ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 9/15 ojú ìwé 24-27
  • Awọn Pápá Ti Funfun fun Ikore ni Brazil

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Pápá Ti Funfun fun Ikore ni Brazil
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Awọn Aṣaaju-ọna Ṣajọpin ninu Ikore Naa
  • Agbara Idari Ẹgbẹ́ Alufaa Nipa Lori Ikore
  • Awọn Isapa Ti Nbaa Lọ Mu Ibukun Wa
  • A Yí Igbesi-aye Pada
  • Nipin in Ni Kikun Ninu Ikore Naa
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 9/15 ojú ìwé 24-27

Awọn Pápá Ti Funfun fun Ikore ni Brazil

“Ẹ gbé oju yin soke, ki ẹ si wo oko; nitori ti wọn ti funfun fun ikore naa. Ẹni ti nkore ngba owo ọ̀yà, o si nko eso jọ si iye ainipẹkun.” (Johanu 4:35, 36) Awọn ọrọ alasọtẹlẹ wọnni ti Jesu Kristi jẹ ootọ lonii ni awọn ibi jijinna ni Brazil ilẹ orilẹ-ede gbigbooro ti South America.

Fun ọpọlọpọ ọdun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Brazil ti ngbadun awọn ibisi rere. Ni April 1991, gongo ti 308,973 awọn olukore Ijọba dari iye ti o ju 401,574 awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile. Ni March 30, 1991, aropọ 897,739 eniyan pejọpọ lati ṣeranti iku Jesu, ẹni ti o bẹrẹ iṣẹ ikore naa.

Laika awọn iyọrisi rere bẹẹ si, apa kan ninu pápá naa ni a ko tii kore sibẹ. Ohun ti o ju million marun un awọn eniyan ngbe ni agbegbe Brazil nibi ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti kere jọjọ tabi ki o ma tilẹ si rara. Ki ni a nṣe lati nasẹ ikore naa sí awọn agbegbe wọnyi?

Awọn Aṣaaju-ọna Ṣajọpin ninu Ikore Naa

Ni saa akoko oṣu mẹfa kan laipẹ yii, ẹka ọfiisi Watchtower Society ni Brazil rán awọn olupokiki Ijọba alakooko kikun—100 aṣaaju-ọna akanṣe onigba diẹ ati 97 aṣaaju-ọna deedee—lọ si awọn ilu 97, ọpọjulọ si iha ila-oorun orilẹ-ede naa nibi ti awọn eniyan tubọ pọ sí. Awọn olupokiki Ijọba lati oniruuru ijọ tun yọnda lati ṣiṣẹ ni awọn agbegbe wọnyi fun awọn saa akoko kukuru. Laika awọn idina ti wọn nilati bori sí, awọn iyọrisi naa ntẹnilọrun.

Fun apẹẹrẹ, ni São João da Ponte, ni ipinlẹ Minas Gerais, awọn aṣaaju-ọna naa kesi olukọ isin ti ile-ẹkọ adugbo naa. Lẹhin gbigbọ ihin-iṣẹ naa, o beere fun ẹda 50 ti iwe naa Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ fun saa ẹkọ isin rẹ̀. Olukọ miiran sọ fun aṣaaju-ọna ti nfi ibẹ silẹ pe: “Ko yẹ ki ẹyin lọ, niwọn bi ẹyin ti nṣe iṣẹ rere tó bayii nihin in. Ẹyin nikan ni ẹ le funni ni alaye Bibeli ṣiṣe kedere.”

Kii ṣe gbogbo eniyan ni ó ní inudidun si iṣẹ rere yii. Fun apẹẹrẹ, ṣayẹwo lẹta kan ti a tẹ̀ jade ninu iwe irohin adugbo kan (Diário de Montes Claros) labẹ akọle iwaju iwe naa “A Fẹsun Kan Alufaa Pe O Nru Iwa-ipa ati Kẹlẹyamẹya Soke.” Lẹta naa wi pe: “Ninu ṣọọṣi, [Alufaa naa] ni aṣa bibu ẹnu atẹ lu awọn eniyan ti wọn tẹle awọn ẹya tabi isin miiran, ani bi o tilẹ jẹ pe ẹgbẹ alufaa adugbo ko pese itọsọna ti Katoliki ati ti Kristẹni nipa Ihinrere fun awọn ọmọlẹhin. Lakooko Gbigba Ara Oluwa, oun ti gbéjà ko awọn ojiṣẹ Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wọn wà ninu ilu, bi o tilẹ jẹ pe wọn ko huwa si awọn Katoliki lọna buburu.” Laifi iru ẹmi ija bẹẹ han, onkọwe ọrọ-ẹkọ naa (ẹlẹkoọ isin kan) wà nibi ọrọ asọye Bibeli naa ti awọn aṣaaju-ọna naa sọ o si mu awọn olufifẹhan miiran dani. Gbogbo wọn gbadun ipade naa.

Awọn arakunrin mẹrin lati Fortaleza rinrin-ajo nipasẹ ọkọ ofuurufu lọ si Erekuṣu Fernando de Noronha, ibusọ 250 lati aarin ilu. Awọn olugbe ti o tó 1,500 ni erekuṣu naa ko tii gba ijẹrii ti o pọ to fun ohun ti o ju ọdun 15 lọ. Laaarin ọjọ mẹwaa, awọn arakunrin fi 50 iwe ati 245 iwe irohin ati iwe pẹlẹbẹ sode, wọn si bẹrẹ awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile 15. Awọn eniyan mejila wá si Iṣe-iranti iku Kristi, eyi ti o bọ́ si akoko ibẹwo wọn. Awọn aṣaaju-ọna naa nireti pe pẹlu iranlọwọ Jehofa iṣẹ naa yoo fidi mulẹ gbọnyingbọnyin laipẹ nibẹ. Awọn arakunrin diẹ ti ronu nipa ṣíṣí lọ si erekuṣu naa.

Agbara Idari Ẹgbẹ́ Alufaa Nipa Lori Ikore

Awujọ awọn akede Ijọba kan ti Ijọ Arpoador ni Rio de Janeiro yọnda lati lo ọsẹ meji ni wiwaasu ninu ọpọlọpọ awọn ilu ni ipinlẹ Mina Gerais, ti o jinna to nǹkan bii 125 ibusọ. Si idunnu wọn wọ́n rí awọn eniyan adugbo naa gẹgẹ bi ẹlẹmii alejo ṣiṣe ati oninuure gidigidi. Awọn ọkunrin ni aṣa gbigbe awọn akẹtẹ wọn soke nigba gbogbo ti a ba ti mẹnukan Ọlọrun tabi orukọ rẹ̀, Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, nitori ọwọ jijinlẹ wọn fun Ọlọrun, a nipa lori wọn lọna ti o rọrun lati ọdọ ẹgbẹ alufaa.

Ni ilu kan alufaa gba awọn eniyan nimọran lati maṣe fetisi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tabi lọ si ipade ti wọn nwewee lati ṣe. Oun tun ṣeto Gbigba Ara Oluwa akanṣe kan ni akoko kan naa ti ipade naa bọ si, o si kede Gbigba Ara Oluwa naa lori ẹrọ gbohungbohun lọna alariwo nla lẹhin ode ṣọọṣi rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, laika awọn isapa rẹ̀ sí, 29 ninu awọn olugbe adugbo wa si ipade naa, ni afikun si awọn ti a fiwe kesi.

Ilu itosi kan yatọ patapata! Nibẹ alufaa sọ fun awọn eniyan lati fetisilẹ nigba ti awọn Ẹlẹrii ba wá. Iyọrisi rẹ̀ ni pe 168 eniyan wa si ipade akọkọ. Lẹhin naa, o sọ fun wọn lati fiyesilẹ si bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe npa Iṣe-iranti mọ, nitori pe, gẹgẹ bi oun ti wi, “wọn nṣe e lọna titọ.” Laaarin ọsẹ meji iṣẹ iwaasu Ijọba naa ni agbegbe yẹn, 1,014 iwe ati 1,052 iwe irohin ati iwe pẹlẹbẹ ni a fi sode.

Awọn Isapa Ti Nbaa Lọ Mu Ibukun Wa

Ni oṣu kan lẹhin naa awọn akede Ijọba 34 pada lọ lati bojuto awọn ikẹkọọ Bibeli ti a bẹrẹ lakooko ibẹwo kìn-ín-ní. Kristẹni alagba naa ti nmu ipo iwaju kọwe pe: “O dunmọni lati ri awọn eniyan olufifẹhan ti wọn kí wa kaabọ pẹlu ọpẹ ati omije ayọ ni oju wọn.” Arabinrin kan ranti pe obinrin kan wa sọdọ oun ati awọn Ẹlẹrii miiran ninu buka ijẹun kan “o nbẹbẹ pẹlu omije ni oju rẹ, pe ki a wá ba oun ṣe ikẹkọọ.” Ọlọmọge miiran kẹkọọ nigba mẹta laaarin ọsẹ naa ti awọn Ẹlẹrii wa nibẹ. Nigba kọọkan, o ti mura ẹkọ rẹ̀ silẹ o si nduro fun ikẹkọọ naa. Ọlọmọge naa wipe oun ti bẹrẹ sii gbadura si Ọlọrun tootọ naa, Jehofa. “Ninu ọkan-aya mi eyi ni ohun ti mo ti nwọna fun nigba gbogbo,” ni ó fikun un.

Lẹhin naa, awọn aṣaaju-ọna meji ni a yan lati bojuto awọn olufifẹhan ni agbegbe yẹn. Gẹgẹ bi o ti ri ni ọrundun kì-ín-ní ti Sanmani Tiwa, “awọn wọnni ti wọn ni itẹsi-ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun di onigbagbọ.” (Iṣe 13:48, NW) Ati bi obinrin ara Samaria naa ẹni ti Jesu jẹrii fun ni eti kanga Jakọbu, wọn bẹrẹ si sọ fun awọn ẹlomiran nipa ohun ti wọn kọ́. (Johanu 4:5-30) Lonii awọn aṣaaju-ọna 2 naa ni awọn ẹni 6 miiran ti nṣiṣẹsin pẹlu wọn, ipindọgba 20 si nwa si awọn ipade ọsọọsẹ.

Bi wọn ti ni itara nipa aṣeyọri si rere iṣẹ akanṣe yii, awọn akede 29 ti Ijọ Arpoador lọ lati waasu ninu ilu Mutum, ti o jinna to nǹkan bi 300 ibusọ. Alagba ti ndari awujọ naa wi pe, “itẹwọgba naa tayọ niti gidi.” “Ọpọjulọ awọn eniyan fetisilẹ pẹlu iru afiyesi ati ifẹ bẹẹ debi pe a bẹrẹ 170 ikẹkọọ Bibeli, a si nimọlara pe ọpọlọpọ ninu wọn yoo maa baa lọ.” Ni ọsẹ meji awọn akede naa waasu 90 wakati ni ipindọgba ẹnikọọkan wọn si fi ohun ti o fẹrẹẹ to ẹyọ iwe ikẹkọọ 1,100 sode lọdọ awọn eniyan. Gongo ti 181 wa si ọrọ asọye itagbangba tí awọn arakunrin naa sọ.

Oṣu diẹ lẹhin naa, ijọ naa háyà ile daradara kan laaarin ilu Mutum fun lilo gẹgẹ bi Gbọngan Ijọba ati ile awọn aṣaaju-ọna. Irohin akọkọ tí awọn arabinrin aṣaaju-ọna meji ti a yan sibẹ fi ranṣẹ si Society kà ni apakan pe: “Pẹlu ọpọlọpọ ikẹkọọ ti a ti bẹrẹ bayii, a nilo awọn aṣaaju-ọna pupọ sii. Ani pẹlu iranlọwọ awọn arakunrin lati Rio de Janeiro lẹẹkan loṣu, iṣẹ naa gadabu. Mẹsan an ninu mẹwaa awọn onile ti a bá sọrọ sọ fun wa lati pada. A tun nilo iranlọwọ lati ṣe awọn ipade.” Aṣaaju-ọna miiran ti darapọ mọ wọn nisinsinyi.

A Yí Igbesi-aye Pada

O ti funni niṣiiri lati ri ki otitọ ta gbongbo ki o si mu awọn eso rere jade. Olufifẹhan kan kọwe pe: “Gbigba imọ Bibeli yii ni ohun ti o dara julọ ti o tii ṣẹlẹ si mi ri. Igbesi-aye mi ti yipada si rere, emi ko si nilati lo oogun orun mọ. . . . Njẹ ki Jehofa san ere fun yin fun ohun gbogbo ti ẹ ti ṣe fun mi.”

Ẹlomiran wi pe: “Bi Jehofa ti là mi loju yà mi lẹnu gidi. Bi o tilẹ jẹ pe mo ti padanu iya mi agba ninu iku ni ọsẹ yii, nisinsinyi mo ni ireti rírí i lẹẹkan si. Mo nireti lati gba iribọmi, ṣugbọn mo fẹ di ẹni ti a murasilẹ daradara lakọọkọ ná. Njẹ ki Jehofa bukun yin fun wíwá tí ẹ wá sihin in lati fi ọna tooro ti o sinni lọ si iye ayeraye han wa.” Sibẹ eniyan miiran wi pe: “Mo fẹ ki ẹ mọ pe mo dawọ siga mimu duro loṣu kan sẹhin. Inu mi dun si iwe irohin ti ẹ fi ranṣẹ si mi. O ni ọpọlọpọ ohun rere ninu ti o ran mi lọwọ lati ṣe bẹẹ.” Dajudaju, ikore naa funni ni idi rere lati yọ.

Bi o ti wu ki o ri, iru awọn ibukun bẹẹ ko dede ṣẹlẹ laisi isapa. Fun apẹẹrẹ, nigba ti iyaafin kan ati ọmọbinrin rẹ̀ bẹrẹ sii kẹkọọ, alufaa adugbo kilọ fun wọn pe bi wọn ba lọ si ipade awọn Ẹlẹrii, ohun yoo yọ wọn kuro ninu ṣọọṣi. Ni pipa ihalẹmọni naa tì, wọn lọ si awọn ipade. Awọn ọrẹ wọn tẹlẹri ta wọn nù lẹ́gbẹ́, diẹ ninu awọn ti o fẹsun ori dídàrú kàn wọn nitori pe “Jehofa yẹn” ko farahan ninu Bibeli Katoliki. Niwọn bi iyaafin naa ko ti le ri orukọ Jehofa ninu Bibeli Katoliki rẹ̀, o kesi awọn aladuugbo lati bẹẹ wo ni ọjọ ikẹkọọ rẹ̀ pẹlu aṣaaju ọna naa. Obinrin kan wa pẹlu ẹda itumọ Bibeli Katoliki ti Paulinas rẹ̀. Nigba ti o ka orukọ Ọlọrun ninu alaye ẹsẹ iwe si Ẹkisodu 6:3, o tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli ninu ile rẹ̀.

Nipin in Ni Kikun Ninu Ikore Naa

Ipa wo ni ṣiṣiṣẹsin ninu ipinlẹ ti a kii ṣe nigba gbogbo ni lori awọn oṣiṣẹ naa funraawọn? Akede Ijọba kan wipe: “Igbokegbodo yii ṣeranwọ lati fun igbagbọ ati ipo-ibatan wa pẹlu Jehofa lokun o si ran wa lọwọ lati gbé awọn ohun ti a fi ṣaaju yẹwo lẹẹkan sii.” Akede miiran wi pe: “Sáà ọlọjọ 14 yẹn mu ifẹ mi fun awọn arakunrin mi pọ sii, ti wọn nsin gẹgẹ bi idile kan pẹlu gongo kan: lati wá awọn oninu tutu pupọ sii rí. O mu ki nfẹran awọn wọnni ti wọn tẹwọgba ihin-iṣẹ wa, niye igba pẹlu omije ni oju wọn, ní fifi oungbẹ tootọ han fun otitọ naa. Ati ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo nimọlara ifẹ Jehofa ni fifun wa ni anfaani lati ṣiṣẹ sin in.”

Alagba kan ti o ṣajọpin ninu wiwaasu ni ipinlẹ ti a kii ṣe deedee tọka si iyatọ ti o wà laaarin igbesi-aye nibẹ ati ninu awọn ilu nla. O wi pe: “Igba gbogbo ni mo nronu bi igbesi-aye awọn arakunrin ti le tubọ lọ́rọ̀ tó nipa ṣiṣi lọ si agbegbe ti o jinna naa. Iwa ipa ko si niti gidi nihin in. Igbesi-aye ninu awọn ilu kekeke ati alaitobi pupọ jẹ iru ọ̀kan ti o fayegba wa kii ṣe kiki lati gbe pẹlu owo ti nwọle ti o mọniwọn nikan ṣugbọn lati tún ni ibakẹgbẹpọ pupọ sii pẹlu awọn arakunrin wa ati lati fun awọn igbokegbodo tẹmi ni akoko pupọ sii. Njẹ awọn arakunrin pupọ sii ti wọn ti fẹhinti lẹnu iṣẹ, awọn ọdọ eniyan ti wọn ko ni ẹru-iṣẹ idile pupọ, tabi awọn arakunrin ti iṣẹ wọn yọnda wọn lati ṣi lọ yoo ha tẹwọgba anfaani alailẹgbẹ yii ki wọn si mu ayọ wa fun araawọn, fun Jehofa, ati fun aladuugbo wọn?”

Irohin yii lori ipinlẹ ti a kii ṣe deedee ni Brazil fẹri han pe papa naa ti funfun fun ikore. Ni ọdun meji pere, iṣẹ ninu papa yii ti yọrisi 191 ijọ titun ati awujọ àdádó. Pupọ sii ṣì wà lati ṣe, ṣugbọn dajudaju Jehofa yoo maa baa lọ lati rọjo ibukun rẹ̀ gẹgẹ bi awọn akede Ijọba pupọ sii ti nkopa ninu ikore ameso jade naa. Iwọ ha le nipin in titobi sii ninu rẹ bi?

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Awọn Ẹlẹrii alayọ lati Rio de Janeiro nipin in ninu ikore naa

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

BRAZIL

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ijẹrii igberiko ni Minas Gerais

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́