Ireti Wo Fun Awọn Oku?
Obinrin kan ni Augusta, Georgia, U.S.A., kọwe pe: “Laipẹ yii mo padanu arabinrin mi kekere ninu ijamba ọkọ ayọkẹlẹ aṣekupani kan. Oun ṣẹṣẹ di ẹni ọdun 18 ni, ti ara rẹ yá gágá ti o si ṣetan lati pari ẹkọ rẹ. Mo ri awọn iwe pẹlẹbẹ yin melookan ti a kó saarin awọn ododo diẹ lori aye iboji rẹ. Wọn ti ran mi lọwọ, emi yoo si fẹ lati beere fun awọn iwe ti o tẹle e yii ti ẹ filọni.”
Obinrin naa beere fun iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. O pari ọrọ pe: “Mo ronu pe yoo ran emi ati idile mi lọwọ lati ri oye diẹ ati alaafia laaarin araawa.”
Bi iwọ ba fẹ lati gba ẹda kan lara itẹjade alaworan meremere yii, kọ ọrọ kun ila ti o baa rin ki o si firanṣẹ.
Ẹ jọwọ fi isọfunni ranṣẹ simi lori bi mo ṣe le gba ẹda kan lara iwe ẹlẹhin lile oloju-ewe 256 naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.