ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 8/1 ojú ìwé 3-4
  • Idajọ Ikẹhin Naa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Idajọ Ikẹhin Naa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹkọ-igbagbọ Kristẹndọmu
  • Ọjọ Idajọ—Akoko Ireti Kan!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?
    Jí!—2010
  • Kí Ni Yóò Ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ sí Iná Ọ̀run Àpáàdì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 8/1 ojú ìwé 3-4

Idajọ Ikẹhin Naa

“NIGBA TI iwọ bá kú ọkan rẹ nikanṣoṣo ni a o daloro; iyẹn yoo jẹ ọrun apaadi kan fun un: ṣugbọn ni ọjọ idajọ ara rẹ yoo darapọ mọ ọkan rẹ, ati nigba naa iwọ yoo ni ọrun apaadi onibeji, ọkan rẹ yoo maa sun èkíkán ẹjẹ, ara rẹ yoo si kun fun irora.”

BAYII ni oniwaasu ọrundun kọkandinlogun naa C. H. Spurgeon ṣapejuwe oju-iwoye awujọ alufaa nipa ọjọ idajọ ati ijiya awọn ti a dá lẹbi hell. Ayaworan ara Italy naa Michelangelo ni igbagbọ biabanilẹru kan ti o farajọ eyi gẹgẹ bi a ti ri i ninu iyaworan rẹ “Idajọ Ikẹhin Naa” (apakan eyi ti a tẹ̀ ẹda rẹ jade loke), lara ogiri ile ijọsin Sistine ni Roomu. The New Encyclopædia Britannica sọ nipa aworan yii pe: “Kristi ninu Idajọ jẹ ọlọrun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ dipo ki o jẹ olugbala Kristẹni, ẹni ti o daniyan ju fun dida iran araye lẹbi ìyà ayeraye ju kíkí awọn olubukun kaabọ si ọrun rere.”

Ẹkọ-igbagbọ Kristẹndọmu

Ni awọn ọrundun ti o ti kọja, ọjọ idajọ ati ina ọrun apaadi jẹ awọn ẹṣin ọrọ iwaasu ti a yàn láàyò. Lati ori awọn aga iwaasu wọn, awọn oniwaasu bi C. H. Spurgeon bú jade pẹlu awọn apejuwe kínníkínní ti awọn idaniloro adayafoni ti nduro de awọn ẹlẹṣẹ. Ni aye ode oni, iru iwaasu yẹn ni a kii saba gbọ. Ṣugbọn ina ọrun apaadi ati idajọ ikẹhin ṣì jẹ awọn ẹkọ ti a faṣẹ si ti pupọ awọn ṣọọṣi.

Eyi ti o pọ julọ ninu awọn isin Kristẹndọmu fohunṣọkan pẹlu ẹkọ Roman Katoliki naa pe awọn idajọ Ọlọrun ńwá ní ipele meji. Lakọkọ, “idajọ gidi” wà. Nigba ti ẹnikan ba ku, ọkan rẹ ti a lero pe ó jẹ àìlèkú ni a dalẹjọ loju ẹsẹ ti a si fi ranṣẹ titi ayeraye yala sinu ọrun apaadi tabi sinu ọrun.a Lẹhin naa ni idajọ ikẹhin, tabi idajọ gbogbogboo dé, ni opin igba ti a so awọn ara oku ti a jí dide pọ ṣọkan pẹlu awọn aileku ọkan wọn.

Ni ọjọ idajọ yii, awọn ọkan ti nbẹ ni ọrun wà nibẹ a si so wọn pọ ṣọkan lẹẹkan sii pẹlu awọn ara ti a ti sọ di ailedibajẹ. Awọn wọnni ti wọn njiya ninu ọrun apaadi wà nibẹ pẹlu, ọkan wọn ni a si tun sopọ pẹlu awọn ara ti a jí dide, ti ko lè dibajẹ. Gẹgẹ bi awọn kan ti wí, eyi mu ki ijiya wọn di eyi ti o muna janjan sii. Awọn wọnni ti wọn ṣì wà laaye gẹgẹ bi eniyan kò kú. A ṣedajọ wọn nigba ti wọn ṣì walaaye wọn si lọ, “ati ọkan ati ara” ki a wí bẹẹ, taarata si ọrun tabi ọrun apaadi.

Ṣiṣeeṣe naa lati farada awọn idaloro ti ko ṣee fẹnusọ ninu ina ọrun apaadi ti mu ki gbogbo ọrọ nipa idajọ ikẹhin lati ọwọ Jesu Kristi di ohun kan ti o kun fun ibẹru lati ronu nipa rẹ. Nitori eyi, yoo ha yà ọ́ lẹnu lati mọ pe, nitootọ, awọn idajọ Ọlọrun niye ìgbà jẹ́ orisun fun idunnu ati pe Ọjọ Idajọ yẹn yoo jẹ́ akoko alayọ julọ ninu gbogbo itan eniyan? Bawo ni eyi ṣe le ri bẹẹ?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Awọn Roman Katoliki tun gbagbọ ninu ṣiṣeeṣe kẹta kan: ijiya onigba kukuru ninu pọgatori ṣaaju wiwọle sinu ọrun nikẹhin.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Random/Sipa Icono

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́