A Mú Orukọ Ọlọrun Padabọsipo
“ÓTI gba ohun ti ó fẹrẹẹ to 60 ọdun ki a tó dá orukọ Ọlọrun, ‘JHWH,’ tí o jẹ Ọlọrun kii ṣe kiki awọn Juu nikan ṣugbọn ti awọn Kristẹni pẹlu, pada si ibi ti ayàwòrán kan fi sí ni ipilẹṣẹ.” Bẹẹ ni iwe irohin German naa Schwarzwälder Bote gbà sọrọ lori imupadabọsipo orukọ Ọlọrun lara ogiri gbọngan ilu ni Horb, guusu Germany. Ṣugbọn eeṣe ti a fi mu orukọ naa kuro?
Iwe irohin naa rohin pe ìta gbọngan ilu naa ni a kùn lọna ọ̀ṣọ́ pẹlu awọn iran alaworan ti ń ṣe ìta ogiri naa lọṣọọ. Eyi ti a fikun un ni Tetragrammaton, lẹta Heberu mẹrin ti o sipẹli orukọ Ọlọrun.
“Orukọ yii, eyi ti o farahan ni igba ti o ju 6,000 ninu Bibeli,” ni iwe irohin naa ń baa lọ, “ni ‘Jehofa’ tabi ohun ti o ba a mu ninu èdè German. Pípè rẹ̀ gan-an ni kò ṣe kedere nitori pe Heberu ti a kọsilẹ ní kiki awọn lẹta kọnsonanti nikan. Ẹni ti ń ka a ni yoo fi fawẹẹli kun un.
Bi o ti wu ki o ri, ni 1934 awọn olùṣaṣojú ti Ẹgbẹ́ Nazi pinnu pe Tetragrammaton “kò baramu pẹlu èrò igbalode” ati fun idi yii a gbọdọ tun un kọ. Lọna ti o muni layọ, Tetragrammaton ni a ti mupadabọsipo nisinsinyi. Iwe irohin naa sọ pe: “Lonii ìta ogiri [gbọngan ilu naa], ti a fi awọn iran onítàn, àmì ilu, ati awọn aworan ṣe lọṣọọ, jẹ́ ibi yíyẹ lati rí ‘naa’ ni Horb.”