ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 2/1 ojú ìwé 31
  • “Ìwérí Ọba ati Ìkéde-ẹ̀rí”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ìwérí Ọba ati Ìkéde-ẹ̀rí”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 2/1 ojú ìwé 31

“Ìwérí Ọba ati Ìkéde-ẹ̀rí”

“NIGBA naa ni [Jehoada alufaa] mu ọmọkunrin ọba jade wá o sì fi ìwérí ọba ati Ìkéde-ẹ̀rí naa le é lori; wọn si tipa bayii ṣe e ni ọba wọn sì fàmì òróró yan an.” (2 Ọba 11:12, NW) Bayii ni iwe Awọn Ọba ṣe ṣapejuwe ìwúyè Ọba Jehoaṣi. Njẹ iwọ ṣakiyesi pe yatọ si “ìwérí ọba,” tabi ìbòrí kabiyesi, Jehoiada tun fi “Ìkéde-ẹ̀rí” sori ọ̀dọ́ ọba naa. Kinni Ìkéde-ẹ̀rí naa? Eesitiṣe ti o fi jẹ apakan ayẹyẹ ìwúyè yii?

Ọrọ Heberu naa ti a tumọ nihin-in si “Ìkéde-ẹ̀rí” niye igba ntọkasi awọn Ofin Mẹwaa tabi Òfin Ọlọrun lapapọ. (Ẹksodu 31:18; Saamu 78:5, Revised Standard Version) Ni ibamu pẹlu eyi, akọsilẹ ti o baradọgba ni 2 Kronika 23:11 kà ninu The Jerusalem Bible (1966) pe: “Nigba naa ni Jehoiada mu ọmọkunrin ọba jade, de e lade, o si fi Òfin naa le e lori.” Bi o ti wu ki o ri, ni 2 Ọba 11:12, itumọ yii fi ọrọ naa “kerewú” dipo “Ìkéde-ẹ̀rí,” bi o tilẹ jẹ pe ọ̀rọ̀ Heberu kannaa farahan ni awọn ẹsẹ iwe mejeeji. Eeṣe?

Alaye ọrọ Bibeli ede Germany kan ti a mọ̀ daradara, Herders Bibelkommentar, ṣalaye pe awọn olutumọ kan ko le ronu pe ọba naa yoo wọ Òfin naa sori rẹ̀ tabi si apa rẹ̀. Niwọnbi o ti jẹ pe, nigba ti a njiroro Ọba Sọọlu, 2 Samuẹli 1:10 (NW) mẹnukan kerewú (tabi, ẹ̀gbà) papọ pẹlu ìwérí ọba naa ti oun wọ̀, wọn gbagbọ pe alaye iwe ti o wa ni 2 Ọba 11:12 ni ipilẹṣẹ gbọdọ ti kà pe “ìwérí ọba ati awọn kerewú naa.” Ṣugbọn eyi wulẹ jẹ ìméfò lasan ni. Fifi “kerewú” rọpo “Ìkéde-ẹ̀rí” duro fun iyipada delẹdelẹ ninu ọrọ ẹsẹ-iwe.

Nitori naa, The New Jerusalem Bible (1985) mu èrò ti Òfin, tabi majẹmu ofin naa padabọsipo, ni titumọ àpólà ọ̀rọ̀ naa si “o sì fun un ni ẹda majẹmu naa kan.” Ṣugbọn njẹ Jehoada fun Jehoaṣi ni “Ìkéde-ẹ̀rí naa”? Loootọ, ọ̀rọ̀ Heberu naa ti a tumọsi “fi si” ni a tun le tumọ si “fun.” Ṣugbọn ninu Awọn Ọba ati Kronika, o farahan ni igba kanṣoṣo, ni titọka si ìwérí ọba ati si Ìkéde-ẹ̀rí naa. Ju bẹẹ lọ, ọ̀rọ̀ Heberu naa “sórí” ni o tẹle e. Fun ìdí yii, “fi si ori (fi sori)” gbọdọ jẹ itumọ titọna. Ìwérí ọba ati Ìkéde-ẹ̀rí ni a “fi sori” Jehoaṣi ọ̀dọ́ Ọba, gẹgẹ bi New World Translation ti fihan.

Nitori naa eeṣe—ati bawo—ni alufaa agba “fi” Ìkéde-ẹ̀rí naa wọ sori ọba naa? Gbe akiyesi ọmọwe akẹkọọjinlẹ ara Germany naa Otto Thenius yẹ̀wò: “Òfin naa, iwe kan ninu eyi ti a kọ awọn aṣẹ ofin ti Mose si. Eyi ni a fi há ori ọba lọna afiṣapẹẹrẹ, lẹhin ti a ti ṣe e lọṣọ pẹlu ìwérí ọba tan.” (Die Bücher der Könige) Lọna ti o farajọra, Ọmọwe Ernst Bertheau sọ pe: “Fifi Òfin naa lé [ọba naa lori] nitootọ ni itumọ afiṣapẹẹrẹ, pe ọba naa ni a fi dandan mu lati ṣakoso ni ibamu pẹlu rẹ̀.”—Die Bücher der Chronik.

Ọlọrun paṣẹ pe nigba ti ọba ba mu ijokoo rẹ lori itẹ, oun nilati kọ ẹda Òfin naa fun araarẹ̀, ní kikẹkọọ rẹ ki o si fisilo ni gbogbo igbesi-aye rẹ̀. (Deuteronomi 17:18-20) Fifi “Ìkéde-ẹ̀rí” sori ọba titun naa le ti jẹ aṣehanjade afiṣapẹẹrẹ ṣoki kan ti o nṣapejuwe pe ani bi o tilẹ jẹ pe oun ni ọba nisinsinyi, oun kò kọja Òfin Jehofa. O ba ni lọkan jẹ pe, lẹhin iku alufaa agba naa Jehoada, Jehoaṣi gbagbe ẹ̀kọ́ pataki yii o si fi ijọsin Jehofa silẹ ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ti o sì ku lọwọ awọn apaniyan lẹhin-ọ-rẹhin.—2 Kronika 24:17-25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́