Jijẹrii ni France—Ilẹ Ọlọ́kankòjọ̀kan
FRANCE jẹ ilẹ orilẹ-ede ọlọkankojọkan ńláǹlà. Awọn oke-nla giga, awọn oke gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, awọn gegele apata ti ìjì ńgbá, etikun oniyanrin ti o lọ́ wọ́ọ́wọ́, pápá oko ọka gbalasa, awọn oko ọlọgba kekere, ọgba ajara gbalasa, ilẹ koriko ìjẹ, awọn igi giga titutu yọ̀yọ̀ ati igbo ẹgan ti nruwe lọdọọdun, awọn abuleko, ati awọn abule, ilu, ati awọn ilu nla ode oni titobi—France ni gbogbo eyi, ati ju bẹẹ lọ.
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọjulọ igberiko ilu naa ṣì ni ẹwa rẹ, irisi France niti ẹgbẹ-oun-ọgba ti ni awọn ayipada lemọlemọ ni awọn ọdun lọ́ọ́lọ́ọ́. “Kii ṣe pe awujọ France nla saa yanpọnyanrin kan kọja,” ni ẹda itẹjade Francoscopie ti 1989 sọ, “bikoṣe ti iyipada ńláǹlà gidi ni o ńlà kọja. Awọn ọna ẹgbẹ-oun-ọgba, ero awọn eniyan niti idiyele ọpa idiwọn, ọpa idiwọn ti aṣa, ati awọn iṣesi ńla awọn iyipada ńláǹlà já ni igbesẹ ti nyara kánkán.”
Awọn iyipada pataki wọnyi ti tun nipa lori ilẹ akoso isin. Bi o tilẹ jẹ pe isin Katoliki jẹ isin ọpọ julọ eniyan sibẹ, o ti wa di aṣa nisinsinyi ju isin ti o ni ipa eyikeyi gidi lori igbesi-aye ọpọjulọ awọn mẹmba rẹ. Idagunla ti npọ sii ti awọn eniyan si iniyelori tẹmi ti dá idagba soke awọn ṣọọṣi duro.
Ni iyatọ gédégédé, igbokegbodo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni France ti tẹ̀ siwaju pẹlu iyara ni awọn ọdun diẹ ti o kọja. Lati Alsace ni ariwa ila-oorun si Brittany lori Atlantic, lati ori Awọn Oke Alps giga fíofío si Afonifoji Loire ti o wà nisalẹ, ani lori erekuṣu Mediterranean ti Corsica paapaa, awọn Ẹlẹrii dojukọ awọn ipo ọtọọtọ wọn si nṣalabapade awọn eniyan ti wọn ni ipilẹ ọtọọtọ. Ẹ jẹ ki a ṣe ibẹwo alaworan ki a si ri bi o ṣe ri lati waasu ihinrere Ijọba ni France, ilẹ ọlọ́kankòjọ̀kan.—Matiu 24:14.
ALSACE
Alsace ti o bá Germany pààlà, jẹ́ ẹ̀kun ti a mọ daradara fun awọn ọgba ajara ati awọn abule ti o kún fun òdòdó afani mọra rẹ. Strasbourg, olu-ilu rẹ, ti jẹ odi agbara Protestant kan lati igba Atunṣe, awọn ara Alsace ni gbogbogboo si ni ọwọ adanida fun Bibeli. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti nwaasu ihinrere Ijọba ni agbegbe yii lati ibẹrẹ ọrundun yii. Lonii, iṣẹ naa ni a ti fidi rẹ mulẹ daradara, gẹgẹ bi a ti ṣapẹẹrẹ rẹ nipa iriri ọdọlangba kan ti njẹ Sylvie, ẹni ti o ṣàmúlò anfaani lati waasu ni ile ẹkọ.
Ninu ijiroro kan pẹlu awọn ọmọ kilaasi ẹlẹgbẹ rẹ melookan, Sylvie mu ete igbesi-aye ati awọn ifojusọna fun ọjọ-ọla jade. Ọmọkunrin kan fifẹhan lọna ti o tó lati mu ki Sylvie ati Ẹlẹrii miiran ké si i ni ile. Sylvie wi pe, “Bi o tilẹ jẹ pe ọdọ Katoliki yii ti jẹ ọmọ ti nṣeranlọwọ nibi pẹpẹ, oun ni ọpọlọpọ ibeere ti a ko tii dahun ri. A lo Bibeli lati fi dahun diẹ lara wọn, o si tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli deedee.” Ọdọmọkunrin naa ni a baptisi ni ọdun kan lẹhin naa ati lẹhin titootun o kó wọnu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee. Sylvie pẹlu ti ko wọnu anfaani iṣẹ-isin yẹn lati igba naa.
BRITTANY
Ni nínà jade sinu Atlantic, Brittany jẹ ibilẹ Katoliki lilagbara. Bi o ti wu ki o ri, nipasẹ awọn isapa alaisinmi ti awọn Ẹlẹrii, iye eniyan ti npọ sii ni agbegbe yii ntẹwọgba ihin-iṣẹ Ijọba naa. Apẹẹrẹ ohun ti nṣẹlẹ kan niyii ni agbegbe ariwa iha iwọ-oorun France yii.
“Ẹlẹrii adugbo kan rohin pe, “Tọkọtaya ọdọ kan kó wa sinu iyara ti o wa loke tiwa. Ni igba diẹ lẹhin naa, mo pade ọdọmọbinrin naa lori àtẹ̀gùn, ti o gbe ọmọkunrin rẹ lọwọ. Ni mimọ pe orukọ ọmọ rẹ njẹ Jonathan, mo beere bi oun ba mọ ipilẹṣẹ orukọ yẹn. O fesi pada pe, ‘Mo ronu pe o wa lati inu Bibeli, ṣugbọn iyẹn ni gbogbo oun ti mo mọ.’ O feti silẹ si alaye ti mo ṣe, o si mẹnu kan an pe oun ati ọkọ rẹ ni Bibeli ru soke. Bi o tilẹ jẹ pe a ni awọn ijumọ sọrọpọ siwaju sii, ohun gúnmọ́ kan ko jẹyọ lẹhin naa.
“Laipẹ lẹhin naa, tọkọtaya naa beere fun imọran lorii awọn iṣoro kan bayii lọwọ mi. Mo lo Bibeli lati fi dahun, isọfunni ti o pese sì wú wọn lori. Mo kesi wọn lẹẹkan sii lati kẹkọọ Bibeli. Ni ọjọ keji ọdọbinrin naa gbà. Ni iwọnba ọsẹ diẹ lẹhin naa, ọkọ rẹ darapọ ninu ikẹkọọ naa. Awọn mejeeji ti di Ẹlẹrii ti a ti baptisi nisinsinyi.”
AWỌN OKE ALPS
Igbekalẹ Awọn Oke Alps jẹ olokiki fun iran mèremère. Awọn eniyan nlọ sibẹ lati ṣe hà si awọn oke titobi, ni pataki Mont Blanc, ori oke ti o ga julọ ni Iha iwọ-oorun Europe. Ni agbegbe yii pẹlu, iye awọn akede Ijọba ti wọn nfogo fun Ẹlẹdaa npọ sii. Awọn eniyan ọjọ ori gbogbo ati lati inu oniruuru ipo igbesi-aye gbogbo ndarapọ mọ òtú wọn, gẹgẹ bi irohin ti o tẹle yii ti fihan.
Awọn ọdọ mẹrin kan ni agbegbe yẹn ti gborukọ lọdọ ọpọlọpọ. Wọn ti ji awọn ọkọ ayọkẹlẹ ati awọn ohun ìní miiran, wọn mutipara niye igba, wọn nlo wọn si nta awọn oogun oloro, wọn si lọwọ ninu iṣe kárùwà ati ibẹmiilo. Wọn ko niṣẹ lọwọ wọn si maa nko sinu wahala pẹlu awọn ọlọpaa lemọlemọ, gbogbo wọn si ti lọ si ẹwọn ri. Bi o ti wu ki o ri, awọn mẹrẹẹrin ti gbọ́ nipa otitọ ni igba ọmọde wọn nitori awọn idile wọn ti kẹkọọ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati igba de igba.
Lẹhin ọdun igbesi-aye ẹhanna diẹ, ọkan lara awọn ọdọ naa ni iyipada ọkan o si pinnu lati ṣiṣẹ sin Jehofa. Eyi fa idahun pada alasokọra. Ni ọjọ kan awọn ọlọpaa nṣe iyẹwo ti wọn maa nṣe deedee, wọn si sọ fun ọkan lara awọn ọdọlangba naa lati ṣi apo rẹ. Ni fifoju sọna lati ri oogun oloro tabi awọn ohun ìní ti a jí, o yà wọn lẹnu lati ri kiki Bibeli ati awọn iwe pẹlẹbẹ diẹ. Ọdọmọkunrin naa lo Bibeli lati ṣalaye ohun ti o mu iyipada ninu igbesi-aye rẹ wa. Ni riri iyẹn gẹgẹ bi eyi ti o ṣoro lati gbagbọ, ọkan lara awọn ọlọpa naa beere pe: “Se ohun ti o nsọ ni pe o kò mugbó, mutí, tabi lo awọn oogun olóró mọ́?” Awọn ọlọpa naa gba alaye rẹ nikẹhin wọn si jẹ ki wọn lọ lai wahala rẹ siwaju sii. Lonii awọn ọdọmọkunrin mẹrin wọnyii ni a ti baptisi, gbogbo wọn nṣiṣẹsin ninu ijọ gẹgẹ bi iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ, mẹta ninu wọn si jẹ aṣaaju ọna deedee.
AFONIFOJI LOIRE
Afonifoji Loire ni a npe ni ọgba France. O nà gbooro lati Orléans, ibusọ 70 siha guusu Paris, dé ibi ti Odo Loire ti wọnu okun ni Etikun Atlantic. Agbegbe yii ni a mọ fun ọpọlọpọ awọn ile ńláńlá rẹ, awọn ibugbe tẹlẹ ri ati awọn ibuwọ ẹran pipa ti awọn ọlọba. Ijọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà ninu gbogbo awọn ilu nla ni agbegbe yii.
Nigba akoko isinmi ranpẹ ni ile-iwe ni ọjọ kan, Emma kekere, ọmọbinrin ọlọdun mẹfa ọlọyaya ati onifẹẹ, pada lọ si yara ikawe rẹ lati kí olukọ rẹ. Oun ni a mu tagìrì lati ri olukọ rẹ ti nmu siga, o bú sẹkun o si sá pada. Olukọ naa sá tẹle o si beere idi ti o fi nsunkun, sibẹ Emma ko sọ nǹkankan. Nigba ti olukọ naa fi dandangbòn lé e, Emma sunkun sinu o si fesi pada pe: “O jẹ nitori pe ẹ nmu siga. Ẹ o ṣaisan ẹ o si ku!”
Ni ọjọ keji olukọ naa pe iya Emma lati sọ bi iṣarasi huwa ọmọbinrin rẹ ti wọ oun lọkan tó. Nitori naa iya naa ṣalaye iduro awọn Ẹlẹrii nipa taba. Lẹhin naa olukọ naa sọrọ aṣiiri pe idile oun ti sọ fun oun lati dawọ siga mimu duro, ṣugbọn ko ṣiṣẹ. Bi o ti wu ki o ri, lakooko yii, oun ni a sun nipasẹ idahun pada ọlọkan rere ti Emma debi pe o dawọ siga mimu duro laarin ọjọ meji.
CORSICA
Erekuṣu Corsica, bi o tilẹ jẹ pe a npè é ni “erekuṣu olooorun didun,” ni a tun mọ fun ẹmi lile awọn olugbe rẹ, ti o maa nyọri niye igba si ija idile ti o ni itajẹ silẹ ninu. Fun ọpọlọpọ ọdun awọn Ẹlẹrii ni a wo gẹgẹ bi isin kan “lati ilẹ Europe.” Bi o ti wu ki o ri, agbara otitọ Bibeli nyi awọn ọkan ọpọlọpọ pada nibẹ.
Ẹlẹrii titun kan ti a ṣẹṣẹ baptisi rohin pe nigba kan ri oun pada lati isinmi lẹnu iṣẹ lati ṣawari pe gbogbo ohun eelo oun ti o ṣee fọwọkọ́ lati inu oko oun ni a ti jí lọ. O sọrọ aṣiiri pe, “Nipa nini igbẹkẹle ninu Jehofa, mo le huwa pada lọna ọtọ si ọna ti emi iba ti gbà huwa pada ni igba atijọ.” Nigba ti o nba awọn aladuugbo rẹ sọrọ, o fi pẹlẹ mẹnukan adanu rẹ.
“Lẹhin naa, awọn aladugbo kan ni awọn iṣoro. Mo fi iṣẹ mi silẹ lati lọ ran wọn lọwọ. Ni awọn ọjọ diẹ lẹhin naa, mo gba ikesini ori tẹlifoonu kan lati ọdọ ọkan lara wọn ti nsọ fun mi pe ki nwa lọgan bi o ba ti le ṣeeṣe tó. Ni rironu pe oun ti kówọnu ijọgbọn lẹẹkan sii, mo sare lọ loju ẹsẹ. O ke si mi lati jokoo o si beere pe: ‘Njẹ o mọ idi ti mo fi pe ọ wá? O jẹ nipa ohun eelo rẹ. Emi ni mo jí i. Ṣugbọn nigba ti mo ri iṣesi oninu-unre ati ẹlẹmi ọrẹ rẹ, mo sọ fun ara mi pe, “Emi ko le ṣe iyẹn sii!” Ati lẹhin igba ti o ran mi lọwọ, emi ko le foju ba oorun mọ ni oru.’” Isin Kristian tootọ ti a fi silo ṣamọna si abajade rere.
Ni opin ogun agbaye keji, nigba ti iṣẹ jijẹrii Ijọba naa ṣí silẹ lẹẹkan sii ni France, kiki 1,700 awọn Ẹlẹrii ni wọn wa ni gbogbo orilẹ-ede naa. Iṣẹ takuntakun ti dide ọdọ gbogbo awọn olugbe pẹlu ihin iṣẹ Ijọba naa dabi ohun ti ko ṣeeṣe. Bi o ti wu ki o ri, la awọn ọdun kọja, Jehofa ti bukun awọn eniyan rẹ ni France pẹlu irin-iṣẹ ti wọn nilo—awọn ile-iṣẹ itẹwe, awọn Gbọngan Ijọba, Gbọngan Apejọ ati bẹẹ bẹẹ lọ—ati ẹmi imuratan lati ṣaṣepari iṣẹ takuntakun naa. Lonii, pẹlu iye akede agbekankan ṣiṣẹ ti wọn ju 117,000 lọ, ihin-iṣẹ naa pe Ijọba Jehofa nipasẹ Kristi ni ireti kanṣoṣo fun araye ni a nwaasu rẹ jakejado ilẹ ọlọ́kankòjọ̀kan naa.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
FRANCE
BRITTANY
AFONIFOJI LOIRE
AWỌN OKE
ALSACE
ATLANTIC OCEAN
OKUN MEDITERRANEAN
ENGLISH CHANNEL