Ayọ̀ Yíká Ilẹ̀-ayé
“KÍYÈSÍ I, awọn iranṣẹ mi yoo kọrin fun inúdídùn.” (Aisaya 65:14) Bẹẹ ni Jehofa wí nipasẹ wolii rẹ̀ Aisaya, irú ìmúṣẹ agbórínlọ́lá wo sì ni awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ńní láàárín awọn Ẹlẹrii Jehofa! Lati ibo ni ayọ̀ ọkàn-àyà wọn ti wá? Lati inú ìjọsìn oniṣọkan wọn fun Jehofa Ọlọrun ni. Oun jẹ́ “Ọlọrun aláyọ̀,” awọn wọnni tí wọn sì ńjọ́sìn rẹ̀ jẹ́ “aláyọ̀ ninu Jehofa.” (1 Timoti 1:11, New World Translation; Sẹkaraya 10:7) Ìfọkànsìn aláyọ̀ yii so wọn pọ̀ ṣọ̀kan di orílẹ̀-èdè kan gẹgẹbi wọn ti nwaasu ihinrere Ijọba naa papọ̀ tí wọn sì ńkígbe ìyìn sí Ọlọrun wọn yíká ilẹ̀-ayé.—Iṣipaya 7:9, 10.
“Ayọ̀ Kan Tí Ẹnikẹni Kò Lè Gbà Kúrò”
Nitootọ, pipolongo orukọ ati Ijọba Ọlọrun jẹ́ orísun ayọ̀ nigbagbogbo fun awọn Ẹlẹrii Jehofa. (Maaku 13:10) Wọn dáhùnpadà sí awọn ọ̀rọ̀ onísáàmù naa: “Ẹ maa ṣògo ní orukọ rẹ̀ mímọ́; jẹ́ kí àyà awọn tí ńwá Oluwa [“Jehofa,” NW] kí ó yọ̀.”—Saamu 105:3.
Níye-ìgbà, wọn ṣẹ́pá awọn ohun ìdínà lati ṣe eyi. Ní Spain, Isidro yà araarẹ̀ sí mímọ́ fun Jehofa, oun sì fẹ́ lati bá awọn ẹlomiran sọ̀rọ̀ nipa Rẹ̀. Ṣugbọn oun jẹ́ awakọ̀ ọkọ̀-akẹ́rù ti o ni àkókò isinmi ranpẹ, ó ńrìnrìn-àjò gígùn la òru já tí ó sì ńsùn lójú ọjọ́. Isidro fẹ́ lati jẹ́rìí fun awọn awakọ̀ ẹrù miiran, ṣugbọn bawo ni oun ṣe lè ṣe eyi?
Oun so redio CB kan (redio ijumọsọrọpọ adani) tí oun lè lò lati fi bá awọn awakọ̀ miiran sọrọ mọ ọkọ̀-ẹrù rẹ̀. Láìpẹ́ ni o ṣàwárí ila ibanisọrọpọ 13 tí a kìí lò pupọ, ó sì pinnu lati lò àǹfààní rẹ̀. Nitootọ, nigbati oun kọ́kọ́ dábàá fun awọn awakọ̀ ẹrù miiran pe kí awọn sọ̀rọ̀ nipa Bibeli lórí redio CB, ìdáhùn naa jẹ́ bẹẹkọ niti gidi. Ṣugbọn awọn kan fetisilẹ. Ọ̀rọ̀ tànkálẹ̀, pupọ ati pupọ síi ninu awọn awakọ̀ ẹrù ara Spain wọnyi sì ńyí redio wọn sí ila ijumọsọrọpọ 13. Láìpẹ́ yii, Isidro gbọ́ pe ó kérétán ẹnikan ńgbé ìgbésẹ̀ lati mú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ tẹsiwaju.
Ní Italy ọkunrin kan gbọ́ nipa awọn Ẹlẹrii Jehofa nipasẹ ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí ó ṣe ninu bọ́ọ̀sì. Aya rẹ̀ bá wọn pade nipasẹ ọ̀rẹ́ kan. Awọn mejeeji kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn sì háragàgà lati ṣàjọpín ohun tí wọn kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran. Ìháragàgà wọn débi pe ọkunrin naa kọ ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ aya rẹ̀ sì kọ iṣẹ́ tí ńmówówá daradara silẹ kí wọn baa lè lò àkókò pupọ síi ní sísọ ihinrere Ijọba naa fun awọn ẹlomiran. Ó ha tóyeyẹ fun un bí? Bẹẹni. Ọkunrin naa wipe: “Lati ìgbà tí a ti wá mọ̀ otitọ, aya mi ati emi ti ní ayọ̀ ti ríran awọn ènìyàn 20 lọwọ lati wá sínú ìmọ̀ pípéye nipa ète Ọlọrun. Nigbati ó di ìrọ̀lẹ́, tí mo padà sí ilé lẹhin ọjọ́ kan ninu iṣẹ́-ìsìn Jehofa, mo nímọ̀lára pe ó rẹ̀ mí, otitọ ni. Ṣugbọn mo láyọ̀, mo sì dúpẹ́ lọwọ Jehofa fun fífún mi ní ayọ̀ tí ẹnikẹni kò lè gbà lọ.”
“Dé Apá Tí Ó Jìnnà Julọ ní Ilẹ̀-ayé”
Awọn wọnni ninu orílẹ̀-èdè aláyọ̀ ti Ọlọrun nfi ìtara kan naa bi eyi hàn níbikíbi tí wọn bá wà, àní ní “apá tí ó jìnnà julọ lórí ilẹ̀-ayé” pàápàá. (Iṣe 1:8, NW) Awọn ibi diẹ ni wọn jìnnà ju ìhà-àríwá Greenland lọ. Sibẹ, àní nibẹ pàápàá, ti o fi ibùsọ̀ 200 jin si Arctic Circle ní àríwá ni ijọ kekere ti Ilulissat wà, tí ó ní awọn ènìyàn 19 ninu. Wọn nwaasu ihinrere kannaa gẹgẹbi tọkọtaya ara Italy yẹn, a sì ru wọn sókè ní ọdun tí ó kọjá lati rí awọn ara Greenland meje tí wọn ṣe baptism ní ìṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn sí Jehofa.
Ni ọpọlọpọ ẹgbẹẹgbẹrun ibùsọ̀ lati Greenland, nitosi ilẹ̀ olóoru erékùṣù Mauritius ni Indian Ocean, ni Anjinee ti ní ayọ̀ ti o ri bi eyi. Awọn nǹkan lekoko fun Anjinee lákọ̀ọ́kọ́. Ní Mauritius lilọ sí awọn ipade Kristian ati wiwaasu níta gbangba nipa Ọlọrun ni a kò fojúwò gẹgẹbi awọn ìgbòkègbodò tí ó yẹ fun ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ Hindu ti India. Ṣugbọn Anjinee forítì í. Nisinsinyi, ọdun mẹ́sàn-án lẹhin tí oun bẹ̀rẹ̀ gẹgẹbi Kristian kan, diẹ ninu awọn ìbátan rẹ̀ tún ńkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu.
Ní ìsopọ̀ pẹlu Anjinee a nilati mẹnukan Emilio pẹlu, ní apá ibomiran ninu ayé, ní Honduras. Emilio gbọ́ ti awọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ ńjíròrò Bibeli ní ibi iṣẹ́ ó sì sọ pe kí wọn jẹ ki oun darapọ. Oun kò lè kàwé ṣugbọn ó fetisilẹ pẹlu inúdídùn nigbati a ńkà awọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ Bibeli. Gẹgẹbi otitọ Kristian ti ńwọlésínú ọkàn-àyà rẹ̀, Emilio dáwọ́ ọ̀nà ìgbésí-ayé oníwà pálapàla dúró ó sì dáwọ́ mímu ọtí ní àmujù dúró. Awọn Ẹlẹrii Jehofa kọ ọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lati kà ati lati kọ, nisinsinyi oun jẹ́ òjíṣẹ́ ninu orílẹ̀-èdè aláyọ̀ ti Ọlọrun.
Ni ẹgbẹẹgbẹrun ibusọ ni àríwá ìwọ̀-oòrùn Honduras, ìyá kan tí ó jẹ́ Eskimo ní Alaska kẹ́kọ̀ọ́ otitọ Kristian kan naa. Obinrin yii ńgbé ní abúlé àdádó kan, ìbápàdé kanṣoṣo ti o si ni pẹlu awọn Ẹlẹrii Jehofa jẹ́ kìkì nipasẹ ifiweranṣẹ. Nitori naa oun kẹ́kọ̀ọ́ nipasẹ ifiweranṣẹ, beere awọn ibeere rẹ̀ nipasẹ ifiweranṣẹ, oun nisinsinyi sì nfi itara ṣàjọpín ohun tí ó mọ̀ pẹlu awọn aládùúgbò rẹ̀. Awọn apẹẹrẹ bí irú awọn wọnyi ni a lè sọdi pupọ ó si fẹrẹẹ jẹ́ láìlópin. Yíká gbogbo ilẹ̀-ayé, awọn ọlọ́kàn tútù ńwá lati “fi ayọ̀ sin Oluwa [“Jehofa,” NW].”—Saamu 100:2.
“Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Araayin”
Ohun kan tí ó fa gbogbo awọn wọnyi mọra ni ìfẹ́ tí ó wà láàárín orílẹ̀-èdè aláyọ̀ ti Ọlọrun. Jesu wipe: “Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin ńṣe, nigbati ẹyin bá ní ìfẹ́ sí ọmọnikeji yin.” (Johanu 13:35) Ìfẹ́ Kristian ni a rí ninu ìgbésí-ayé ọjọ́-dé-ọjọ́ ti awọn Kristian ojúlówó, ati ní pataki ní awọn àkókò ìjábá.
Ní ilẹ̀ Africa kan níbití a ti fòfindè ìgbòkègbodò awọn Ẹlẹrii Jehofa lọna tí ó ṣeniláàánú, ọ̀gbẹlẹ̀ mímúná kan ṣẹlẹ̀. Ẹgbẹrun mẹ́wàá awọn ènìyàn kú, ti odidi ọ̀wọ́ agbo ẹran maluu sì ṣègbé. Bawo ni awọn Ẹlẹrii ṣe làájá? Nipa jíjẹ awọn gbòǹgbò ewéko ati hóró inu avocado tí a sè! Ṣugbọn ipò ìṣòro wọn ni a múrọrùn lọna àrà nigba ti, pẹlu iranlọwọ Ọlọrun, awọn Ẹlẹrii ní awọn ilẹ̀ miiran gba àṣẹ lọna àìròtẹ́lẹ̀ lati fi 25 ton awọn ìpèsè iranlọwọ ranṣẹ. Nitootọ, láìka ìfòfindè naa sí, awọn ìpèsè wọnyi ni awọn ológun daabobo tí wọn sì tẹ̀lé lati mú ìfijíṣẹ́ wọn dájú láìséwu!
Nítòótọ́, awọn Ẹlẹrii ara Africa wọnni kún fun ayọ̀ gidigidi lati gba ẹ̀rí ìfẹ́ awọn arakunrin wọn fun wọn yii gẹgẹbi wọn ti nírìírí ìmúṣẹ awọn ọ̀rọ̀ Aisaya: “Kiyesi, ọwọ́ Oluwa [“Jehofa,” NW] kò kúrú lati gbani, bẹẹ ni etí rẹ̀ kò wúwo tí kì yoo fi gbọ́.”—Aisaya 59:1.
Awọn Ènìyàn Alalaafia
Awọn ẹni ọlọ́kàntútù ni a tún fàmọ́ra sí orílẹ̀-èdè aláyọ̀ ti Ọlọrun nitoripe awọn memba rẹ̀ ti pa awọn ọ̀nà arógunyọ ayé yii tì ‘wọn sì ti fi awọn idà wọn rọ abẹ-ohun-èèlò ìtúlẹ̀.’ (Aisaya 2:4) Ní El Salvador, ilé ọkunrin ológun tẹlẹri kan ni ó kún fun awọn ohun ìránnilétí iṣẹ́ igbesi-aye ológun rẹ̀. Ṣugbọn nigbati ó bẹrẹ sii kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹrii Jehofa, oun mú awọn ìfẹ́-ọkàn alalaafia gbèrú. Àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀, ó kó ohun gbogbo tí ó niiṣe pẹlu ogun kuro ninu ilé rẹ̀ ó sì bẹrẹ iṣẹ́ iwaasu pẹlu ìtara.
Nigbati awọn ọmọ ogun aṣòdì sí ijọba gba àkóso abúlé rẹ̀, a mú un ní ẹlẹ́wọ̀n—ó hàn gbangba pe ẹnikan ti ṣalaye nipa rẹ̀ pé oun jẹ́ ọkunrin ológun kan tẹlẹri. Bí ó ti wù kí ó rí, oun ṣàlàyé pe oun kii ṣe ọmọ-ogun mọ́ ṣugbọn ọ̀kan lára awọn Ẹlẹrii Jehofa. Awọn adojú ijọba dé fi ẹ̀sùn níní awọn ohun-ìjà ogun ninu ilé rẹ̀ kàn án, ṣugbọn ayẹwo kinnikinni kò ṣípayá ọ̀kankan. Ẹni tí ó wà ní àmójútó awọn adojú ijọba dé naa beere lọwọ awọn aládùúgbò nipa rẹ̀ lẹhin naa. Ọkan lara awọn alaye wọn ni pe: “Oun kan ńlọ sókèsódò lójú-pópó ní wiwaasu nipa Bibeli lojoojumọ ni.” Ọkunrin naa ni a dásílẹ̀. Láìsí iyèméjì, ìtara rẹ̀ ṣèrànwọ́ lati gba ẹmi rẹ̀ là.
Ìròhìn kan lati ilẹ̀-orílẹ̀-èdè Africa kan sọ nipa awọn ọmọ-ogun meji tí wọn kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹrii Jehofa. Ọ̀kan ṣiṣẹ́sìn ninu ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ijọba, ekeji jà fun awọn ọlọ̀tẹ̀. Àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀, awọn mejeeji pinnu lati “fi idà wọn rọ abẹ ohun-èèlò ìtúlẹ̀” wọn sì kọ̀wé fi iṣẹ́ ológun silẹ. Nigbati wọn lọ sí awọn ipade Kristian fun ìgbà àkọ́kọ́, ọmọ-ogun aṣòdì sí ijọba naa beere lọwọ eyi ekeji: “Kinni iwọ ńwá níhìn-ín?” Oun fèsìpadà: “Kinni iwọ naa ńwá níhìn-ín?” Ìròhìn naa pari rẹ pe: “Lẹhin naa ní fífi ọwọ́ gba araawọn mọ́ra, wọn da omijé ayọ̀ pòròpòrò nitori wọn lè wà papọ̀ ní alaafia.” Awọn ọkunrin ológun meji tẹlẹri wọnyi láìsí iyèméjì gbàdúrà sí Ọlọrun pe: “Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, iwọ Ọlọrun ìgbàlà mi: ahọ́n mi yoo sì maa kọrin òdodo rẹ kíkan.”—Saamu 51:14.
“Iwọ Ti Rò Ti Ìṣẹ́ Mi”
“Emi yoo yọ̀, inú mi yoo sì dùn ninu àánú rẹ: nitori ti iwọ ti rò ti ìṣẹ́ mi; iwọ ti mọ ọkàn mi ninu ìpọ́njú.” (Saamu 31:7) Bẹẹni onisaamu gbàdúrà, ọpọlọpọ lonii sì yọ̀ nitoripe Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ràn wọn lọwọ lati kojú awọn ìpọ́njú wọn. Ní France ọ̀kan lára awọn Ẹlẹrii Jehofa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹlu obinrin kan ẹni tí ó jìyà lọwọ schizophrenia (àrùn ọpọlọ). Obinrin yii ti wà lábẹ́ ìtọ́jú àrùn ọpọlọ fun ìgbà kan, ṣugbọn eyi kò ṣèrànlọ́wọ́. Ọsẹ kan lẹhin tí oun ti bẹrẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, dokita ọpọlọ naa beere pe: “Njẹ iwọ niti tootọ lóye ohun tí obinrin yii ńṣàlàyé fun ọ lati inú Bibeli?” Nitori naa ní ọsẹ tí ó tẹle e, Ẹlẹrii naa lọ sí ọfiisi rẹ̀ ó sì kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu obinrin naa tí dokita naa sì wà níbẹ̀.
Lẹhin ìkẹ́kọ̀ọ́ naa, dokita ọpọlọ naa sọ fun Ẹlẹrii naa pe: “La awọn ọdun já mo ti nífẹ̀ẹ́ ninu ìsìn awọn ti ńgbàtọ́jú lọdọ mi, ṣugbọn mo ṣàkíyèsí pe isin kankan kò pèsè ìtìlẹhìn gidi eyikeyii. Ṣugbọn, ní ọ̀ràn tìrẹ, awọn nǹkan yàtọ̀. Ìyáàfin P— ńwá lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ lati wa ri mi gẹgẹ bi dokita kan, oun sì ńsanwó fun mi. Sibẹ, pẹlu ẹ̀kọ́ Bibeli rẹ ati ìmọ̀ràn rere, iwọ ńṣiṣẹ́ dídára jù lọ́fẹ̀ẹ́. Obinrin naa ńní itẹsiwaju daradara. Maa baalọ, mo sì mú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ mi kíkún dá ọ lójú bí iwọ bá nilati nílò rẹ̀.”
Bibeli wipe: “Ibukun ni fun [“aláyọ̀ ni,” NW] awọn ènìyàn tí ó mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa [“Jehofa,” NW], wọn yoo maa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ. Orukọ rẹ ni wọn yoo maa yọ̀ ní ọjọ́ gbogbo.” (Saamu 89:15, 16) Olukuluku awọn Ẹlẹrii Jehofa mọ̀ pe saamu yii jẹ́ òótọ́. Lati ẹnu wọn igbe ayọ̀ yíká ilé-ayé ńgòkè sí ìyìn Jehofa. Pupọ ati pupọ síi ńtújáde lati inú awọn orílẹ̀-èdè lati yin Ọlọrun papọ̀ pẹlu wọn. Eeṣe tí iwọ kò fi darapọ̀ kí o sì nírìírí ayọ̀ yẹn fun araàrẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Awọn Ẹlẹrii Jehofa ní ìhà-oòrùn Europe ńyọ̀ nisinsinyi ninu ominira titun ti wọn ní lati kẹ́kọ̀ọ́ “Ilé-ìṣọ́nà” ni awọn èdè tiwọn funraawọn