Sm. 27:14.
Jèhófà jẹ́ ká ní ìrètí àgbàyanu pé a máa wà láàyè títí láé. Àwọn kan nírètí láti di ẹni ẹ̀mí táá máa gbé títí láé lọ́run. (1 Kọ́r. 15:50, 53) Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú wa ló nírètí àtigbé ayé níbi tí kò ti ní sí àìsàn mọ́, tá à sì máa láyọ̀ títí láé. (Ìfi. 21:3, 4) Torí náà, bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé, gbogbo wa la mọyì ìrètí tá a ní. Ìrètí tá a ní yìí dá wa lójú torí pé Jèhófà ló jẹ́ ká nírètí náà. (Róòmù 15:13) A mọ àwọn ìlérí tó ṣe fún wa, a sì mọ̀ pé kò sóhun tí Jèhófà sọ tí kò ní ṣẹ. (Nọ́ń. 23:19) Ó dá wa lójú pé ó wu Jèhófà kó ṣe àwọn ohun tó ṣèlérí fún wa, a sì mọ̀ pé ó lágbára láti ṣe àwọn nǹkan náà. Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan, ó sì fẹ́ ká fọkàn tán òun. Tí ìrètí tá a ní nínú Jèhófà bá dá wa lójú, àá lè fara da ìṣòro, àá sì máa láyọ̀, láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí. w22.10 24 ¶1-3
Tuesday, February 20
Ọlọ̀tẹ̀ èèyàn ni wọ́n, . . . wọn kò fẹ́ gbọ́ òfin Jèhófà.—Àìsá. 30:9.
Torí pé àwọn èèyàn náà kọ̀ láti gbọ́rọ̀ sí Jèhófà lẹ́nu, Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà máa jẹ́ kí àjálù dé bá wọn. (Àìsá. 30:5, 17; Jer. 25:8-11) Bó sì ṣe rí nìyẹn torí àwọn ará Bábílónì kó wọn lẹ́rú lọ sígbèkùn. Àmọ́ àwọn Júù kan wà lára wọn tó jẹ́ olóòótọ́, Àìsáyà sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìrètí wà fún wọn. Ó sọ fún wọn pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí Jèhófà máa gbà wọ́n sílẹ̀. (Àìsá. 30:18, 19) Ohun tí Jèhófà sì ṣe nìyẹn. Ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì. Àmọ́ kì í ṣe ojú ẹsẹ̀ ló gbà wọ́n sílẹ̀. Gbólóhùn náà “Jèhófà ń fi sùúrù dúró láti ṣojúure sí yín” fi hàn pé àkókò díẹ̀ máa kọjá kí Jèhófà tó gba àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sílẹ̀. Kódà, àádọ́rin (70) ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò nígbèkùn Bábílónì kó tó di pé Jèhófà gba àwọn tó kù sílẹ̀ láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù. (Àìsá. 10:21; Jer. 29:10) Nígbà tí wọ́n pa dà dé ìlú ìbílẹ̀ wọn, ẹkún wọn dayọ̀. w22.11 9 ¶4
Wednesday, February 21
Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo.—Mát. 5:10.
Lónìí, wọ́n ń ṣenúnibíni sáwọn ará wa láwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n sì ń fara dà á bíi tàwọn àpọ́sítélì ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Léraléra làwọn adájọ́ tó wà ní ilé ẹjọ́ gíga jù lọ àwọn Júù “pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù mọ́.” (Ìṣe 4:18-20; 5:27, 28, 40) Wọ́n mọ̀ pé ẹni tó láṣẹ jù lọ ló ‘pàṣẹ fún wọn pé káwọn wàásù fún àwọn èèyàn kí wọ́n sì jẹ́rìí kúnnákúnná’ nípa Kristi. (Ìṣe 10:42) Torí náà, Pétérù àti Jòhánù tó ṣojú fáwọn Kristẹni yòókù fìgboyà sọ pé Ọlọ́run làwọn máa fetí sí dípò àwọn adájọ́ yẹn àti pé àwọn ò ní yéé wàásù nípa Jésù. (Ìṣe 5:29) Lẹ́yìn táwọn Júù yẹn nà wọ́n tán, àwọn àpọ́sítélì kúrò nílé ẹjọ́ gíga jù lọ àwọn Júù, “wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù,” wọn ò sì dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró!—Ìṣe 5:41, 42. w22.10 12-13 ¶2-4
Thursday, February 22
Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.—Sm. 73:28.
Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ òtítọ́ nìkan la kọ́. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó pe àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ náà ní “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀.” Kì í ṣe pé ó fojú kéré “ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀,” kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi wé wàrà tó ń ṣe ọmọ ọwọ́ láǹfààní. (Héb. 5:12; 6:1) Ó tún rọ gbogbo àwọn Kristẹni pé kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ òtítọ́ nìkan ló yẹ kí wọ́n mọ̀, ó tún yẹ kí wọ́n mọ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jinlẹ̀. Ṣé ó ń wù ẹ́ kó o máa kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ nínú Bíbélì? Ṣé ó ń wù ẹ́ kó o nímọ̀ sí i, kó o sì túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé? Kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára wa láti kẹ́kọ̀ọ́. Ṣé bó ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn? Nígbà tó o wà nílé ìwé, ṣé o kọ́ bá a ṣe ń kàwé àti bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́? Ṣé o máa ń gbádùn bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ tó o sì ń rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́? Àbí ìwé kíkà tètè máa ń sú ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ lo nírú ìṣòro yẹn. Àmọ́ Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹni pípé ni, òun sì ni Olùkọ́ tó dáa jù lọ. w23.03 9-10 ¶8-10
Friday, February 23
Kí ìwà tútù yín mú kí ọ̀rọ̀ tó lè gbà yín là fìdí múlẹ̀ nínú yín.—Jém. 1:21.
Tá a bá ní ìwà tútù, àá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí ìwà wa pa dà. Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, tá ò sì fi ohun tá à ń kà nínú Bíbélì dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, ìgbà yẹn la máa kọ́ bá a ṣe lè fàánú àti ìfẹ́ hàn. Ìwà tá à ń hù sáwọn èèyàn máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá à ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí èrò wa pa dà. Torí pé àwọn Farisí ò jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wọ́n lọ́kàn, wọ́n máa ń “dá àwọn tí kò jẹ̀bi lẹ́bi.” (Mát. 12:7) Lọ́nà kan náà, ìwà tá à ń hù sáwọn èèyàn máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá à ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí èrò wa pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ó mọ́ wa lára láti máa sọ nípa ìwà tó dáa táwọn ẹlòmíì ní, àbí ibi tí wọ́n kù sí la máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀? Ṣé a máa ń fàánú hàn, ṣé a sì máa ń dárí ji àwọn èèyàn, àbí ṣe la máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, tá a sì ń dì wọ́n sínú? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ò ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí èrò ẹ, ìṣe ẹ àti bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ pa dà.—1 Tím. 4:12, 15; Héb. 4:12. w23.02 12 ¶13-14
Saturday, February 24
Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, ẹni tó ń sọ fún ọ pé, “Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.”—Àìsá. 41:13.
Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jósẹ́fù ará Arimatíà. Ẹni táwọn Júù bọ̀wọ̀ fún gan-an ni. Ó tún wà lára ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, ìyẹn ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù. Àmọ́ lásìkò tí Jésù ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Jósẹ́fù ò nígboyà. Jòhánù tiẹ̀ sọ pé ó “jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ tí kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí pé ó ń bẹ̀rù àwọn Júù.” (Jòh. 19:38) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù nífẹ̀ẹ́ ìhìn rere tí Jésù ń wàásù ẹ̀, kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun nígbàgbọ́ nínú Jésù torí ó lè máa ronú pé àwọn èèyàn ò ní bọ̀wọ̀ fún òun mọ́. Èyí ó wù ó jẹ́, Bíbélì sọ fún wa pé lẹ́yìn tí Jésù kú, Jósẹ́fù “fi ìgboyà wọlé lọ síwájú Pílátù, ó sì ní kó gbé òkú Jésù fún òun.” (Máàkù 15:42, 43) Ní báyìí, Jósẹ́fù ò bẹ̀rù mọ́ láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù lòun. Ṣé ìwọ náà máa ń bẹ̀rù àwọn èèyàn bíi ti Jósẹ́fù? w23.01 30 ¶13-14
Sunday, February 25
Aláyọ̀ ni àwọn èèyàn rẹ, aláyọ̀ sì ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ!—1 Ọba 10:8.
Òkìkí kàn dé ọ̀dọ̀ ọbabìnrin Ṣébà pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbádùn àlàáfíà, wọ́n sì ń rí gbogbo ohun tí wọ́n nílò bí Sólómọ́nì ṣe ń ṣàkóso wọn. Ni ọbabìnrin náà bá gbéra láti ìlú ẹ̀ tó jìnnà wá sí Jerúsálẹ́mù kó lè fojú ara ẹ̀ rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀. (1 Ọba 10:1) Ẹ̀yìn tó wo gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba Sólómọ́nì ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lókè yẹn. Àmọ́ ìtọ́wò lásán ni ohun táwọn èèyàn gbádùn nígbà àkóso Sólómọ́nì tá a bá fi wé ohun tí Jèhófà máa ṣe fáráyé nígbà tí Jésù Ọmọ rẹ̀ bá ń ṣàkóso. Gbogbo ọ̀nà ni Jésù fi ju Sólómọ́nì lọ. Aláìpé ni Sólómọ́nì, ó sì ṣe àwọn àṣìṣe ńlá tó kó àwọn èèyàn Ọlọ́run síṣòro. Àmọ́ alákòóso pípé ni Jésù, kì í sì í ṣàṣìṣe. (Lúùkù 1:32; Héb. 4:14, 15) Jésù ti fi hàn pé òun ò lè dẹ́ṣẹ̀ tàbí ṣe ohunkóhun tó máa pa àwọn olóòótọ́ èèyàn lára nínú ìjọba rẹ̀. Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run dá wa lọ́lá gan-an bó ṣe fi Jésù ṣe Ọba wa. w22.12 11 ¶9-10
Monday, February 26
Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì máa tẹrí ba, torí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí yín.—Héb. 13:17.
Kí ló yẹ ká ṣe tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ń jà níbi tá à ń gbé? Ó yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ tí wọ́n bá ní ká máa fọwọ́ wa, tí wọ́n bá ní ká máa jìnnà síra wa dáadáa, tí wọ́n bá ní ká máa wọ ìbòmú tàbí tí wọ́n bá ní ká sé ara wa mọ́lé nítorí àrùn náà. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ìyẹn á fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa. Nígbà míì tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn aládùúgbò wa àtàwọn oníròyìn lè sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Dípò kó jẹ́ pé “gbogbo ọ̀rọ̀” tá a bá gbọ́ la máa gbà gbọ́, ohun tí ìjọba àtàwọn dókítà bá sọ ló yẹ ká gbà gbọ́. (Òwe 14:15) Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń rí i dájú pé àwọn mọ òótọ́ nípa ọ̀rọ̀ kan kí wọ́n tó sọ bá a ṣe máa ṣe ìpàdé àti bá a ṣe máa wàásù. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń sọ fún wa, a ò ní kó ara wa àtàwọn míì síṣòro. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará àdúgbò máa rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé òfin ìjọba.—1 Pét. 2:12. w23.02 23 ¶11-12
Tuesday, February 27
Fetí sílẹ̀, kí o sì kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ.—Diu. 31:13.
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n tẹ̀ dó sí. Torí pé ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé jìnnà síra, ìyẹn lè jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti mọ bí nǹkan ṣe ń lọ fáwọn yòókù. Àmọ́ Jèhófà ṣètò pé kí wọ́n máa pé jọ látìgbàdégbà, kí wọ́n lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì ṣàlàyé ẹ̀ fún wọn. (Diu. 31:10-12; Neh. 8:2, 8, 18) Ẹ wo bí inú ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣe máa dùn tó nígbà tó bá dé Jerúsálẹ́mù, tó sì rí àìmọye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiẹ̀ tí wọ́n wá láti ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, kí wọ́n lè jọ́sìn Jèhófà! Ètò tí Jèhófà ṣe yìí ló jẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ wà níṣọ̀kan. Nígbà tó yá, wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì wà níbẹ̀. Olówó làwọn kan, àwọn kan ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, ibi tí wọ́n ti wá sì yàtọ̀ síra. Àmọ́ wọ́n jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ níṣọ̀kan torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni tó lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn tó ti di Kristẹni ṣáájú wọn máa ní láti ṣàlàyé ẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì máa pé jọ pẹ̀lú wọn déédéé.—Ìṣe 2:42; 8:30, 31. w23.02 3 ¶7
Wednesday, February 28
Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 17:3.
Jèhófà ṣèlérí pé àwọn tó bá ń gbọ́ràn sí òun lẹ́nu ló máa rí “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Róòmù 6:23) Tá a bá ń ronú lórí ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ṣe fún wa yìí, ó dájú pé ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀. Rò ó wò ná: Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an débi tó fi ṣèlérí pé títí láé lòun á máa wà pẹ̀lú wa. Ìlérí tí Jèhófà ṣe pé a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun ń mú ká fara da àwọn ìṣòro wa. Kódà táwọn ọ̀tá wa bá halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa pa wá, a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà dójú ikú, ó dá wa lójú pé ó máa jí wa dìde, a ó sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé. (Jòh. 5:28, 29; 1 Kọ́r. 15:55-58; Héb. 2:15) A mọ̀ pé Jèhófà lè mú ká wà láàyè títí láé torí pé Òun ló fún wa ní ẹ̀mí, kò sì lè kú láé àti láéláé. (Sm. 36:9) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé láti ayérayé ni Jèhófà ti wà, kò sì lè kú láé.—Sm. 90:2; 102:12, 24, 27. w22.12 2 ¶1-3
Thursday, February 29
Ta ló máa yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ṣé ìpọ́njú ni àbí wàhálà àbí inúnibíni.—Róòmù 8:35.
Kì í ya àwa èèyàn Jèhófà lẹ́nu tí ìṣòro bá dé bá wa. A mọ ohun tí Bíbélì sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.” (Ìṣe 14:22) A tún mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìṣòro tá a ní ló máa yanjú títí a máa fi wọnú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí níbi tí ‘kò ti ní sí ikú mọ́, tí kò sì ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.’ (Ìfi. 21:4) Nígbà míì, Jèhófà máa ń fàyè gba pé kí àdánwò dé bá wa. Àmọ́, ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á. Kíyè sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó ń gbé ní Róòmù. Ó kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn ìṣòro kan tí òun àtàwọn ará ní. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “À ń ja àjàṣẹ́gun nípasẹ̀ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa.” (Róòmù 8:36, 37) Èyí fi hàn pé bí ìṣòro tó dé bá ẹ ò bá lọ, o ṣì máa rọ́wọ́ Jèhófà láyé ẹ. w23.01 14 ¶1-2