Àríyànjiyàn Lori Ikú Jesu
NI ỌJỌ Irekọja 33 C.E., ìfìyà iku jẹni mẹta papọ ni o waye. Awọn ọkunrin mẹta ti a dajọ iku fun ni a dà lọ si ibi aye kan lẹhin ogiri Jerusalẹmu ti a si pa ni ọkan lara awọn ọna onirora ati atiniloju julọ: ìkànmọ́gi lori awọn opo-igi ti a gbénànró. Iru awọn ìfìyà-ikú-jẹni bẹẹ wọpọ ni akoko awọn ara Roomu, nitori naa a le ṣereti rẹ pe nisinsinyi awọn ipaniyan ọjọ Irekọja naa ni yoo ti di igbagbe tipẹtipẹ. Bi o ti wu ki o ri, ọkan lara awọn ọkunrin ti a pa ni Jesu Kristi. Iku rẹ tú iyipada ati àríyànjiyàn pataki ti o jẹ ti isin silẹ.
Ẹgbẹrun ọdun meji ti fẹrẹ kọja lati igba iṣẹlẹ yẹn, nitori naa, iwọ le ni itẹsi lati kaa si itan igbaani lasan. Bi o ti wu ki o ri, njẹ iwọ mọ pe àríyànjiyàn naa ti o dide ni a ko tii yanju rẹ̀ rara?
Gẹgẹbi iwọ ti le mọ, araadọta ọkẹ gbagbọ pe Jesu ku fun wọn. Wọn gbagbọ lọna gbigbonajanjan pe iku Kristi ni kọkọrọ naa si idande ati idariji ẹṣẹ, pe igbagbọ ninu iku rẹ ni ọna si igbala. Ṣugbọn, lọna ti o yanilẹnu ọrọ ẹkọ kan ninu Anglican Theological Review rohinsọ pe igbagbọ ti a ṣikẹ yii wa “ninu ijangbọn.” “Ijangbọn” naa si nwa lati ọdọ awọn aṣaaju isin.
Anglican Theological Review ṣalaye pe: “Ẹkọ-igbagbọ etutu ninu ironu Kristian wa ninu ijangbọn nitori pe awọn ipilẹ rẹ̀ ti Bibeli wa ninu iyemeji, ìronúgbékalẹ̀ rẹ̀ ni a ti di ẹru pa pẹlu awọn erongba ti ko tọ́jọ́ [onígbà diẹ] . . , tí ifihanjade rẹ ninu ipo tẹmi ọpọlọpọ eniyan sì ti jẹ ni ọna igbonara òdì ti ara-ẹni ati idara-ẹni lare laisi ariwisi.” Nitootọ, awọn ẹlẹkọ-isin Protestant ati Katoliki ti kuna lati dori ifohunṣọkan eyikeyii, bi iyatọ eyikeyii ba wa, niti ki ni iku Jesu Kristi tumọsi.
Iwọ le nimọlara pe eyi wulẹ jẹ riworiwo lati ọdọ awọn ògbóǹkangí ẹlẹkọọ isin diẹ, pe ko nii ṣe pẹlu ẹmi rẹ. Ṣugbọn ronu nipa eyi: Bi iku Jesu ba wepọ mọ iduro rẹ niwaju Ọlọrun ati ifojusọna rẹ fun iwalaaye ainipẹkun (ni ọrun tabi nibikibi miiran) nitootọ nigba naa àríyànjiyàn yii beere igbeyẹwo rẹ.
Eeṣe ti awọn ẹlẹkọọ isin fi ńjiyàn lori ọran naa sibẹ? Fun apẹẹrẹ, gbe Ṣọọṣi Roman Katoliki yẹwo. O ni ẹkọ ti a ṣalaye kedere lori aileku ọkan ati lori Mẹtalọkan. Sibẹ, ṣọọṣi naa jẹ alaileṣe ipinnu lọna ti o ṣajeji nipa itunrapada nipasẹ iku Kristi. New Catholic Encyclopedia gba pe: “Ọpọlọpọ ati ọtọọtọ awọn eto ni a ti mú gbèrú lati ṣalaye bi a ti da eniyan nide kuro lọwọ ibi ti ẹṣẹ mu wá ti a si mú un padabọsipo si oore ọ̀fẹ́ . . . Ṣugbọn ko si ọkankan ninu awọn eto wọnyi ti o tii ṣe aṣeyọrisirere delẹ. . . . Ẹkọ-isin Itunrapada ni a ko tii rí gbámú ni awọn apa diẹ o si nbaa lọ lati farahan gẹgẹbi iṣoro ninu ẹkọ-isin.”
Nigba naa, ko nilati jẹ iyalẹnu fun ọ, pe lara awọn araadọta ọkẹ ti wọn nfi igbonara sọ leralera pe ‘Jesu ku fun wa,’ awọn diẹ ní ero ti ko ṣe kedere niti ohun ti iyẹn tumọsi niti gidi. Gẹgẹbi Anglican Theological Review ti ṣe sọ ọ́: “Nigba ti a ba beere lọwọ wọn leralera . . . niye igba ni Kristian onigbagbọ ko le tọkasi orisun ẹkọ-igbagbọ naa ninu bibeli, tabi lati ṣalaye bi o ṣe nṣiṣẹ.” Pẹlu ẹrù ẹkọ ti wọn ko loye tabi le ṣalaye ti a dì lé wọn lori, awọn olujọsin ninu ṣọọṣi dojukọ iṣoro lati ri bi iku Jesu ṣe tan mọ igbesi-aye wọn.
Ikuna Kristẹndọm lati sọrọ ẹkọ-igbagbọ itunrapada jagaara ti tun sọ awọn isapa rẹ lati de ọdọ awọn Júù, Hindu, onisin Buddha, ati awọn miiran pẹlu ihin-iṣẹ Kristian naa di alaigbeṣẹ. Nigba ti o jẹ pe ọpọlọpọ iru awọn wọnyi nifẹẹ ti wọn si bọwọ fun awọn ẹkọ Jesu, idarudapọ ti o yi iku Kristi ka ati ohun ti o tumọsi duro gẹgẹbi ìdínà fun igbagbọ.
Njẹ ijẹpataki iku Kristi wulẹ jẹ ohun ijinlẹ kan lasan—ti o rekọja imoye ẹda-eniyan? Tabi alaye rẹ ti o lọgbọn ninu, ti a gbekari Bibeli ha wa? Awọn ibeere wọnyi lẹtọọsi igbeyẹwo rẹ, nitori Bibeli sọ ọrọ yiyanilẹnu yii nipa Kristi pe: ‘Ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ ki yoo ṣegbe, ṣugbọn yoo ni iye ainipẹkun.’—Johanu 3:16.