ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 3/1 ojú ìwé 14
  • “Awọn Agutan Fetisi Ohùn Rẹ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Awọn Agutan Fetisi Ohùn Rẹ̀”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Fetisilẹ Nígbẹ̀hìn Gbẹ́hìn
  • A Gbọ Adura Obinrin Olufọkansin Kan
  • Ibi Tí A Ti Lè Rí Ìtùnú Gbà
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà àti Agbo Àgùntàn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Bẹ Ilẹ Naa Wò, Bẹ Awọn Agutan Naa Wò!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ẹ Ṣọ́ra Fún “Ohùn Àwọn Àjèjì”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 3/1 ojú ìwé 14

Awọn Olùpòkìkí Ijọba Rohin

“Awọn Agutan Fetisi Ohùn Rẹ̀”

◻ JESU wipe: “Awọn agutan sì gbọ́ ohùn [oluṣọ agutan]: o sì pe awọn agutan tirẹ̀ ni orukọ, o sì ṣe amọna wọn jade.” (Johanu 10:3) Oun tun fikun un siwaju sii pe: “Mo mọ awọn agutan temi, awọn agutan temi sì mọ̀ mi.” (Johanu 10:14, NW) Awọn ẹni bi agutan nfetisi ohùn Jesu gẹgẹ bi oun ti nba wọn sọrọ nipasẹ Bibeli. Ṣakiyesi bi awọn eniyan aláìlábòsí ọkàn meji ni Italy ṣe tẹle ipa-ọna yii.

O Fetisilẹ Nígbẹ̀hìn Gbẹ́hìn

◻ Alberto kọwe pe: “Mo jẹ ẹni ọdun mẹrindinlogun nigba ti mo bẹrẹ sii mu igbó ti mo sì nlo oogun lile LSD, nigba ti mo di ẹni ọdun mejidinlogun mo yijusi lilo heroin. Ki ọwọ́ mi baa lè tẹ oogun naa, mo ṣe ohunkohun ti o ṣeeṣe. Mo jalè, mo ta oogun laibofinmu, mo luni ni jìbìtì, mo ta gbogbo awọn ohun ìní mi. Emi kò wulẹ le dawọ duro. Lilo akoko isinmi loke okun, saa gigun ninu igberiko, tabi ikowọnu oṣelu pẹlu awọn awujọ oniyiipada tegbòtigaga ti wọn ranrí mọ́ gbigbejako aiṣedajọ-ododo—ko si ọkankan ninu iwọnyi ti o ṣeranlọwọ. Mo gbiyanju igbeyawo, ṣugbọn laipẹ mo pada sí ẹsẹ owurọ. Ani bibi ọmọbinrin kan kò tilẹ da mi lọwọ duro ninu lilo oogun. Nitootọ, awọn nnkan wá buru jai, niwọnbi mo ti nilo owo ti o pọ sii nisinsinyi. Lẹhin naa iyawo mi fi mi silẹ, ati laaarin ọdun meji ti mo fi danikan gbe, mo ri ọmọbinrin mi kìkì lẹẹmeji. Mo nsa kiri fun awọn ti nta oogun laibofinmu ti mo jẹ lówó, mo sì jiya lọpọlọpọ igba lọwọ aisan ti didawọ duro mi múwá.

“Lẹhin naa mo ranti iwe kan ti awọn Ẹlẹrii Jehofa ti fun mi ni awọn ọdun melookan sẹhin. Mo ṣì ní in lọwọ mo sì bẹrẹ sii kà á papọ pẹlu Bibeli. Ni ọna yii mo wa mọ Ọlọrun tootọ naa, Jehofa, mo sì gbadura fun iranlọwọ. Gẹgẹ bi mo ti nfi awọn ohun ti mo nkẹkọọ rẹ̀ silo diẹdiẹ, irora ti o jẹ àmì fun idawọduro mi tubọ nlọsilẹ. Mo ri iṣẹ kan, ati pẹlu iranlọwọ Jehofa mo gbe idile mi ró pada. Mo lọ si Gbọngan Ijọba, nibẹ mo sì ti mọ daju pe awọn Ẹlẹrii Jehofa ní otitọ. Bi a ti pada sopọṣọkan, emi ati iyawo mi kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹrii ati ni asẹhinwa asẹhinbọ a ṣe baptisi. Nisinsinyi, iru ayọ wo ni o jẹ fun mi lati ṣajọpin ireti wa pẹlu awọn ẹlomiran gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee!”

A Gbọ Adura Obinrin Olufọkansin Kan

◻ Obinrin kan rohin pe: “Ni 1958, mo nlọwọ ninu awọn igbokegbodo ṣọọṣi pẹlu akikanjuuṣẹ, paapaa ninu irin ajo isin lọ si Ile Ijọsin Madonna ti Ifẹ Atọrunwa ni Rome. Laipẹ mo di ọ̀rẹ́ timọtimọ fun alufaa agbà kan ẹni ti o jẹ aṣoju alufaa ni Rome, mo si ti nìkan bá Pope Paul Kẹfa ati John Paul Keji sọrọ pọ niye igba. Lẹhin ọdun mẹẹdọgbọn ṣiṣeto irin ajo isin, mo gba iwe ẹ̀rí ìyìn. Bi o ti wu ki o ri, laipẹ igbagbọ mi gẹgẹ bi Katoliki onitara kan bẹrẹ sii mì. Mo ṣakiyesi olè jija, iluni ni jìbìtì, ojurere olójúsàájú si ẹbí ẹni, ati ìtajà fàyàwọ́. Mo bẹrẹ sii wo ṣọọṣi naa pẹlu oju ti o yatọ gẹgẹ bi mo ti rii pe ofin Ọlọrun ni a maa nfi ẹsẹ tẹ̀ mọ́lẹ̀ niye igba. Iru awọn nnkan bẹẹ daamu mi, mo sì beere lọwọ Ọlọrun pe ki o ràn mi lọwọ nitori pe mo nsọ igbagbọ mi nù. Mo sunkún lọpọlọpọ ìgbà.

“Lẹhin naa, ni ọdun mẹrin sẹhin, ọmọkunrin mi mu awọn ẹ̀dà iwe irohin Ilé-ìṣọ́nà ati Ji! diẹ wa fun mi ti oun ti gba lọwọ awọn Ẹlẹrii Jehofa. Awọn iwe irohin naa fanilọkan mọra debi pe mo sọ fun un ki o gba diẹ sii fun mi wa. Laipẹ lẹhin naa mo ri Gbọngan Ijọba awọn Ẹlẹrii Jehofa mo sì fi ìwé pélébé kan silẹ lẹnu ilẹkun ni bibeere fun ẹni kan lati bẹ̀ mi wò. Awọn Ẹlẹrii naa wá ni ọjọ mẹrin lẹhin naa. Mo bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli mo sì tẹsiwaju de ori baptism. Nisinsinyi o da mi loju pe nikẹhin mo ti ri ohun ti mo nwa nigba gbogbo—otitọ!”

Awọn eniyan wọnyi fetisilẹ si ohùn Oluṣọ Agutan Rere naa, Jesu Kristi, ‘otitọ sì sọ wọn di ominira.’—Johanu 8:32.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 14]

Garo Nalbandian

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́