“Omi Ìyè” Rú Jade ní Cape Verde
“WÍWÀ ati ṣiṣe ijọsin Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Cape Verde lati ọdun 1958 jẹ́ otitọ kan ti ó yẹ ní kikiyesi,” ni minista ti ń bojuto ọran idajọ ni Republic of Cape Verde ṣalaye. Ó ń bá awọn Ẹlẹ́rìí meji ti ó ti pè wá sinu ọfiisi rẹ̀ sọrọ. “A kábàámọ̀ pe ó gba akoko gigun tobẹẹ ki Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tó di awọn ti a dá mọ lọna ofin,” ni ó fi kun un.
Ipade yẹn, ti a ṣe ni November 30, 1990, ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Cape Verde yoo maa ranti fun ìgbà pipẹ. Ó jẹ́ itọka sí ìdámọ̀ wọn ti a faṣẹ sí gẹgẹ bi ẹgbẹ́ onisin tí ó bá ofin mu kan ni orilẹ-ede yẹn. Bi o ti wu ki o ri, fun awọn Ẹlẹ́rìí mejeeji tí ó wà nibẹ, ó jẹ́ iriri ti ń ru imọlara ara-ẹni soke, nitori pe ni 1958 ni ọ̀kan lara wọn—Luis Andrade—ṣalabaapade iwe ikẹkọọ Bibeli diẹ ti a tẹjade lati ọwọ Watch Tower Society. Lẹhin kika awọn itẹjade naa lati páálí dé páálí, ó mọ̀ pe oun ti rí otitọ. Pẹlu ìháragàgà, ó ṣalabaapin ohun ti ó ti kẹkọọ rẹ̀ pẹlu Francisco Tavares, ọ̀rẹ́ ọlọ́jọ́ pipẹ kan. Ni awọn ọdun diẹ tí ó tẹle e, awọn mejeeji ń baa lọ lati gba omi otitọ naa sinu nipa kika iwe irohin Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji!, ti wọn gbà nipasẹ asansilẹ-owo. Ọdun mẹwaa lẹhin naa, ni 1968, a bamtisi wọn lakooko ibẹwo akọkọ alaboojuto arìnrìn-àjò si Cape Verde.
Arakunrin Andrade ati Tavares mọ ẹrù-iṣẹ́ wọn lati ní ipin ninu pipolongo ikesini naa: “Maa bọ . . . gba omi ìyè naa lọfẹẹ.” (Iṣipaya 22:17) Wọn muratan lati tẹwọgba ipenija ipinlẹ wọn tí ó fọ́nká gátagàta tí ó sì ṣoro. Cape Verde ní awọn erekuṣu pataki mẹwaa ati awọn erekuṣu kekere diẹ ninu Agbami-Okun Atlantic nínú, ni nǹkan bii 350 ibusọ sí iwọ-oorun Dakar, Senegal. Orukọ naa Cape Verde, tí ó tumọsi “Ilẹ ṣonṣo tí ó yọri jade lati inu omi tí ó ni àwọ̀ eweko,” ní ipilẹṣẹ wà fun ilẹ ti omi fẹrẹẹ yika ti etikun Africa. Bi o ti wu ki o ri, awọn erekuṣu wọnyi kò ni àwọ̀ eweko rara, niwọn bi ojo rírọ̀ ti mọ níwọ̀n, ti 350,000 awọn olugbe sì gbọdọ tiraka gbọ́ bùkátà lati inu ilẹ tí ó ti ṣá naa.
Ni ẹnu iwọn 30 ọdun tí ó kọja, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ati awọn aṣaaju-ọna akanṣe ti ṣiṣẹ kára gẹgẹ bi ojiṣẹ alakooko kikun ní mimu omi ìyè lọ fun awọn olugbe erekuṣu naa. Ki ni o ti jẹ́ abajade iru òpò bẹẹ? Lẹnu aipẹ yii, alaboojuto arìnrìn-àjò kan lati Portugal ṣe ibẹwo si awọn ijọ ni Cape Verde. A o jẹ ki o sọ ohun tí ó ri fun wa.
São Vicente Gbọ́ “Ede Mimọgaara” Naa
Ibuduro wa akọkọ ní Cape Verde ni ilu Porto Grande ní ori Erekuṣu São Vicente. Ní wíwakọ̀ lati pápá ọkọ-ofuurufu lọ sinu ilu, a ri awọn ẹ̀gbẹ́ oke olokuuta tí awọn iyẹpẹ tí atẹgun ń fẹ kiri bò. Sisọ ilẹ di aṣalẹ ti Ariwa Africa ti dé erekuṣu Cape Verde naa! Lati December dé February, ọyẹ́—atẹgun gbigbona, tí ó gbẹ lati Sahara—a maa fẹ́ la agbami okun já ti yoo sì fẹ́ iyẹ̀pẹ̀ ati eruku bo awọn erekuṣu naa. Nigba miiran kùrukùru eruku naa a maa nipọn tobẹẹ debi pe ọkọ ofuurufu kò ni lè fò. Iwọnba koriko diẹ tí ó bá ṣẹku ni yoo gbẹ danu nigba ti ọyẹ́ bá dé.
Bi o ti wu ki o ri, ti a ba ń sọrọ nipa tẹmi, orisun omi wà larọọwọto pẹlu irọrun. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fidii ijọ meji mulẹ ni Porto Grande, 167 awọn akede Ijọba ni ọwọ wọn sì dí ni mímú omi ti ń funni ni ìyè lọ sọdọ 47,000 awọn olugbe ti Erekuṣu São Vicente. Ni ipari ọsẹ, nǹkan bi 400 eniyan a maa wá si awọn ipade ti a gbekari Bibeli ni Gbọngan Ijọba.
Ni akoko awọn ibẹwo tí ó gùn fun ọ̀sẹ̀ kan naa, awọn iṣeto àṣekágbá ni a ti ń ṣe fun Apejọpọ Agbegbe “Ede Mimọgaara” ti a o ṣe ni gbọngan iṣere ti ó dara julọ ninu ilu naa. (Sefanaya 3:9) Papọ pẹlu awọn eniyan adugbo, awọn ayanṣaṣoju lati awọn erekuṣu Santo Antão ati São Nicolau mu ki iye eniyan tí ó wá dé gongo 756. Awọn eniyan mẹrinlelogun ni a bamtisi. Itolẹsẹẹsẹ naa ní awokẹkọọ Bibeli kan ti a gbekalẹ lati ọwọ awọn Ẹlẹ́rìí naa ninu. Ọkunrin kan tí ó jẹ́ oludari àṣefidánrawò fun imujade aworan sinima kan wá si ibi awokẹkọọ naa ó sì ṣalaye pe: “A ń ṣe idanilẹkọọ fun ọdun kan ati sibẹ paapaa lẹhin naa a ń ní ọpọlọpọ iṣoro. Awọn olukopa ninu awokẹkọọ yin ṣe daradara pupọpupọ pẹlu kiki idanilẹkọọ oṣu meji.” Pẹlu ipari apejọpọ naa tí ó kẹ́sẹjárí, akoko tó fun wa lati ṣí lọ si ilu Praia, olu-ilu Cape Verde Republic, lori erekuṣu São Tiago.
Awọn Eniyan Ti A Ti Sọ Di Mímọ́
Ni awọn ọdun ẹnu aipẹ yii ọpọlọpọ awọn olugbe awọn erekuṣu miiran ti wọ́ lọ si olu-ilu ni wíwá iṣẹ́ kiri. Gẹgẹ bi iyọrisi, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ahéré ti ìgbà atijọ ni a ti kọ́ si ẹhin ode ilu naa, eyi tí ó tubọ ń mú ipese omi ati awọn ipese imọtoto tí ó mọniwọn ṣoro sii. Lati ṣafikun owo ti ń wọle fun wọn, ọpọlọpọ idile ń sin ewurẹ, ẹlẹdẹ, ati adiyẹ. Ó wọpọ lati rí ki awọn wọnyi maa rin kaakiri fàlàlà ni oju títì. Eyi si ti dákún itankalẹ àrùn.
Bi o ti wu ki o ri, laika iru awọn ipo iṣoro bẹẹ si, ijọ meji ti ń gbèrú ni ó wà nisinsinyi ni Praia, pẹlu iye awọn akede Ijọba ti apapọ wọn to nǹkan bii 130. Awọn Ẹlẹ́rìí alayọ wọnyi ni ó daju pe wọn ti ‘ṣe araawọn lanfaani’ nipa fifi ohun ti wọn ti kọ́ lati inu Bibeli silo. Ni gbigbiyanju lati jẹ́ awọn eniyan alaileeri ati mímọ́, awọn ará wa ati awọn ọmọ wọn ti gbadun ilera didara ju, nipa tẹmi ati nipa ti ara. Bi o tilẹ jẹ pe igbesi-aye wọn ṣoro, wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ nipa tẹmi.—Aisaya 48:17; 1 Peteru 1:15, 16.
Bi a ti gúnlẹ̀, awọn ará ni ọwọ́ wọn dí ni mimurasilẹ fun apejọpọ agbegbe wọn. Awọn Ẹlẹ́rìí ati awọn olufifẹhan lati gbogbo São Tiago ati bakan naa lati erekuṣu Sal ati Fogo lọ si apejọpọ naa, Jehofa sì bukun fun wọn pẹlu gongo 472 awọn eniyan ti wọn wá. Gbogbo eniyan ni o layọ gidigidi, titikan ọpọlọpọ awọn ọmọde ti oju wọn ń dán! Bi a ti jokoo laaarin awujọ awọn eniyan pupọ ti ń tẹ́tísílẹ̀ yẹn, ó ṣe kedere pe a kò gbọdọ ṣainaani “ọjọ ohun kekere.” (Sekaraya 4:10) Gbogbo eyi ti roke lati ori ẹni meji tí ó kẹkọọ otitọ ni ohun tí ó wulẹ jẹ́ 30 ọdun sẹhin!
Ki a tó fi erekuṣu naa silẹ, a lọ ṣebẹwo sọdọ awujọ kekere meji naa, Vila Assomada ati Tarrafal, ni ẹhin ode ilu naa. Erekuṣu naa jẹ́ olókè, aṣálẹ̀, ati ilẹ̀ gbigbẹ. Ṣugbọn lọ́tùn-ún lósì, a rí awọn ohun ọgbin gátagàta ti eweko ati awọn igi ti wọn ń gbilẹ—ọpọ eékà awọn igi àgbọn, ọ̀gẹ̀dẹ̀, ìbẹ́pẹ, máńgòrò, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eyi pe asọtẹlẹ wolii Aisaya wá si ọkàn pe ni ọjọ kan ani aṣálẹ̀ paapaa yoo rúwé. (Aisaya 35:1) Bii ibi omi ninu aginju, ani awujọ kekere meji ti Awọn Ẹlẹ́rìí naa nisinsinyi pese ọpọ yanturu ounjẹ ati ohun mímu tẹmi fun ẹgbẹẹgbẹrun ti ó walaaye, gẹgẹ bi o ti ri, ninu ilẹ aṣálẹ̀ nipa tẹmi.
Itara Ajóbíiná ni Erekuṣu Fogo
Erekuṣu tí ó kàn ni Fogo, tí ó tumọsi “iná.” Ipilẹṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi oke ayọná yọ èéfín ṣalaye orukọ naa. Sibẹsibẹ Cano Peak ṣì jẹ́ oke ti ń yọná yọ èéfín. Ó yọri jade lati inu òkun lọna kan tí o mu kí o fẹrẹẹ dabi òkòtó aborí ṣonṣo tí o ga de gongo 9,300 ẹsẹ bata. Erekuṣu naa ṣẹṣẹ ní ojo rírọ̀ ti ó pọ̀ tó ni, akọkọ iru eyi tí ó dunlẹ̀ bẹẹ ni ọpọ ọdun. Imọlara idunnu wà laaarin awọn eniyan, ọwọ́ wọn sì dí gidigidi pẹlu irugbin ẹ̀wà ati gbágùúdá wọn, tí ó jẹ́ ounjẹ tí ó wọ́pọ̀ ni Cape Verde.
Bi o ti wu ki o ri, awọn eniyan onimọriri wọnyi ni ọwọ́ wọn kò dí jù lati duro ki wọn sì mu omi otitọ lati inu Bibeli. Ó ṣeeṣe fun wa lati pade awujọ ọtọọtọ mẹta, ani bi o tilẹ jẹ pe ìsapá nla ni lati dé ọdọ wọn nitori pe ọkọ ayọkẹlẹ mọ niwọn wọn sì wà ni ipo ti kò dara. Ayọ wa kún akunwọsilẹ nigba ti àròpọ̀ 162 awọn eniyan wá si ipade, nitori pe kiki 42 awọn akede Ijọba ni o wà lori erekuṣu naa. Eyi jẹ́ ifihan itara awujọ kekere yii ti awọn arakunrin ati arabinrin, ti wọn ń lo ipindọgba wakati 15 loṣooṣu ni mímú omi iṣapẹẹrẹ ti otitọ ati ìyè tọ awọn olugbe 32,000 ti Erekuṣu Fogo lọ.
Awọn Eso Ni Ilẹ Katoliki Kan
A kò ì tíì ṣebẹwo sọdọ awọn ará wa lori erekuṣu Santo Antão ati São Nicolau. Gẹgẹ bi awọn orukọ wọnyi ti fihan, Ṣọọṣi Roman Katoliki ti lo agbara idari rẹ̀ lori erekuṣu naa fun awọn ọrundun melookan. Bi o tilẹ jẹ pe isin Katoliki ṣì jẹ́ isin pataki ni Cape Verde, ọpọlọpọ awọn eniyan oloootọ ọkàn ń yiju si Bibeli fun omi otitọ atunilara rẹ̀.
Awọn akede Ijọba 49 ti wọn wà ninu ijọ kekere meji ni ikangun tí ó wa ni odikeji síra ni Santo Antão ṣiṣẹ kára lati kájú aini tẹmi awọn 44,000 olugbe inú rẹ̀. Nigba ti 512 awọn eniyan wá si ọrọ-asọye Bibeli fun gbogbo eniyan ni Ijọ Porto Novo, ó ṣe kedere fun awọn akede Ijọba 32 ti wọn wà nibẹ pe ọpọlọpọ awọn eniyan bi agutan ni Santo Antão ni oungbẹ ń gbẹ fun omi otitọ.
Iṣẹ lori Erekuṣu São Nicolau bẹrẹ ni ọdun diẹ sẹhin nigba ti arabinrin aṣaaju-ọna kan ni Portugal dari ikẹkọọ Bibeli kan pẹlu idile kan lori erekuṣu naa nipasẹ ikọweranṣẹ. Lẹhin naa, ni 1978, aṣaaju-ọna miiran ni Portugal pinnu lati pada si erekuṣu ibilẹ rẹ̀, São Nicolau, lati ṣajọpin otitọ Bibeli pẹlu awọn 15,000 olugbe rẹ̀. Nigba tí ó dari ipade Bibeli akọkọ lori erekuṣu naa, iye eniyan tí ó wá jẹ́ ẹyọkan péré—oun funraarẹ! Ṣugbọn Jehofa Ọlọrun dahun awọn adura onígbòóná-ọkàn ti ó gbà ni ipade yẹn. Nigba ibẹwo wa, awọn akede 48 ninu awọn ijọ mẹtẹẹta layọ lati rí i pe aropọ 335 eniyan ti wá si awọn ipade naa.
Apejọ ayika akọkọ lori erekuṣu naa ni a ṣe ni akoko ibẹwo wa, ile iṣere adugbo ni a sì mú wà larọọwọto fun wa lọfẹẹ. Awọn alaṣẹ ilu pese ohun èèlò gbohùngbohùn ati ọkọ irinna ọ̀fẹ́. Awọn akede 19 ti ijọ tí ó gbalejo naa bojuto ile gbigbe fun awọn 100 ayanṣaṣoju wọn sì se ounjẹ fun 208 eniyan ti ó wá. Laika ọpọlọpọ inira ti awọn ará wa ń dojukọ lojoojumọ sí wọn ṣe ìtọrẹ fun Owo-akanlo Society fun Gbọngan Ijọba.
Iwa rere Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a mọ daradara nihin-in, ọpọlọpọ awọn olugbanisiṣẹ sì ń wá wọn nigba ti wọn bá nilo oṣiṣẹ. Fun apẹẹrẹ, ẹni tí ó ni ile-epo kanṣoṣo tí ó wà lori erekuṣu naa sọ fun Ẹlẹ́rìí kan lati ṣiṣẹ fun oun, niwọn bi o ti nilo ẹnikan tí ó jẹ́ alailabosi. Arakunrin naa ti ní iṣẹ kan ṣaaju ṣugbọn ó sọ pe oun yoo wò ó bi oun bá lè ri ẹlomiran. “Kiki bi ó bá jẹ Ẹlẹ́rìí ti a ti bamtisi!” ni ẹni tí ó ni iṣẹ naa fi itẹnumọ sọ. Oṣu meji lẹhin naa ó sọ fun arakunrin wa pe: “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni kiki awọn eniyan ti wọn gbọdọ bojuto owó!”
Ibuduro Ikẹhin—Erekuṣu Sal
Ibuduro wa tí ó kẹhin ninu ìrìn-àjò yii ni erekuṣu Sal. Orukọ rẹ̀ tumọsi “iyọ̀,” iyẹn sì tọka si ile iṣẹ kanṣoṣo lori erekuṣu naa lọna rirọrun. Nihin-in ijọ kekere naa ni awọn akede 22, ti wọn ń ṣiṣẹ kára lati mú ihin-iṣẹ Ijọba naa tọ awọn olùgbé 6,500 lọ. Ó jẹ́ ayọ gidi lati ṣajọpin ihinrere pẹlu awọn eniyan erekuṣu wọnyi, nitori pe o fẹrẹẹ jẹ́ pe ni gbogbo ile ni wọn ti kesi wa wọle a sì lè sọrọ fun awọn mẹmba agbo ile melookan.
Ibẹwo si Erekuṣu Sal ni ó pari ìrìn-àjò ibẹwo wa. Iru ibukun wo ni o jẹ́ lati ṣiṣẹ pẹlu awọn iranṣẹ oluṣotitọ ti Jehofa wọnyi ni Cape Verde! Awọn akede Ijọba 531 ni wọn wà ni awọn erekuṣu wọnyi nisinsinyi, iye yẹn ni ó sì daju pe yoo ga sii bi 2,567 awọn eniyan ti wọn wá si Iṣe-iranti iku Kristi ni 1991 ti ń baa lọ lati gba awọn ipese tẹmi. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ julọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nihin-in ní iwọnba diẹ niti ohun ti ara, wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ a sì bọ́ wọn yó daradara nipa tẹmi. Bawo ni wọn sì ṣe kún fun ọpẹ tó pe Jehofa ń jẹ́ ki omi ìyè rú jade lọpọ yanturu lori awọn erekuṣu wọnyi si ogo ati iyin rẹ̀!
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an.)
CAPE VERDE
SANTO ANTÃO
SÃO VICENTE
SÃO NICOLAU
SANTA LUZIA
SAL
BOA VISTA
MAIO
SÃO TIAGO
FOGO
BRAVA
Praia
Atlantic Ocean