Irohin Amọ́kànyọ̀ Lati Soviet Union
Otente Alayọ si Ijẹrii Ọlọgọrun un Ọdun
“LATI fi Iwe Aṣẹ Ibudo Idari Eto- ajọ Isin ti ‘Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa silẹ labẹ ofin ni U.S.S.R.’”
Eyi ni itumọ awọn ọrọ akọkọ ti iwe akọsilẹ lede Russia ti a tẹ ẹda rẹ jade loju ewé yii. Loootọ, awọn ọrọ wọnyi duro fun idahun ọpọlọpọ adura. Iwe akọsilẹ naa ni a fọwọsi ti a si fi edidi di ni Moscow lati ọwọ ọga agba kan ní Ile-iṣẹ Ijọba ti Nbojuto Ọran Idajọ ti R.S.F.S.R. (Russian Soviet Federated Socialist Republic). O tumọ si pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa di eto-ajọ isin ti a fọwọsi jakejado U.S.S.R. Nipa bayii, ọgangan ìṣẹ́rí pada kan ni wọn dé ninu itan ọlọgọrun un ọdun wọn ni ilẹ gbigbooro yẹn.
Ibẹrẹ Kekere Gan an
Itan ọlọgọrun un ọdun kẹ̀? Bẹẹni. Ni awọn akoko ode oni, oniwaasu ihinrere ti a kọ́kọ́ mọ ní ilẹ yẹn ni Charles Taze Russell, ẹni ti o rohin ibẹwo kan sibẹ ni September 1891. Ninu itẹjade Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence ti 1891, ó rohin pe oun rinrin ajo lọ sí Kishinev, Russia, lakooko irin ajo kan lọ si Europe. Nibẹ ni o ti pade Joseph Rabinowitch kan bayii, ẹni ti o gbagbọ ninu Kristi ti o si ngbiyanju lati waasu fun awọn idile Juu ni agbegbe naa. Russell rohin ni kikun lori ibẹwo rẹ sọdọ Rabinowitch ati awọn ijumọsọrọpọ jijinlẹ, ti o gbadun mọni ti wọn ní nipa Ijọba naa.
Ihinrere Naa Ni A Gbọ Lẹẹkan Sii
Lẹhin ibẹwo Russell, diẹ ni a gbọ nipa ijẹrii ninu ibi ti a mọ nisinsinyi sí U.S.S.R., ṣugbọn iyẹn ko tumọ si pé a kò ṣaṣepari ohunkohun. Ni 1927 ijọ mẹta ni Soviet Union fi irohin awọn ipade Iṣe-iranti wọn ranṣẹ si Society. Ṣugbọn kò jọ bi ẹni pe itẹsiwaju yára kánkán titi di akoko ogun agbaye keji. Ogun yẹn yọrisi ìfọ́nkáàkiri yiyanilẹnu fun ọpọlọpọ awọn eniyan ni Europe. Ọkan ninu iyọrisi awọn ìṣílọ wọnyi ti a ko reti tẹ́lẹ̀ ni imuwọle ọpọlọpọ awọn oniwaasu Ijọba sinu Soviet Union.
Fun apẹẹrẹ, itẹjade Ilé-ìṣọ́nà ti February 1, 1946, rohin pe: “Iye awọn akede ti wọn ju ẹgbẹrun kan ti nwaasu ni ede Ukraine ni apa ila-oorun Poland tẹlẹri ni a ti ṣí nipo pada nisinsinyi lọ si aarin gbùngbùn Russia. . . . Lẹhin naa, pẹlu, ọgọrọọrun awọn arakunrin ti wọn ngbe ni Bessarabia, ti o jẹ apakan Rumania tẹlẹri, jẹ́ olugbe Russia nisinsinyi wọn si nba iṣẹ wọn ti sisọ awọn orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin lọ.”
Siwaju sii, nigba ogun agbaye keji, ọpọlọpọ awọn ara ilu Soviet jiya ninu àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi. Fun awọn kan iriri lilekoko yii ti ṣamọna si awọn ibukun ti a ko rò tẹ́lẹ̀. Irohin kan sọ nipa 300 awọn ọdọbinrin Russia ti a fi sẹ́wọ̀n ni Ravensbrück. Nibẹ ni wọn ti pade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, wọn dahun pada si otitọ, wọn si tẹsiwaju dé ori ṣiṣe baptism. Awọn ohun ti o farajọra ṣẹlẹ ni awọn ibudo miiran. Nigba ti a tú awọn Ẹlẹrii titun ti a baptisi wọnyi silẹ lẹhin ogun naa, wọn mu ihinrere Ijọba naa pada pẹlu wọn lọ si Soviet Union. Ni ọna yii ogun agbaye keji yọrisi ibisi ti o yára kánkán ninu iye awọn oniwaasu Ijọba ni agbegbe Soviet. Ni 1946 a fojudiwọn rẹ pe 1,600 awọn akede jẹ agbékánkánṣiṣẹ nibẹ.
Wiwaasu Ninu Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
Awọn ọgbà ẹ̀wọ̀n nbaa lọ lati kó ipa pataki ninu titan ihinrere kálẹ̀ ni Soviet Union. Lẹhin ogun naa, awọn alaṣẹ fi aṣiṣe wo awọn Ẹlẹrii gẹgẹ bi ewu kan, ọpọlọpọ ni wọn si fi sinu ẹwọn. Ṣugbọn eyi kò dá iwaasu wọn duro. Bawo ni ó ṣe lè ṣe bẹẹ, nigba ti wọn gbagbọ nitootọ pe ihin-iṣẹ naa nipa Ijọba Ọlọrun ni irohin ti o dara julọ fun araye? Nitori naa fun ọpọlọpọ ninu wọn, ọgbà ẹ̀wọ̀n di ipinlẹ wọn, àìlóǹkà awọn ẹlẹwọn ti wọn gbọ́ si dahun pada. Irohin kan ni 1957 wi pe: “Ninu gbogbo awọn ti a mọ pe wọn wà ninu otitọ lonii ni Russia a pari ero si pe ipin ogoji ninu ọgọrun un ni wọn ri otitọ gba ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n ati ninu àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.”
Awọn Ẹlẹrii naa ha rẹ̀wẹ̀sì nipa ìhàlẹ̀ ìfinisẹ́wọ̀n lemọlemọ yii? Kí á má ri! Irohin kan ni 1964 wi pe: “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan wà ninu awọn ibudo wọnni ti wọn ti wà nibẹ fun igba keji tabi ẹkẹta, bi o ti jẹ pe wọn ko dawọ wiwaasu ihin-iṣẹ naa duro lẹhin ti a ba tú wọn silẹ.” Irohin naa nbaa lọ pe, awọn miiran jẹ awọn ọdaran ti a fi sẹwọn tabi si ibudo ti wọn si pade awọn Ẹlẹrii nigba ti wọn wà nibẹ. Wọn tẹwọgba otitọ wọn si tẹsiwaju dé ori ṣiṣe baptism ṣaaju ki a tó tú wọn silẹ.
Mimu Iyọlẹnu Dinku
Ni agbedemeji awọn ọdun 1960, awọn alaṣẹ bẹrẹ sii ní ẹmi-ironu ti ko fi bẹẹ rorò si awọn Ẹlẹrii. Boya wọn mọ pe awọn eniyan Jehofa kii ṣe ewu si ofin ati ìwàlétòlétò awujọ. Nitori naa nigba ti igbokegbodo awọn Kristẹni onirẹlẹ wọnyi ko tii si labẹ ofin sibẹ, ifaṣẹ ọba muni ati titu awọn ile wọn wò ti wọn niriiri rẹ mọniwọn, wọn si kun fun imoore fun iyọlẹnu ti ó dinku yii. Ifẹ pataki wọn ni lati maa bá igbesi-aye Kristẹni ati iṣẹ wọn lọ ni idakẹjẹẹ, iparọrọ, ati ni alaafia niwọn bi o ti wà ni ọwọ́ wọn.—Roomu 12:17-19; 1 Timoti 2:1, 2.
Ni 1966 gbogbo awọn wọnni ti a ti rán lọ si ìgbèkùn ni Siberia fun akoko gigun ni a fun ni ominra ti a si yọọda fun wọn lati lọ si ibikibi ti wọn bá fẹ ni orilẹ-ede naa. Ọpọlọpọ pada sile lẹhin ọpọlọpọ ọdun àìsí nile, awọn kan si yàn lati maa wà niṣo ninu papa amesojade yẹn. Kii si ṣe gbogbo awọn ti wọn pada ni wọn yàn lati duro. Arabinrin kan, ti a ti lé lọ si Siberia gẹgẹ bi ọdọmọbinrin kan pẹlu idile rẹ̀, pada si iwọ-oorun Russia pẹlu awọn obi rẹ. Ṣugbọn oun wà nibẹ fun kiki igba diẹ. O nifẹẹ awọn ara Siberia onirẹlẹ, ẹlẹmii alejo gan an debi pe ó fi idile rẹ silẹ ó si pada si ila oorun lati maa bá wiwaasu fun awọn eniyan afetisilẹ wọnni lọ.
Iriri ti o ba akoko mu gẹ́lẹ́ kan ni akoko yii wémọ́ arakunrin kan ti o ṣí kuro lati ilu kan si omiran. Lẹhin igba diẹ ó ṣawari awọn Ẹlẹrii meji miiran. Awọn mẹtẹẹta gbadura fun iranlọwọ ati laipẹ wọn pade ọdọbinrin kan ti ó ní ipilẹ Greek Orthodox (Ṣọọṣi Ila-oorun). Ó yara tẹwọgba otitọ o si mu awọn arakunrin naa lọ sọdọ awọn olufifẹhan meji miiran—iya rẹ̀ ati aburo rẹ obinrin. Irohin naa pari pe: “Lonii awọn ogoji eniyan ni wọn ndarapọ pẹlu awọn arakunrin wọnyi, ọgbọn ninu wọn si kẹkọọ otitọ laaarin oṣu mẹfa ti o kọja.”
Bi o ti wu ki o ri, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a dí lọwọ ninu igbokegbodo wọn nitori pe a kò mọ wọn labẹ ofin. Awọn ipade ni a nṣe pẹlu iṣọra. Iwaasu ni a nṣe pẹlu iṣọra. Ifinisẹwọn ṣì jẹ ṣiṣeeṣe kan, ijẹrii ile dé ile ni gbangba ko ṣeeṣe. Bi o ti wu ki o ri, laika eyi sí, awọn Kristẹni oluṣotitọ Soviet wọnyi nbaa lọ lati sin Ọlọrun wọn pẹlu iṣotitọ ati lati jẹ́ ara ilu rere ninu orilẹ-ede wọn. (Luuku 20:25) Ni sisọ ironu wọn jade, ọkan ninu wọn kọwe pe: “O jẹ́ anfaani ńláǹlà lati farada gbogbo adanwo ki ẹnikan si duro ni oloootọ si Jehofa Ọlọrun, lati yin Ọlọrun titilae ninu igbesi-aye ẹni ki a ba le jere iye ainipẹkun lati ọdọ Jehofa nipasẹ Jesu Kristi.” Ẹ wo apẹẹrẹ rere tí ifarada ati iṣotitọ awọn Ẹlẹrii ni Soviet wọnyi ti jẹ!
Dídi Mímọ̀ Labẹ Ofin Nígbẹ̀hìn Gbẹ́hín!
Ni 1988 nǹkan bẹrẹ sii yipada ni awọn ilẹ ti wọn sopọ pẹlu Soviet Union. Ayika ominira pupọ sii bẹrẹ si gbodekan, awọn orilẹ-ede ti wọn si ti ká igbokegbodo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ́wọ́ kò bẹrẹ sii mu awọn ilana titun lo. Poland, Hungary, Romania, ati awọn ilẹ miiran ka awọn Kristẹni oloootọ ọkan wọnyi si labẹ ofin, ni yiyọnda fun wọn lati ṣiṣẹ ni gbangba laisi ibẹru ìjìyà. Ẹ wo ọdun alayọ ti ọdun mẹta ti o kẹhin wọnyi ti jẹ ni Ila-oorun Europe! Ẹ wò ó bi awọn ará ti wọn wà nibẹ ti lo anfaani ominira ti wọn ṣẹṣẹ rí lati tan ihin-iṣẹ alalaafia ti Ijọba naa kálẹ̀! Ẹ si wò ó bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni iyooku aye ti layọ pẹlu wọn to!
Awọn Ẹlẹrii ni Soviet ti janfaani lati inu ominira wọn ti ngbooro si. Ẹgbẹẹgbẹrun—ti awọn diẹ wá lati ibi ti o jinna bii etikun Pacific ti Asia—pesẹ si awọn apejọpọ ti o sàmì sí ibẹrẹ sanmani titun kan ni Poland ni 1989 ati lẹẹkan sii ni 1990, nigba ti 17,454 awọn Ẹlẹrii lati Soviet Union wà nibẹ ni Warsaw. Ẹ wo iru awọn iranti ti wọn mu pada lọ si ile pẹlu wọn! Ọpọ ko tii jọsin pẹlu awọn ti o ju iwọnba diẹ lọ rí. Nisinsinyi wọn ti wà laaarin ogunlọgọ ẹgbẹẹgbẹrun lọna mẹwaa mẹwaa!
Wọn pada lọ si Soviet Union ti o tubọ ndi onifarada sii. Awọn Ẹlẹrii yika aye nṣakiyesi wọn si nṣe kayefi pe: “Nigba wo ni a o mọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa labẹ ofin ni Soviet Union? O dara, ó ṣẹlẹ ni 1991—ni ọgọrun un ọdun géérégé lẹhin ibẹwo Charles Taze Russell sibẹ! Ni March 27, 1991, “Ibudo Idari Eto-ajọ Isin awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni U.S.S.R.” ni a fi orukọ rẹ silẹ sinu iwe akọsilẹ ti Ojiṣẹ ti Nbojuto Ọran Idajọ ti R.S.F.S.R. ni Moscow fọwọsi. Iru ominira wo ni a yọọda fun awọn Ẹlẹrii?
Iwe ofin ẹgbẹ titun ti a forukọ rẹ silẹ naa ní ipolongo ti o tẹle e yii ninu: “Ete Eto-ajọ Isin naa ni lati maa ba iṣẹ sisọ orukọ Jehofa Ọlọrun ati awọn ipese onifẹẹ rẹ fun araye nipasẹ Ijọba ọrun lati ọwọ Jesu Kristi di mímọ̀ lọ.”
Bawo ni a o ṣe ṣe eyi? Awọn ọna ti a tò lẹsẹẹsẹ ní ninu wiwaasu ni gbangba ati bibẹ ile awọn eniyan wò; kikọ awọn eniyan ti wọn muratan lati fetisilẹ ni otitọ Bibeli; didari awọn ikẹkọọ Bibeli lọfẹẹ pẹlu wọn pẹlu iranlọwọ awọn itẹjade ikẹkọọ Bibeli; ati ṣiṣeto fun titumọ, kiko wọle, imujade, titẹ, ati pínpín awọn Bibeli kiri.
Iwe akọsilẹ naa tun ṣe ilalẹsẹẹsẹ eto awọn Ẹlẹrii labẹ Ẹgbẹ Oluṣakoso, papọ pẹlu awọn ijọ ti o ní ẹgbẹ awọn alagba, Igbimọ Alaboojuto [Ẹka] ti o ní mẹmba meje fun orilẹ ede naa, ati awọn alaboojuto ayika ati agbegbe.
Ni kedere, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè ṣiṣẹ falala ati ni gbangba ni Soviet Union nisinsinyi gẹgẹ bi wọn ti nṣe ni ọpọlọpọ awọn ilẹ miiran. Finu woye ayọ marun un ninu awọn mẹmba meje ti Igbimọ Alaboojuto ati awọn alagba ijọ marun un ti wọn ti wa tipẹtipẹ ti wọn lanfaani lati fọwọsi iwe akọsilẹ afipitan yii ti wọn si ri ti a fi edidi di i lati ọwọ Olori Ẹka ti Nforukọ Awọn Ẹgbẹ Ara Ilu ati ti Isin Silẹ! Lọna ti o ba a mu rẹgi, Milton Henschel ati Theodore Jaracz ti Ẹgbẹ Oluṣakoso awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà nibẹ pẹlu lati jẹrii si iṣẹlẹ manigbagbe yii. Laaarin awọn awujọ wọnni ti R.S.F.S.R. fọwọsi, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ó kọkọ gba iwe akọsilẹ aṣẹ iforukọ silẹ wọn. Iru ere wo ni eyi jẹ fun awọn arakunrin oluṣotitọ ara Russia wọnni lẹhin ọpọlọpọ ọdun ifarada onisuuru!
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nibi gbogbo kun fun imoore fun awọn alaṣẹ Soviet ti wọn yọọda ìdámọ̀ labẹ ofin yii. Ni pataki ni wọn dupẹ lọwọ Jehofa pẹlu gbogbo ọkan-aya wọn fun ominira titun awọn ara wọn ni Soviet. Wọn yọ̀ pẹlu awọn Ẹlẹrii ẹlẹgbẹ wọn ni U.S.S.R. ati ni awọn ilẹ Ila-oorun Europe miiran ti wọn le sin Jehofa Ọlọrun daadaa sii nisinsinyi ni gbangba. Njẹ ki Jehofa Ọlọrun bukun wọn jigbinni bi wọn ti nlo ominira yii ni kikun si iyin orukọ mimọ rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Kremlin ni Moscow
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Awọn àyànṣaṣojú ara Russia ni apejọpọ kan lẹhin ode Soviet Union ni 1990