ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 5/15 ojú ìwé 24-27
  • Awọn Ará India Ti Ẹ̀yà Goajiro Dahunpada Lọna Rere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ará India Ti Ẹ̀yà Goajiro Dahunpada Lọna Rere
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Ìrísí Akọkọ
  • Wiwa Awọn Ile Kàn
  • Ni Ojukoju Pẹlu Awọn Goajiro
  • Ọpọ Olùpésẹ̀ Ju Bi A Ti Fọkansi Lọ
  • Abajade Alaṣeyọrisi Rere
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 5/15 ojú ìwé 24-27

Awọn Ará India Ti Ẹ̀yà Goajiro Dahunpada Lọna Rere

NI JIJOKOO sabẹ ìbòji igi nla kan ati wiwọ ẹwu awọkanlẹ dudu kan, àgbà obinrin naa dabi pe o wá lati iran-iṣẹdalẹ miiran. Bakan naa o tun ń sọrọ ni ede ti o ṣajeji ni eti wa. “Ẹ tun pada wa,” ni o fi titaratitara sọ. Ni titọka si awọn 50 eniyan miiran lati iran rẹ̀ ti wọn jokoo yi i ka, o fikun un pe: “Gbogbo wa fẹ ki ẹ tun pada wa. Ẹ maa wa lọsọọsẹ!”

Ta ni awọn eniyan wọnyi? Eeṣe ti wọn fi ń háragàgà tobẹẹ lati ri i pe a pada wa, bi o tilẹ ṣe pe wọn kò tii bá wa pade rí? Fun wa laaye lati sọ fun ọ nipa ọjọ kan ti a lò laaarin awọn ará India ti ẹ̀yà Goajiro ti n gbe ni La Guajira Peninsula ni ariwa ila-oorun Colombia ati nitosi ariwa iwọ-oorun Venezuela.

Ìrísí Akọkọ

Ni gbigbera lati olu-ilu orilẹ-ede Venezuela, Caracas, ibi ti a ti kọkọ duro ni ilu Maracaibo. Bi a ti wakọ wọnu ilu, a ṣakiyesi awọn ọdọbinrin mẹta ti ń rin lọ loju ọna ninu awọn ẹwu gigun, alawọ arabara. Irisi ara wọn yatọ si ti eyi ti o wọpọ julọ ninu awọn ọmọ ilẹ Venezuela—párì ẹrẹkẹ giga, àwọ̀ ara alawọ ilẹ̀, irun dudu gigun gbọọrọ. Ni siṣakiyesi ìrìn tẹ̀sọ̀tẹ̀sọ̀, lọna iyi wọn, rírí awọn ará India ti ẹ̀yà Goajiro fìrí lakọọkọ ru ifẹ-ọkan wa soke.

Ojumọ ọjọ ìrìn àjò wa si ilẹ La Guajira Peninsula mọ́ rekete o sì parọ́rọ́. Ṣaaju ki oorun aarọ to gbonaju, awa ti a jẹ́ 50 wọnu ọkọ bọọsi kan, pẹlu iwuri ti nini ipa kan ninu akanṣe ipolongo kárí orilẹ-ede naa lati mu ihin-iṣẹ Bibeli de awọn agbegbe ti o jẹ àdádó nihin in ni orilẹ-ede Venezuela. Ilu Paraguachón, ní oju ààlà ipinlẹ pẹlu orilẹ-ede Colombia, ni a forile.

Ni fifi ilu-nla Maracaibo sẹhin, a la ọpọ awọn ilu keekeeke ati ileto kọja, ti ọkọọkan ni ọjà kan pẹlu awọn ìsọ̀ ìtajà melookan ti wọn ti ń ta awọn salubata híhun ati awọn ẹwu gigun, alawọ àràbarà ti a ń pe ni mantas. Olukuluku ileto ni o ní gbangba ojude ti gbogbogboo ati ṣọọṣi alawọ rẹ́súrẹ́sú mimọ tonitoni kọọkan, ti ń fun gbogbo iran naa ni irisi aláwọ̀ gbigbadunmọni kan. Gbogbo awọn eniyan naa ni wọn ni irisi ti ara India kan. Bi o tilẹ jẹ pe wọn yatọ pupọpupọ si wa ni irisi, a nilati ran araawa leti pe awọn wọnyi jẹ diẹ lara awọn ará Venezuela ipilẹṣẹ.

Wiwa Awọn Ile Kàn

Nikẹhin a dé ibi ti a ń lọ. Ọkọ bọọsi wa yà si ẹgbẹ ọ̀nà o si duro lẹba ogiri rirẹlẹ kan labẹ ibòji igi kan ti o tẹ́rẹrẹ. Lodikeji ogiri naa ni ile-ẹkọ ileto naa wà—ti a tì nitori pe o jẹ ọjọ Sunday.

Ni pipinra si awujọ meji, a bá ọna ọtọọtọ lọ ni wiwa awọn ile kiri. A fẹ kesi olukuluku wa sibi ọrọ asọye Bibeli ti a fẹ sọ ni ede Goajiro ni agogo mẹta ọsan ọjọ naa ninu ọgba ile-ẹkọ naa. Evelinda, ọmọ ibilẹ India ti ẹ̀yà Goajiro, ni alabaarin wa. A nireti pe eyi yoo mu ki a tubọ ṣetẹwọgba sii, nitori bi o tilẹ jẹ pe a le sọ ede Spanish, a kò mọ ohunkohun nipa ede Goajiro.

Ni gbàrà ti a ti jade kuro ninu ileto naa, a ni ọpọ ìrìn lati rin laaarin ile si ile. Bi a ti ń rìn lọ si isalẹ opopona gigun kan ti o dígbó lapa mejeeji, ọmọde kekere kan ti o jẹ nǹkan bii ọmọ ọdun mẹwaa ń rin lẹgbẹẹ wa ti o si tẹjumọ wa pẹlu kayefi ti o han kedere. Evelinda rẹrin-in musẹ sii ti o sì ṣalaye ete ikesini wa si adugbo naa fun un ni ede Goajiro. Orukọ rẹ̀ ni Omar, o sì fò lantolanto lọ kuro lọdọ wa lẹhin igba ti a fun un ni ikesini wa si awiye naa.

Ni yíyà kuro loju ọna naa, a gba ipa ọna wúruwùru kan ti o ṣì tutu fun omi òjò ti ó rọ̀ laipẹ kọja. A gbọ́ pe ibi yii ni ipa ọna awọn onífàyàwọ́ laaarin orilẹ-ede Colombia ati Venezuela. Ṣe ni atẹgun kunfọfọ fun òórùn koriko ti ó kún ṣìkìtì-ṣìkìtì. Bi o tilẹ jẹ pe atẹgun olóoru naa ninilara, eyi kò kó irẹwẹsi ba itara wa. Bi o ti wu ki o jẹ, gbogbo inira naa ni a gbagbe bi ipa ọna ti o gba inu igbo dídí ti inu ilẹ olóoru naa ti jásí ojude gbayawu kan—ọ̀dẹ̀dẹ̀ agbo ile ti o jẹ ti Goajiro kan.

Ni Ojukoju Pẹlu Awọn Goajiro

Ewurẹ bii mejila, pẹlu apapọ àwọ̀ funfun, dudu, ati pupa rúsúrúsú ẹlẹ́wà lara wọn, jokoo sabẹ ibòji, ti wọn ń jẹun pẹlu ìdẹ̀rùn. Ni idubulẹ lori ibusun ti a sorọ̀ saaarin igi meji, ni obinrin kan wà ti ń fun ọmọ rẹ̀ ni ounjẹ. Awọn ọmọ wẹwẹ melookan ń ṣere nitosi ibẹ̀. Obinrin naa wà nita lẹgbẹ ọgba ti a fi igi pẹlu waya tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe yika ile koriko kan ti o ni ogiri ti a fi ọparun ati amọ̀ ṣe pẹlu orule koriko. Awọn àtíbàbà melookan sì wà ni ayika ibẹ̀. Ọkan dajudaju jẹ́ ile ìdáná, nibi ti ina igi ti ń jó lori ilẹ laaarin awọn ìkòkò nla ti wọn dabi ìkòkò onirin. Awọn awọ ewurẹ ni a sorọ̀ si itosi lati sá wọn gbẹ.

Nigba ti ọkunrin kan ti o duro si ẹnu ọna ri wa ti a ń bọ̀, o sare siwaju o si gbe apoti ijokoo meji silẹ fun wa lẹgbẹẹ obinrin ti o wà lori ibusun ti a sorọ̀ naa. Evelinda kí ọkunrin ati obinrin naa ni ede wọn o si ṣalaye ireti fun ọjọ iwaju lati inu Iwe Mimọ ni lilo iwe pẹlẹbẹ naa Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae! Awọn ipo alalaafia ti ó wà ni adugbo naa mu ki a mọ̀ pe awọn rukerudo lati orilẹ-ede kan si ikeji tabi ibisi ninu ifipajanilole ni itagbangba ni agbegbe ti awọn talaka kun fọfọ ni awọn ilu-nla ki yoo jẹ akori ti o ṣe wẹ́kú nihin in. Ẹlẹ́rìí kan ninu awujọ naa ti ṣalaye pe niwọn bi o ti jẹ́ pe iwa ẹ̀dá awọn ará India ti ẹ̀yà Goajiro ni o jẹ lati lọra ni sisọ èrò wọn jade, o ṣe pataki lati fi ọ̀yàyà ati ojulowo ọkan-ifẹ han lati ìbẹ̀rẹ̀pàá “A saba maa ń beere nipa ilera idile, nipa ikore, boya òjò rọ̀ laipẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ,” ni obinrin naa wi. “Eyi maa ń ṣí ọna silẹ fun wa lati sọ fun wọn nipa Ijọba Ọlọrun ati lati fi han wọn pe Jehofa yoo mu gbogbo ijiya ati Satani Eṣu, ẹni ti wọn ń bẹru lọna ara-ọtọ, kuro laipẹ.”

Bi Evelinda ti ń sọrọ, awọn olugbọ rẹ̀ ń fi ifohunsọkan wọn han, laipẹ obinrin kan ati awọn ọmọde melookan si darapọ pẹlu wa. A ti sọ ọ di mímọ̀ fun wa ṣaaju pe ofin ẹ̀yà Goajiro fayegba ọkunrin kan lati ni ju aya kan lọ. Eyi ha lè jẹ bi ọran ti ri nihin in? Eyi mu wa ronu nipa Yenny, ẹni fifanimọra ọlọjọ-ori 21 kan ara Goajiro ti ń gbe ni Maracaibo. Ọkunrin ọlọla ara Goajiro kan fi iye owo ìdáná ti o dara kan lelẹ nitori rẹ̀. Ṣugbọn awọn obi rẹ̀, ti kii ṣe Ẹlẹ́rìí Jehofa ni èrò yiyatọsira lori ọ̀ràn naa. Bi o tilẹ jẹ pe iya rẹ̀ gbà pe ki wọn fẹ́ araawọn, baba rẹ̀ sọ pe bẹẹkọ. Ọkunrin naa ti ó fẹ́ fẹ́yàwó ti gbé anti Yenny niyawo ni iṣaaju!

Nigba ti Evelinda pari iwaasu rẹ̀, ọkunrin naa gba iwe pẹlẹbẹ kan. Obinrin ti o duro lẹhin rẹ̀ pẹlu beere fun ọkan, a si layọ lati ṣe bi wọn ti wi. Ni ìgbà yẹn awọn ọ̀rẹ́ wa yooku ti kọja lọdọ wa. Nitori naa a kesi idile naa wa si ọrọ asọye ti ọsan a si fi ibẹ silẹ, nitori ti a kò fẹ sọnu ninu igberiko ti a kò mọ̀ daradara yii.

Ẹlẹ́rìí kan ninu awujọ naa sọ ohun ti o ti ṣẹlẹ si oun fun wa. Ọkunrin kan ninu ibusun ti a sorọ̀ tẹtisilẹ bẹ̀lẹ̀jẹ́ bi iyawo rẹ̀ ti lọ mu awọn ìpápánu diẹ wa—ife chicha meji, ti a fi agbado ṣe. Pẹlu ìyẹ́nisí, arakunrin wa tẹwọgba a o si mu ún. Lẹhin naa, alabaarin rẹ̀ ara Goajiro, Magaly, ṣalaye bi a ti ṣe ṣe ohun mímu naa. Bi o ti saba maa ń rí, ehín ni a fi ń lọ agbado naa! Obinrin naa kò lè ṣe ohun miiran ju pe ki o búsẹ́rín-ín bi o ti ṣakiyesi pe oju ọkunrin naa kọ́rẹ́lọ́wọ́.

Ọkunrin ọmọluwabi ara India miiran, ti ó hàn gbangba pe isapa awọn arakunrin wa lati mu ihin iṣẹ Bibeli naa de ile rẹ̀ fun ni ìwúrí, fo silẹ lati inu ibusun àsorọ̀ rẹ̀. Ni wiwọ ẹ̀wù kan, o fúnraarẹ̀ samọna wọn lọ si ibudo kan ti o wa ni kọ̀rọ̀ ti a ti fisilẹ sẹhin láìrí.

Bi a ti ń gba ojúde miiran kọja nibi ti diẹ lara awọn ọ̀rẹ́ wa ti ń jiroro pẹlu awọn ti wọn dagba ni agbo ile naa, a ri awujọ awọn ọmọde kekere ti wọn wa ni ihoho pẹlu inu wọn ti o yọ kẹnrẹndẹn ti wọn duro jẹ́jẹ́ sabẹ igi kan. A loye mọ̀ pe ohun ti o fa ipo yii ni apapọ aijẹunrekanu ati awọn kokoro-arun afòmọ́ni. Ọpọlọpọ awọn eniyan wọnyi kò ní omi ẹ̀rọ ati ipese ina mànàmáná. Eyi, dajudaju tumọsi pe kò si ẹ̀rọ amóhun-tutù, fáàànù, tabi ina mànàmáná.

Ọpọ Olùpésẹ̀ Ju Bi A Ti Fọkansi Lọ

Owurọ ti kọja lọ ni wàrà-ǹ-ṣesà. Bi a ti pada lọ si idi ọkọ bọọsi wa lati jẹ ounjẹ ọsan wa, a ń ṣe kayeefi nipa iye awọn ti yoo wá lara awọn ti a ti kesi pe ki wọn wa si ọrọ asọye Bibeli ti ọsan naa.

Ni agogo 2:45 ọsan, a ṣe kayeefi boya kìkì iye awa ti a wa pẹlu ọkọ bọọsi wa ni yoo jẹ awujọ olugbọ fun arakunrin wa ara Goajiro, ti o ti mura asọye oniṣẹju 45 ni ede adugbo naa. Ṣugbọn bẹẹkọ! Idile kekere akọkọ wa sinu ọgbà ile-ẹkọ naa pẹlu itiju. Iyalẹnu ni o nilati jẹ fun wọn bi gbogbo eniyan ti fi tọyayatọyaya ki wọn kaabọ. Ni iṣẹju melookan ti o tẹle e, pupọ sii wá, ti o si ṣe kedere pe pupọ ti rìn wa lati ọna jinjin. Idile ti ń gbe ni ojúde ti ewurẹ mejila wà wá pẹlu! Bawo ni obinrin ti o wà ninu ibusun ti a sorọ̀ naa ti yatọ tó ninu aṣọ manta rẹ̀ dudu, mimọtonitoni ti o si dara! Ani Omar kekere pẹlu, ẹni ti a ba sọrọ loju ọna, wá, o sì daju pe ń ṣe ni o dá wá fúnraarẹ̀. Bi awọn miiran ti ń de, àtẹ̀gùn gigun ti a fi kọnkere ṣe kanṣoṣo ti o wa ninu ọgbà ile-ẹkọ naa ti a lò gẹgẹ bi ijokoo kún fun èrò. Pẹlu eyi awakọ̀ bọọsi wa oniwa-bi-ọrẹ bẹrẹ sii yọ awọn ijokoo inu ọkọ jade fun awọn eniyan lati jokoo ni akoko ọrọ asọye naa.

Apapọ 55 awọn ará India ti ẹ̀yà Goajiro ni wọn jokoo ti wọn si fetisilẹ bi Eduardo ti funni ní asọye Bibeli naa. Bi o ti wu ki o ri, wọn kò jokoo sibẹ bi olúńdù. Bi wọn bá fohunṣọkan pẹlu koko kan ti olubanisọrọ sọ, wọn yoo fi itẹwọgba wọn han nipa siṣe hùn ùn tabi kíkùn. Nigba ti o sọrọ nipa opin iwa buruku ti ń bọ̀, àgbà obinrin ti a mẹnukan ni ibẹrẹ lohun si i. “Bẹẹni, iwa buruku pupọ ni o wà,” ni obinrin naa sọ soke debi pe gbogbo eniyan fi lè gbọ. “Ki a sootọ, awọn eniyan buruku melookan wà ti wọn jokoo sihin in lọwọlọwọ bayii. Nitori naa mo lero pe wọn ń gbọ́ o!” Arakunrin Eduardo fi ọgbọn ẹwẹ fihan pe oun gbọ ọrọ afikun rẹ̀ o si ń ba ọrọ asọye rẹ̀ lọ.

Lẹhin ti ọrọ asọye naa pari, ẹnikan lara awujọ wa ya fọto kan. Eyi dunmọ awọn Goajiro ninu wọn si beere boya awọn lè na iwe Gbádùn Iwalaaye wọn soke ni igba fọto keji. Diẹ ninu wọn fi wa silẹ lọ ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ṣugbọn nǹkan bii ìdajì duro ti wọn si ń wò wá bi a ti ń goke wọnu bọọsi naa. Wọn mu ki a jẹ́jẹ̀ẹ́ lati tun pada wa, lẹhin naa wọn duro wọn si ń juwọ si wa titi tí wọn kò fi rí bọọsi wa mọ́.

Bi a ti ń wakọ lọ, dajudaju a nimọlara pe o ti jẹ anfaani fun wa lati mu ihinrere Ijọba Ọlọrun tọ awọn eniyan wọnyi lọ. Fun ọpọlọpọ akọkọ ti wọn ń gbọ ọ niyii. Awọn Ẹlẹ́rìí ni Maracaibo ti ń sọrọ nipa ibẹwo wọn ti yoo tẹle e. Njẹ itan yii yoo ha ni abajade bi?

Abajade Alaṣeyọrisi Rere

Awọn ará naa pada lọ ni ọsẹ meji lẹhin naa. Awọn iwe ikẹkọọ Bibeli pupọ ni wọn fi sode, wọn sì ṣe ipadabẹwo sọdọ awọn ti wọn fifẹhan, wọn a si bẹrẹ awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile. Ju bẹẹ lọ, awọn ara India 79 ni wọn wá si ipade itagbangba ẹlẹẹkeji fun gbogbo eniyan. Ni igba yẹn awọn arakunrin ṣalaye pe awọn yoo pada wá lẹhin ọsẹ mẹta dipo meji nititori apejọ ayika kan. Awọn ara India naa ni a mu tagìrì. “A lè kú ṣaaju ìgbà naa!” ni ọkan ninu wọn sọ. Wọn beere ohun ti apejọ ayika kan jẹ. O dabi ohun didara tobẹẹ leti ìgbọ́ wọn ti wọn fi pinnu pe awọn naa fẹ́ lati wà nibẹ pẹlu! A ṣe awọn eto, 34 ninu wọn ni o sì ṣeeṣe fun lati wá si apejọ naa ni ilu Maracaibo, nibi ti awọn arakunrin ti wọn ń sọ ede Goajiro ti ṣeranwọ fun wọn lati loye itolẹsẹẹsẹ ti ede Spanish naa.

Ifẹ inu Jehofa ni pe “ki gbogbo eniyan . . . wa sinu imọ otitọ.” (1 Timoti 2:3, 4) Ẹ wo iru ayọ ti o jẹ lati ri iru idahunpada rere bẹẹ lati ọdọ awọn India olùwá otitọ kiri wọnyi ti wọn wà lori ilẹ La Guajira Peninsula!

[Box on 26]

Igbesi-Aye Ti Awọn Otitọ Bibeli Mu Sunwọn Sii

Iris ati Margarita, awọn ọdọlangba ara Goajiro meji layọ lati ri iwe pẹlẹbẹ naa Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! Ṣugbọn wọn ni iṣoro kan. Wọn kò mọ iwe kà. Ẹlẹ́rìí ti o bẹ̀ wọn wò yọnda lati ran wọn lọwọ ni lilo iwe mọọkọ-mọọka naa Learn to Read and Write. Laipẹ, awọn ọmọdebinrin naa ni a mu iwuri ba pe awọn lè kọ ki wọn si pe orukọ Jehofa lọna ti o tọna.

Bi wọn ti ń tẹsiwaju, haa ṣe wọn nipa ireti agbayanu ti a nawọ rẹ̀ jade sini ninu Bibeli. A ru imọlara wọn soke ni pataki nipa ileri naa pe gbogbo iran eniyan yoo gbadun ominira. “Igbesi-aye nihin in jẹ ti onibanujẹ fun awa ọdọlangba,” ni wọn ṣalaye. “A saba maa ń fi wa fọ́kọ nigba ti a ṣì kere gidi gan an, ifipabanilopọ sì jẹ ewu igba gbogbo.”

Ohun pataki julọ kan fun Iris ati Margarita ni wiwa ti wọn wa si apejọ ayika kan ni ilu Maracaibo. Oju wọn fi ayọ ti wọn ni lọkan wọn han, paapaa ni ìgbà ti a ba ń kọ awọn orin. Nigba gbogbo ni wọn maa ń fi ìháragàgà duro lẹnu ọna nigba ti Ẹlẹ́rìí naa bá wá fun ikẹkọọ Bibeli wọn, wọn kò si pa awọn asọye fun gbogbo eniyan ti a ń ṣe ni abule wọn jẹ rí. Awọn ọdọmọbinrin wọnyii ni imọlara pe igbesi-aye wọn ni a ti mu sunwọn sii nitootọ nipasẹ nini imọ Jehofa Ọlọrun ati ete rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́