Ki Ni Mímọ Orukọ Ọlọrun Ní Ninu?
IṢẸDA ti ara jẹrii si wíwà Ọlọrun, ṣugbọn kò ṣí orukọ Ọlọrun payá. (Saamu 19:1; Roomu 1:20) Fun ẹnikan lati mọ orukọ Ọlọrun duro fun ohun ti o ju didi ojulumọ pẹlu ọrọ naa ni ṣákálá lọ. (2 Kironika 6:33) Ó tumọsi mímọ Ẹni naa gan-an—awọn ète, igbokegbodo, ati animọ rẹ̀ gẹgẹ bi a ti ṣipaya rẹ̀ ninu Ọrọ rẹ̀. (Fiwe 1 Ọba 8:41-43; 9:3, 7; Nehemaya 9:10.) Eyi ni a ṣapejuwe rẹ̀ ninu ọran ti Mose, ọkunrin kan ti Jehofa ‘fi orukọ mọ̀,’ iyẹn ni pe, ó mọ̀ ọ́n ní àmọ̀dunjú. (Ẹkisodu 33:12) Mose lanfaani lati ri ifihansode ogo Jehofa ati pẹlu lati ‘gbọ́ pípè orukọ Jehofa.’ (Ẹkisodu 34:5) Ipolongo yẹn kii wulẹ ṣe asọtunsọ orukọ naa Jehofa ṣugbọn ó jẹ́ gbolohun ọrọ kan nipa awọn ànímọ́ ati igbokegbodo Ọlọrun. “Oluwa [“Jehofa,” NW], Oluwa [“Jehofa,” NW], Ọlọrun alaaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni ti o pọ ni oore ati otitọ; ẹni ti ó ń pa aanu mọ́ fun ẹgbẹẹgbẹrun, ti o ń dari aiṣedeedee ati irekọja ati ẹṣẹ jì, ati nitootọ ti ki i jẹ ki ẹlẹ́bi lọ laijiya; a maa bẹ ẹṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, ati lara awọn ọmọ ọmọ, lati irandiran ẹkẹta ati ẹkẹrin.” (Ẹkisodu 34:6, 7) Bakan naa, orin Mose, ti o ni awọn ọrọ naa “nitori ti emi yoo kokiki orukọ Oluwa [“Jehofa,” NW]” ninu, rohin awọn ibalo Ọlọrun pẹlu Isirẹli ó sì ṣapejuwe animọ rẹ̀.—Deutaronomi 32:3-44.
Nigba ti Jesu Kristi wà lori ilẹ-aye, ó ‘fi orukọ Baba rẹ̀ han’ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. (Johanu 17:6, 26) Bi o tilẹ jẹ pe wọn ti mọ orukọ yẹn tẹlẹ ti wọn sì ti mọ̀ nipa awọn igbokegbodo Ọlọrun gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Iwe Mímọ́ lede Heberu, awọn ọmọ-ẹhin wọnyi wá tubọ mọ Jehofa daradara ati ni ọna ti o tubọ tobilọla sii nipasẹ Ẹni naa ti ó “ń bẹ ni oókan àyà Baba.” (Johanu 1:18) Kristi Jesu ṣoju fun Baba rẹ̀ lọna pipe, ni ṣiṣe awọn iṣẹ Baba rẹ̀ ti ó sì ń sọrọ, kii ṣe lati inu ìdánúṣe tirẹ funraarẹ, bikoṣe awọn ọrọ Baba rẹ̀. (Johanu 10:37, 38; 12:50; 14:10, 11, 24) Idi niyẹn ti Jesu fi lè sọ pe, “Ẹni ti o bá ti rí mi, o ti rí Baba.”—Johanu 14:9.
Eyi fihan kedere pe kiki awọn ẹni ti o mọ Ọlọrun nitootọ ni awọn wọnni ti wọn jẹ́ awọn iranṣẹ rẹ̀ onigbọran. (Fiwe 1 Johanu 4:8; 5:2, 3.) Ọrọ idaniloju Jehofa ni Saamu 91:14, nitori naa, ṣee fisilo fun iru awọn ẹni bẹẹ: “Emi yoo gbé e lékè, nitori ti o mọ orukọ mi.” Orukọ naa funraarẹ kii ṣe oògùn mádàáríkàn, ṣugbọn Ẹni naa ti a pè ni orukọ yẹn lè pese aabo fun awọn eniyan rẹ̀ olufọkansin. Nipa bayii orukọ naa duro fun Ọlọrun funraarẹ. Idi niyẹn ti owe fi sọ pe: “Orukọ Oluwa [“Jehofa,” NW], ile-iṣọ agbara ni: olododo sá wọ inu rẹ̀, ó sì là.” (Owe 18:10) Eyi ni awọn eniyan ti wọn kó ẹru inira wọn lọ sọdọ Jehofa ń ṣe. (Saamu 55:22) Bakan naa, lati nifẹẹ (Saamu 5:11), kọ awọn orin iyin si (Saamu 7:17), ké pè (Jẹnẹsisi 12:8), fi ọpẹ́ fun (1 Kironika 16:35), búra nipasẹ (Deutaronomi 6:13), ranti (Saamu 119:55), bẹru (Saamu 61:5), wakiri (Saamu 83:16), gbẹkẹle (Saamu 33:21), gbélékè (Saamu 34:3), ati nireti ninu (Saamu 52:9) orukọ naa ni lati ṣe awọn nǹkan wọnyi pẹlu ọ̀wọ̀ fun Jehofa funraarẹ. Lati sọrọ lọna èébú nipa orukọ Ọlọrun jẹ́ lati sọrọ òdì si Ọlọrun.—Lefitiku 24:11, 15, 16.
Jehofa ń jowu fun orukọ rẹ̀, kò fayegba ibanidije tabi aiṣootọ ninu awọn ọran ijọsin. (Ẹkisodu 34:14; Esikiẹli 5:13) Awọn ọmọ Isirẹli ni a paṣẹ fun lati maṣe mẹnukan orukọ awọn ọlọrun miiran. (Ẹkisodu 23:13) Nitori otitọ naa pe orukọ awọn ọlọrun èké farahan ninu Iwe Mímọ́, itọka naa ni kedere tan mọ mimẹnukan orukọ awọn ọlọrun èké ni ọna ijọsin kan.
Ikuna Isirẹli gẹgẹ bi awọn eniyan ti a pè ni orukọ Ọlọrun lati kún oju iwọn awọn aṣẹ ododo rẹ̀ papọ jẹ́ bíba orukọ Ọlọrun jẹ́ tabi sisọ orukọ Ọlọrun di àìmọ́. (Esikiẹli 43:8; Amosi 2:7) Niwọn bi aiṣotitọ awọn ọmọ Isirẹli ti yọrisi pe ki Ọlọrun fìyà jẹ wọn, eyi tun ṣí anfaani silẹ fun orukọ rẹ̀ lati di eyi ti a sọrọ sí lọna ailọwọ nipasẹ awọn orilẹ-ede miiran. (Fiwe Saamu 74:10, 18; Aisaya 52:5.) Bi wọn ti kuna lati mọ pe ijẹniya naa wá lati ọdọ Jehofa, awọn orilẹ-ede wọnyi fi aitọna ka awọn ijaba ti o ṣubu lu Isirẹli si ailagbara Jehofa lati daabo bo awọn eniyan rẹ̀. Lati fọ orukọ rẹ̀ mọ́ kuro ninu iru ẹ̀gàn bẹẹ, Jehofa gbegbeesẹ nititori orukọ rẹ̀ ó sì mu aṣẹku Isirẹli padabọsipo si ilẹ wọn.—Esikiẹli 36:22-24.
Nipa fifi araarẹ han ni awọn ọna akanṣe, Jehofa jẹ ki orukọ rẹ̀ di eyi ti a ranti. Ni awọn ibi ti eyi ti ṣẹlẹ, awọn pẹpẹ ni a kọ́.—Ẹkisodu 20:24; fiwe 2 Samuẹli 24:16-18.
Orukọ Ọmọkunrin Ọlọrun
Nitori diduro ni oluṣotitọ titi dé oju iku, Jesu Kristi ni a san ẹsan rere fun lati ọdọ Baba rẹ̀, ni gbígba ipo ti o gaju ati “orukọ kan . . . ti o bori gbogbo orukọ.” (Filipi 2:5-11) Gbogbo awọn ti ó bá fẹ́ ìyè gbọdọ mọ ohun ti orukọ yẹn duro fun (Iṣe 4:12), papọ pẹlu ipo Jesu gẹgẹ bi Onidaajọ (Johanu 5:22), Ọba (Iṣipaya 19:16), Alufaa Agba (Heberu 6:20), Olurapada (Matiu 20:28), ati Olori Aṣoju igbala.—Heberu 2:10.
Kristi Jesu gẹgẹ bi “Ọba awọn ọba, ati Oluwa awọn oluwa” ni o tun nilati ṣaaju awọn ọmọ ogun ọrun lati wọja ogun ododo. Gẹgẹ bi olumudaajọ ẹ̀san Ọlọrun ṣẹ, oun yoo maa fi agbara ati animọ ti ó ṣajeji patapata si awọn wọnni ti ń jà lodi sii hàn. Lọna ti o ba a mu, nigba naa, ‘ó ni orukọ kan ti a kọ, ti ẹnikẹni kò mọ̀ bikoṣe oun tikaraarẹ.’—Iṣipaya 19:11-16.
Oniruuru Ọna Ti A Gbà Lo Ọrọ naa “Orukọ”
Orukọ pàtó kan ni a lè “pè mọ́” ẹnikan, ilu, tabi ile. Jakọbu, nigba ti ó ń gba awọn ọmọkunrin Josẹfu ṣọmọ, wi pe: “Ki a sì pe orukọ mi mọ́ wọn lara, ati orukọ Aburahamu ati Isaaki.” (Jẹnẹsisi 48:16; tun wo Aisaya 4:1; 44:5.) Orukọ Jehofa ti o di eyi ti a pè mọ awọn ọmọ Isirẹli lara tọka si pe wọn jẹ́ eniyan rẹ̀. (Deutaronomi 28:10; 2 Kironika 7:14; Aisaya 43:7; 63:19; Daniẹli 9:19) Jehofa tun gbé orukọ rẹ̀ ka Jerusalẹmu ati tẹmpili, ni titipa bayii tẹwọgba wọn gẹgẹ bi ibudo idari titọna ti ijọsin rẹ̀. (2 Ọba 21:4, 7) Joabu yan lati maṣe pari fifi ipá gba Raba ki a má baa fi orukọ rẹ̀ pe ilu naa, iyẹn ni pe, ki o ma baa ka ṣiṣẹgun gba ilu naa sí tirẹ.—2 Samuẹli 12:28.
Ẹni kan ti o kú laifi ọmọ ọkunrin silẹ ni a ‘pa orukọ rẹ̀ rẹ́ kuro’ gẹgẹ bi o ti rí. (Numeri 27:4; 2 Samuẹli 18:18) Nitori naa, iṣeto igbeyawo pẹlu arakunrin ọkọ tí Ofin Mose là lẹsẹẹsẹ ṣeranwọ lati pa orukọ ọkunrin ti o ti kú naa mọ́. (Deutaronomi 25:5, 6) Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, iparun orilẹ-ede kan, awọn eniyan, tabi idile tumọ si pípa orukọ wọn rẹ́.—Deutaronomi 7:24; 9:14; Joṣua 7:9; 1 Samuẹli 24:21; Saamu 9:5.
Lati sọrọ tabi lati huwa ‘ni orukọ’ ẹlomiran duro fun ṣiṣe bẹẹ gẹgẹ bi aṣoju ẹni yẹn. (Ẹkisodu 5:23; Deutaronomi 10:8; 18:5, 7, 19-22; 1 Samuẹli 17:45; Ẹsiteri 3:12; 8:8, 10) Bakan naa, lati gba ẹni kan ni orukọ ẹnikan yoo tọka si mimọ ẹni yẹn daju. Nitori naa, lati ‘gba wolii ni orukọ wolii’ yoo duro fun gbigba wolii kan nitori jíjẹ́ ti o jẹ́ bẹẹ. (Matiu 10:41, King James Version, NW) Ati lati bamtisi ni “orukọ ti Baba ati ti Ọmọkunrin ati ti ẹmi mímọ́” yoo tumọsi mímọ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ daju.—Matiu 28:19.