August
Friday, August 1
Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.—Sm. 34:19.
Ẹ kíyè sí kókó pàtàkì méjì tó wà nínú sáàmù yìí: (1) Àwọn olóòótọ́ èèyàn máa ń níṣòro. (2) Jèhófà máa ń gbà wá tá a bá níṣòro. Báwo ni Jèhófà ṣe ń gbà wá? Ọ̀nà kan ni pé ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàkigbà ni ìṣòro lè dé bá wa nínú ayé burúkú yìí. Jèhófà ṣèlérí pé a máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin òun, àmọ́ kò ṣèlérí fún wa pé a ò ní níṣòro kankan. (Àìsá. 66:14) Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa ronú nípa ọjọ́ iwájú níbi tó ti fẹ́ ká gbádùn ayé wa títí láé. (2 Kọ́r. 4:16-18) Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó. (Ìdárò 3:22-24) Kí la kọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́ àti tòde òní? Àpẹẹrẹ wọn máa jẹ́ ká rí i pé ìṣòro lè dé bá wa nígbàkigbà, àmọ́ tá a bá gbára lé Jèhófà, ó máa bójú tó wa.—Sm. 55:22. w23.04 14-15 ¶3-4
Saturday, August 2
Máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.—Róòmù 13:1.
A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà tí wọ́n ṣègbọràn sí ìjọba bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. (Lúùkù 2:1-6) Nígbà tí oyún inú Màríà pé nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án, ìjọba ṣòfin kan tí ò rọrùn fún wọn láti pa mọ́. Augustus tó ń ṣàkóso ìjọba Róòmù pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀ nílùú ìbílẹ̀ wọn. Torí náà, Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò gba òkè gbágungbàgun lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìrìn àjò náà sì tó nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà (150). Ó dájú pé ìrìn àjò yẹn ò lè rọrùn, pàápàá fún Màríà. Ẹ̀rù lè máa ba àwọn méjèèjì torí wọn ò fẹ́ kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí Màríà àti oyún inú ẹ̀. Wọ́n lè máa ṣàníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí Màríà bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí. Ìdí sì ni pé oyún Mèsáyà tí gbogbo èèyàn ń dúró dè ló wà nínú ẹ̀. Ṣéyẹn á wá mú kí wọ́n má ṣègbọràn síjọba? Jósẹ́fù àti Màríà ò jẹ́ káwọn nǹkan yẹn dí wọn lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí òfin yẹn. Inú Jèhófà dùn sí wọn, ó sì jẹ́ kí ìrìn àjò wọn yọrí sí rere. Màríà dé sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láyọ̀ àti àlàáfíà, ó bí ọmọ náà wẹ́rẹ́, ó sì ṣe ohun tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ!—Míkà 5:2. w23.10 8 ¶9; 9 ¶11-12
Sunday, August 3
Ká máa gba ara wa níyànjú.—Héb. 10:25.
Kí lo lè ṣe tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti dáhùn nípàdé? Múra ìdáhùn ẹ dáadáa. (Òwe 21:5) Bó o bá ṣe múra ohun tẹ́ ẹ fẹ́ kọ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ lọkàn ẹ máa balẹ̀ láti dáhùn. Bákan náà, jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe ṣókí. (Òwe 15:23; 17:27) Tí ìdáhùn ẹ bá ṣe ṣókí, ẹ̀rù ò ní bà ẹ́. Tó o bá dáhùn ṣókí lọ́rọ̀ ara ẹ, ìyẹn fi hàn pé o múra sílẹ̀ dáadáa àti pé ohun tá à ń kọ́ yé ẹ. Ká sọ pé o tẹ̀ lé gbogbo àwọn àbá tá a sọ yìí, àmọ́ tẹ́rù ṣì ń bà ẹ́ láti dáhùn ju ẹ̀ẹ̀kan lọ ńkọ́? Mọ̀ dájú pé Jèhófà mọyì bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti dáhùn. (Lúùkù 21:1-4) Rántí pé Jèhófà ò retí pé kó o ṣe ju agbára ẹ lọ. (Fílí. 4:5) Ó yẹ kíwọ fúnra ẹ mọ ohun tí agbára ẹ gbé, kó o mọ bó o ṣe máa ṣe é, kó o sì gbàdúrà sí Jèhófà kẹ́rù má bà ẹ́ mọ́. Ohun tó o lè fi bẹ̀rẹ̀ ni pé kó o dáhùn lẹ́ẹ̀kan nípàdé, kó o sì jẹ́ kó ṣe ṣókí. w23.04 21 ¶6-8
Monday, August 4
Gbé àwo ìgbàyà wọ̀, kí o sì dé akoto.—1 Tẹs. 5:8.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àwa Kristẹni wé àwọn sójà tó máa ń wà lójúfò, tí wọ́n sì máa ń múra sílẹ̀ de ogun. Àwọn èèyàn gbà pé ó yẹ kí sójà kan múra sílẹ̀ láti jà torí ìgbàkigbà ni ogun lè dé. Bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ là ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà, ó yẹ ká gbé àwo ìgbàyà wọ̀, ìyẹn ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, ká sì dé akoto, ìyẹn ìrètí tá a ní. Àwo ìgbàyà máa ń dáàbò bo àyà sójà kan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ṣe máa ń dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. Àwọn ànímọ́ yìí máa ń jẹ́ ká sin Jèhófà nìṣó, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ìgbàgbọ́ tá a ní máa ń jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa san èrè fún wa tá a bá sìn ín tọkàntọkàn. (Héb. 11:6) Ó máa ń jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jésù Aṣáájú wa kódà bá a tiẹ̀ ń fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro. A lè mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àpẹẹrẹ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lásìkò wa yìí bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fara da inúnibíni tàbí ìṣòro àìlówó lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, tá ò bá fẹ́ kó sínú ìdẹkùn kíkó ohun ìní jọ, ó yẹ ká máa fara wé àwọn tí wọ́n jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. w23.06 10 ¶8-9
Tuesday, August 5
Ẹni tó bá ń wo ṣíṣú òjò kò ní kórè.—Oníw. 11:4.
Ẹni tó bá ń kó ara ẹ̀ níjàánu máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó má bàa ṣe ohun tí ò dáa. A gbọ́dọ̀ kó ara wa níjàánu kọ́wọ́ wa lè tẹ àfojúsùn wa, pàápàá tí ohun tá a fẹ́ ṣe yẹn ò bá rọrùn tàbí tí kò bá wù wá. Máa rántí pé ìkóra-ẹni-níjàánu wà lára àwọn ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní, torí náà bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ kó o lè túbọ̀ máa kó ara ẹ níjàánu. (Lúùkù 11:13; Gál. 5:22, 23) Má dúró dìgbà tí gbogbo nǹkan máa dán mọ́rán. Kò dájú pé ìgbà kan máa wà tí gbogbo nǹkan á dán mọ́rán fún wa nínú ayé yìí. Torí náà, tá a bá sọ pé a fẹ́ dúró dìgbà tí gbogbo nǹkan máa dáa, ọwọ́ wa lè má tẹ àfojúsùn wa. A lè rẹ̀wẹ̀sì torí ó lè máa ṣe wá bíi pé ohun tá a fẹ́ ṣe yẹn ti le jù, ọwọ́ wa ò sì ní lè tẹ̀ ẹ́. Tó bá jẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ nìyẹn, ṣé o lè ronú nípa àwọn àfojúsùn míì tọ́wọ́ ẹ lè tètè tẹ̀? Tó bá jẹ́ pé ànímọ́ kan ló wù ẹ́ kó o ní, o ò ṣe kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi ànímọ́ náà hàn díẹ̀díẹ̀? Tó bá jẹ́ àfojúsùn ẹ ni pé kó o ka gbogbo Bíbélì parí, á dáa kó o kọ́kọ́ máa fi àkókò díẹ̀ kà á lójoojúmọ́. w23.05 29 ¶11-13
Wednesday, August 6
Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ tó ń mọ́lẹ̀ sí i títí di ọ̀sán gangan.—Òwe 4:18.
Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ń lo ètò rẹ̀ láti fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà ká lè máa rìn ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” nìṣó. (Àìsá. 35:8; 48:17; 60:17) A lè sọ pé ìgbàkigbà tí ẹnì kan bá ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.” Àwọn kan á rìn díẹ̀, wọ́n á sì kúrò lójú ọ̀nà náà. Àmọ́, àwọn míì pinnu pé àwọn á máa rìn lójú ọ̀nà náà títí wọ́n á fi dé ibi tí wọ́n ń lọ. Ibo ni wọ́n ń lọ? Ibi tí “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” máa gbé àwọn tó ń lọ sí ọ̀run dé ni “párádísè Ọlọ́run” tó wà ní ọ̀run. (Ìfi. 2:7) Àmọ́ ọ̀nà náà máa jẹ́ káwọn tó fẹ́ gbé ayé di pípé nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá máa fi parí. Tó o bá ń rìn ní ọ̀nà yẹn lónìí, má wẹ̀yìn o. Má sì kúrò lójú ọ̀nà náà títí tó o fi máa dénú ayé tuntun! w23.05 17 ¶15; 19 ¶16-18
Thursday, August 7
A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.—1 Jòh. 4:19.
Tó o bá ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ, wàá túbọ̀ mọyì Jèhófà, wàá sì ya ara ẹ sí mímọ́ fún un. (Sm. 116:12-14) Bíbélì sọ pé Jèhófà ló ń fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jém. 1:17) Èyí tó tóbi jù lọ nínú gbogbo ẹ̀bùn tó fún wa ni Jésù Ọmọ ẹ̀ tó fi rúbọ nítorí wa. Ẹ̀yin náà ẹ wo àǹfààní tíyẹn ṣe wá! Ìràpadà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ Jèhófà, ká sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tí Jèhófà ṣe yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé. (1 Jòh. 4:9, 10) Torí náà, ọ̀nà kan tó o lè gbà fi hàn pé o mọyì ẹ̀bùn tó ga jù lọ tí Jèhófà fún ẹ àtàwọn nǹkan rere míì tó ṣe fún ẹ ni pé kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún un.—Diu. 16:17; 2 Kọ́r. 5:15. w24.03 5 ¶8
Friday, August 8
Ẹni tó ń rìn nínú ìdúróṣinṣin ń bẹ̀rù Jèhófà.—Òwe 14:2.
Tá a bá wo bí ìwàkiwà ṣe kún inú ayé lónìí, ó dájú pé bí nǹkan ṣe rí lára Lọ́ọ̀tì náà ló rí lára wa. Bíbélì sọ pé ó “banú jẹ́ gidigidi nítorí ìwà àìnítìjú àwọn arúfin èèyàn” torí ó mọ̀ pé Baba wa ọ̀run kórìíra ìwà burúkú. (2 Pét. 2:7, 8) Kí nìdí tí Lọ́ọ̀tì fi kórìíra ìwà burúkú ìgbà ayé ẹ̀? Ìdí ni pé ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Bákan náà lónìí, ìwà burúkú ló gba ayé kan torí pé àwọn èèyàn ò bẹ̀rù Ọlọ́run. Bó ti wù kó rí, àwa Kristẹni ṣì lè jẹ́ oníwà mímọ́ tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tá a sì ń bẹ̀rù ẹ̀ tọkàntọkàn. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn ohun tó yẹ ká ṣe àtàwọn ohun tí ò yẹ ká ṣe sínú ìwé Òwe, ó sì rọ̀ wá pé ká máa ṣe ohun tó tọ́. Torí náà, gbogbo àwa Kristẹni pátápátá lọ́mọdé lágbà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin la máa jàǹfààní tá a bá ń fi ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò. Tá a bá bẹ̀rù Jèhófà lóòótọ́, kò yẹ ká máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń hùwàkiwà. w23.06 20 ¶1-2; 21 ¶5
Saturday, August 9
Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀, kó máa gbé òpó igi oró rẹ̀ lójoojúmọ́, kó sì máa tẹ̀ lé mi.—Lúùkù 9:23.
Ó ṣeé ṣe káwọn ìdílé ẹ máa ṣenúnibíni sí ẹ, o sì ti lè yááfì àwọn ohun ìní tara kan kó o lè fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. (Mát. 6:33) Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ gbogbo nǹkan tó ò ń ṣe torí ìjọsìn ẹ̀. (Héb. 6:10) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni Jésù sọ nígbà tó sọ pé: “Kò sí ẹni tó fi ilé tàbí àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, ìyá, bàbá, àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá sílẹ̀ nítorí mi àti nítorí ìhìn rere, tí kò ní gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) àwọn ilé, àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, àwọn ìyá, àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni ní báyìí àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀.” (Máàkù 10:29, 30) Kò sí àní-àní pé àwọn ìbùkún tó o ti rí gbà pọ̀ gan-an ju ohunkóhun tó o yááfì lọ.—Sm. 37:4. w24.03 9 ¶5
Sunday, August 10
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.—Òwe 17:17.
Nígbà tí ìyàn ńlá mú àwọn ará ní Jùdíà, àwọn ará tó wà ní ìjọ Áńtíókù ti Síríà gbọ́ nípa ìyàn náà. Torí náà, wọ́n “pinnu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí agbára kálukú wọn gbé, láti fi nǹkan ìrànwọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ará tó ń gbé ní Jùdíà.” (Ìṣe 11:27-30) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi táwọn ará tí ìyàn náà mú ń gbé jìnnà gan-an, àwọn ará tó wà ní Áńtíókù pinnu pé àwọn gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́. (1 Jòh. 3:17, 18) Àwa náà lè fàánú hàn sáwọn ará wa lónìí tá a bá gbọ́ pé àjálù ṣẹlẹ̀ sí wọn. Bá a ṣe lè fi hàn pé à ń káàánú àwọn ará wa ni pé tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí wọn, ká tètè béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà bóyá a lè yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù. Yàtọ̀ síyẹn, a lè fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé tàbí ká gbàdúrà fáwọn tí àjálù dé bá. Ó tún lè pọn dandan pé ká ran àwọn ará wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò. Torí náà, tí Jésù Kristi Ọba wa bá dé láti ṣèdájọ́ ayé burúkú yìí, ó máa rí i pé à ń fàánú hàn sáwọn èèyàn, á sì pè wá pé ká wá “jogún Ìjọba” náà.—Mát. 25:34-40. w23.07 4 ¶9-10; 6 ¶12
Monday, August 11
Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.—Fílí. 4:5.
Jésù máa ń fòye báni lò bíi ti Jèhófà. Jèhófà rán an wá sáyé kó lè wàásù fún “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.” Síbẹ̀, ó máa ń fòye báni lò bó ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn. Nígbà kan, obìnrin kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀ ẹ́ pé kó wo ọmọbìnrin òun sàn torí pé ‘ẹ̀mí èṣù ń yọ ọ́ lẹ́nu gidigidi.’ Àánú obìnrin yẹn ṣe Jésù, ó ṣe ohun tó sọ, ó sì wo ọmọbìnrin ẹ̀ sàn. (Mát. 15:21-28) Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ míì. Lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ mi . . . , èmi náà máa sẹ́ ẹ.” (Mát. 10:33) Àmọ́ nígbà tí Pétérù sẹ́ ẹ lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣé ó pa á tì? Rárá. Jésù mọ̀ pé Pétérù kábàámọ̀ ohun tó ṣe, olóòótọ́ sì ni. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kó fi dá a lójú pé òun ti dárí jì í àti pé òun ṣì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Lúùkù 24:33, 34) Jèhófà àti Jésù Kristi máa ń fòye báni lò. Àwa ńkọ́? Jèhófà fẹ́ káwa náà máa fòye báni lò. w23.07 21 ¶6-7
Tuesday, August 12
Ikú ò ní sí mọ́.—Ìfi. 21:4.
Kí la lè sọ fáwọn tí ò gbà pé Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé? Àkọ́kọ́, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ṣèlérí yẹn. Ìwé Ìfihàn sọ pé: “Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ sọ pé: ‘Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’” Jèhófà ní ọgbọ́n àti agbára láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ohun tó sì fẹ́ ṣe nìyẹn. Ìkejì, ó dá Jèhófà lójú háún-háún pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ́ bíi pé ó ti ṣẹ. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni. . . . Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀!” Ìkẹta, tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ ohun kan, ó dájú pé ó máa parí ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Èmi ni Ááfà àti Ómégà.” (Ìfi. 21:6) Torí náà, Jèhófà máa fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, kò sì lè dí òun lọ́wọ́ láti mú ìlérí òun ṣẹ. Torí náà, tẹ́nì kan bá sọ pé, “Àlá tí ò lè ṣẹ ni,” ka Ìfihàn 21:5, 6 fún ẹni náà, kó o sì ṣàlàyé ẹ̀. O lè jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé Jèhófà ti fi dá wa lójú pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, òun sì ti fi òòtẹ̀ lù ú.—Àìsá. 65:16. w23.11 7 ¶18-19
Wednesday, August 13
Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá.—Jẹ́n. 12:2.
Jèhófà ṣèlérí yìí fún Ábúráhámù nígbà tó pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75), tí kò sì lọ́mọ kankan. Ṣé Ábúráhámù rí ìlérí yẹn nígbà tó ṣẹ? Rárá, àmọ́ ó rí díẹ̀ lára ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tó sọdá Odò Yúfírétì, tó sì ti dúró kí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) kọjá, ó ṣojú ẹ̀ nígbà tí Jèhófà jẹ́ kí ìyàwó ẹ̀ bí Ísákì lọ́nà ìyanu. Ọgọ́ta ọdún (60) lẹ́yìn náà, ó ṣojú ẹ̀ nígbà tí wọ́n bí àwọn ọmọ ọmọ ẹ̀, ìyẹn Ísọ̀ àti Jékọ́bù. (Héb. 6:15) Àmọ́, Ábúráhámù ò sí láyé mọ́ nígbà táwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ di orílẹ̀-èdè ńlá, tí wọ́n sì gba Ilẹ̀ Ìlérí. Síbẹ̀, ọkùnrin olóòótọ́ yìí ò fi Ẹlẹ́dàá ẹ̀ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ sílẹ̀. (Jém. 2:23) Ẹ wo bí inú Ábúráhámù ṣe máa dùn tó nígbà tó bá jíǹde, tó sì mọ̀ pé ìgbàgbọ́ àti sùúrù tóun ní ló jẹ́ kí Jèhófà bù kún gbogbo aráyé! (Jẹ́n. 22:18) Kí la rí kọ́? Ohun tá a kọ́ ni pé gbogbo ìlérí tí Jèhófà ṣe lè má ṣẹ lójú wa. Àmọ́, tá a bá ní sùúrù bíi ti Ábúráhámù, ó dájú pé Jèhófà máa san èrè fún wa báyìí, á sì tún san èrè tó jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ayé tuntun tó ṣèlérí.—Máàkù 10:29, 30. w23.08 24 ¶14
Thursday, August 14
Ní gbogbo àkókò tó ń wá Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ó láásìkí.—2 Kíró. 26:5.
Onírẹ̀lẹ̀ ni Ọba Ùsáyà nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Bíbélì sọ pé ó “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.” Ọdún méjìdínláàádọ́rin (68) ló lò láyé, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ ni Jèhófà bù kún un. (2 Kíró. 26:1-4) Ùsáyà ṣẹ́gun èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀tá wọn, ó sì rí i pé òun dáàbò bo Jerúsálẹ́mù. (2 Kíró. 26:6-15) Ó dájú pé inú Ùsáyà dùn gan-an torí gbogbo nǹkan tí Jèhófà jẹ́ kó gbé ṣe. (Oníw. 3:12, 13) Ọba ni Ùsáyà, torí náà ó máa ń pàṣẹ fáwọn èèyàn. Ṣé ìyẹn lè mú kó ronú pé ohun tó bá wu òun lòun lè ṣe? Lọ́jọ́ kan, Ùsáyà wọ inú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jèhófà ò gba àwọn ọba láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Kíró. 26:16-18) Torí náà, Àlùfáà Àgbà Asaráyà tọ́ ọ sọ́nà, àmọ́ ńṣe ló gbaná jẹ. Ó ṣeni láàánú pé Ùsáyà ba orúkọ rere tó ní lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́, Jèhófà sì fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú. (2 Kíró. 26:19-21) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ì bá má ṣẹlẹ̀ sí i ká ní ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. w23.09 10 ¶9-10
Friday, August 15
Ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, torí ó ń bẹ̀rù àwọn tó dádọ̀dọ́.—Gál. 2:12.
Kódà lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù di Kristẹni ẹni àmì òróró, ó ṣì ń bá àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan yí. Nígbà tó di ọdún 36 S.K., Pétérù wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run fẹ̀mí yan Kọ̀nílíù tí kì í ṣe Júù. Èyí jẹ́ ká rí i kedere pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,” ó sì fẹ́ káwọn tí kì í ṣe Júù di ara ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 10:34, 44, 45) Àtìgbà yẹn ni Pétérù ti ń jẹun pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Júù torí kì í ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àmọ́ àwọn Júù kan ṣì ń rò pé kò yẹ káwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù máa jẹun pa pọ̀. Nígbà táwọn Júù tó nírú èrò yẹn wá sí Áńtíókù, Pétérù ò jẹun pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù mọ́, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé kò fẹ́ múnú bí àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí ohun tí Pétérù ṣe yìí, ó bá a wí lójú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀. (Gál. 2:13, 14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ṣàṣìṣe, ó ń sin Jèhófà nìṣó. w23.09 22 ¶8
Saturday, August 16
Ó máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in.—1 Pét. 5:10.
Tó o bá ṣàyẹ̀wò ara ẹ dáadáa, o lè rí i pé ó láwọn ibi tó o kù sí, àmọ́ má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Bíbélì sọ pé: “Onínúure ni [Jésù] Olúwa,” ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. (1 Pét. 2:3) Àpọ́sítélì Pétérù fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run . . . máa fúnra rẹ̀ parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yín. Ó máa fún yín lókun.” Ìgbà kan wà tí Pétérù ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Lúùkù 5:8) Àmọ́ torí pé Jèhófà àti Jésù ràn án lọ́wọ́, ó ṣiṣẹ́ kára kó lè máa jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi nìṣó. Torí náà, Jèhófà fún Pétérù láǹfààní láti “wọlé fàlàlà sínú Ìjọba ayérayé ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” (2 Pét. 1:11) Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn! Tá a bá fara wé Pétérù, tá a jẹ́ kí Jèhófà dá wa lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, tá ò sì jẹ́ kó sú wa, àá gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun. ‘Ọwọ́ wa sì máa tẹ èrè ìgbàgbọ́ wa, ìyẹn ìgbàlà wa.’—1 Pét. 1:9. w23.09 31 ¶16-17
Sunday, August 17
Ẹ jọ́sìn Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé.—Ìfi. 14:7.
Inú àgbàlá kan ni àgọ́ ìjọsìn wà, wọ́n sì ṣe ọgbà yí i ká. Ibẹ̀ ni àwọn àlùfáà ti máa ń ṣiṣẹ́. Pẹpẹ bàbà ńlá kan tí wọ́n ń rú ẹbọ sísun lórí ẹ̀ wà nínú àgbàlá náà, bàsíà kan tí wọ́n fi bàbà ṣe tún wà níbẹ̀. Inú ẹ̀ ni àwọn àlùfáà ti máa ń bu omi láti fi wẹ̀ kí wọ́n tó ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́. (Ẹ́kís. 30:17-20; 40:6-8) Lónìí, àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró ń ṣiṣẹ́ ní àgbàlá inú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tó wà láyé. Omi tó wà nínú bàsíà ńlá ń rán àwọn ẹni àmì òróró létí pé, ó yẹ kí wọ́n jẹ́ mímọ́ nínú ìwà wọn àti nínú ìjọsìn wọn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ń rán àwa Kristẹni yòókù létí. Ibo wá ni “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” ti ń jọ́sìn? Àpọ́sítélì Jòhánù rí wọn tí “wọ́n dúró níwájú ìtẹ́.” Ní ayé níbí, iwájú ìtẹ́ yẹn ló ṣàpẹẹrẹ àgbàlá ìta níbi tí “wọ́n [ti] ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún [Ọlọ́run] tọ̀sántòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Ìfi. 7:9, 13-15) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà jẹ́ ká máa jọ́sìn òun nínú tẹ́ńpìlì ńlá rẹ̀ tẹ̀mí! w23.10 28 ¶15-16
Monday, August 18
Nítorí ìlérí Ọlọ́run, . . . ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú kó di alágbára.—Róòmù 4:20.
Àwọn alàgbà wà lára àwọn tí Jèhófà ń lò láti fún wa lókun. (Àìsá. 32:1, 2) Torí náà, tí nǹkan kan bá ń dà ẹ́ láàmú, sọ nǹkan náà fáwọn alàgbà. Tí wọ́n bá láwọn fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́, má kọ ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe fún ẹ. Ìdí sì ni pé Jèhófà lè lò wọ́n láti mú kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára. Àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé àwọn Kristẹni kan máa gbé ọ̀run títí láé, àwọn yòókù sì máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè máa ń jẹ́ ká nírètí. (Róòmù 4:3, 18, 19) Ìrètí tá a ní yìí ń fún wa lókun ká lè fara da ìṣòro, ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì máa ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́. (1 Tẹs. 1:3) Ìrètí yẹn kan náà ló fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lókun. Ó sọ pé wọ́n ‘há òun gádígádí, ọkàn òun dà rú, wọ́n ṣe inúnibíni sí òun, wọ́n sì gbé òun ṣánlẹ̀.’ Kódà, ẹ̀mí ẹ̀ máa ń wà nínú ewu. (2 Kọ́r. 4:8-10) Pọ́ọ̀lù rí okun gbà torí pé ó tẹjú mọ́ ohun tó ń retí, ìyẹn sì jẹ́ kó fara da àwọn ìṣòro ẹ̀. (2 Kọ́r. 4:16-18) Pọ́ọ̀lù tẹjú mọ́ èrè ọjọ́ iwájú tó ní láti gbé ọ̀run títí láé. Ó máa ń ronú nípa ìrètí yẹn, torí náà, ó ń di “ọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.” w23.10 15-16 ¶14-17
Tuesday, August 19
Jèhófà yóò fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní agbára. Jèhófà yóò fi àlàáfíà jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀.—Sm. 29:11.
Tó o bá ń gbàdúrà, wò ó bóyá àsìkò ti tó lójú Jèhófà láti dáhùn àdúrà ẹ. Ó lè máa ṣe wá bíi pé kí Jèhófà dáhùn àdúrà wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà mọ àsìkò tó dáa jù láti dáhùn àdúrà wa. (Héb. 4:16) Tá ò bá tètè rí ìdáhùn àdúrà wa, a lè rò pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà wa. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé kò tíì tó àsìkò lójú ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin ọ̀dọ́ kan lè bẹ Jèhófà pé kó wo òun sàn. Àmọ́ Jèhófà ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sọ pé Jèhófà wò ó sàn lọ́nà ìyanu ni, Sátánì lè sọ pé torí pé Jèhófà wò ó sàn ló ṣe ń sin Jèhófà. (Jóòbù 1:9-11; 2:4) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti mọ ìgbà tó máa mú gbogbo àìsàn kúrò pátápátá. (Àìsá. 33:24; Ìfi. 21:3, 4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, a ò lè retí pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa wò wá sàn lọ́nà ìyanu. Torí náà, arákùnrin yẹn lè bẹ Jèhófà pé kó fún òun lókun, kó sì jẹ́ kọ́kàn òun balẹ̀ kóun lè máa fara da àìsàn náà, kóun sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. w23.11 23 ¶13
Wednesday, August 20
Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa, kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.—Sm. 103:10.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sámúsìn ṣe àṣìṣe ńlá, síbẹ̀ kò jẹ́ kó sú òun láti máa sin Jèhófà. Ó lo àǹfààní tó ní láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un, ìyẹn ni pé kó gbéjà ko àwọn Filísínì. (Oníd. 16:28-30) Sámúsìn bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun ‘gbẹ̀san lára àwọn Filísínì.’ Ọlọ́run tòótọ́ dáhùn àdúrà Sámúsìn, ó sì fún un lágbára lọ́nà ìyanu. Àwọn Filísínì tí Sámúsìn pa lọ́tẹ̀ yìí pọ̀ gan-an ju àwọn tó pa tẹ́lẹ̀ lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sámúsìn jìyà àbájáde àṣìṣe tó ṣe, kò ṣíwọ́ láti máa sin Jèhófà. Torí náà tá a bá ṣàṣìṣe, tí wọ́n sì bá wa wí tàbí tá a pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa sin Jèhófà nìṣó. Máa rántí pé Jèhófà kì í jẹ́ kọ́rọ̀ wa sú òun. (Sm. 103:8, 9) Torí náà, tá a bá tiẹ̀ ṣe àwọn àṣìṣe kan, Jèhófà ṣì lè lò wá bó ṣe lo Sámúsìn. w23.09 6 ¶15-16
Thursday, August 21
Ìfaradà ń mú ìtẹ́wọ́gbà wá; ìtẹ́wọ́gbà sì ń mú ìrètí wá.—Róòmù 5:4.
Tó o bá nífaradà, Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà ẹ́. Àmọ́ kì í ṣe torí pé o níṣòro tàbí torí àdánwò tó dé bá ẹ ni Jèhófà ṣe tẹ́wọ́ gbà ẹ́. Ìwọ ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, kì í ṣe àwọn ìṣòro ẹ. Torí pé o nífaradà ni inú Jèhófà ṣe ń dùn sí ẹ. Ṣéyẹn ò múnú ẹ dùn? (Sm. 5:12) Rántí pé Ábúráhámù fara da àwọn àdánwò tó dé bá a, Jèhófà sì tẹ́wọ́ gbà á. Jèhófà pè é ní olódodo, ó sì sọ ọ́ di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jẹ́n. 15:6; Róòmù 4:13, 22) Ọlọ́run lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwa náà. Kì í ṣe irú iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run tàbí bí iṣẹ́ tá à ń ṣe ṣe pọ̀ tó ni Ọlọ́run máa fi tẹ́wọ́ gbà wá. Ohun tó ń múnú Jèhófà dùn sí wa ni pé a jẹ́ olóòótọ́, a sì nífaradà. Láìka ọjọ́ orí wa, ohun tí agbára wa gbé tàbí ipò wa sí, gbogbo wa la lè nífaradà. Ṣé àdánwò kan wà tó ò ń fara dà lọ́wọ́lọ́wọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, máa rántí pé inú Ọlọ́run ń dùn sí ẹ, kó o sì jẹ́ kíyẹn máa mára tù ẹ́. Bá a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wá ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ọwọ́ wa máa tẹ àwọn ohun rere lọ́jọ́ iwájú. w23.12 11 ¶13-14
Friday, August 22
Ṣe bí ọkùnrin.—1 Ọba 2:2.
Arákùnrin kan gbọ́dọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń báni sọ̀rọ̀. Ó gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, kó sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíì. (Òwe 20:5) Ó yẹ kó máa kíyè sí ohùn tẹ́nì kan fi sọ̀rọ̀, bó ṣe ṣojú àti ìṣesí ẹ̀. O ò lè kíyè sí àwọn nǹkan yìí tó ò bá kí í bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Tó bá jẹ́ gbogbo ìgbà lò ń fi fóònù bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, tó o sì ń lò ó láti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, ó máa nira fún ẹ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Torí náà, máa wáyè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. (2 Jòh. 12) Ọkùnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ gbọ́dọ̀ lè bójú tó ara ẹ̀ àti ìdílé ẹ̀. (1 Tím. 5:8) Ohun tó dáa jù ni pé kó o kọ́ṣẹ́ táá jẹ́ kó o máa ríṣẹ́ ṣe. (Ìṣe 18:2, 3; 20:34; Éfé. 4:28) Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òṣìṣẹ́ kára ni ẹ́, tó o bá sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kan, o máa ń parí ẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o ríṣẹ́, kó má sì bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. w23.12 27 ¶12-13
Saturday, August 23
Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ bí olè ní òru.—1 Tẹs. 5:2.
Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa “ọjọ́ Jèhófà,” ohun tó ń sọ ni ìgbà tó máa pa àwọn ọ̀tá ẹ̀ run, tó sì máa gba àwọn èèyàn ẹ̀ là. Nígbà àtijọ́, Jèhófà fìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè kan. (Àìsá. 13:1, 6; Ìsík. 13:5; Sef. 1:8) Lákòókò tiwa yìí, “ọjọ́ Jèhófà” máa bẹ̀rẹ̀ nígbà táwọn alákòóso ayé bá pa Bábílónì Ńlá run, ó sì máa parí nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Tá ò bá fẹ́ wà lára àwọn tó máa pa run lọ́jọ́ yẹn, ó yẹ ká bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ báyìí. Jésù kọ́ wa pé kì í ṣe ká kàn máa retí ìgbà tí “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀, ó tún yẹ ká máa “múra sílẹ̀” de ọjọ́ yẹn. (Mát. 24:21; Lúùkù 12:40) Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù láti kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà, ó lo ọ̀pọ̀ àpèjúwe láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe máa múra sílẹ̀ de ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àkókò yẹn kọ́ ni ọjọ́ Jèhófà máa dé. (2 Tẹs. 2:1-3) Síbẹ̀, ó gba àwọn ará yẹn níyànjú pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ bíi pé ọ̀la ló máa dé, ó sì yẹ káwa náà fi ìmọ̀ràn yẹn sílò lónìí. w23.06 8 ¶1-2
Sunday, August 24
Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ dúró gbọn-in, ẹ má yẹsẹ̀.—1 Kọ́r. 15:58.
Lọ́dún 1978, wọ́n kọ́ ilé tó ní ọgọ́ta (60) àjà sílùú Tokyo, lórílẹ̀-èdè Japan, òun sì ni ilé tó ga jù nílùú yẹn. Àmọ́, nítorí ìmìtìtì ilẹ̀ tó máa ń ṣẹlẹ̀ nílùú yẹn, àwọn èèyàn rò pé ilé náà máa wó. Báwo ni wọ́n ṣe kọ́ ilé náà tí kò fi wó nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ ṣẹlẹ̀? Àwọn tó kọ́ ilé náà ṣe ìpìlẹ̀ ẹ̀ lọ́nà tó dúró digbí, ó sì lè fì sọ́tùn-ún fì sósì débi pé tí ìmìtìtì ilẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ ilé náà ò ní wó. Àwa Kristẹni náà dà bí ilé gogoro yẹn. Lọ́nà wo? Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ dúró gbọin-in, a ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ tó le jù mú nǹkan. Ó yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin tó bá dọ̀rọ̀ ká tẹ̀ lé òfin àtàwọn ìlànà Jèhófà. Ó tún yẹ ká “ṣe tán láti ṣègbọràn,” ká má sì yí ìpinnu wa pa dà. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká jẹ́ ẹni tó ń “fòye báni lò” tàbí ẹni tó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò tá a bá rí ibi tó yẹ ká ti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jém. 3:17) Tí Kristẹni kan bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ tó le jù mú nǹkan, kò sì ní jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú nǹkan. w23.07 14 ¶1-2
Monday, August 25
Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—1 Pét. 1:8.
Jésù borí ìdẹwò Sátánì kódà nígbà tó sọ pé kó ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí. (Mát. 4:1-11) Ohun tí Sátánì fẹ́ ṣe ni pé kí Jésù ṣẹ̀ sí Jèhófà kó má bàa lè san ìràpadà. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé, ó fara da àwọn àdánwò míì tó le. Àwọn ọ̀tá ẹ̀ ṣenúnibíni sí i, wọ́n sì fẹ́ pa á. (Lúùkù 4:28, 29; 13:31) Yàtọ̀ síyẹn, ó fara da àìpé àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ torí pé wọ́n máa ń ṣe ohun tó dùn ún. (Máàkù 9:33, 34) Nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ ẹ̀, wọ́n fìyà jẹ ẹ́ gan-an, wọ́n sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́. Nígbà tí wọ́n fẹ́ pa á, wọ́n dá a lóró, wọ́n sì dójú tì í. (Héb. 12:1-3) Ní gbogbo àkókò tó fi fara da àwọn ìṣòro yìí, Jèhófà ò gbà á sílẹ̀. (Mát. 27:46) Ká sòótọ́, ohun kékeré kọ́ ni Jésù ṣe láti san ìràpadà. Torí náà, tá a bá ń ronú nípa ohun tí Jésù ṣe nígbà tó fi ara ẹ̀ rúbọ fún wa, ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. w24.01 10-11 ¶7-9
Tuesday, August 26
Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.—Òwe 21:5.
Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ó máa ń jẹ́ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. (Jém. 1:19) Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Kì í jẹ́ ká tètè fara ya tàbí sọ ohun tí ò dáa tá a bá ní ìdààmú ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ní sùúrù, tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá, a ò ní tètè bínú. Dípò ká gbẹ̀san, ṣe làá ‘máa fara dà á fún ara wa, àá sì máa dárí ji ara wa fàlàlà.’ (Kól. 3:12, 13) Tá a bá ń ní sùúrù, ó máa jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́. Dípò ká kánjú ṣe ohun kan láì ro ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí, ṣe ló yẹ ká ṣèwádìí nípa nǹkan náà ká lè ṣèpinnu tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wáṣẹ́, a lè fẹ́ gba iṣẹ́ tá a kọ́kọ́ rí. Àmọ́ tá a bá ní sùúrù, á jẹ́ ká ronú nípa àkóbá tí iṣẹ́ náà lè ṣe fún ìdílé wa àti ìjọsìn wa. Torí náà, tá a bá ń ní sùúrù, kò ní jẹ́ ká ṣe ìpinnu tí ò dáa. w23.08 22 ¶8-9
Wednesday, August 27
Mo rí òfin míì nínú ara mi tó ń bá òfin tó ń darí èrò mi jagun, tó sì ń sọ mí di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ara mi.—Róòmù 7:23.
Inú ẹ lè má dùn torí pé nígbà míì nǹkan tí ò dáa máa ń wá sí ẹ lọ́kàn. Àmọ́, tó o bá ń ronú nípa ìlérí tó o ṣe fún Jèhófà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, wàá lókun tí wàá fi borí ìdẹwò náà. Lọ́nà wo? Nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe lo sẹ́ ara ẹ. Ìyẹn ni pé o ti kọ gbogbo ìwà tínú Jèhófà ò dùn sí àtàwọn nǹkan tí ò dáa tó lè máa wù ẹ́. (Mát. 16:24) Torí náà, tí ìdẹwò bá dé, o ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú nǹkan tó o máa ṣe. Ìdí ni pé o ti mọ ohun tó o máa ṣe tẹ́lẹ̀, ìyẹn sì ni pé wàá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ìpinnu ẹ ni pé o fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dà bíi Jóòbù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó láwọn ìṣòro tó le gan-an, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!”—Jóòbù 27:5. w24.03 9 ¶6-7
Thursday, August 28
Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.—Sm. 145:18.
Jèhófà “Ọlọ́run ìfẹ́” wà pẹ̀lú wa! (2 Kọ́r. 13:11) Ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Torí náà, ó dá wa lójú pé ‘ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí wa ká.’ (Sm. 32:10) Bá a bá ṣe ń ronú lórí ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé ó ń bójú tó wa, àá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. A láǹfààní láti gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì sọ fún un pé kó túbọ̀ fìfẹ́ hàn sí wa. A lè sọ gbogbo ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa fún un, kó sì dá wa lójú pé ó mọ ohun tá a fẹ́, á sì ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 145:19) Bó ṣe máa ń wù wá pé ká yáná nígbà tí òtútù bá mú wa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń wù wá kí Jèhófà fìfẹ́ hàn sí wa. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa lágbára gan-an, ìfẹ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ sì ni. Jẹ́ kínú ẹ máa dùn torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa gbà kí Jèhófà máa fìfẹ́ hàn sí wa, ká sì máa sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà”!—Sm. 116:1. w24.01 31 ¶19-20
Friday, August 29
Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ.—Jòh. 17:26.
Jésù ò kàn sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run torí pé àwọn Júù tí Jésù ń kọ́ ti mọ orúkọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀. Àmọ́ Jésù ni “ẹni tó ṣàlàyé” ẹni tí Jèhófà jẹ́ lọ́nà tó dáa jù. (Jòh. 1:17, 18) Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì máa ń gba tẹni rò. (Ẹ́kís. 34:5-7) Jésù jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí yé wa dáadáa nígbà tó sọ àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá àti bàbá ẹ̀. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì ń gba tẹni rò. Nígbà tí bàbá yìí rí ọmọ ẹ̀ tó ti ronú pìwà dà tó “ń bọ̀ ní òkèèrè,” ó sáré lọ pàdé ẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó sì dárí jì í tọkàntọkàn. (Lúùkù 15:11-32) Torí náà, Jésù ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. w24.02 10 ¶8-9
Saturday, August 30
Fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ tu àwọn míì nínú.—2 Kọ́r. 1:4.
Jèhófà máa ń tu àwọn tó níṣòro nínú, kára lè tù wọ́n. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà bó ṣe ń ṣàánú àwọn èèyàn, tó sì ń tù wọ́n nínú? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká láwọn ànímọ́ táá jẹ́ ká máa tu àwọn èèyàn nínú. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ náà? Kí lá jẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn, ká sì ‘máa tu ara wa nínú’ lójoojúmọ́? (1 Tẹs. 4:18) Ohun táá jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa bára wa kẹ́dùn, ká ní ìfẹ́ ará àti inú rere. (Kól. 3:12; 1 Pét. 3:8) Báwo làwọn ànímọ́ yìí ṣe máa ràn wá lọ́wọ́? Tá a bá lójú àánú, tá a sì tún láwọn ànímọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí, kò sí bá ò ṣe ní máa tu àwọn tó níṣòro nínú. Jésù sọ pé “ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ. Ẹni rere máa ń mú ohun rere jáde látinú ìṣúra rere rẹ̀.” (Mát. 12:34, 35) Torí náà, ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni pé ká máa tù wọ́n nínú. w23.11 10 ¶10-11
Sunday, August 31
Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa lóye.—Dán. 12:10.
Ká tó lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àfi kí ẹnì kan ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Ká sọ pé o fẹ́ lọ síbì kan tó ò mọ̀, àmọ́ ọ̀rẹ́ ẹ kan tó mọ ibẹ̀ dáadáa tẹ̀ lé ẹ lọ. Bẹ́ ẹ ṣe ń lọ, ó mọ ibi tẹ́ ẹ dé, ó sì mọ ibi tí ọ̀nà kọ̀ọ̀kan já sí. Ó dájú pé inú ẹ á dùn pé ọ̀rẹ́ ẹ bá ẹ lọ. Jèhófà ló dà bí ọ̀rẹ́ yẹn torí ó mọ ibi tí ọ̀rọ̀ ayé yìí dé àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, ká lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó yẹ ká fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Dán. 2:28; 2 Pét. 1:19, 20) Bíi ti òbí rere kan, Jèhófà fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ òun dáa. (Jer. 29:11) Àmọ́ Jèhófà yàtọ̀ sáwọn òbí wa torí pé òun lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, táá sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó ní kí wọ́n kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ sínú Bíbélì ká lè mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀.—Àìsá. 46:10. w23.08 8-9 ¶3-4