ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/15 ojú ìwé 24-27
  • Ihinrere Dé Awọn Igberiko South Africa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ihinrere Dé Awọn Igberiko South Africa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • “Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi” Kan ni Ilẹ Zululand
  • Ni Ilẹ Pápá Eleruku
  • Baalẹ Kan Gbe Ofin Jade!
  • Fifi Tayọtayọ Ran Ọpọ Awọn Olùwá Otitọ Kiri Lọwọ
  • Eso Làálàá Naa
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/15 ojú ìwé 24-27

Ihinrere Dé Awọn Igberiko South Africa

AWUJỌ eniyankeniyan onibiinu, awọn   ọlọpaa apaná ìjọ̀ngbọ̀n, afẹfẹ ti ntaniloju. Ni awọn ọdun lọ́ọ́lọ́ọ́, awọn ilu ati ilu nla South Africa ni iru rogbodiyan bẹẹ ti dàrú. Àní awọn agbegbe igberiko ẹlẹwa paapaa—nibi ti iye ti ó ju ipin 40 ninu ọgọrun-un awọn ara ilu ńgbé—kò bọ lọwọ awọn ifiṣofo oniwa ipa ti oṣelu. Bi o ti wu ki o ri, laaarin gbogbo eyi, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti nba a lọ lati polongo “ihinrere alaafia.”—Efesu 6:15.

Fun ọpọlọpọ ọdun awọn Ẹlẹ́rìí ti dari igbetaasi iwaasu oloṣu mẹta lọdọọdun ti a dari rẹ̀ si awọn olugbe igberiko ni pato. Fun apẹẹrẹ, ni 1990 awọn akede Ijọba ti wọn ju 12,000 lati 334 ijọ kó ipa ninu igbetaasi naa. Gẹgẹ bi ẹnikan ti lè rò, ọpọlọpọ oke iṣoro ni a gbọdọ ṣẹpa lati de ọdọ awọn ti ńgbé igberiko gátagàta ti iha guusu Africa wọnyi.

Laaarin awọn nǹkan miiran, awọn Ẹlẹ́rìí gbọdọ dojukọ oniruuru aṣa ati ede pupọ. Ẹ sì wo idapọmọra oniruuru ti ó jẹ́! Fun apẹẹrẹ, awọn agbẹ ti nsọ ede Gẹẹsi ati Afrikaan wà, bakan naa pẹlu ni awọn Pedi, Sotho, Tsonga, Tswana, Venda, Xhosa, ati Zulu wà. Awujọ kọọkan ni aṣa ati ede yiyatọ. Awọn ọna ti wọn jin ti wọn sì ní gárígádá tun wà. Gbogbo eyi beere fun ẹmi ifara ẹni rubọ ati ilo akoko ati owo pupọ rẹpẹtẹ. Sibẹ, Jehofa ti bukun awọn isapa ti wọn ṣe lọna jingbinni. Ẹ jẹ ki a sọ diẹ fun yin nipa awọn inira ati aṣeyọri iha titayọ yii nipa iṣẹ ijẹrii.—Fiwe Malaki 3:10.

“Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi” Kan ni Ilẹ Zululand

Ni aarin gbùngbùn adamọdi ilẹ olooru Zululand ni afonifoji jijin ti Odo Umvoti wà. Lati ori bebe awọn apata giga, ẹnikan lè rí iṣupọ orule onikoriko ti awọn abule Zulu (awọn abuleko) ti wọn tò lọ jàáǹtìrẹrẹ ni ọ̀kánkán. Ni ọjọ Sunday kan ni 1984, awọn akede Ijọba meji gba oju ọna kọ́rọkọ̀rọ, eleruku wá sinu afonifoji naa. Ibẹ gbona o sì mooru tobẹẹ debi pe agbegbe naa ni a sọ ni orukọ inagijẹ naa Kwa-Sathane (Ibugbe Satani)—itọka ti kò ṣe taarata sí igbagbọ èké ti ina ọrun apaadi kan tí Eṣu ńkoná rẹ̀!

Awọn arakunrin naa ti òógùn ti wẹ̀, tọ obinrin kan ti njẹ Doris lọ, ẹni ti ndari kilaasi ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi kan. Lẹhin gbigbọ ihin-iṣẹ Ijọba naa, Doris ké si awọn Ẹlẹ́rìí naa lẹsẹkẹsẹ lati ba awujọ rẹ̀ ti ó to nǹkan bi 40 awọn ọdọ sọrọ. Ki ni iyọrisi rẹ̀? Awọn arakunrin naa pada ni ọsẹ ti ó tẹle pẹlu 70 ẹ̀dà itẹjade naa Iwe Itan Bibeli Mi fun ìlò ni ile-ẹkọ agbegbe naa. Laaarin iwọnba ọsẹ diẹ, ayika ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi naa ti yipada si ti awujọ ikẹkọọ Bibeli kan. Dipo awọn orin isin ṣọọṣi, orin Ijọba ni a kọ ni ọna ti Africa, pẹlu iṣọkan adanida ti ó gbadunmọni. Laipẹ awujọ naa pọ dé iye ti ó ju 60 lọ. Arakunrin kan polongo pe: “Iriri amọkanyọ wo ni ó jẹ́ lati ṣajopin ninu yiyi ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi yii pada si ibi ijọsin tootọ kan!”

Ni Ilẹ Pápá Eleruku

Nitori tí ṣọọṣi nlọwọ ninu irukerudo oṣelu, ọpọlọpọ awọn agbẹ alawọ funfun jẹ́ oluṣọra tabi olufura nipa ẹnikẹni ti ó bá tọ̀ wọn lọ pẹlu ihin-iṣẹ Bibeli. Ṣakiyesi irohin yii lati ọdọ awujọ kan lati Johannesburg ti wọn rin irin ajo nǹkan bi 400 ibusọ lati waasu ihinrere Ijọba ni apa kan Transvaal.

“A ti nrinrin ajo lọ si ariwa la igbo pápá oloke ati gẹrẹgẹrẹ kọja fun ohun ti ó sunmọ wakati mẹrin nisinsinyi. Ooru tí nfarahan bi omi ńbù soke wìrìrìrì lori ọ̀gbanrangandan ọna ti nkọ mọna labẹ oorun Africa. Lojiji, ọna ọlọ́dà naa dopin ọna eleruku sì bẹrẹ, táyà ti mu ki ó jinkoto ó sì kún fun awọn kòtò keekeeke. Nikẹhin, ọna tooro oniyanrin kan mu wa de oko kan.

“‘Ẹ kaaarọ, Meneer [Sà],’ ni a sọ ni ikini si agbẹ ti ó taagun kan.

“‘Ẹ kaarọ,’ ni ó fèsì pẹlu ikanra. ‘Ṣe mo lè ran yin lọwọ?’

“Lẹhin sisọ ẹni ti a jẹ́, a ṣalaye idi fun ikesini wa. Awọn ọrọ naa fẹrẹ ma tii jade lẹnu wa tan nigba ti o pariwo pe: ‘Dominee [ojiṣẹ ṣọọṣi] mi ti kilọ fun mi nipa yin! Kọmunisti ati Aṣodi sí Kristi ni gbogbo yin. Àfira ẹ kuro ni oko mi ki nto . . . !’

“Iṣarasihuwa agbẹ naa fihan pe oun lè fi ija pẹẹta nigbakigba. Bi ó ti jẹ́ pe yíyàn tí a ní kò pọ̀, a pinnu lati fi ibẹ silẹ a sì ‘gbọn eruku ẹsẹ wa.’ (Matiu 10:14) Eruku ti ó pọ tó wà lati ṣe eyi niti gidi gan-an.

“Ni oko ti ó tẹle e, idahunpada naa ri bakan naa. Lẹhin naa a wá mọ pe waya tẹlifoonu agbegbe ni ojiṣẹ ṣọọṣi Dutch Reformed ti ngbe ibẹ ti nlo, ẹni ti ó ti nkilọ fun ‘agbo rẹ̀’ nipa ‘ewu’ ti nrọdẹdẹ ni adugbo naa. Nikẹhin a pade agbẹ kan ẹni ti, bi o tilẹ jẹ pe kò nifẹẹ funraarẹ, sọ pe: ‘Bẹẹni, ẹ lè ba awọn lébìrà mi sọrọ.’

“A ti nwọna fun iyẹn gan-an. Lẹgbẹẹ awọn igi ẹ̀wọ̀n ti ó forikọraawọn ni ahere keekeeke onibiriki bii mẹwaa tí ó ṣùpọ̀ mọra wà. A nimọlara pe awọn ti nṣe kayefi bẹrẹ si naju wode lati inu ahere bi a ti nko awọn iwe ti a tojọ mẹrẹnmẹrẹn si ori ibori iwaju ọkọ ayọkẹlẹ wa. Akojọ kan ti awọn Bibeli, omiran akojọ awọn iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, itojọ kan ti Iwe Itan Bibeli Mi, ati oniruuru awọn iwe pẹlẹbẹ ṣaṣepe ifihanni naa. Ọkan ninu awọn ọmọdekunrin adugbo naa sare lati lọ sọ fun awọn ara abule naa nipa dídé wa. Laipẹ awọn ero ti ó tó nǹkan bii 30 ti péjọ yí ọkọ ayọkẹlẹ wa ká lati gbọ ihin iṣẹ naa.

“Iwaasu kan ti a ti gbà silẹ ni a gbé sáfẹ́fẹ́ fun wọn ni ede Tswana. Awọn eniyan wọnyẹn ti layọ tó lati gbọ ihinrere Ijọba Ọlọrun ati ireti Paradise naa ni ede wọn! Imọlara ayọ pupọ si i ni ó wà nigba ti a fi awọn itẹjade naa lọni. Laipẹ, agbara káká ni a fi le maa ba a lọ pẹlu awọn ifisode naa. Ọkunrin agbalagba kan tilẹ fi iye owo kan lọni fun teepu igbohunsilẹ naa. A ru imọlara wa soke lọna jijinlẹ bi imọriri fun ihinrere naa ti nfarahan ni awọn ọna keekeeke pupọ—ẹ̀rín músẹ́ onitiju, ifọwọkanni, ‘ẹ ṣeun’ ti a sọ pẹlẹpẹlẹ.

“Laigbero tẹlẹ, awọn ọmọde ṣeto ìlà ti kò gún kan wọn sì kọ orin idagbere ti ibilẹ kan. Lojiji, awọn oju ọna eleruku naa, ti táyà ti mu jinkoto ati awọn idahunpada akọ ni awọn igba miiran ni ó dabi eyi ti kò tó nǹkan. O ti jẹ́ eyi ti ó toye fun gbogbo igbesẹ isapa naa!”

Baalẹ Kan Gbe Ofin Jade!

Ijọ kan lati Soweto ní iṣẹ ayanfunni lati lọ waasu ni ayika ẹ̀yà kan nitosi ilu ila oorun naa Piet Retief. Aṣa ibẹ beere pe ki alejo kan kọkọ la ọran ti ó bá wá silẹ lẹsẹlẹsẹ fun induna (baalẹ) agbegbe naa. Awọn arakunrin naa ṣegbọran si eto naa. O ti yanilẹnu tó nigba ti baalẹ naa gbà wọn tọwọtẹsẹ ti ó tilẹ pese ibùwọ̀ fun wọn ninu ile rẹ̀! Ni afikun sii, ni lilo òǹtẹ̀ agbara oyè rẹ̀, oun kọ iwe ifinihanni kan fun awọn akede naa lati mu dani lati ẹnu ilẹkun de ẹnu ilẹkun. O wi pe: “Eyi ni awọn oniwaasu Ijọba Ọlọrun. Ẹ gbà wọn sinu ile yin, ki ẹ sì fetisilẹ si wọn.”

Idahunpada naa galọ́lá debi pe awọn Ẹlẹ́rìí naa ṣeto lati sọ awiye fun gbogbo eniyan ni agbala ile baalẹ ni ọsan ọjọ Sunday yẹn. “Gbọngan” ti ó ṣí silẹ gbalasa naa ni ó kunfọfọ, ipade naa ni a bẹrẹ ti a sì pari pẹlu orin ati adura. Iru awọn iriri ti o farajọra pẹlu awọn ẹni ọlọkan yiyẹ ni a ti gbadun ni awọn ayika igberiko miiran.

Iru eniyan kan bẹẹ ni Nathaniel, ni abule kekere ti Pitsedisulejang ni kọ̀rọ̀gún kan ti ọ̀dá dá ni Bophuthatswana. Oun jẹ́ olumu awujọ adugbo gberu kan ti ọwọ rẹ̀ dí ninu eto kikọ awọn eniyan adugbo lati mu awọn ohun ọgbin ti ó tutu yọ̀yọ̀ dagba lọna ti ó gbeṣẹ. Oun ti lalaa yiyi ibi ti ó ti ṣá yii pada si paradise kan. Ṣugbọn nigba ti oun loye wi pe paradise jakejado aye kan yoo dé laipẹ, oju rẹ̀ mọlẹ yòò. O fi iharagaga kọ gbogbo ẹsẹ Bibeli ti awọn akede naa fihan an. Nathaniel ni a tete mú ní isopọ pẹlu ijọ ti ó sunmọtosi julọ, eyi ti ó jinna tó 20 ibusọ.

Fifi Tayọtayọ Ran Ọpọ Awọn Olùwá Otitọ Kiri Lọwọ

“Jehofa fihan wa wi pe ipo òṣì ko dí ẹni ti ebi ńpa nipa tẹmi lọwọ lati mọ otitọ,” ni Monika sọ, aṣaaju-ọna kan, tabi olupokiki Ijọba alakooko kikun. Oun jẹ́ ọkan lara ẹgbẹ awọn aṣaaju-ọna ti ó waasu lati oko dé oko rekọja awọn ọna gbalasa ti Orange Free State ni apa aarin gbùngbùn orilẹ-ede naa. Bawo ni imọlara awọn aṣaaju-ọna naa ti ri nipa níná ara wọn ninu mimu ihinrere naa lọ sọdọ awọn eniyan wọnyi? “Ta ni ó lè dá iye lé awọn ohun ti a ti niriiri rẹ?” ni wọn dahunpada. Niti tootọ, awọn aṣaaju-ọna wọnyi ni a san ẹsan rere fun nipa tẹmi fun awọn isapa wọn.

Ani ailekawe kò dí ẹnikan ti ebi ńpa nipa tẹmi lọwọ lati kọ́ otitọ ti Iwe mimọ. Iwe pẹlẹbẹ ti a yaworan si lọna daradara naa Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! ni pataki ni awọn ti kò mọọkọ-mọọka tabi ti wọn lè kawe diẹ tẹwọgba daradara. Ọmọde ati agbalagba bakan naa ni awọn aworan alawọ meremere Paradise famọra sii. Oṣiṣẹ alakooko kikun kan ẹni ti ó ṣeranlọwọ ninu titẹ iru ohun akojọpọ bẹẹ woye pe: “Iwe pẹlẹbẹ yii nran awọn eniyan lọwọ lati ri Paradise gẹgẹ bi ohun ti ó ṣe gidi kan eyi sì tun mu ki ọ̀wọ̀ ati ibẹru ọlọwọ adanida wọn fun Bibeli ga sii.”

Fun idi kan naa yii, itẹjade naa Iwe Itan Bibeli Mi ti di eyi ti o gbajumọ lọna titayọ. Ni ayika ẹ̀yà Lebowa kan ti ó wà ni àdádó, meji ninu awọn arabinrin wa nipa ti ẹmi ni ó yà lẹnu lati ri ọkunrin agbalagba kan, ti oju rẹ fẹrẹẹ fọ́ tan ati iyawo rẹ̀ ti wọn ni ẹda iwe yẹn kan ni ede Sepedi. Awọn tọkọtaya yii lo o gẹgẹ bi iwe ẹkọ fun kíkọ́ awọn ọmọ adugbo. Niti tootọ, iwe naa ni a ti kẹkọọ daradara ti a sì ti fami sí debi pe ó njabọ sọtọọtọ. Ẹ wo bi wọn ti ni inudidun tó lati gba ẹda titun kan!

Bẹẹ ni ó ri pe awọn itẹjade Kristẹni tootọ ńdí alafo aini nla kan ti riran awọn ẹni ti ebi otitọ npa lọwọ. Lọna ti ó ru ifẹ soke, apa tí ó pọ̀ ninu gbogbo awọn ohun títẹ̀ ní pupọ awọn ede adugbo iha guusu Africa ni a ṣe jade lati ọwọ Watch Tower Society. Ni 1990 nikan, 113,529 iwe, iwe pẹlẹbẹ, ati iwe irohin ti Society tẹjade ni a pin ni awọn igberiko guusu Africa.

Eso Làálàá Naa

Njẹ awọn iriri daradara ati ifiwesode wọnyi ha ti mu eso pipẹtiti wá ni awọn igberiko South Africa bi? Wọn ti ṣe bẹẹ dajudaju. Lati 1989 awọn ijọ mẹrin ati awujọ àdádó mẹsan-an ni a ti dasilẹ gẹgẹ bi abajade taarata kan ti pipokiki ihinrere naa ni awọn igberiko South Africa. Awọn aṣaaju-ọna akanṣe onigba diẹ ati awọn aṣaaju-ọna deedee ni wọn ṣagbatẹru pupọ ninu awọn iṣẹ yii.

Iwọ ha ṣì ranti Doris ati Ile-ẹkọ ọjọ isinmi rẹ̀ ni afonifoji jijinna yẹn ni Zululand bi? Lonii, oun jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa oluṣeyasimimọ, ti a ti bamtisi. Ni afikun, awujọ awọn olupokiki Ijọba mẹsan-an ti ngberu naa nbaa lọ lati maa tẹsiwaju nipa tẹmi nibẹ. Pupọ awọn ẹni titun ni wọn nwa si awọn ipade ti a nṣe ni ile Doris, awọn ẹni meje ti oun dari ikẹkọọ Bibeli wọn ni a sì bamtisi ni apejọpọ agbegbe ti a ṣe ni Durban ni December 1990.

Iru eso bayii jẹ́ irunisoke amọkanyọ kan fun awọn akede Ijọba naa ni South Africa. Wọn fi ọrọ apọsiteli Pọọlu naa sọkan pe: “Njẹ bi a ti nri akoko, ẹ jẹ́ ki a maa ṣoore fun gbogbo eniyan.” (Galatia 6:10) Bẹẹni, awọn iranṣẹ Jehofa ti pinnu lati dé ọdọ gbogbo awọn eniyan alailabosi ọkan, eyi ti ó ni ninu awọn ti wọn ngbe ninu igberiko ti “ibi ti ó jinna . . . ni ilẹ-aye” yii.—Iṣe 1:8, NW.

[Àwọn àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Lebowa

TRANSVAAL

Soweto

Piet Retief

Bophuthatswana

ORANGE FREE STATE

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́