ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 3/15 ojú ìwé 26-28
  • Pipolongo Ihin Rere ni “Ilu Polynesia” Ti New Zealand

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pipolongo Ihin Rere ni “Ilu Polynesia” Ti New Zealand
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Awọn Ara Samoa Ńní Itẹsiwaju
  • Idahunpada awọn ara Niue
  • Awọn Itẹjade Lede Polynesia
  • Yíyọ̀ Nidii Tabili Tẹmi Kan
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 3/15 ojú ìwé 26-28

Pipolongo Ihin Rere ni “Ilu Polynesia” Ti New Zealand

“ILU Polynesia Titobi Julọ ni Agbaye.” Iyẹn ni ohun ti awọn kan ti pe Auckland olu-ilu New Zealand. Eeṣe? Kii wulẹ ṣe nitori pe o jẹ ile awọn Maori, awọn ara Polynesia ti New Zealand funraarẹ, ṣugbọn nitori pe ẹgbẹẹgbẹrun mẹwaa mẹwaa awọn ara Polynesia miiran tun ngbe nibẹ. Ni awọn ọdun lọọlọọ yii wọn ti ṣíwá lati Iwọ-oorun Samoa, Erekuṣu Cook, Tonga, Niue, ati awọn erekuṣu okun Pacific miiran. Eeṣe, awọn Maori Erekuṣu Cook pupọ ni wọn wà ni New Zealand nisinsinyi ju ni gbogbo awujọ Erekuṣu Cook funraarẹ! Lọna ti o farajọra, awọn olugbe ara Niue ni Auckland rekọja awọn wọnni ti wọn ngbe ni Niue ní ifiwera.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn ara erekuṣu Pacific wọnyi ti ṣilọ si Auckland ni ipilẹṣẹ fun ọran ìṣúnná owo, wọn tun ni awọn aini miiran lati kún. Ọkan ti o ṣe pataki fun awọn eniyan ti wọn pilẹ nifẹẹ Bibeli wọnyi ni aini tẹmi wọn. (Matiu 5:3) Ni mimọ eyi daju, awọn Ẹlẹrii Jehofa ni New Zealand ti fi aapọn sapa lati polongo “ihin rere ijọba naa” laaarin awọn ara erekuṣu wọnyi. (Matiu 24:14, NW) Ki ni a ti ṣe nipa eyi, bawo sì ni awọn ara erekuṣu naa ṣe dahunpada?

Awọn Ara Samoa Ńní Itẹsiwaju

Ọrọ ti ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan ni Samoa sọ jẹ ki a mọ ohun kan nipa oju-iwoye awọn ara erekuṣu naa lori awọn nnkan tẹmi. Oun ṣalaye pe, “Nigba ti iwọ ba kọkọ pade ẹnikan ni New Zealand, o jẹ àṣà lati beere nipa iṣẹ ọwọ́ rẹ̀.” “Ni Samoa ibeere akọkọ ti a saba maa nbeere tanmọ isin ti ẹnikan ndarapọ mọ.” Nitori naa, ko wá gẹgẹ bi iyalẹnu kankan pe ijọ meji ti awọn Ẹlẹrii Jehofa ti wọn nsọ èdè Samoa ni Auckland nyara dagba ni kanmọ ju awọn ijọ ti a saba maa nri ní New Zealand.

Ijọ Samoa akọkọ ni Auckland ni a dasilẹ ni 1977. Nitori idagba ti Ọlọrun fifun wọn, ekeji ni a dasilẹ ni ọdun meje lẹhin naa. (Fiwe 1 Kọrinti 3:6.) Ninu awọn ijọ mejeeji wọnyi, apapọ 154 olupokiki Ijọba ni wọn wà, 12 ninu wọn ńgbékánkán ṣiṣẹ ninu iṣẹ ojiṣẹ alakooko kikun. Ni ọpọ julọ awọn ọjọ Sunday, awọn eniyan ti wọn ju 275 maa npesẹ si awọn ipade ti a gbekari Bibeli eyi ti a nṣe ni Gbọngan Ijọba.

Awọn arakunrin ati arabinrin ni Samoa fi ọwọ pataki mu igbagbọ wọn, gẹgẹ bi a ti fihan ni kedere nipa itara ati ipinnu ti o fidimulẹ ṣinṣin ti wọn fihan ninu iṣẹ wiwaasu Ijọba ati sisọni di ọmọ-ẹhin wọn. (Matiu 28:19, 20) Eyi ni a lè ri lati inu iriri arabinrin ara Samoa kan ti o tẹle e:

Ninu iṣẹ ojiṣẹ ile-de-ile, arabinrin naa pade obinrin kan ti o fẹsun kan gbogbo isin pe wọn jẹ agabagebe ti o sì pa ilẹkun rẹ̀ de. Arabinrin naa ti a ko ipaya ati imujakulẹ ba ronu ohun ti oun nilati ṣe. O ronu pe, ‘Emi kò lè fi i silẹ pẹlu rironu pe awọn Ẹlẹrii Jehofa jẹ alagabagebe.’ Nitori naa o pinnu lati kọ iwe kekere kan silẹ. “Ni ṣoki mo ṣalaye ipilẹ Iwe Mimọ fun iṣẹ mi mo sì beere bi oun yoo ba fun mi ni akoko lati ṣalaye ireti ti Bibeli fi funni fun un. Mo tun fi nọmba fóònù mi kún un.”

Arabinrin naa nba iṣẹ ojiṣẹ rẹ̀ lọ, ni lilọ si awọn ile miiran. Bi oun ti de ile kẹrin ni opopo ọna yẹn, a sọ ihin-iṣẹ kan ti o wa lati ori tẹlifoonu fun un pe ki o pada sọdọ obinrin naa ti o ti fi pẹlu ibinu ti ilẹkun rẹ̀ ni iṣaaju. Arabinrin naa rohin pe, “Obinrin naa tọrọ aforiji fun idahunpada rẹ̀ akọkọ, o sì sọrọ imọriri jade fun iwe kekere ti mo kọ silẹ. Ijiroro amesojade tẹle e, ikẹkọọ Bibeli inu ile ni a sì fìdí rẹ̀ mulẹ.”

O tun muni lọkan yọ lati ri ẹmi ifara ẹni rubọ ti ojihin-iṣẹ-Ọlọrun tí diẹ lara awọn Ẹlẹrii ara Samoa fihan. Arakunrin kan ati idile rẹ̀ ṣi lọ lati Auckland si Wellington ni 1981 lati ran awujọ kekere ti wọn nṣiṣẹ laaarin awọn eniyan ara Samoa nibẹ lọwọ. Bẹrẹ lati awujọ awọn akede Ijọba 11 ni akoko yẹn, ijọ kan ti o ni 47 eniyan ninu ti gbèrú. Arakunrin naa wipe: “Awọn èrè naa tẹ̀wọ̀n ju awọn ifirubọ naa lọ.” Lẹnu aipẹ yii, oun ati idile rẹ̀ ti dahun si ‘ìpè Makedonia’ wọn sì ti ṣi pada lọ si ìhà Iwọ-oorun Samoa. (Iṣe 16:9, 10) Awọn miiran tun ti pada si awọn ibi ibugbe wọn tẹlẹri wọn sì ti bẹrẹ aṣaaju-ọna akanṣe, ijihin-iṣẹ-Ọlọrun, tabi iṣẹ-isin Bethel.

Idahunpada awọn ara Niue

Iṣẹ iwaasu tun ntẹsiwaju laaarin awọn ara Niue ni Auckland. Alaboojuto arinrin-ajo rohin pe: “Ninu iṣẹ ojiṣẹ ile-de-ile, o jẹ àṣà lati kesini wọlé. Bibeli idile ni o saba maa nwa larọọwọto, a sì kà á si ohun ti o ba ilana mu lati jiroro rẹ̀.”

Ijọ Niue agbekankanṣiṣẹ ti wà ni Auckland nisinsinyi. Nigba ibẹwo alaboojuto arinrin-ajo ni ọdun ti o kọja, awọn akede Ijọba 76 ti wọn ndarapọ mọ́ ọn ni o ṣeeṣe fun lati gba 127 awọn eniyan ni alejo si asọye Bibeli fun gbogbo eniyan ni ọjọ Sunday. Ẹmi rere sì wà laaarin awọn arakunrin ati awọn arabinrin.

Alaboojuto arinrin-ajo naa ṣakiyesi pe, “Ibẹwo naa ni a wò gẹgẹ bi akanṣe ọsẹ ifunni ni iṣiri fun gbogbo eniyan. Akoko ounjẹ kọọkan jẹ ti gbogbo ijọ. Iwọnyi sì jẹ akoko fun gbigbe iru ounjẹ ayanlaayo awọn ara Niue kalẹ iru bii takihi (ounjẹ ìbẹ́pẹ [papaya], taros [ohun ọ̀gbìn onígbòǹgbò kan ti ilẹ olooru], ati àdídùn omi àgbọn ti a dì sinu ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀), pitako (ìṣù àkàrà ti a ṣe lati inu taros, ọ̀gẹ̀dẹ̀, ati tapioca), ati punu povi (ẹran námà inu agolo), ti a maa ntọkasi lọna àwàdà nigba miiran gẹgẹ bii tìǹkó awọn ara erekuṣu.”

Awọn Itẹjade Lede Polynesia

Lati tẹ́ aini tẹmi awọn eniyan Polynesia ni Auckland ati nibomiran lọrun, Watch Tower Society ti ṣeto lati mu iye awọn itẹjade Bibeli ni awọn èdè Polynesia jade. Fun apẹẹrẹ, Watchtower ti Rarotongan, tabi ti Maori Erekuṣu Cook, ni a ntẹjade lẹẹmeji loṣu. Watchtower Niue oloṣooṣu ni a tun ngba daradara pẹlu. Ipinkiri awọn ẹda itẹjade Watchtower ni èdè Rarotonga ati Niue ti to nnkan bii 1,000 ẹ̀dà kọọkan ni lọwọlọwọ, nnkan bii 900 ẹda ninu ẹda itẹjade ti Samoa ni a sì npin kiri ni New Zealand nisinsinyi.

Ni afikun si The Watchtower, iye awọn iwe ati iwe pẹlẹbẹ melookan wà larọọwọto ni oniruuru awọn èdè Polynesia. Iwe naa Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, ti a tẹjade ni Niue ni 1989, ni itẹjade akọkọ ni èdè yẹn ti npese oye awọn ẹ̀kọ́ ipilẹ Bibeli. Eyi ti o gbeṣẹ ni pataki ni pápá Maori ti Erekuṣu Cook (ti Rarotongan) ni iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye ni èdè yẹn. O fẹrẹẹ jẹ gbogbo awọn ikẹkọọ Bibeli ile ni a ndari pẹlu iranlọwọ iwe yẹn. Alagba kan ṣakiyesi pe: “Ohun tí njẹrii si jijẹ ti o jẹ aranṣe ikọnilẹkọọ ti o gbeṣẹ ni imuratan ti awọn akẹkọọ fi bẹ̀rẹ̀ sii lọ si awọn ipade ijọ.”

Ni afikun si ipinkiri igba gbogbo ti awọn itẹjade wọnyi lati ile-de-ile, awọn eniyan Jehofa fi ọpọlọpọ iwe ikẹkọọ sode ni ohun ti a lè pe ni ijẹrii ọjà àtutà. Nitori àkúnya awọn eniyan Polynesia ni Auckland ni awọn ọdun lọọlọọ, awọn ọja titobi pẹlu awọn ibi ipatẹ onigba kukuru ti wọn fi iṣẹ wọn mọ sori tita awọn ounjẹ ati iṣẹ́ ṣiṣe ọnà Erekuṣu Pacific ti rú jáde. Awọn eniyan ti wọn pọ̀ tó 25,000 lè wa si iru ọja bẹẹ ni owurọ ọjọ Saturday. Ni lilo anfaani yii pẹlu ọgbọ́n, awọn Ẹlẹrii yoo lọ si awọn ọja wọnyi wọn sì ba awọn ọlọja ati onibaara sọ̀rọ̀ nipa Ijọba Ọlọrun.

Nipasẹ iṣẹ ojiṣẹ wọn, o ti ṣeeṣe fun awọn Ẹlẹrii Jehofa lati gbin irugbin Ijọba lọpọ yanturu ki wọn sì fi ọpọlọpọ iwe ikẹkọọ Bibeli sode lọdọ awọn eniyan Polynesia. Ẹka ọfiisi Watch Tower Society rohin pe laaarin ọdun iṣẹ isin 1990, ẹyọ iwe ikẹkọọ 23,928 lede Polynesia ni a fi ranṣẹ lati ile iṣẹ.

Yíyọ̀ Nidii Tabili Tẹmi Kan

Ni jijẹ ẹni ti aini tẹmi njẹ lọkan, awọn Ẹlẹrii Polynesia fi ijẹpataki akọkọ sori lilọ si awọn ipade Kristian ọsọọsẹ ni Gbọngan Ijọba, ati pẹlu lilọ si awọn apejọ ati apejọpọ wọn. (Heberu 10:23-25) Ni Apejọpọ Agbegbe “Idajọ-ododo Atọrunwa” ti a ṣe ni Auckland ni December 1988, akoko ijokoo ọtọọtọ ni a ṣe ni Maori ti Samoa, Niue, ati Erekuṣu Cook. Koko itẹnumọ kan ninu itolẹsẹẹsẹ lede Samoa ni awokẹkọọ Bibeli arunisoke ti a murasilẹ daradara. Awọn Ẹlẹrii ara Niue ati ara erekuṣu Cook ni Auckland ṣaṣefihan ẹmi igbanilalejo Kristian wọn nipa ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi olugbanilalejo oloore fun awọn olubẹwo lati awọn erekuṣu ibilẹ wọn. Apejọpọ naa jasi akoko kan fun jíjàsè ati yíyọ̀ nidii tabili tẹmi Jehofa. Ni Apejọpọ “Èdè Mímọ́gaara” 1990 ni Auckland, gongo 503 awọn eniyan wá si akoko ijokoo lede Samoa.

Idahunpada ti o ṣe taara si ihin-iṣẹ Ijọba jẹ ami ti o ṣe kedere pe awọn eniyan Erekuṣu Polynesia ti guusu okun Pacific ti ‘nduro fun ofin Oluwa [“Jehofa,” NW].’ (Fiwe Aisaya 42:4, 12.) Ni iha tiwọn ẹ̀wẹ̀, pẹlu ayọ ni wọn fi ṣajọpin ninu pipolongo ihin rere naa ni “ilu Polynesia” ti New Zealand.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́