Ipenija Fífún Irugbin Ijọba ni Iha Guusu Chile
BAWO ni o ti dun mọni ninu to lati rìn la awọn ọna agbegbe igberiko didakẹrọrọ ni apa guusu Chile kọja! Agbo maluu nfi alaafia jẹ koriko ninu pápá tí igi tò gẹnrẹn sí niwaju awọn oke onina tí nru eefin tíi yinyin fi ọlanla bo ori rẹ. Iwọ lè gbọ́ awọn ẹyẹ ti wọn nke wótòwótò ati iro mímì awọn ewé ninu afẹfẹ. Bi awọn ayika yii tilẹ dabii eyi ti o ni itura alalaafia tó, awọn ipenija wà nihin-in fun awọn wọnni ti nfunrugbin otitọ Ijọba naa.
Iwọ ha fẹ lati pade diẹ ninu awọn aṣaaju-ọna wa, tabi awọn olupokiki Ijọba alakooko-kikun? Ki ni ti lilo ọjọ kan tabi meji pẹlu wọn gẹgẹ bi wọn ṣe nwaasu ihinrere naa? Lakọọkọ, jẹ ki a fetisilẹ gẹgẹ bi Jaime ati Oscar ṣe ṣapejuwe awọn idunnu ati ipenija iru ọjọ kan bẹẹ ni ìhà guusu Chile.
Ọjọ Kan ninu Iṣẹ Iwaasu Naa
“Awa bẹrẹ sii runra a sì wa kiyesi pe otutu naa ti wọnu ibugbe wa kekere. Ni wiwọ awọn ibọsẹ onirun gẹ̀ùgẹ̀ù ati pẹlu fìlà kan ti o wà lori rẹ̀ sibẹsibẹ, Oscar dide kuro lori ibusun rẹ̀. Oun tanná si ohun idana onigi, o sì tanná sí gáàsì kekere amule mooru naa lati gbọn otutu jìnnìjìnnì kuro ninu iyara naa, lẹhin naa ti o sì pada sori ibusun rẹ̀ ti o ti lọ́wọ́ọ́wọ́. Okunkun ṣì wà ni ode sibẹ, awa sì lè gbọ́ òjò naa ti o ti nrọ ni gbogbo òru. A yọju jade ni oju ferese ati lẹhin naa ti a sì wo ara wa. Óò, bawo ni yoo ṣe rọrun tó lati gba isinmi loni yii! Nigba naa a ranti awọn iwewee wa fun ọjọ naa ati aini naa lati ṣiṣẹ ni ipinlẹ adado kan ti a kò dé rara ni ọdun ti o kọja. A ru wa soke lati bẹrẹ iṣẹ.
“Ni oju ọna wa ṣaaju agogo mẹjọ, a rìn kánmọ́kánmọ́ a sì nireti pe ẹni kan yoo fi ọkọ gbé wa tabi pe bọ́ọ̀sì kan yoo ba wa lọna, ki a baa lè mu irin ajo wa yarakankan si awọn ọna ẹ̀hìn naa ti o ṣamọna si awọn ile àdádó ati awọn àgọ́ ti o wà ninu ipinlẹ wa. Nihin-in ni ọkọ katakata kan dé ti nfa ile àgbérìn onibusun pẹlu awọn oṣiṣẹ diẹ ninu rẹ̀. Awakọ naa duro o sì gba wa laaye lati gòkè sinu ọkọ. Inu wa dun pe, lonii awa lè bọ́ lọwọ iriri igbagbogbo ti ririn ninu erukuru, ọpẹlọpẹ òjò alẹ àná. Bi awa ṣe ńbá jàgàjìgì wa kọ, a nṣalabaapin ihinrere naa pẹlu awọn oniṣẹ àgbẹ̀. Nigba ti o to akoko lati sọkalẹ, a fun wọn ni awọn iwe irohin diẹ. Bawo ni awa ṣe kun fun ọpẹ to fun wiwọkọ ti o gbà wa lọwọ ririn irin ibusọ meje!
“Yoo gbà wa ni ọjọ gigun kan bi awa ṣe nrin sokesodo ninu agbegbe igberiko naa ninu iwakiri awọn ẹni yiyẹ. Nigba ti a kọkọ bẹrẹ iṣẹ wa, awa kò le loye idi ti awọn eniyan yoo fi nilati fohunṣọkan pẹlu ohun ti a sọ ṣugbọn ki wọn jọbi ẹni ti o nlọtikọ lati tẹwọgba iwe ikẹkọọ Bibeli. Awa mọ pe lọpọ igba eyi jẹ nitori pe wọn kò lè kawe. Nitori naa a rii pe o ṣanfaani lati tọka rẹ jade fun wọn pe awọn iwe wa jẹ ẹbun agbayanu fun awọn ọmọ ati ibatan wọn, awọn ẹni ti wọn le pada ṣajọpin awọn ọrọ inu rẹ̀ pẹlu wọn. Eyi ti o pọ julọ ninu awọn ti a ba sọrọ ni kò ni ọpọlọpọ ninu awọn ohun dukia aye yii. Ṣugbọn niwọn bi wọn ti layọ lati ṣajọpin ohun ti wọn ni, nigba ti wọn ba ti gba iwe ikẹkọọ Bibeli, lọpọ igba wọn nfun wa ni ẹyin, ọ̀dùnkún, beets, alubọsa, ẹwa, erèé, ati garbanzos.”
Jaime ti kẹkọọ lati ṣe awọn idamọran nigba ti onile kan ba fẹ lati fi awọn ohun eelo tọrẹ fun iwe ikẹkọọ Bibeli ti oun fifun wọn. Eeṣe? Ni akoko kan, awọn aṣaaju-ọna naa pada pẹlu ìwọ̀n 30 pọun awọn ewebẹ, ti alajumọṣiṣẹpọ rẹ̀ sì nilati gbe aaye adiyẹ kan sinu apo iwe rẹ̀ fun akoko gigun ni ọjọ naa! Jaime lọpọ igba maa ndamọran merquén, ohun eelo amohundun ti a fi ata tutu ati eroja atasansan ṣe. Irohin naa nbaa lọ pe:
“Ni lila awọn papa naa kọja, a dé awọn rucas [ile] ti awọn ọmọ ibilẹ Mapuche [ti o tumọsi, “Awọn eniyan ilẹ yii”]. O jẹ ohun ti o ṣoro lati ba awọn Mapuche ti wọn ti dagba sọrọ, nitori ọpọlọpọ nsọ kiki ede ibilẹ wọn. Nigba ti awọn ti wọn jẹ ọdọ ba wà nitosi, wọn saba maa nṣiṣẹ gẹgẹ bi olutumọ. Bi awa ṣe tubọ rin wọnu agbegbe igberiko naa, a pade awọn eniyan ti wọn ko tíì figba kan ri Bibeli ri tabi ṣe ibẹwo si ilu ti o tobi gẹgẹ bi Temuco, olu ilu ẹkun naa. Eyi gbe ipenija ti riran wọn lọwọ lati mọ bi awọn ipo aye ti nburu sii to kalẹ. Awa nilati ṣe eyi ni ṣisẹntẹle, ni fifi han wọn bi awọn iṣoro adugbo ti fi ohun ti nṣẹlẹ ni apa ibomiran han.
“Bi ọjọ ti nlọ, ẹsẹ̀ wa ti o ti rẹ̀ nbeere fun isimi. Ipo oju ọjọ ti yí pada kuro ni ti itanṣan oorun mimọlẹ yòò si ti ojo ti ngbara jọ ti o sọ agboorun wa di alaiwulo. Awọn papa ti a ṣẹṣẹ tú laipẹ yii mu ki bata tẹkowìì wa di eyi ti àbàtà lẹ̀ mọ́ pẹ́típẹ́tí. Nigba ti a gbọ awọn ọrọ naa Pase no más (Ẹ wọle wá), a fi imọriri wọle sinu ile idana ti a si ngbadun ooru aaro onigi, ife ‘kọfi’ ti a fi ọka ṣe, wàràkàṣì, ati burẹdi aṣenile ti ngbona fẹlifẹli. Áà, ẹ gbọ oorun aladun burẹdi ti a ṣẹṣẹ ṣe yẹn!
“Pẹlu okun inu ti a sọ dọtun, awa nbaa lọ titi di ọwọ irọlẹ ni sisọda awọn papa ti a kii saba mọ odi yika, bi o tilẹ jẹ pe iwọ yoo ri awọn papa ọka bàbà diẹ ti a paala si nipasẹ igbo kan ti a npe ni pica-pica, agbajọ igbo kan ti o nfigba gbogbo tutu yọ̀yọ̀ pẹlu awọn ododo alawọ ofeefee. Niwọn bi oorun yoo ti wọ laipẹ ti a si gbọdọ de oju ọna nla miiran lati ba le wọ ọkọ ero ti o kẹhin pada si ilu, irin wa onibusọ 12 yoo wa si opin laipẹ.
“A pada wale ni alaafia oun ara lile, o rẹ wa ṣugbọn a layọ, nitori pe a ti ni ọpọlọpọ ijumọsọrọpọ onidunnu pẹlu awọn ẹni bi agutan. Lẹhin igba ti a ni anfaani lati jẹun, awa ṣayẹwo ọjọ naa ti a si wọ́ ara wa ti o ti rẹ̀ sori ibusun.”
Ibẹwo si Chiloé
Agbajọpọ erekuṣu Chiloé ní ọpọlọpọ awọn erekuṣu kekeke ninu. Erekuṣu titobiju rẹ jẹ 110 ibusọ ni gigun o si ni awọn oke onigbo titutu yọyọ ti a pin sọtọọtọ nipasẹ awọn adagun omi kekeke. Iru awọn iran etikun fifanimọra wo ati awọn abule ipẹja atijọ wo ni o le ri nibikibi ti iwọ ba lọ!
Ninu ilu Achao, nitosi erekuṣu nla naa, awa ri Rubén ati Cecilia. Nigba ti wọn de ni March 1988, alufaa adugbo naa kilọ fun awọn eniyan naa ‘lati maṣe feti silẹ si tọkọtaya ti nrin kaakiri erekuṣu naa lati sọrọ nipa Bibeli.’ Awọn ilohunsi odi rẹ pa awọn diẹ lọkan dé ṣugbọn o ru itọpinpin awọn miiran soke. Bi akoko ti nlọ Rubén ati Cecilia ndari 28 ikẹkọọ Bibeli.’ Ọpọlọpọ ninu awọn ikẹkọọ naa jẹ pẹlu awọn olukọ, ti mẹrin ninu wọn ti nlo itẹjade Watch Tower naa “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial” ati Iwe Itan Bibeli Mi lati kọni ni ẹkọ isin ninu ile ẹkọ wọn.
Jehofa nbojuto awọn aṣaaju-ọna oṣiṣẹ kara wọnyi, awọn ẹni ti wọn nrin eyi ti o to 20 ibusọ loojọ ninu iwaasu Ijọba naa ati iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin. (Matiu 24:14; 28:19, 20) Ni ọjọ kan, Rubén and Cecilia nrin ni ẹgbẹ ọna kan ti o pẹ́kun si etikun kan nigba ti wọn ṣakiyesi pe pẹlu omi okun ti ko rugùdù pupọ, ọpọ yanturu awọn choritos (iru òkòtó odò kan) wà larọọwọto wọn. Rubén bẹrẹ sii kórè, ṣugbọn bawo ni wọn yoo ṣe ko wọn de ile? Cecilia yanju iṣoro yẹn. O sọ awọn ibọsẹ rẹ di apo. Awọn aṣaaju-ọna naa tipa bayii ni eroja fun pipese ounjẹ etikun aladun kan!
Ni ariwa Achao gan-an, awọn oniwaasu Ijọba alakooko kikun meji ti a mọ gẹgẹ bi aṣaaju-ọna akanṣe nkẹgbẹpọ pẹlu ijọ kekere kan ni Linao. Iṣẹ iwaasu naa bẹ̀rẹ̀ nibẹ ni 1968, Ẹlẹrii Jehofa akọkọ ni Linao ni a baptisi ni 1970. Fun ọdun mẹrin arakunrin yii wa ni oun nikan ninu iṣẹ iwaasu naa ti o si nilati farada ifiniṣẹsin lati ọdọ awọn mẹmba idile ati awọn ojulumọ. Nigbẹ̀hìn gbẹ́hín, ni 1974, iyawo rẹ dahunpada lọna daradara si otitọ Bibeli ti a si baptisi rẹ. Tẹle eyi ni mẹrin ninu awọn arakunrin ọmọ iya rẹ̀, arabinrin mẹrin, awọn arakunrin baba rẹ̀ mẹrin, awọn ọmọ arakunrin rẹ̀ mẹfa, ati ana rẹ̀ ọkunrin pẹlu iyawo rẹ̀ ṣe baptisi. Ijọ naa ti a da silẹ nibẹ jẹ idile nla kan. Bi akoko ti nlọ, mẹta ninu awọn arakunrin marun-un naa bẹrẹ si ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alagba ati ọkan gẹgẹ bi iranṣẹ iṣẹ ojiṣẹ.
Luis ati Juan jẹ oniwaasu alakooko kikun ti wọn kori afiyesi wọn jọ sori fifunrugbin eso Ijọba naa ni Quemchi, ilu kekere kan ti o wa ni 20 ibusọ lati Linao. Lojoojumọ, wọn yoo gun awọn ọgba, kọja awọn papa ti o dijupọ pẹlu eweko ti wọn yoo gùn òkè tabi sọkalẹ lori awọn oke, pẹlu iji ati ojo gẹgẹ bi alabaakẹgbẹpọ wọn nigba gbogbo. Lati de awọn erekuṣu ti o wa nitosi, wọn nlo awọn ọkọ oju omi kekeke ti o maa nrinrin ajo lọ si erekuṣu Chiloé nigba meji tabi mẹta ni ọsẹ kan. Wọn duro si erekuṣu kan fun awọn ọjọ diẹ. Irin ajo laaarin awọn erekuṣu le mu ẹni alaini iriri ninu ìtukọ̀ loju omi ni imọlara èébì, ṣugbọn inurere ati ifẹ alejo siṣe awọn olugbe erekuṣu wọnyi jẹ isanpada rere ti o pọ to fun eyi. Luis ati Juan ni awọn akede Ijọba miiran darapọ mọ, wọn jumọ gbiyanju lati de ọdọ 11,500 awọn eniyan ti wọn wa ninu ipinlẹ wọn. Bi o tilẹ jẹ pe ibisi naa falẹ, Luis ati Juan layọ lọpọlọpọ lati ri 36 ti o wá si ibi ayẹyẹ Iṣe-iranti 1989.
Pada si Ori Ilẹ Nla
Ni biba a lọ si iha ariwa, a rekọja oju odo Chacao ti a si de oril ilẹ nla. Ni agbegbe yii, Ramón ati Irene ti wọn jẹ aṣaaju-ọna nṣiṣẹ ninu ipinlẹ fifẹ ti o ni awọn awujọ àdádó ni Maullín, Carelmapu, ati Pargua ninu. Awọn Ẹlẹrii ni erekuṣu Chiloé yoo rin fun wakati kan lẹhin naa ti wọn yoo si wọnu transbordador (ọkọ omi akẹ́rùkérò) lati resọda ọna omi tooro ti o so omi titobi meji pọ lati pesẹ si awọn ipade Kristian ni Pargua. Ramón rinrin ajo fun wakati kan ati ogun iṣẹju ninu bọọsi lati Maullín lati le dari awọn ipade ti awọn eniyan ti wọn tó ilọpo meji awọn akede saba maa npesẹ sii. Eeṣe ti o fi maa ngba akoko ti o gun tobẹẹ lati rin ọna ti ko ju kiki 24 ibusọ? Nitori pe awọn bọọsi maa nduro loju ọna lati ko awọn ero ọkọ ti wọn di ẹru awọn apo eso ati ewebẹ, àpò ìdọ̀họ ọ̀dùnkún ati alubọsa, ati ni awọn igba miiran pẹlu awọn òòyẹ̀ ẹlẹdẹ ati adiyẹ. Ohunkohun ti a ko ba ti le gbe sori bọọsi naa yoo wa ninu rẹ̀. Abajade rẹ ni irin ajo gigun pẹlu ọpọlọpọ òórùn, oriṣiriṣi iran ati awọn iro ohùn.
Niwọn bi iye ti o kere gan an ninu awọn aṣaaju-ọna wọnyi ni wọn ni ọkọ ayọkẹlẹ, pipadanu bọọsi kan ti o nrin laaarin awọn ilu maa nyọrisi rinrin ọna jijin, ayafi ti ẹnikan ba finnu findọ gbé e ninu ọkọ̀ rẹ̀. Bi Ramón ati akẹkọọ Bibeli rẹ ti nlọ pẹlu awakọ kan, oun beere pe: “Bawo ni awọn eniyan naa ti ndahunpada sí iṣẹ yin?” Ni ṣiṣakiyesi awọn irisi oju agbewadii dide, oun wipe: “Emi jẹ alufaa ni pueblo yii, ẹyin si jẹ Ẹlẹrii Jehofa. Mo mọ iṣẹ yin daradara mo si fẹran awọn iwe-irohin yin.” Ijiroro onibeere ati idahun ṣẹlẹ ṣaaju ki oun to já wọn silẹ ni Pargua lakooko fun ipade. Dajudaju alufaa naa ri idahun si awọn ibeere miiran bi o ṣe nbaa lọ lati ka iwe-irohin wa.
Kii fi igba gbogbo rọrun fun Ramón ati Irene lati de 20 awọn ile nibi ti wọn ti ndari ikẹkọọ Bibeli. Diẹ ninu wọn wà ni odikeji Odo Maullín tabi ni awọn abule ipẹja ti o wà ni adado ti a si nilati débẹ̀ pẹlu ọkọ oju omi kekere. Bi o tilẹ jẹ pe ọ̀wàrà ojo naa le korẹwẹsi bani, o han kedere pe iforiti ti wọn ṣaṣefihan rẹ papọ pẹlu awọn olupokiki Ijọba 18 miiran ti wọn fọ́n kaakiri jakejado ipinlẹ igberiko yii nmu eso jade nigbati 77 pade pọ fun Iṣe-iranti.
Ni Los Muermos, awọn olupokiki Ijọba alakooko kikun Juan ati Gladys ti dari 23 ikẹkọọ Bibeli. Awọn irin jijin lori awọn ọna alábàtà ni a san ere fun nigba ti irugbin Ijọba ta gbongbo ninu ọkan-aya awọn eniyan ti wọn ṣee kọ́ lẹkọọ. Ni agbegbe àdádó kan ni etikun oloke lẹba Estaquilla, Juan ati Gladys ṣiṣẹ ni awọn agbegbe kan ti a ko tii ṣebẹwo si tẹlẹtẹlẹ. Wọn beere lọwọ akẹkọọ Bibeli naa bi oun ba le ya wọn ni ẹṣin rẹ fun ọjọ naa. “Bẹẹni,” ni oun fesi pada. “Njẹ mo le lọ pẹlu yin?” Juan wa mọ lẹhin naa pe eyi ti nilati jẹ idaritọsọna Jehofa. Iba ti jẹ ohun ti o rọrun lati sọnu sinu igbo kìjikìji naa, ṣugbọn olufifẹhan naa mọ agbegbe yii daradara o si ṣamọna wọn si awọn ile ti ko farahan sode lati awọn oju ọna oke nla naa. Pẹlu ara ríro lẹhin wakati mẹsan irinsẹ ati gigun ẹṣin, ọkan ninu awọn aṣaaju ọna akanṣe naa beere lọwọ akẹkọọ Bibeli naa ohun tí ó jẹ imọlara rẹ̀. Ọkunrin naa dahun pada pe: “Ohun kanṣoṣo ti mo beere ni pe ki ẹ mu mi dani nigba miiran.” Olumọriri eniyan yii nbaa lọ lati maa dàgbà nipa tẹmi ti a si baptisi rẹ ni January 1988. Iyawo rẹ ni a baptisi laipẹ ni Apejọ ayika kan.
Laarin ibẹwo alaboojuto ayika, awọn akede 11 ti wọn wa ni Estaquilla layọ lati ri 110 ti wọn wá si asọye fun gbogbo eniyan. Ni ilu kekere kan ti o ni eniyan 1,000 ti o wa nitosi Los Muermos, 66 pade fun Iṣe-iranti. Nitori naa, ọpọlọpọ iṣẹ ni o wa lati ṣe ninu papa titobi yii.—Matiu 9:37, 38.
Ni guusu jijinna réré, awa ri awọn aṣaaju-ọna Alan ati Fernando. Bi wọn ṣe nrin lọ loju ọna eleruku kan ni ọjọ kan, awakọ kan yọnda lati gbe wọn ninu ọkọ akẹ́rù rẹ̀. Lẹhin ti wọn ti sọkalẹ tan, wọn nilati rẹrin-in nitori pe ipele eruku ninipọn bo wọn lati ori de atẹlẹsẹ. Imọlara idunnu ati ayọ didari 20 ikẹkọọ Bibeli inu ile ṣeranlọwọ lati bori iru inilara bawọnyii. Woye idunnu wọn nigba ti 65 eniyan wa si Iṣe-iranti ti awọn eniyan meji lati adugbo naa si darapọ mọ wọn ninu Iṣẹ iwaasu naa ni oṣu ti o tẹle e!
Rirekọja Bío-Bío
Lati de ọdọ awọn ẹni bi agutan ti o wa nitosi Oke Andes, o pọndandan lati sọda idagẹrẹ omi odo Bío-Bío ti nbu ramuramu ni 150 ẹsẹ bata nisalẹ. Eyi ni a nṣe lori igi ẹlẹgẹ kan ti a sorọ̀ lara ori okun ti o na rekọja ìdàgẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ iṣan omi naa. Pẹlu iyemeji, iwọ yoo goke sori pepele naa ti iwọ yoo si tẹ ìṣíkà kan ti yoo jẹ́ ki o ba okùn naa yi lọ si isalẹ okun naa. Iwọ yoo gbá igi idabuu ẹgbẹ patako pẹlẹbẹ naa mu bi iwọ ṣe nyara kánkán lọ la aarin gbùngbùn idagẹrẹgẹrẹ iṣan omi naa kọja, nibi ti iwọ yoo ti fi dirodiro titi iwọ yoo fi gúnlẹ̀. Lẹhin ti oju rẹ ba walẹ, iwọ yoo ti ìṣíkà miiran siwa sẹhin, ti iwọ yoo si rọra re apa keji ti o ku kọja. Dajudaju kii ṣe fun awọn alailọkan! Sibẹsibẹ, arabinrin kan nṣe eyi lọsọọsẹ lati de ọdọ awọn eniyan ẹni bi agutan ni abule olókè kan ti o jinna!
Apẹẹrẹ rere awọn aṣaaju-ọna ati awọn akede Ijọba miiran fun awọn olufifẹhan tí wọn ni ọkan imọriri niṣiiri lati sapa lọnakọna ki wọn ba lè lọ si awọn ipade Kristian. (Heberu 10:24, 25) Idile kan maa nrin irin 25 ibusọ lori ẹṣin si Odo Bío-Bío ati lẹhin naa ti wọn yoo rin 7 ibusọ miiran de Gbọngan Ijọba.
Ki ni ohun ti awọn aṣaaju-ọna naa ranti nigba ti wọn ba wẹhin pada si awọn ọdun ti o ti kọja? Oke onina ti yinyin bo lori, awọn papa ologo, ati awọn ìdàgẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odo? Eruku, òjò, àbàtà, ati irin jijinna? Bẹẹni, ṣugbọn awọn ni pataki julọ ranti eniyan oniwa bi ọrẹ ti wọn fi ojurere dahun pada si ihinrere naa. Awọn ẹni bi agutan wọnyii dajudaju nṣe gbogbo isapa ti o yẹ. Iru idunnu wo ni o jẹ lati funrugbin Ijọba naa ni apa iha guusu Chile!