April
Tuesday, April 1
Kí lo ṣe fún mi yìí? . . . Kí ló dé tí o fi tàn mí jẹ?—Jẹ́n. 29:25.
Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́ láwọn ìṣòro tí wọn ò rò pé ó lè dé bá wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jékọ́bù. Bàbá ẹ̀ ní kó lọ fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Lábánì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà, bàbá ẹ̀ sì fi dá a lójú pé Jèhófà máa bù kún ẹ̀. (Jẹ́n. 28:1-4) Jékọ́bù sì ṣe ohun tí bàbá ẹ̀ sọ. Ó fi ilẹ̀ Kénáánì sílẹ̀, ó sì rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ Lábánì tó lọ́mọ obìnrin méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Líà àti Réṣẹ́lì. Nígbà tí Jékọ́bù débẹ̀, ìfẹ́ Réṣẹ́lì tó jẹ́ àbúrò wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé ó gbà láti ṣiṣẹ́ ọdún méje fún Lábánì kó lè fẹ́ ọmọ ẹ̀. (Jẹ́n. 29:18) Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bí Jékọ́bù ṣe rò, ṣe ni Lábánì tàn án jẹ kó lè fẹ́ Líà tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, Lábánì gbà kí Jékọ́bù fẹ́ Réṣẹ́lì, àmọ́ ó sọ pé àfi kó tún ṣiṣẹ́ ọdún méje míì fún òun. (Jẹ́n. 29:26, 27) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Lábánì àti Jékọ́bù jọ dòwò pọ̀, ó tún rẹ́ ẹ jẹ. Torí náà, odindi ogún (20) ọdún ni Lábánì fi ṣe ohun tí ò dáa sí Jékọ́bù!—Jẹ́n. 31:41, 42. w23.04 15 ¶5
Wednesday, April 2
Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.—Sm. 62:8.
Tá a bá fẹ́ ìtùnú àti ìtọ́sọ́nà, ọ̀dọ̀ ta ló yẹ ká lọ? Àwa náà mọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ló yẹ ká lọ, ká gbàdúrà sí i. Ohun tí Jèhófà sì fẹ́ ká ṣe nìyẹn. Ó fẹ́ ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo” sí òun. (1 Tẹs. 5:17) Kò sígbà tá ò lè gbàdúrà sí i, ká sì ní kó tọ́ wa sọ́nà nígbèésí ayé wa ojoojúmọ́. (Òwe 3:5, 6) Torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ń ṣe fún wa, ó sọ pé kò sígbà tá ò lè gbàdúrà sí òun. Jésù mọ̀ pé àdúrà wa ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Kí Jésù tó wá sáyé, ó máa ń rí bí Bàbá ẹ̀ ṣe ń dáhùn àdúrà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Bí àpẹẹrẹ, Jésù wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bàbá ẹ̀ nígbà tó dáhùn àdúrà àtọkànwá tí Hánà, Dáfídì, Èlíjà àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ míì gbà. (1 Sám. 1:10, 11, 20; 1 Ọba 19:4-6; Sm. 32:5) Abájọ tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí wọ́n sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wọn!—Mát. 7:7-11. w23.05 2 ¶1, 3
Thursday, April 3
Ìbẹ̀rù èèyàn jẹ́ ìdẹkùn, àmọ́ ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà yóò rí ààbò.—Òwe 29:25.
Àlùfáà Àgbà Jèhóádà bẹ̀rù Jèhófà. Ó fi hàn bẹ́ẹ̀ nígbà tí Ataláyà ọmọbìnrin Jésíbẹ́lì fipá gbàjọba nílẹ̀ Júdà. Torí pé ó fẹ́ di ọbabìnrin, ó pa àwọn ọmọ ọmọ ẹ̀ ọkùnrin torí kó lè máa ṣàkóso lọ! (2 Kíró. 22:10, 11) Àmọ́ kò rí Jèhóáṣì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọmọ ẹ̀ pa torí pé Jèhóṣábéátì ìyàwó Jèhóádà dáàbò bò ó. Òun àti ọkọ ẹ̀ ló gbé ọmọ náà pa mọ́, wọ́n sì ń tọ́jú ẹ̀. Ohun tí Jèhóádà àti Jèhóṣábéátì ṣe yìí ló jẹ́ kí àwọn ọmọ Dáfídì máa jọba nìṣó. Lásìkò yẹn, Jèhóádà ti dàgbà, àmọ́ ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kò sì bẹ̀rù. Nígbà tí Jèhóáṣì pé ọmọ ọdún méje, Jèhóádà tún fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ó dá ọgbọ́n kan. Tí ọgbọ́n náà bá ṣiṣẹ́, Jèhóáṣì máa di ọba, á sì jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì, àmọ́ tí ọgbọ́n náà ò bá ṣiṣẹ́, ó ṣeé ṣe kí Jèhóádà fikú ṣèfà jẹ. Ṣùgbọ́n Jèhófà ràn án lọ́wọ́, ọgbọ́n tó dá yìí ṣiṣẹ́. w23.06 17 ¶12-13
Friday, April 4
Mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá sì wù ú ló ń gbé e fún.—Dán. 4:25.
Ọ̀rọ̀ tí Dáníẹ́lì sọ yìí lè mú kí Ọba Nebukadinésárì gbà pé ọ̀tá òun ni Dáníẹ́lì, kó sì pa á. Àmọ́ Dáníẹ́lì fìgboyà sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba. Kí ló ṣeé ṣe kó ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ tó fi nígboyà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀? Ó dájú pé nígbà tó wà lọ́mọdé, ó kẹ́kọ̀ọ́ lára àpẹẹrẹ rere ìyá àti bàbá ẹ̀. (Diu. 6:6-9) Kì í ṣe pé Dáníẹ́lì mọ àwọn Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ni, irú bí Òfin Mẹ́wàá, ó tún mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa òfin náà. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ ohun tó yẹ kó jẹ àtohun tí ò yẹ kó jẹ. (Léf. 11:4-8; Dán. 1:8, 11-13) Dáníẹ́lì tún mọ ìtàn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà àtohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn torí pé wọn ò tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. (Dán. 9:10, 11) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé Dáníẹ́lì jẹ́ kó dá a lójú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì ẹ̀ alágbára máa ran òun lọ́wọ́.—Dán. 2:19-24; 10:12, 18, 19. w23.08 3 ¶5-6
Saturday, April 5
Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.—Òwe 11:2.
Obìnrin tó gbọ́n tó sì nígboyà ni Rèbékà, ìyẹn ló mú kó ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. (Jẹ́n. 24:58; 27:5-17) Síbẹ̀, ó máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn ọkùnrin, ó sì máa ń tẹrí ba fún wọn. (Jẹ́n. 24:17, 18, 65) Torí náà ẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin, tẹ́ ẹ bá nírẹ̀lẹ̀ bíi Rèbékà, tẹ́ ẹ sì ń ṣègbọràn sáwọn tí Jèhófà ní kó máa bójú tó ìdílé àti ìjọ, ẹ máa jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni jẹ́ ànímọ́ tó yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ní. Obìnrin tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, tó sì bẹ̀rù Ọlọ́run ni Ẹ́sítà. Torí pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, kò gbéra ga nígbà tó di ayaba. Nígbà tí Módékáì ìbátan ẹ̀ tó jù ú lọ gbà á nímọ̀ràn, ó ṣe ohun tó sọ. (Ẹ́sít. 2:10, 20, 22) Torí náà, tó o bá ń jẹ́ káwọn èèyàn gbà ẹ́ nímọ̀ràn tó dáa, tó o sì ṣe ohun tí wọ́n sọ, ìyẹn á fi hàn pé o mọ̀wọ̀n ara ẹ. (Títù 2:3-5) Ẹ́sítà tún ṣe nǹkan míì tó fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. Obìnrin yìí “lẹ́wà gan-an, ìrísí rẹ̀ sì fani mọ́ra,” síbẹ̀ kò fi ẹwà tó ní ṣe fọ́rífọ́rí.—Ẹ́sít. 2:7, 15. w23.12 19-20 ¶6-8
Sunday, April 6
Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.—1 Jòh. 3:20.
Kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi ṣáá torí ohun tá a ṣe. Ẹrù tó yẹ ká jù nù ni. Tá a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a ronú pìwà dà, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́, kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi mọ́. Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà ti dárí jì wá. (Ìṣe 3:19) Tá a bá ti ṣe àwọn nǹkan yìí, Jèhófà ò fẹ́ ká máa dá ara wa lẹ́bi mọ́. Ó mọ̀ pé ó lè pa wá lára tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 31:10) Tá a bá jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn bò wá mọ́lẹ̀, ó lè má jẹ́ ká sáré ìyè náà mọ́. (2 Kọ́r. 2:7) Tó o bá ń dá ara ẹ lẹ́bi ṣáá, máa rántí pé tí Ọlọ́run bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ẹ jì ẹ́, kò ní rántí ẹ̀ mọ́. (Sm. 130:4) Ó ṣèlérí pé tóun bá ti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, òun ò “ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” (Jer. 31:34) Ìyẹn ni pé lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti dárí jì ẹ́, kò tún ní rántí ẹ̀ mọ́. Tó o bá ti pàdánù àwọn iṣẹ́ tó ò ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá, má banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ. Jèhófà ti gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ, ó sì yẹ kíwọ náà gbàgbé ẹ̀. w23.08 30 ¶14-15
Monday, April 7
Ẹ dúró gbọn-in, ẹ má yẹsẹ̀.—1 Kọ́r. 15:58.
Nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà, ọkàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tẹ̀ lé ohun tí ètò Ọlọ́run sọ balẹ̀, àmọ́ wàhálà bá àwọn tó fetí sí ìròyìn èké táwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn gbé jáde. (Mát. 24:45) Ó yẹ ká gbájú mọ́ “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:9, 10) Ìpínyà ọkàn lè jẹ́ ká máa fi àkókò wa ṣòfò, dípò ká máa fi ṣe àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. Bí àpẹẹrẹ, ohun tá a máa jẹ, tá a máa mu, eré ìnàjú àti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa lè má jẹ́ ká ráyè mọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. (Lúùkù 21:34, 35) Yàtọ̀ síyẹn, ojoojúmọ́ là ń gbọ́ ìròyìn nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń bá ara wọn fà láàárín ìlú. Torí náà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé a ò dá sí àríyànjiyàn tó ń lọ láàárín àwọn ará ìlú. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbè sẹ́yìn àwọn kan nínú ọkàn wa. Gbogbo àwọn nǹkan tá a ti sọ yìí ni Sátánì máa ń lò láti mú ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. w23.07 16-17 ¶12-13
Tuesday, April 8
Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.—Lúùkù 22:19.
Ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi ló ṣe pàtàkì jù lọ fáwa èèyàn Jèhófà lọ́dún. Ọjọ́ yẹn nìkan ni Jésù dìídì pa láṣẹ pé káwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa rántí. (Lúùkù 22:19, 20) Ó máa ń jẹ́ ká rántí onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì bí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Ó tún máa ń jẹ́ káwa àtàwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láǹfààní láti “fún ara wa ní ìṣírí.” (Róòmù 1:12) Bákan náà, ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó bá wá síbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn máa ń gbọ́ àtohun tí wọ́n máa ń rí máa ń mú kó wù wọ́n láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tún ronú nípa bí Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń mú káwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan kárí ayé. Abájọ tí Ìrántí Ikú Kristi fi ṣe pàtàkì gan-an sí wa! w24.01 8 ¶1-3
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 9) Lúùkù 19:29-44
Wednesday, April 9
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 3:16.
Bá a bá ṣe ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Jèhófà àti Jésù san láti rà wá pa dà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Gál. 2:20) Jèhófà gbà kí Jésù san ìràpadà, àmọ́ ìdí pàtàkì tó fi ṣe é ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Jèhófà fi hàn pé lóòótọ́ lòun nífẹ̀ẹ́ wa bó ṣe yọ̀ǹda ohun tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ ẹ̀ jìyà, kó sì kú nítorí wa. Kì í ṣe pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa nìkan ni, ó tún ń jẹ́ ká mọ bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. (Jer. 31:3) Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Fi wé Diutarónómì 7:7, 8.) Kò sóhun náà, kò sì sẹ́ni tó lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ rẹ̀. (Róòmù 8:38, 39) Báwo ni ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ẹ yìí ṣe rí lára ẹ? w24.01 28 ¶10-11
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 10) Lúùkù 19:45-48; Mátíù 21:18, 19; 21:12, 13
Thursday, April 10
Nítorí ìrètí, a máa dá ìṣẹ̀dá fúnra rẹ̀ sílẹ̀.—Róòmù 8:20, 21.
Àwọn ẹni àmì òróró mọyì ìrètí tí wọ́n ní. Arákùnrin Frederick Franz tó jẹ́ ọ̀kan lára wọn sọ bí ìrètí tó ní ṣe rí lára ẹ̀, ó ní: “Ìrètí wa dájú, gbogbo àwa tá a wà lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa rí ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí fún wa gbà. Èrè yẹn sì dáa ju gbogbo ohun míì tá a ní lọ.” Lọ́dún 1991, Arákùnrin Franz sọ pé: “Ìrètí tá a ní ṣe pàtàkì gan-an. . . . Bá a ṣe ń dúró dè é la túbọ̀ ń mọyì ẹ̀. Ohun tó yẹ ká máa retí ni. . . . Mo ti wá túbọ̀ mọyì ìrètí tá a ní yìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ.” Bóyá ọ̀run là ń retí láti gbé títí láé tàbí ayé, ìrètí ológo tá a ní ń fún wa láyọ̀. Ìrètí tá a ní yìí sì lè túbọ̀ dá wa lójú. w23.12 9 ¶6; 10 ¶8
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 11) Lúùkù 20:1-47
Friday, April 11
Ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.—Héb. 10:4.
Pẹpẹ kan tí wọ́n fi bàbà ṣe wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn ní Ísírẹ́lì àtijọ́, orí ẹ̀ ni wọ́n ti ń fi ẹran rúbọ sí Jèhófà. (Ẹ́kís. 27:1, 2; 40:29) Àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú yẹn ò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn kúrò pátápátá. (Héb. 10:1-3) Àmọ́, àwọn ẹbọ tí wọ́n rú nínú àgọ́ ìjọsìn yẹn ń ṣàpẹẹrẹ ẹbọ kan ṣoṣo tó máa mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé kúrò títí láé. Jésù mọ̀ pé Jèhófà rán òun wá sáyé kóun lè fi ẹ̀mí òun ra aráyé pa dà. (Mát. 20:28) Torí náà, nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó fi gbogbo ara ẹ̀ fún Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Jòh. 6:38; Gál. 1:4) Jésù fi ẹ̀mí ẹ̀ rúbọ “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé” láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ẹni tó bá nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Héb. 10:5-7, 10. w23.10 26-27 ¶10-11
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 12) Lúùkù 22:1-6; Máàkù 14:1, 2, 10, 11
ỌJỌ́ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
Saturday, April 12
Ìyè àìnípẹ̀kun ni ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fúnni nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.—Róòmù 6:23.
Kò sí bí àwa fúnra wa ṣe lè ra ara wa pa dà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Sm. 49:7, 8) Nǹkan ńlá ni Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n san kí Jésù lè fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. Bá a bá ṣe ń ronú lórí ohun ńlá tí Jèhófà àti Jésù san yìí, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa mọyì ìràpadà náà. Nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ó pàdánù àǹfààní tó ní láti wà láàyè títí láé, ìyẹn sì kan gbogbo àtọmọdọ́mọ ẹ̀ náà. Ká lè rí ohun tí Ádámù sọ nù gbà pa dà, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé rúbọ. Jálẹ̀ ìgbà tí Jésù fi wà láyé, “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, kò sì sí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.” (1 Pét. 2:22) Torí náà, nígbà tí Jésù kú, ẹni pípé ni bíi ti Ádámù kí Ádámù tó dẹ́ṣẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kí ẹbọ tí Jésù fi ẹ̀mí ẹ̀ rú bá ohun tí Ádámù gbé sọ nù mu rẹ́gí.—1 Kọ́r. 15:45; 1 Tím. 2:6. w24.01 10 ¶5-6
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 13) Lúùkù 22:7-13; Máàkù 14:12-16 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 14) Lúùkù 22:14-65
Sunday, April 13
Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ ọmọ màlúù ló gbé wọnú ibi mímọ́, àmọ́ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ ni, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì gba ìtúsílẹ̀ àìnípẹ̀kun fún wa.—Héb. 9:12.
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. A ti wá rí i pé ètò tí Jèhófà ṣe ká lè máa ṣe ìjọsìn mímọ́ nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù àti iṣẹ́ àlùfáà rẹ̀ ló dáa jù lọ. Àwọn èèyàn ló ṣe Ibi Mímọ́ Jù Lọ tí àlùfáà àgbà máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran wọ̀, àmọ́ inú “ọ̀run gangan” ni ibi mímọ́ jù lọ tí Jésù wọ̀, kó lè wá síwájú Jèhófà. Ibẹ̀ ló ti gbé ẹbọ pípé fún Jèhófà torí “ó fi ara rẹ̀ rúbọ kó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ [wa] kúrò.” (Héb. 9:24-26) Torí náà, gbogbo wa la lè jọ́sìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí bóyá ọ̀run là ń lọ àbí ayé la máa gbé. w23.10 28 ¶13-14
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 14) Lúùkù 22:66-71
Monday, April 14
Ẹ jẹ́ ká sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, ká sọ̀rọ̀ ní fàlàlà.—Héb. 4:16.
Ronú nípa ohun tí Jésù Ọba wa àti Àlùfáà Àgbà tó lójú àánú ń ṣe fún wa látọ̀run. Nípasẹ̀ rẹ̀, a lè wá síwájú “ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” Ọlọ́run, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣàánú wa, kó sì ràn wá lọ́wọ́ “ní àkókò tó tọ́.” (Héb. 4:14, 15) Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá láìronú nípa ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún wa àtohun tí wọ́n ṣì ń ṣe fún wa. Torí náà, ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa yẹ kó mú ká máa fìtara wàásù, ká sì máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù tá a lè ṣe láti fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa ni pé ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọmọlẹ́yìn Jésù. (Mát. 28:19, 20) Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà ṣe nìyẹn. Ó mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé “ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.”—1 Tím. 2:3, 4. w23.10 22 ¶13-14
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 15) Mátíù 27:62-66
Tuesday, April 15
Ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.—Ìfi. 21:4.
Ọ̀pọ̀ lára wa ló máa ń ka ẹsẹ Bíbélì yìí tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú Párádísè, ó sì máa ń múnú wọn dùn. Báwo la ṣe lè jẹ́ kó dá àwa àtàwọn tá à ń wàásù fún lójú pé àwọn ohun rere tí Jèhófà sọ nínú Ìfihàn 21:3, 4 máa ṣẹ lóòótọ́? Kì í kàn ṣe pé Jèhófà ṣe àwọn ìlérí tó ń múnú wa dùn nìkan ni, ó tún jẹ́ ká rí àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ ká gbà pé Párádísè tí Jèhófà ṣèlérí máa dé wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a fẹ́ sọ yìí. Àwọn ẹsẹ náà sọ pé: “Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ sọ pé: ‘Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’ Ó tún sọ pé: ‘Kọ ọ́ sílẹ̀, torí àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni.’ Ó sọ fún mi pé: ‘Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀! Èmi ni Ááfà àti Ómégà, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin.’”—Ìfi. 21:5, 6a. w23.11 3 ¶3-5
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 16) Lúùkù 24:1-12
Wednesday, April 16
Máa gba àwọn ọ̀dọ́kùnrin níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ aláròjinlẹ̀.—Títù 2:6.
Nǹkan tó máa fi hàn pé arákùnrin kan ní làákàyè ni bó ṣe ń múra àti irú irun tó ń gẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, tó sì ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ oníṣekúṣe ló máa ń ṣe àwọn aṣọ tuntun jáde, tí wọ́n sì máa ń polówó ẹ̀. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe àwọn aṣọ tó ń fún mọ́ èèyàn lára àti aṣọ tó ń jẹ́ káwọn ọkùnrin dà bí obìnrin fi hàn pé ìṣekúṣe ló wà lọ́kàn wọn. Torí náà, àwọn ìlànà Bíbélì ló yẹ kí ọ̀dọ́kùnrin Kristẹni kan máa tẹ̀ lé tó bá fẹ́ yan irú aṣọ tó máa wọ̀, kó sì tún máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó ń wọṣọ tó dáa nínú ìjọ. Ó lè bi ara ẹ̀ pé: ‘Ṣé àwọn aṣọ tí mò ń wọ̀ fi hàn pé mo láròjinlẹ̀, mo sì ń gba tàwọn ẹlòmíì rò? Ṣé àwọn aṣọ tí mò ń wọ̀ ń jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé olùjọsìn Ọlọ́run ni mí lóòótọ́?’ (1 Kọ́r. 10:31-33) Tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá ní làákàyè, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin á máa bọ̀wọ̀ fún un, á sì tún rí ojúure Jèhófà. w23.12 26 ¶7
Thursday, April 17
Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Ká ní Ìjọba mi jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ì bá ti jà.—Jòh. 18:36.
Láwọn ìgbà kan, “ọba gúúsù” ti ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Jèhófà. (Dán. 11:40) Bí àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ogun Àgbáyé Kejì, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni wọ́n jù sẹ́wọ̀n torí pé wọn ò lọ́wọ́ sógun, wọ́n sì tún lé àwọn ọmọ wọn kúrò nílé ìwé nítorí ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó dán àwọn èèyàn Jèhófà wò láwọn ìlú tí “ọba gúúsù” ti ń ṣàkóso. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ìpolongo ìbò, arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè fẹ́ gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí olóṣèlú kan. Ó lè má dìbò, àmọ́ lọ́kàn ẹ̀, ó lè fẹ́ kí ẹgbẹ́ òṣèlú kan wọlé. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká má dá sọ́rọ̀ òṣèlú rárá, kódà kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́kàn wa.—Jòh. 15:18, 19. w23.08 12 ¶17
Friday, April 18
Ìyìn ni fún Jèhófà, tó ń bá wa gbé ẹrù wa lójoojúmọ́.—Sm. 68:19.
Bá a ṣe ń sáré ìyè nìṣó, ó yẹ ká ‘sáré lọ́nà tí àá fi lè gba èrè.’ (1 Kọ́r. 9:24) Jésù sọ pé tá ò bá ṣọ́ra, ‘àjẹjù, ọtí àmujù àti àníyàn ìgbésí ayé lè di ẹrù pa ọkàn wa.’ (Lúùkù 21:34) Ẹsẹ Bíbélì yìí àtàwọn míì lè jẹ́ kó o rí àwọn ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe bó o ṣe ń sá eré ìyè nìṣó. Ó yẹ kó dá wa lójú pé a máa yege bá a ṣe ń sáré ìyè torí Jèhófà máa fún wa lókun tá a máa fi sáré náà. (Àìsá. 40:29-31) Torí náà, má jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́! Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó fi gbogbo okun ẹ̀ sáré kó lè gba èrè tí Jèhófà fẹ́ fún un. (Fílí. 3:13, 14) Ìwọ fúnra ẹ lo máa sá eré yìí torí wọn kì í báàyàn sá a, àmọ́ Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè sáré náà dópin. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ẹrù tó yẹ, kó o sì ju àwọn tí ò yẹ nù. Torí náà, mọ̀ pé Jèhófà máa dúró tì ẹ́, á sì jẹ́ kó o fi ìfaradà sá eré ìyè náà parí! w23.08 31 ¶16-17
Saturday, April 19
Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.—Ẹ́kís. 20:12.
Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá (12), Jésù àtàwọn òbí ẹ̀ lọ ṣe àjọyọ̀ kan ní Jerúsálẹ́mù, àmọ́ nígbà tí wọ́n ń pa dà sílé, wọn ò mọ̀ pé kò tẹ̀ lé àwọn. (Lúùkù 2:46-52) Ojúṣe Jósẹ́fù àti Màríà ni láti rí i dájú pé gbogbo àwọn ọmọ wọn wà lára àwọn tí wọ́n jọ ń rìn pa dà sílé lẹ́yìn àjọyọ̀ náà. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jósẹ́fù àti Màríà pa dà rí Jésù, ńṣe ni Màríà dá Jésù lẹ́bi pé òun ló kó àwọn sí wàhálà. Jésù lè sọ pé bí wọ́n ṣe dá òun lẹ́bi yẹn ò dáa. Ṣùgbọ́n kò ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló dá wọn lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, ó sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ‘ohun tí Jésù ń sọ fún Jósẹ́fù àti Màríà ò yé wọn,’ síbẹ̀ ó ṣì “ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.” Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ó máa ń nira fún yín láti gbọ́ràn sáwọn òbí yín lẹ́nu tí wọ́n bá ṣàṣìṣe tàbí tí wọ́n ṣì yín lóye? Kí ló máa ràn yín lọ́wọ́? Ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà. Bíbélì sọ pé tó o bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí ẹ, “èyí dára gidigidi lójú Olúwa.” (Kól. 3:20) Jèhófà mọ̀ pé nígbà míì, àwọn òbí ẹ lè má lóye ẹ, wọ́n sì lè ṣe àwọn òfin kan tó lè má rọrùn fún ẹ láti tẹ̀ lé. Àmọ́ tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, inú Jèhófà máa dùn sí ẹ. w23.10 7 ¶5-6
Sunday, April 20
Ẹ máa fòye báni lò, kí ẹ sì jẹ́ oníwà tútù sí gbogbo èèyàn.—Títù 3:2.
Ọmọ ilé ìwé wa kan lè sọ pé káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí èrò wa pa dà nípa àwọn tó ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Á dáa ká jẹ́ kó mọ̀ pé gbogbo èèyàn la máa ń fìfẹ́ hàn sí, a sì mọ̀ pé kálukú ló máa pinnu ohun tóun máa fayé òun ṣe. (1 Pét. 2:17) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á fún wa láǹfààní láti jẹ́ kó mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ náà àti pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣe wá láǹfààní tá a bá tẹ̀ lé e. Tẹ́nì kan bá ta ko ohun tá a gbà gbọ́, kò yẹ ká gbà pé a mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ ilé ìwé ẹ kan bá sọ pé òmùgọ̀ làwọn tó gbà pé Ọlọ́run wà ńkọ́? Ṣé ó yẹ kó o rò pé ó gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, ó sì mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó má tíì ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà rí. Torí náà, o lè ní kó lọ ka ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá lórí ìkànnì jw.org. Tó bá yá, ó lè fẹ́ jíròrò àpilẹ̀kọ tó kà tàbí fídíò tó wò níbẹ̀. Ẹ ò rí i pé tá a bá ṣàlàyé fún wọn lọ́nà yìí, tá a sì bọ̀wọ̀ fún wọn, ó lè mú kí wọ́n yí èrò wọn pa dà. w23.09 17 ¶12-13
Monday, April 21
Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.—Sm. 86:5.
Ó dá wa lójú pé tá a bá ṣàṣìṣe, àmọ́ tá a ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣàtúnṣe tó yẹ, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa lò wá, ó sì máa bù kún wa. (Òwe 28:13) Òótọ́ ni pé aláìpé ni Sámúsìn, síbẹ̀ kò jẹ́ kó sú òun láti máa sin Jèhófà nìṣó, kódà lẹ́yìn tó fẹ́ Dẹ̀lílà tó dalẹ̀ ẹ̀. Jèhófà náà ò sì jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. Ọlọ́run tún lo Sámúsìn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Jèhófà rí i pé ọkùnrin tó nígbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Sámúsìn, ó sì jẹ́ kí orúkọ ẹ̀ wà lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ tá a kọ orúkọ wọn sínú Hébérù orí kọkànlá (11). Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó bá a ṣe mọ̀ pé Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa là ń sìn, ó sì máa ń wù ú láti fún wa lókun nígbà ìṣòro! Torí náà, bíi ti Sámúsìn, ẹ jẹ́ káwa náà máa bẹ Jèhófà pé: “Jọ̀ọ́ rántí mi, jọ̀ọ́ fún mi lókun.”—Oníd. 16:28. w23.09 7 ¶18-19
Tuesday, April 22
Ẹ máa dúró de ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà máa wà níhìn-ín, kí ẹ sì máa fi í sọ́kàn dáadáa.—2 Pét. 3:12.
A mọ̀ pé ọjọ́ Jèhófà ò ní pẹ́ dé, torí náà a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn. Síbẹ̀ nígbà míì, ẹ̀rù lè máa bà wá láti wàásù. Kí nìdí? Ìdí ni pé a lè máa bẹ̀rù ohun táwọn èèyàn máa sọ tàbí ohun tí wọ́n máa ṣe fún wa. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù náà nìyẹn. Lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ Jésù, ẹ̀rù ba Pétérù débi tó fi sọ pé òun kì í ṣe ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Kódà, léraléra ló sọ pé òun ò mọ Jésù rí. (Mát. 26:69-75) Pétérù yìí kan náà wá fi ìdánilójú sọ nígbà tó yá pé: “Ẹ má bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà.” (1 Pét. 3:14) Ohun tó sọ yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé àwa náà lè borí ìbẹ̀rù èèyàn. Kí ló máa jẹ́ ká borí ìbẹ̀rù èèyàn? Pétérù sọ fún wa pé: “Ẹ gbà nínú ọkàn yín pé Kristi jẹ́ mímọ́.” (1 Pét. 3:15) Ọ̀rọ̀ yẹn jẹ́ ká rántí pé Jésù Kristi ni Olúwa àti Ọba wa, ó sì lágbára gan-an. w23.09 27 ¶6-8
Wednesday, April 23
Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ìṣekúṣe àti ìwà àìmọ́ èyíkéyìí . . . láàárín yín.—Éfé. 5:3.
Ó yẹ ká sapá ká má bàa máa ṣe “àwọn iṣẹ́ tí kò lérè tó jẹ́ ti òkùnkùn.” (Éfé. 5:11) Àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ti jẹ́ ká rí i pé téèyàn bá ń wo ìwòkuwò, tó ń sọ ọ̀rọ̀ rírùn tàbí tó ń tẹ́tí sí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ó máa rọrùn fún un láti ṣèṣekúṣe. (Jẹ́n. 3:6; Jém. 1:14, 15) Sátánì àtàwọn èèyàn ayé yìí máa ń fẹ́ ká gbà pé àwọn nǹkan tó burú tí ò sì mọ́ lójú Jèhófà ò burú rárá. (2 Pét. 2:19) Ọ̀kan lára ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí Sátánì ti máa ń lò ni pé ó máa ń mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Àìsá. 5:20; 2 Kọ́r. 4:4) Kò yà wá lẹ́nu pé àwọn fíìmù, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn ìkànnì kan máa ń gbé àwọn nǹkan tó ta ko ìlànà òdodo Jèhófà lárugẹ. Sátánì ń fẹ́ ká gbà pé àwọn ìwà àti ìṣe tí ò dáa ò lè ṣe èèyàn ní jàǹbá.—Éfé. 5:6. w24.03 22 ¶8-10
Thursday, April 24
Àwọn èèyàn yìí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ bí àpẹẹrẹ àti òjìji àwọn nǹkan ti ọ̀run.—Héb. 8:5.
Wọ́n ṣe àgọ́ ìjọsìn lọ́nà tó ṣeé gbé láti ibì kan sí ibòmíì, gbogbo ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń lọ ni wọ́n sì máa ń gbé e lọ. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún ni wọ́n fi lo àgọ́ náà, kó tó di pé wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì kan sí Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́kís. 25:8, 9; Nọ́ń. 9:22) Àgọ́ ìjọsìn ni ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti máa ń jọ́sìn, tí wọ́n sì ti máa ń rúbọ. (Ẹ́kís. 29:43-46) Àmọ́, àgọ́ ìjọsìn tún ṣàpẹẹrẹ ohun kan tó dáa jù. Ó jẹ́ “òjìji àwọn nǹkan ti ọ̀run,” ó sì ṣàpẹẹrẹ tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “àgọ́ [tàbí àgọ́ ìjọsìn] yìí jẹ́ àpèjúwe fún àkókò yìí.” (Héb. 9:9) Torí náà, nígbà tó fi máa kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, wọ́n ti ń jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Ọdún 29 S.K. ló bẹ̀rẹ̀. Ọdún yẹn ni Jésù ṣèrìbọmi, tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ “àlùfáà àgbà” ńlá fún Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí.—Héb. 4:14; Ìṣe 10:37, 38. w23.10 26 ¶6-7
Friday, April 25
Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.—Fílí. 4:5.
Táwa Kristẹni bá fẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà dáa sí i, a gbọ́dọ̀ lè tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún, ká má sì máa rin kinkin mọ́ nǹkan. A gbọ́dọ̀ máa fòye báni lò. Táwọn àyípadà kan bá ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa, ká má ṣe máa rin kinkin mọ́ èrò wa, ká má sì máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ nítorí ìpinnu tí wọ́n bá ṣe. Ó yẹ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa fòye báni lò. Ó tún yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká sì máa fàánú hàn. Bíbélì pe Jèhófà ní “Àpáta náà” torí pé adúróṣinṣin ni, ó sì máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo. (Diu. 32:4) Síbẹ̀, ó tún máa ń fòye báni lò. Bí nǹkan ṣe ń yí pa dà láyé, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń ṣe àwọn àyípadà kan kó lè mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Torí pé Jèhófà dá wa ní àwòrán ara ẹ̀, ó máa ń rọrùn fún wa láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, táwọn nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa. Nínú Bíbélì, Jèhófà fún wa láwọn ìlànà tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́ láìka ìṣòro yòówù kó dé bá wa sí. Àpẹẹrẹ tó dáa tí Jèhófà fi lélẹ̀ àtàwọn ìlànà tó fún wa ti jẹ́ ká rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni “Àpáta náà,” ó máa ń fòye báni lò. w23.07 20 ¶1-3
Saturday, April 26
Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.—Sm. 94:19.
Nínú Bíbélì, Jèhófà fi ara ẹ̀ wé ìyá kan tó máa ń fìfẹ́ hàn sí ọmọ ẹ̀. (Àìsá. 66:12, 13) Ẹ fojú inú wo ìyá kan tó ń fìfẹ́ bójú tó ọmọ ẹ̀ kékeré. Lọ́nà kan náà, tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn, ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fìfẹ́ bójú tó wa. Tá a bá ṣàṣìṣe, kì í pa wá tì. (Sm. 103:8) Léraléra làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tó dun Jèhófà, síbẹ̀ nígbà tí wọ́n ronú pìwà dà, ó fìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wọn, ó ní: “O ti wá ṣeyebíye ní ojú mi, a dá ọ lọ́lá, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.” (Àìsá. 43:4, 5) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní ò tíì yí pa dà. Kódà tá a bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe ńlá, tá a bá ronú pìwà dà, tá a sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, àá rí i pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ wa. Ó ṣèlérí pé òun ‘máa dárí jì wá fàlàlà.’ (Àìsá. 55:7) Bíbélì sọ pé tí Jèhófà bá dárí jì wá, “àsìkò ìtura . . . látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀” máa dé bá wa.—Ìṣe 3:19. w24.01 27 ¶4-5
Sunday, April 27
Ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run mi wà lára mi.—Ẹ́sírà 7:28.
Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá wa ká lè lọ sí àpéjọ agbègbè tàbí tá a bá ní kí wọ́n yí àkókò iṣẹ́ wa pa dà ká lè ráyè máa wá sí gbogbo ìpàdé ìjọ, àá rí ọwọ́ Jèhófà lára wa. Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lè yà wá lẹ́nu gan-an. Ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ẹ́sírà fi ìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Gbogbo ìgbà tíṣẹ́ tó fẹ́ ṣe bá ti kà á láyà, ó máa ń fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà. (Ẹ́sírà 8:21-23; 9:3-5) Torí pé Ẹ́sírà gbára lé Jèhófà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù ràn án lọ́wọ́, wọ́n sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó ní. (Ẹ́sírà 10:1-4) Tá a bá ń ṣàníyàn nípa àtijẹ àtimu tàbí nípa bá a ṣe máa dáàbò bo ìdílé wa, ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́. w23.11 18 ¶15-17
Monday, April 28
Ábúrámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, Ó sì kà á sí òdodo fún un.—Jẹ́n. 15:6.
Jèhófà ò sọ pé ó dìgbà tá a bá ṣe ohun tí Ábúráhámù ṣe gangan kóun tó lè pè wá ní olódodo. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé onírúurú ọ̀nà la lè gbà ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. Àwọn nǹkan tá a lè ṣe ni pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó wá sípàdé nígbà àkọ́kọ́ àti gbogbo àwọn ará, ká máa ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìní, ká sì máa ṣohun rere sáwọn tó wà nínú ìdílé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì bù kún wa. (Róòmù 15:7; 1 Tím. 5:4, 8; 1 Jòh. 3:18) Ọ̀nà pàtàkì tá à ń gbà fi hàn pé a nígbàgbọ́ ni pé a máa ń fìtara wàásù fáwọn èèyàn. (1 Tím. 4:16) Torí náà, gbogbo wa la lè ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́ pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ àti pé ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan ló dáa jù lọ. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Ọlọ́run máa pè wá ní olódodo, àá sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. w23.12 2 ¶3; 6 ¶15
Tuesday, April 29
Jẹ́ alágbára, kí o sì ṣe bí ọkùnrin.—1 Ọba 2:2.
Nígbà tó ku díẹ̀ kí Ọba Dáfídì kú, ó sọ ohun tó wà lókè yìí fún Sólómọ́nì. (1 Ọba 2:1, 3) Ó ṣe pàtàkì kí gbogbo àwọn ọkùnrin Kristẹni fi ìmọ̀ràn yìí sílò lónìí. Kí wọ́n tó lè ṣàṣeyọrí, ó yẹ kí wọ́n kọ́ bí wọ́n á ṣe máa pa òfin Ọlọ́run mọ́, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ní gbogbo apá ìgbésí ayé wọn. (Lúùkù 2:52) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn ọ̀dọ́kùnrin di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn? Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ làwọn ọkùnrin Kristẹni máa ń ṣe nínú ìdílé àti nínú ìjọ. Torí náà ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ti máa ronú nípa àwọn ojúṣe tẹ́ ẹ máa ní lọ́jọ́ iwájú. Ó lè wù ẹ́ kó o di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Ó tún ṣeé ṣe kó o fẹ́ láya, kó o sì bímọ. (Éfé. 6:4; 1 Tím. 3:1) Tó o bá fẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àwọn nǹkan yìí, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ. w23.12 24 ¶1-2
Wednesday, April 30
Àkókò ò ní tó tí n bá ní kí n máa sọ̀rọ̀ nípa Gídíónì.—Héb. 11:32.
Àwa èèyàn Jèhófà ṣeyebíye lójú ẹ̀, àwọn alàgbà ló sì yàn pé kí wọ́n máa bójú tó wa. Àwọn ọkùnrin tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn yìí mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa bójú tó àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ kára láti jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn . . . tí á máa bójú tó wọn dáadáa.” (Jer. 23:4; 1 Pét. 5:2) A mà dúpẹ́ o pé a nírú àwọn alàgbà yìí láwọn ìjọ wa! Ẹ̀yin alàgbà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Gídíónì onídàájọ́. (Héb. 6:12) Ó dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì tún bójú tó wọn. (Oníd. 2:16; 1 Kíró. 17:6) Bíi ti Gídíónì, Jèhófà ti yan àwọn alàgbà pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn èèyàn òun lásìkò tí nǹkan le gan-an yìí. (Ìṣe 20:28; 2 Tím. 3:1) Torí náà, ẹ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Gídíónì nípa bó ṣe mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, bó ṣe nírẹ̀lẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ onígbọràn. Iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un jẹ́ kó mọ̀ bóyá òun ní ìfaradà tàbí òun ò ní. Bóyá alàgbà ni wá tàbí a kì í ṣe alàgbà, gbogbo wa ló yẹ ká mọyì iṣẹ́ takuntakun táwọn alàgbà ń ṣe nínú ìjọ, ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́.—Héb. 13:17. w23.06 2 ¶1; 3 ¶3